|
Títí di ìgbà tí ó máa fi kó ẹrù rẹ̀ lọ pátápátá, kí oníkálùkù ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ohunkóhun tó bá rí jẹ. |
|
Ó mọ bí ó ṣe má a tọ́jú ara rẹ̀ àti Tinú. |
|
Kí Àlàmú kọ́ bí ó ṣe máa tọ́jú ara rẹ̀. |
|
Kí ìyá rẹ̀ má tún padà wá láti máa jágbe kí ó sì pòwe ìkà kankan. |
|
Báyìí, ó ti di kí olórí dorí ẹ̀ mú, kí oníkálùkù wà fún ra ara rẹ̀, Ọlọ́run wà fún gbogbo wa. |
|
Làbákẹ́ ń ṣe iṣẹ́ "òun ló mọ" ọkàn rẹ̀ déédé gbé sókè láti kọ orin rẹ̀ pẹ̀lú ohùn òkè, ohùn rẹ̀ dún bí i agogo. |
|
Ìrísí rẹ̀ fi inú dídùn rẹ̀ hàn. |
|
Ó sọ fún ara rẹ̀ pé òun kò ní ìṣòro kankan. |
|
Kò ní nǹkankan láti dààmú fún. |
|
Kò sí obìnrin náà lórí ilẹ̀ ní gbogbo ayé tí inú rẹ̀ dùn tó bí inú rẹ̀ ṣe dùn. |
|
Kí lo ṣe tí inú rẹ kò ní dùn? |
|
Ọjọ́ rẹ̀ ti níye nínú ilé Àlàmú. |
|
Ọjọ́ ìbànújẹ́ àti wàhálà rẹ̀ ti níye. |
|
Ẹjọ́ ìkọ̀sílẹ̀ ti wà lọ́nà, òun náà ti fẹ́rẹ̀ ẹ́ wọ́gilé àwọn nǹkan rẹ̀ tán. |
|
Tinú ò sì fún un ní wàhálà kankan, ọmọbìnrin kékeré náà kúnfún ìyè, ẹ̀mí àlàáfíà tó péye ni Ọlọ́run fi jíǹkí òun fún ara rẹ̀. |
|
Làákàyè ìnira tó wà nílẹ̀ ó sì rẹwà síbẹ̀, ìdúró rẹ̀ dùn síbẹ̀. |
|
Kò sí ẹni tó má rí tá sọ pé obìnrin tó ní ìṣòro ni. |
|
Pẹ̀lú ìrísí omidan tí ò ní lọ́wọ́ lọ́wọ́ yìí, o lè padà sí England kí o sì tún padà sí àyè oge ṣíṣe é. |
|
A kàn nílò láti tún ara rẹ̀ ṣe fún bí oṣù mẹ́ta sí mẹ́rin, a padà sípò. |
|
Fún ìdí èyí, kò sí àbámọ̀, ó rẹ́rìn-ín tariyá-tariyá, ó gbìmọ̀, ó jó. |
|
Ohùn òkè rẹ̀ dúdú, ó sì ń gbọ̀n rìrì, ó judi sí ìlù àti orin inú afẹ́fẹ́ tí ó ń rò lọ́kàn, ó ka ìwọ̀n ẹsẹ̀ díẹ̀ síwájú-sẹ́yìn ó ń fò sókè tìdùnnú-tìdùnnú, ó tún sọ fún ara rẹ̀ léraléra pé obìnrin tí ó láyọ̀ ni òun, ó láyọ̀... l-a-y-o! láyọ̀... láyọ̀ gidi gan. |
|
Làbákẹ́ na ẹ̀yìn, ó sì ti àyà sí iwájú, ó júpá láìsíìwọ, ó ń gbé ẹsẹ̀ sọ́tùn-ún, sọ́tùn-ún sósì, ó ń làágùn! |
|
Ṣùgbọ́n dúró ná o... kí gan-an ló ń ṣẹlẹ̀? |
|
Làbákẹ́ dúró díẹ̀ láti bi ara rẹ̀ ní èyí. |
|
Ó ṣe èémí fún ìṣẹ́jú kan, ó ń wòye. |
|
Kíni ìdí fún gbogbo àfihàn ìdùnnú àti ìyìn yìí? |
|
Ṣé òun ti ń ya wèrè? Ṣé òun náà ti ń ya wèrè ni? |
|
"Rárá, Rárá o", ó dá ara rẹ̀ lóhùn... Rárá. |
|
Àlàmú ló ń ṣìnwín, kódà, Àlàmú ló ti ya wèrè. |
|
Kì í ṣe òun...kì í ṣe òun! |
|
Níwájú Ọlọ́run àti ènìyàn! |
|
Làbákẹ́ na ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì síwájú, ó sì jó pẹ̀lú ìtara sí ìlú àrólé orin náà. |
|
Kò sí ìṣòro fún un mọ́. |
|
Inú rẹ̀ dùn, ó dùn dáadáa. Ó bẹ́ wo inú yàrá ìgbafẹ́ pẹ̀lú ìgbésẹ̀ ìjọ rẹ̀ tó lọ́pọ̀, ìṣọwọ́jùdi rẹ̀ ṣàjèjì, ó ń rìn súnmọ́ gíláàsì adádúró díẹ̀díẹ̀ níbi tí inú rẹ̀ ti tún bọ́ dùn sí i. |
|
Ó ju ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sínú afẹ́fẹ́ ó sì yípoyípo láìmọye ìgbà títí tí òyì fi kọ́ ọ. |
|
Ó sì ṣubú sínú àga tí ó wà nítòsí, ó ń mì lókèlókè. |
|
Lẹ́yìn èyí ni gbogbo ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò àjọ pàtàkì sínú òfúrufú pẹ̀lú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àdáwàkọ̀ òfúrufú... |
|
Kíni ìdí? Kíni ìdífún gbogbo èyí? Ó tún ara rẹ̀ bí. Kí ló ń ṣẹlẹ̀? Ṣé orí tìrẹ náà ò ti máa yí báyìí? |
|
Sènábù mí kanlẹ̀ láti ẹ̀yìn ìlẹ̀kùn ilé ìkóúnjẹpamọ́ sí níbi tí ó ti ń dúró wòran màdáámú rẹ̀. |
|
Ó ti gbọ́ àwọn orin àjèjì màdáámú, ó sì tún ti rí ijó abàmì rẹ̀ tí ó balù mu. |
|
Bí ó ṣe wá ń gbìyànjú àti padà sínú ilé oúnjẹ láti má jẹ́ kí wọ́n rí i, ó sérí mọ́ ògiri, ó sì ṣiṣẹ́ sórí àwọn abo tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kó wọ ilé oúnjẹ náà. |
|
Nǹkankan máa ń wà nípa màdáámú báyìí tí ó ń lé Sènábù lára rẹ̀ ní gbogbo ìgbà. |
|
Nígbàkúgbà tí ó bá rí i, nǹkankan máa ń sọ fún un pé kí ó sá lọ, tàbí kí ó sá pamọ́. |
|
Mádáámú ti ń kanra ganan lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí. |
|
Kò fẹ́ jọ pé ó fẹ́ràn rẹ mọ́ ìṣòwò wọ̀ ọ́ àti bí o ṣe ń bá sọ̀rọ̀. |
|
Nígbàkúgbà tí Madáámú bá farahàn ní yàrá ìgbafẹ́, kíá ni Sènábù máa ń wábi gbà wọ ilé ìgbọ̀nsẹ̀ láti lọ ṣẹ́yọ! |
|
Ṣùgbọ́n kò fẹ́ jọ pé ọgbọ́n yẹn máa ṣiṣẹ́ mọ́. |
|
Nítorí àna àdáyé ni màdáámú sì kígbe pé: Sènábù! Sènábù! Ibo ni èké kékeré yí wà? |
|
Níbi Màdáámú! Níbi Màdáámú! Sènábù dáhùn. |
|
Nílé ìgbọ̀nsẹ̀, bí o ṣe ń ṣe? Kí ni ò ń bá ọlọ́ṣì kékeré yìí jà ná? |
|
Gbogbo ìgbà ni ilé ìgbọ̀nsẹ̀ “kò sí nǹkankan Madáámú, ẹ̀mí rẹ̀ ẹ́ màdáámú” Sènábù dúró níwájú rẹ̀, ó ń wò pẹ̀lú ojú ẹ̀bẹ̀. |
|
Ọwọ́ màdáámú ti yára gbá etí Sènábù kékeré mú ó sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìríra sí i, ó gbọ́ ọ jìgìjìgì síbí sọ́hùn-ún. |
|
Ó pariwo, “Wá á tó lọ, iṣẹ́ ẹ ti fẹ́rẹ̀ ẹ́ tán, ó dàbí i pé o ò mọ̀. |
|
Láìpẹ́, wọ́n á dá ẹ padà fún àwọn ènìyàn rẹ. |
|
Fúnmi lọ́jọ́ méjì sí mẹ́ta. |
|
Làbákẹ́ tú ọwọ́ rẹ̀, Sènábù sì ṣubú, gbà!. |
|
Kò sẹ́nikẹ́ni nítòsí láti sọ gbogbo èyí fún. |
|
Ó wu Sènábù púpọ̀ láti rẹ́ni sọ ìrírí rẹ̀ fún - ẹni tó ṣe é fọkàn tán, ẹni tí yóò yè, tí yóò sì káàánú ẹ̀. |
|
Ẹ wòye bí ayọ̀ rẹ̀ ṣe kún tó nígbẹ̀yìn gbẹ́yín tí màmá àgbà tún kan ilẹ̀kùn ilé yẹn. |
|
Tí ó tún bá òun nìkan nílé! |
|
Màmá ò tíì jòókò tàìjókòó tí ahọ́n Sènábù bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀n bí i ti irú ajá tí ó ń mí tí ó bá rí olówó rẹ̀. |
|
Mádáámú ti ya wèrè! Sènábù kéde fún màmá àgbà. |
|
Wọ́n ti ya wèrè gan-an! Ó ti jó ẹhànnà, bí ológbò-ìgbọ́. |
|
Irun rẹ̀ tí ó kì bí i igbó yẹn ti dá wálẹ̀ sí èjìká rẹ̀, èyí sì ń jẹ́ kí jó eṣú. |
|
Ẹ̀ẹ̀kanná rẹ̀ ti wá gùn gan-an ó sì mú, a fi bí ti ẹnu ẹyẹ. |
|
Ọjọ́ kan ò lè kọjá kí màdáámú má ti èékánná yẹn bò ó lẹ́ẹ̀kẹ́ kí ó sì fà á létí. |
|
Ó fi etí àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ wíwú han màmá. |
|
Mádáádáá a sì yà á sí wẹ́wẹ́ níjọ́ kan pẹ̀lú bí ó ṣe ń lọ yìí, pẹ̀lú èékánná gígùn rẹ̀ tí ó mú yẹn tàbí ẹ̀yìn irin rẹ̀ yẹn nítorí ó ti ya wèrè. |
|
Wèrè gidi, Sènábù jẹ́wọ́ pé ó ti sú òun, á sì wu òun láti padà sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ nílé. |
|
Màmá láyọ̀ ńlá bí ó ṣe ń tẹ́tí sí bí Sènábù ṣe ń sọ ìtàn rẹ̀. |
|
Ó fi ọwọ́ lu ọmọ náà jẹ́jẹ́ lẹ́yìn, ó sì sọ fún un pé kí ó má ṣe dààmú. |
|
Ohun gbogbo á dára níkẹyìn... |
|
Ó dára bí Làbákẹ́ ṣe ń yí lórí. |
|
Ohun tí wọ́n ń retí ni. |
|
Èyí kò sì jẹ́ ìyàlẹ́nu fún màmá. |
|
Èṣùníyì ti sọ fún un pé Làbákẹ́ á jẹ nínú ẹ̀fọ́ ìka tí ó ti rọ kí ó tó pẹ́. |
|
Ní báyìí, ó ti wá ń ṣẹlẹ̀, nǹkan tí ó ju èyí á tó máa ṣẹlẹ̀. |
|
Irun-orí àti èékánná Làbákẹ́ ni màmá wa gbà ní ìgboro. |
|
Èṣùníyì fẹ́ lò ó láti fi túnbọ̀ ba ti Làbákẹ́ jẹ́. |
|
Kò ní láti ya ẹnikẹ́ni lẹ́nu lẹ́yìn èyí láti rí Làbákẹ́ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan tàbí méjì ní àwọn òpópónà kí ó sì dúró sí gbàgede ọjà níbi tí àwọn ènìyàn tí wọ́n wá ṣe kárà-kátà á ti rí ìran pípẹ́ wò. |
|
Èṣùníyì ti sọ ọ́, màmá sì mọ̀ pé bí ó ṣe máa ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. |
|
Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, Làbákẹ́ á fi orúnkún rẹ̀ ráwọ́ ọgbà Èṣùníyì pẹ̀lú ìrònúpìwàdà. |
|
Ní ti Àlàmú, Èṣùníyì ti sọ fún màmá pé kò séwu lóko mọ́. |
|
Ipò tí Àlàmú wà á máa yàtọ̀ sí dáadáa láti ìsìnyí lọ. |
|
Inú màmá dùn, gbogbo nǹkan tí Èṣùníyì sọ fún ló ti ń wá sí i músẹ́. |
|
Àlàmú padà délé, ó sì bá ìyá rẹ̀ pẹ̀lú ìrísí tó fi inú dídùn hàn. |
|
Ó kí ìyá náà pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ lẹ́nu ní ìdọ̀bálẹ̀. |
|
Ó ń ti ibi iṣẹ́ kan pàtàkì nígboro bọ̀, èyí tí àyọríṣí rẹ̀ mú un daraya. |
|
Fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú oṣù mẹ́sàn-án, Àlàmú mí ìmí ìtura. |
|
Fún odidi oṣù mẹ́sàn-án gbáko ni ó ti yí ara rẹ̀ ká pẹ̀lú àdììtú kan tí ó ru gbogbo ènìyàn lójú; àṣírí kan tí kò ṣe é ṣe fún ẹnikẹ́ni láti tú – yàtọ̀ sí ọkùnrin kan tí ó súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí - Àdìó ọ̀rẹ́ rẹ̀ kanṣoṣo. |
|
Níbo, òpin àdììtú yẹn ti wà nítòsí. |
|
Òpin sì dàrúdàpọ̀ ọpọlọ àti ìrora rẹ̀ ti súnmọ́ itòsí. |
|
Wọ́n ti sọ fún un pé kí ó dúró fún ọ̀sẹ̀ méjì sí i tí gbogbo ìṣororẹ̀ á fi yanjú pátápátá. |
|
Àlàmú kò gba etí rẹ̀ gbọ́. |
|
Pẹ̀lú ìwàǹwára ni ó fi ń ka àwọn ọjọ́, ẹni, èjì, ẹ̀tà, erin, àrùn, ẹwà, mẹ́rìndínlógún... |
|
Ọjọ́ mẹ́rìnlá sí i! Ó ń ka wákàtí! ìṣẹ́jú! |
|
Ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún Àdìó bí Àlàmú ṣe ń ṣe àfihàn ìrúsókè ìdùnnú rẹ̀. |
|
Bẹ́ẹ̀, ọ̀sẹ̀ méjì sì ni wọ́n sọ, ìdájọ́ á sì wáyé? |
|
Ìyẹn kéré púpọ̀ níye sí oṣù mẹ́sàn-án tí ó ti fi ń dúró. |
|
Ṣé yóò sunkún ni, tàbí yóò rẹ́rìn-ín músẹ́ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì? |
|
Wọ́n tisọ fún un pé a rẹ́rìn-ín músẹ́. |
|
Gbogbo nǹkan ló sì tọ́ka sí i dájúdájú pé yóò rẹ́rìn –ín músẹ́. |
|
Fún ìdí èyí, ó tọ́ kí ó kúkú bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ́rìn- ín músẹ́ láti ìsinyìí nínú ìrètí àti ìgbàgbọ́ pé gbogbo nǹkan á ṣiṣẹ́ fún rere. |
|
Ìdí nìyí tí ó fi fi ẹ̀rín músẹ́ tó rí yán-ràn yán-ràn kò mọ̀nà pàdé ìyá rẹ̀... |
|
Màmá ń wo ọmọ rẹ̀, ọkàn rẹ̀ sì kọrin fayọ̀. |
|
Ọmọ rẹ̀ wá rẹ̀ ẹ́ tó ń rẹ́rìn-ín músẹ́ sí i tí ó sì ń fèsì bí ó ṣètò sí ìbéèrè àti àsọgbà ọ̀rọ̀ wọn. |
|
Kílótun kú, Àlàmú fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ tọrọ ìyọ̀ǹda lọ́wọ́ ìyá rẹ̀ pé òun sì tún ní àwọn nǹkan mìíràn láti ṣe ní ìgboro. Fún ìdí èyí ó fẹ́ padà jáde ṣùgbọ́n kò níí pẹ́. |
|
Ọmọ rẹ̀ ti wà ní ìbúyí fún un, láti gba ààyè! Apá kìíní iṣẹ́ náà ti parí! A dáa fún Èṣùníyì. |
|
Màmá dúró pẹ̀lú sùúrù pé kí Làbákẹ́ dé. |
|
Nígbà tí ó sì rí i tí ó ń bọ̀ lọ́ọ̀ọ́kán, ó tètè tú apẹ̀rẹ̀ tí ó gbé wá láti ìgbèríko, ó sì mú ìgò kékeré tí ó tọ́jú oògùn babalawo rẹ̀ sí. |
|
Èṣùníyì ti sọ bí ó ṣe máa lò ó fún un. |
|
Nísinsìnyí, ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n sẹ́nu ọ̀nà yàrá Làbákẹ́, ó sì wọn oògùn náà sílẹ̀ sórí ìlà tẹ́ẹ́rẹ́ kan. |
|
Ó ṣe pàtàkì kí Làbákẹ́ dá a kọjá bí ó bá ti ń wọ yàrá rẹ̀ kí tiẹ̀ lè túbọ̀ bá a ní tọkàn-tara. |
|
Lẹ́yìn tí ó bá ti wọn oògùn náà tán, Màmá yípo yípo lẹ́ẹ̀márùn-ún gẹ́gẹ́bí babaláwo rẹ̀ ṣe là kalẹ̀. |
|
Bí ó ṣe wà lórí ẹ̀ẹ̀kẹ́rin, Làbákẹ́ wọlé, ó ń wo ìyá àgbà náà, pẹ̀lú ẹnu rẹ̀ ní lílà sílẹ̀. |
|
Màmá dúró fún ìgbà díẹ̀, kanrí mọ́lẹ̀ ní èsì kíkí Làbákẹ́ ó sì fẹ̀yìntì ògiri tí ó kọjú sí ògiri yàrá Làbákẹ́, ó ń sọ àwọn ìpèdè tí wọ́n ní kò pẹ́ tí ó bá ti fojú gan-an-ní Làbákẹ́ sí ara rẹ̀ láìmọye ìgbà. |
|
Ní òpin gbogbo rẹ̀, màmá bú sẹ́rìn-ín. |
|
Ìrísí Làbákẹ́ jọ ti ẹhànnà gidi, ó tiẹ̀ tún banileru ju bí Sènábù ti ṣàpèjúwe rẹ̀. |
|
Làbákẹ́ ti wá ya wèrè gidi báyìí – bí ó ṣe rí, ó dàbí i ewèlè tí ó wá láti inú ihò àpáta tí ó ti ṣetán ìjà! |
|
Irun rẹ̀ tí ó dàbí i igbó dá wálẹ̀ sọ́rùn àti èjìká rẹ̀, ó sì bo apá ibìkan lójú rẹ̀. |
|
Irun yẹn... bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀kan lára àwọn nǹkan tí ìyá wa wá rè é. |
|
Kí o tó máa lọ sí ìgbèríko ní ìrọ̀lẹ́, o gbọdọ̀ rí i pé o rí èyí tó tó wọn nínú irun náà gé kí o sì tọ́jú rẹ̀ sínú apẹ̀rẹ̀ rẹ̀. |
|
Lẹ́yìn náà ni ẹ̀ẹ̀kaná gígùn ọwọ́ Làbákẹ́, ẹ̀ẹ̀kan gígùn pupa rẹ̀. |
|
Ìyẹn tún ni nǹkan tí ó wá mú. |
|
Ojú màmá ń wò láti irun orí Làbákẹ́ dúdú dé ẹ̀ẹ̀kaná pupa rẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. |
|
Nígbẹ̀yìn, ó wo Làbákẹ́ tààrà ó sì ní; |
|
"Em Em Em!", ó kọ́kọ́ tún ọ̀nà ọ̀fun rẹ̀ ṣe. "Em....Ìwọ. Ìwọ sì wà níbí?" |
|
Làbákẹ́ fi ojú pààrẹ́ ó sì rìn lọ sí ọ̀nà yàrá rẹ̀. “Kí ló tún ń dúró ńbí fún?” |
|
"Ṣé èmi?", Làbákẹ́ béèrè. |
|
Ó wọ yàrá rẹ̀ lọ ní dída ibodè màmá kọjá! Ó kó sínú pańpẹ́ màmá! Panpẹ babalawo! |
|
Ní ìṣẹ́jú kan, ó kù gìrì jáde láti inú yàrá rẹ̀, ó dojúkọ màmá pẹ̀lú ìwọ tí ó lè pànìyàn lójú rẹ̀. "Mo ti ń gbọ́ báyìí!" |
|
Ó wò ó. "Kí ni ó ń sọ, ìyá àgbà?" |
|
"Mo ń bi ẹ́..." |
|
"Bí mi ni kí ni, ìyá àgbà?" |
|
"Bóyá o ò..." |
|
"Bóyá o ò ṣe kí ni, ìyá àgbà!" |
|
"Tí ì lọ..." |
|
"Lọ ìbò, ìyá àgbà!", Làbákẹ́ ti súnmọ́ màmá báyìí, tí ó sì ń ná ẹ̀ẹ̀kaná pupa gígùn rẹ̀ tìhò-tìhò. |
|
"Ṣé o fẹ́ nà mí ni?" |
|
Wò ó ìyá! Àtẹ̀lẹwọ́ ń yún mi, ó ń ṣe mí bí kí n gba ojú àjẹ́ àgbà kan! |
|
Ṣé o rí bí ìka ọwọ́ mi ṣe ń sùn yìí, ó ń ṣe wọ́n bí i kí wọ́n fa ẹyin ojú àjẹ́ méjèèjì yọ láti inú akọ. |
|
"Èmi! Èmi, Làbákẹ́?" |
|
"Mo ń ní àìbalẹ̀ nínú ẹnu mi! Mo fẹ́ dánbí ẹ̀yìn ẹnu mi ṣe mú tó wò! |
|
Nípa rírí wọn bọ inú àwo híhunjọ àgbàdo kan" |
|
"Tani? Ìwọ àgbàlà yìí ni! Ìwọ ló ya wèrè!" |
|
"Èmi? wèrè?" |
|
Bẹ́ẹ̀ni, wèrè! Ó wò yípo yípo bí i ẹni tí gìrì wàràpa gbé. |
|
O lè mọ ògiri bí ajá gbígbọ́ tó rẹ̀. |
|
Ó ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́ kẹ̀lẹ́ bí ewúrẹ́ alágbàtọ́ tí ó ń jẹ àpọ̀jẹ lẹ́nu! Wẹ́rẹ! Wẹ́rẹ ni mo sọ! Kí tún ni ẹ́ bí kò ṣe wẹ́rẹ́ lobìnrin! |
|
Làbákẹ́ dúró, ó ń mí lókèlókè lé màmá. |
|
Bí màmá bá sọ gbólóhùn kan sí i, bó bá sọ ẹyọ ọ̀rọ̀ kan, Làbákẹ́ ò bá ti bo ìyá àgbà náà, á sì rán an lọ sí sàréè láìtó ọjọ́. |
|
Màmá rẹ́rìn-ín músẹ́, ó sì fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ jáwọ́. |
|
Kò bínú, kò bínú rárá. |
|
Oògùn ló ń ṣiṣẹ́ lára Làbákẹ́. |
|
Làbákẹ́ ti gbẹ́ kòtò ara rẹ̀ nísìnyí tí ó ti dá ilà oògùn kọjá lẹ́nu ọ̀nà yàrá rẹ̀. |
|
Ohun tí ó kàn kù fún un ni kí ó gbé Làbákẹ́ sínú pósí, kí ó kàn án pa, kí ó sì sin-ín sínú ilé tí ó gbé. |
|
Màmá yọwọ́, ó sì gba Làbákẹ́ láàyè láti tẹ̀síwájú láti máa sọ̀rọ̀ fitafita pẹ̀lú ìrunú. |
|
Láti ìsinyí lọ, sọgbà ẹ agbaya! Yé ẹ na imú híhúnjọ́ rẹ yẹn! Ó ti gbélé ayé kọjá ìwúlò rẹ. |
|
Fi mí sílẹ̀ àjẹ́ àgbàyà! Fi mí lọ́rùn sílẹ̀! Padà lọ sí ìgbèríko láti lọ ṣe àdúrà ìkẹyìn rẹ̀ lórí ilẹ̀ eèpẹ̀. |
|
Àsìkò rẹ̀ tiẹ̀ títọ́, sáré rẹ̀ sì ti wà nílẹ̀. |
|
Má wá sí ìgboro mọ́ láé. |
|
Ṣóògbó bẹ́ yẹn àjẹ́! |
|
Màmá ò fèsì ọ̀rọ̀ kan, kàkà bẹ́ẹ̀ ń ṣe ló ń rẹ́rìn-ín músẹ́, ó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀. |
|
Làbákẹ́ ti ya wèrè báyìí. |
|
Wẹ́rẹ sán-ún sán-ún. Gẹ́gẹ́ bí Èṣùníyì ṣe sọ fún, ìdí èyí kò ní èsì kankan, láìpẹ́, Làbákẹ́ á kẹ́rù lọ sí ilé rẹ̀ tuntun ní gbàgede ọjà. Fún ìdí èyí, kí idán ìbínú sọ̀rọ̀ náà tẹ̀síwájú: Tẹ̀síwájú! |
|
Bẹ́ẹ̀ ni, kò tẹ̀síwájú! Ṣé ó ti rẹ̀ ẹ́ ni? |
|
Kò tí ì yẹ kí ó rẹ̀ ẹ́! Ó gbọdọ̀ jẹ́ kí ó tẹ̀síwájú lọ́nàkọnà! |
|
Ìdákẹ́rọ́rọ́ wà lẹ́yìn ìṣẹ́jú márùn-ún, màmá ṣẹ́jú sí Sènábù; kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ náà ni ọmọbìnrin kékeré náà kanrí mọ́lẹ̀ padà. |
|
Ó ti mọwọ́ màmá tó bẹ́ẹ̀ tí ìbánisọ̀rọ̀ ti wá rọrùn láàrín wọn. |
|
Lẹ́yìn tí ó ti da ara rẹ̀ láàmú, tí ó ti gbé ẹ̀mí ara rẹ̀ gbóná Làbákẹ́ gbọ̀nà yàrá lọ láti sanra pẹ̀lú omi tútù, ní kíá sì ni Sènábù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ |
|
Kì í ṣe àjèjì sí yàrá màdáámú, gbogbo ibi kọ́lọ́fín àti ìrúkèrúdò yàrá náà ni ó mọ́. |
|
Ó mọ gbogbo ibi tí màdáámú ń tọ́jú àwọn nǹkan ẹ̀ sí títí mọ́ àwọn nǹkan àṣírí rẹ̀. |
|
Nísinsìnyí tí màdáámú ti fẹ́rẹ̀ ẹ́ kó ẹrù rẹ̀ tán, ó rọrùn fún un láti rí àwọn nǹkan méjì tí ó wà. Láàárín ìṣẹ́jú mẹ́ta, ó ti parí iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún un ó sì jáde láti inú yàrá màdáámú, tí ó sì di nǹkan méjèèjì mowó, ó fi bébà àtijọ́ kan wé e, tí ó sì rí tónítóní, ó sì ń rẹ́rìn-ín músẹ́ sí màmá. |
|
Màmá gbà á ó sì tètè fi sínú apẹ̀rẹ̀ rẹ̀. |
|
Nígbà tí màdáámú jáde láti inú balùwẹ̀, ohun tí ó rí nipé Sènábù kékeré ń bá Tinú ṣeré lẹ́nu ọ̀nà, màmá sì ń dágbére fún Àlàmú tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wọlé dé, tí wọ́n sì ń ṣe ìlérí láti wá wò ó kí ó tó di òpin ọ̀sẹ̀ náà. |
|
Àwọn nǹkan méjì náà wà ní ìpamọ́ nínú apẹ̀rẹ̀ rẹ̀. |
|
Màmá ti jí àwọn nǹkan náà wò nínú apẹ̀rẹ̀ rẹ̀, ó sì tẹ́ ẹ lọ́rùn; mẹ́rin nínú èékánná pupa ọwọ́ Làbákẹ́ tí ó fi nawọ́ sí i láìpẹ́ yìí, tí ó yọ nígbà tí ó wọ yàrá. |
|
Ẹ̀ẹ̀kan-nà ayédèrú! Àti díẹ̀ nínú irun Làbákẹ́ tí ó dá wálẹ̀ sára rẹ̀ láìpẹ́ yìí tí ó yọ nígbà tí ó fẹ́ wọ balùwẹ̀, ayédèrú irun rẹ̀! |
|
Àwọn nǹkan méjì yìí ti wà nílẹ̀ fún Èṣùníyì. |
|
Àsìkò náà ti súnmọ́, tí Làbákẹ́ á sáré jáde nínú ilé níhòòhò wo òpópónà: ìgbà tí ó máa sọ gbàgede ọjà di ilé, ìgbàtí a rákò lórí orúnkún rẹ̀ wọ ọgbà Èṣùníyì tí ó wà ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìyàsọ́tọ̀ nínú igbó ìgbèríko. |
|
Gbogbo ìyẹn ló dojúkọ ìdánmọ̀ràntó hàn lójú màmá bí ó ṣe ń ròyìn ìtàn àṣeyọrí ìrìnàjò rẹ̀ sí ìgboro fún Èṣùníyì. |
|
Ipò Àlàmú ti yàtọ̀, kò ní í kan àbùkù orí fífọ́ mọ́. Kò ní jìyà ìrenisílẹ̀ tí wọ́n á ti jù ú sí yàráfunfun ilé wẹ́rẹ́ pẹ̀lú àwọn ògidì asínwín tí wọ́n máa ń hàn tí wọ́n tún ń pariwo gẹ́gẹ́ bí alagbaagbe. |
|
"Wáhálà ni mo ṣì í ń rí yìí", màmá gbọ́ tí Èṣùníyì sọ èyí “Ìjọ̀ngbọ̀n ò tí ì parí pátápátá. |
|
Ní wọ́n ìgbà tí aṣojú àwọn ọ̀tá bá sì wà nínú ilé pẹ̀lú ọmọ rẹ̀, ohunkóhun ló sì lè ṣẹlẹ̀. |
|
Màmá wo Èṣùníyì, "Kí la wá fẹ́ ṣe pẹ̀lú Làbákẹ́ báyìí?". |
|
Làbákẹ́ ẹni ègún. |
|
Aṣojú àwọn ọ̀tá. |
|
Ó ń ṣe màmá bí ìgbà tí abẹ́rẹ́ tó mú gùn-ún lọ́kàn Làbákẹ́ sì ni abẹ́rẹ́ náà. |
|
"A ní láti tì í jáde", Èṣùníyì tẹ̀síwájú, "kíákíá sì ni pẹ̀lú." |
|
Lẹ́yìn náà ni a tó lè rímú mí. |
|
Ṣùgbọ́n pẹ̀lú nǹkan méjì tí ẹ ti mú wàyí... |
|
Èṣùníyì yọ bébà tí wọ́n di irun àti èèkàná Làbákẹ́ sí yìí jáde... "Kò sí wàhálà, Màmá". |
|
Màmá tún ọ̀nà ọ̀fun rẹ̀ ṣe. |
|
Bẹ́ẹ̀, ẹ ṣeun. Ohun tí mo fẹ́ kí ẹ ṣe nísìnyí ni pé kí..kí... kí... |
|
Ohùn ẹjọ́ wuuru kìkì kan láti ọ̀kan nínú àwọn yàrá ilé wèrè náà ni ó dá ọ̀rọ̀ mọ́ wọn lẹ́nu |
|
"Ohun tí màá fẹ́ kí ẹ...ẹ...ẹ..." |
|
Ohùn wuuru tí ó wá láti inú ilé wẹ́rẹ́ náà ti wá di ariwo ńlá, tí ó fẹ́rẹ̀ di ènìyàn létí. |
|
Èyí ni àbùdá àhámọ́ Èṣùníyì kan. |
|
Láìsí àní-àní, àwọn èèyàn rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ eré ìje wọn bí wọ́n ṣe máa ń ṣe. |
|
Ìjà tí wọ́n máa ń jà fún ti bẹ̀rẹ̀ nìyẹn. |
|
Nígbàkúgbà tí wọ́n bá sì bẹ̀rẹ̀, gbẹgẹdẹ máa ń gbiná. |
|
Wọ́n á bo ara wọn bí i ajá olókùnrùn, wọ́n á lu ara wọn, wọ́n á tún ya ara wọn jẹ. |
|
Ariwo àwọn wèrè náà mú ohùn màmá wálẹ̀. |
|
Màmá ti bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Bàbá olóògùn pẹ̀lú ìtara, pé kí ó lo gbogbo agbára rẹ̀ láti yanjú Làbákẹ́ ní kíákíá – lónìí sẹ́yìn. |
|
Kí ó mú un wálẹ̀ lórí orúnkún rẹ̀. |
|
Kí ó jẹ́ kí àwọn ọ̀tá ọmọ rẹ̀ yòókù tí ò ṣe é fojú rí rìn lọ níhòòhò sínú igbó kìjikìji tí ìkòkò àti àmọ̀tẹ́kùn á ti máa dúró láti dojú kọ wọ́n, ohun tí Màmá fẹ́ nìyẹn. |
|
Nǹkan tí ó ń sọ fún Èṣùníyì pé kí ó ṣe nìyẹn tí ariwo àwọn wèrè yẹn fi tún pọ̀ sí i. |
|
Èṣùníyì dìde gìrì, ó sáré ṣọ́nà ibi tí ariwo náà ti ń wá. |
|
Láàárín ìṣẹ́jú kan, ó ti sáré padà. |
|
Ó sáré wọ yàrá kan nínú ìyẹ̀wù tirẹ̀. |
|
Ó jáde pẹ̀lú àtarí kan tí ó kà yí orí rẹ̀. |
|
Ojú rẹ̀ ràn. Ìmọ́lẹ̀ dá dúró lọ́tọ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ líle, ètè rẹ̀ ń gbọ̀n, ara rẹ̀ ń gbọ̀n pẹ̀lú ìbínú àti ìmí-ẹ̀dùn. |
|
Ní àwọn ìgbà tó ṣe gẹ́gẹ́, Èṣùníyì máa ń tutù, a jọ aláìṣẹ̀, ara rẹ̀ balẹ̀, a máa sọ̀rọ̀ díẹ̀díẹ̀, láìṣirò. |
|
A rẹ́rìn-ín músẹ́ jẹ́jẹ́, a máa wojú yín bí ó ṣe ń sọ̀rọ̀. |
|
Nígbà yẹn ó dàbí i gbogbo ọkùnrin, bí ọkùnrin gidi bí ìwọ àti èmi. |
|
Ṣùgbọ́n lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan báyìí, tí yán-pọ́n-yán-rin bá wà nínú àgọ́ yí, Èṣùníyì máa ń di ọkùnrin àrà ọ̀tọ̀. |
|
A pariwo àṣẹ rẹ̀, pẹ̀lú ohùn rẹ̀ tí ó ń búramú-ramu bí àtẹ́wọ ààrá. Ó jẹ́ ọkùnrin tí ó kúnfún okùn ńlá àti ìrísí. |
|
A gbá ẹni tí ó ṣẹ́ mú pẹ̀lú ìwà èérí àti ìrọ̀rùn ẹkún. |
|
Ìṣàn apá rẹ̀ á yí, á wá le koko. |
|
Egungun rẹ̀ á nà, á fẹ́rẹ̀ ẹ́ lè kan. |
|
Ẹni tí ó gbá mú náà á pariwo ìbẹ̀rù, á sì padà sẹ́yìn pẹ̀lú ìjówó pátápátá bí i ti òòkùn tí àti rà mọ́lẹ̀. |
|
Yàtọ̀ sí ti ipa ojú kò-ojú, Èṣùníyì ní àwọn ìlànà mìíràn. |
|
Wà á rí i tí ó di ìwo ẹtu rẹ̀ tí ẹ̀jẹ̀ ti yí mú sókè nínú afẹ́fẹ́, a máa bá àwọn àwòmọ́ mẹ́rin ayé sọ̀rọ̀, àwọn adarí kádàrá ẹ̀dá – ó ń perí àwọn ẹ̀mí inú afẹ́fẹ́ láti ṣiṣẹ́ nínú iṣan gbígbóná àwọn wèrè náà kí ara wọn lè wálẹ̀. |
|
Ó sì máa rí bẹ́ẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀. |
|
Ṣùgbọ́n nísìnyí, ìlànà wámú-wámú-wámú ni ó fẹ́ lò. |
|
Fúnbí i ìṣẹ́jú márùn-ún, Màmá ń gbọ́ ohùn àtòkè lára àwọn ènìyàn ara rẹ̀ sì sùnkí. |
|
Ibí yìí kì í ṣe ibi lásán rárá. |
|
Ní òpin ìgbésẹ̀ ìfìyà-jènìyàn rẹ̀, Èṣùníyì padà lọ bá màmá pẹ̀lú ìkórajọ ènìyàn tí ó pé, pẹ̀lú ojú ọmọlúàbí lẹ́ẹ̀kan sí i. |
|
"Ó ní láti rí báyẹn", ó sọ fún màmá, "Bí ó ṣe yẹ kí ó rí ni yẹn màmá...bí bẹ́ẹ̀kọ́...bí bẹ́ẹ̀kọ́..." Màmá kanrí mọ́lẹ̀ ní ìdáhùn. |
|
Ó mọ ohun tí ìtumọ̀ "bí bẹ́ẹ̀kọ́" Èṣùníyì jẹ́... |
|
Bí bẹ́ẹ̀kọ́, àwọn wèrè fúnrawọn náà àgbàjọba ilẹ̀ náà. |
|
Bí bẹ́ẹ̀kọ́, wọ́n á sọ ibẹ̀ di pápá ogun. |
|
Bí bẹ́ẹ̀kọ́ wọ́n á dojúkọ Èṣùníyì lọ́jọ́ kan, wọ́n á sì lé e jáde kúrò nínú ọgbà rẹ̀. Wọ́n tún lè pa á |
|
Bí bẹ́ẹ̀kọ́, wọ́n á dáná sun gbogbo ilé inú àgọ́ náà, wọ́n á sì na pápá bora. |
|
Kò sí nǹkan tí wọn ò lè ṣe tí òfin àti àṣẹ bá dàrú. |
|
Màmá mi ìmí ìtura. |
|
Ó ní ìdí láti máa fọpẹ́ fún Olódùmarè. |
|
Kí ni ìbá ṣe kani pé Àlàmú wà láàrín àwọn ènìyàn yìí, tí yóò sì gba ìhùwàsí ìrọ̀rùn burúkú yìí? |
|
Kí ni ìbá ṣe kani ọmọ rẹ̀ ni ó dúró lábẹ́ igi ọ̀kánkán yẹn, tí ó ti fẹ́rẹ̀ ẹ́ já sí ìhòhò tán, tí ó ń nawọ́ sí nǹkan tí ó ṣí, tí ó sì ń bá afẹ́fẹ́ òfìfo sọ̀rọ̀? |
|
Bí ó bá jẹ́ Àlàmú ni ó ń rìn yíká ilé kékeré yẹn láìnídìí nínú irú ìrìn láyípo yìí? Kí ni ìbá ṣe? Kò sí. |
|
Bí ó bá jẹ́ Àlàmú ni ó wo àkísà tí ó tún ń tọ̀ sí àtẹ́lẹwọ́ ọwọ́-ọṣì rẹ̀ tí ó nà síwájú tí ó tún ń rẹ́rìn-ín? |
|
Èṣùníyì wo màmá, ó sì ṣàkíyèsí ìkorò tó wà lójú rẹ̀. |
|
Màmá, kò sí ìdí fún ìbẹ̀rù. |
|
Ohun gbogbo á dára níkẹyìn. |
|
Gbogbo iṣẹ́ náà ti fẹ́rẹ̀ ẹ́ parí. |
|
Ṣùgbọ́n ẹ ṣì ní láti mú u wá síbí |
|
"Mú tani wá?" Màmá béèrè |
|
"Ẹ mú ọmọ yín wá màmá. Ọmọkùnrin ti yín?" |
|
"Èyí túmọ̀ sí pé... pé... Àlàmú tún ní láti... láti... wá" |
|
Bẹ́ẹ̀ ni, ó ní láti wà níbí, fúnrarẹ̀. |
|
A mú láti inú ìkòkò àgbò, a wẹ̀ nínú odò àgbò ní gbangba, a a sì sin gbére sí i lẹ́ẹ̀kẹ́, ní ìgbà àyà àti abìyà rẹ̀. |
|
Ọmọ yín ní láti ní ìdáàbòbò tó péye. |
|
Nǹkankan ò gbọdọ̀ yọ ọ́ lé. |
|
Ìwọ ìdààmú wà lójú màmá. |
|
Báwo ni yóò ṣe rọrùn fún un láti mú Àlàmú wá sí ìgbèríko, pàápàá jùlọ, sí ọgbà Èṣùníyì? Apá ọ̀rọ̀ yìí ṣẹ̀ṣẹ̀ hàn dé sí ni. Báwo ni ó ṣe máa ṣe é? |
|
Ṣé kí ó dọ́gbọ́n àìsàn, kí ó ránṣẹ́ sí i nígboro pé kí ó wá rí i kíákíá ni dùbúlẹ̀ àìsàn rẹ̀? |
|
Kí ni yóò sọ fún un tó bá ti wá dé? |
|
ṣé kí ó wá sọ òótọ́ fún un ni? |
|
Òtítọ́ tí ó korò nípa ipò rẹ̀? |
|
Òtítọ́ tí òun gan alára kò mọ̀ láti iye ọjọ́ yìí? |
|
Màmá rò ó fún ìṣẹ́jú kan. |
|
Ọkàn rẹ̀ ṣáko lọ. |
|
Bẹ́ẹ̀, kò sí àní-àní, kò sí àní-àní, ó ní láti ṣe é. |
|
Ó jẹ́ iṣẹ́ tí ó gbọdọ̀ ṣe. |
|
Paríparí ẹ̀, ọmọ rẹ ṣáà ni, ọmọ rẹ kan ṣoṣo. |
|
Ètò rẹ̀ ni láti jẹ́ kí ó mọ gbogbo òótọ́ ọ̀rọ̀ náà, bí ó bá tiẹ̀ dùn mọ́ ọn. |
|
"Ó ti ya wèrè!", A jẹ́ kí ọmọ rẹ̀ mọ̀, a díjú sọ ọ́ láìtàsénu. |
|
Dájúdájú kò ní gba etí rẹ̀ gbọ́, ó lè dùn-ún, ó lè tàbùkù bá a. |
|
Ṣùgbọ́n kò ní wọ ìyẹn. |
|
A tún un sọ dáadáa. |
|
"Ó ti ya wèrè Àlàmú! Ìṣòwòsọ̀rọ̀ rẹ̀ gan-an fi hàn pé ó ya wèrè. |
|
Ìhùwàsí rẹ̀ fihàn pé ó ya wèrè. |
|
Bí ó ṣe ń wò gan-an fi hàn pé ó ya wèrè. |
|
Bẹ́ẹ̀ ni. Ọmọ mi ò ti ya wèrè! Ṣùgbọ́n Àlàmú, iṣẹ́ àwọn ọ̀tá ni. |
|
Ó máa ṣe pàtàkì láti jẹ́ kí ó mọ̀, "Iṣẹ́ àwọn ọ̀tá ni èyí." |
|
Àti wí pé, pabanbarì gbogbo rẹ̀ ò ṣẹ̀yìn ìyàwó rẹ̀, ìyàwó rẹ̀ gan-an. Òun ni aṣojú àwọn ọ̀tá. |
|
Bóyá Àlàmú gba èyí gbọ́ tàbí kò gbà á kò ṣe pàtàkì sí i. |
|
Kò kàn án bín-ín-tín báyìí. |
|
Wàhálà ti Àlàmú nìyẹn. |
|
Nǹkan tí ó ṣe pàtàkì ni láti jẹ́ kí o mọ ǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, gbogbo òtítọ́ ibẹ̀. "ṣùgbọ́n jẹ́ kí n sọfún ẹ Àlàmú, Làbákẹ́ yẹn á fẹnu tútù. Ìwọ ṣáà má ṣèyọnu.", á tu ọmọ rẹ nínú pẹ̀lú èyí. |
|
Ìwọ ṣáà má ṣèyọnu. |
|
"Mo ti sa gbogbo ipá mi láti wá ojútùú sí i, Èṣùníyì sì ti ń ràn wá lọ́wọ́ gidi. |
|
Èyí ló fà á tí o fi wà láàyè lónìí, ìdí nìyí tó ò ṣe tí ì já sí ìgboro – ìwọ lè má mọ̀. |
|
Nítorí tìrẹ. Mo ti rúbọ àwọn òrìṣà pẹ̀lú ewúrẹ́, àdàbà, ataare àti epo pupa. |
|
Màmá mọ̀ pé gbogbo èyí á já Àlàmú láyà bí ó bá gbọ́, ṣùgbọ́n ṣé ó yẹ kí ìyẹn tún da òun fún ráre láàmú? |
|
Rárá, kò ní wulẹ̀ gbé orí sókè láti wojú ọmọ rẹ̀. |
|
"Àlàmú gbáradì", a pàpà sọ fún un "A jọ ń lọ rí Èṣùníyì nísìnyí". |
|
"Èmi? Fún kí ni?", Ó ń rò ó bí ọmọ rẹ̀ ṣe ń dáhùn ìbéèrè padà, tí ó ń tẹnumọ́ pé. |
|
"Èmi kọ́! Èmi kọ́!" |
|
"Ìwọ ni Àlàmú!", ó pinnu láti pariwo mọ́ ọn padà, Ìwọ ni, Ìwọ, Ìwọ àti èmi! A jọ ń lọ lónìí ni, sọ́dọ̀ oníṣègùn. |
|
Wà á mu láti inú ìkòkò àgbò rẹ. Wà á wẹ̀ nínú ibú omi tí ó wà ní àárín ibùdó rẹ, wọ́n á sì sin gbére sí ọ lára. |
|
Àfàìmọ̀ kí Àlàmú má fi ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí kí ó kàn kúrò níwájú rẹ̀, tàbí kí ó tilẹ̀ ki èrè mọ́lẹ̀. |
|
Màmá fúnrarẹ̀ á lé e mu. |
|
Màmá wòye ara rẹ̀ bí ó ṣe ń lé Àlàmú lọ ṣọ́nà igbó olókùúta náà. |
|
Tí ó ń lé e lọ sọ́nà etí odò Akokura, tí ó bẹ́ẹ̀ pé kí ó padà, tí ó ń bẹ́ẹ̀ kí ó tó di wí pé ó kọjá odò náà. |
|
Kí ó tó di wí pé ó kọjá ibi tí kò ti ní lè padà. |
|
Bí ó bá filé kọjá odò Akokura, kò ní í sí ìrètí kankan fún un mọ́. |
|
Kò gbọdọ̀ kọjá odò kankan, bí bẹ́ẹ̀ kọ́... Ó ń wòye bí ọmọ rẹ̀ ṣe ń kánjú lọ. |
|
Ọwọ́ agbára ńlá àwọn ọ̀tá wà lára rẹ̀, ó ń tì í, tì í, ó ń jẹ́ kí ó máa kó gbogbo ìgbìyànjú láti mú kí orí-rẹ̀ pé. Ó ń gbọ́ bí Àlàmú ṣe ń jágbe mọ́ ọn. |
|
Màmá, ẹ padà sábúlé! Ẹ lọ sinmi lábúlé! Èmi á padà sí ìgboro. |
|
Bí a ṣe lè: Dẹ́nà ìdojúkọ Fíjì |
|
Ìtúnwọ́ Ìkẹyìn 9-6-2017 |
|
Nípasẹ̀ ìmúgbòòrò ààbò rẹ lórí ayélujára, o lè ṣ'alábàápàdé òṣèré ibi t'ó pète láti sọ ààbò rẹ di yẹpẹrẹ. |
|
Òṣèré burúkú ni a pe irú ọ̀tá, tàbí adojúkọni báwọ̀nyí. |
|
Bí adojúkọni bá fi ímeèlì tàbí ìsopọ̀ tó jọ gidi, àmọ́ tí ó jẹ́ àrànkan ni à ń pè ní Fisiini. |
|
Ìdojúkọ Fisíìsì sábà máa ń rí gẹ́lẹ́ bíi iṣẹ́-ìjẹ́ láti tàn ọ́: |
|
Kí o ṣọ́ra tẹ́ |
|
ìsopọ̀ adaríẹni s'ójú ìwé míì |
|
Kí o gba ẹ̀dà iṣẹ́-àìrídìmú sílẹ̀ sórí ẹ̀rọ-ayárabíàṣáa rẹ; tàbí |
|
Kí ó tẹ orúkọ ìdánimọ̀ àti ọ̀rọ̀-ìfiwọléẹ rẹ̀ sórí ibùdó-ìtàkùn tó jọ ògidì. |
|
Ìdojúkọ Fisíìsì lè tàn ọ́ fi kí o fi ọ̀rọ̀-ìfiwọléẹ rẹ sílẹ̀, tàbí tàn ọ́ láti fi iṣẹ́-àìrídìmú àìdara sórí ẹ̀rọọ rẹ. |
|
Adojúkọni lè lo iṣẹ́-àìrídìmú àrànkan láti fi pàṣẹ fún ẹ̀rọọ rẹ̀, jí ìwífún-un rẹ̀, tàbí fi ṣe alámì. |
|
Ìtọ́nà yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti tètè dá ìdojúkọ Fisíìsì mọ̀ ní kété tí o bá ṣ'alábàápàdéẹ wọn àti àwọn ọ̀nà tó wúlò tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbáradì fún wọn |
|
Àwọn oríisì ìdojúkọ Fíníhásì tó wà |
|
Fífúniní fún Ọ̀rọ̀-ìfiwọlé (tí a mọ̀ sí kíkọ́rẹ̀ẹ́ ìwé-ẹ̀rí) |
|
Fíṣíìnì fún Ọ̀rọ̀-ìfiwọlé lè tàn ọ́ kí o ṣ'èsì fún wọn ní ọ̀rọ̀-ìfiwọléẹ rẹ nípa fífi ìsopọ̀ ṣ'owó sí ọ. |
|
Ojúlé ìtàkùn àgbáyé inú iṣẹ́-ìjẹ́ lè darí ẹni sí ibòmíràn. |
|
Lórí ẹ̀rọ-ayárabíàṣáa rẹ, o máa rí URL tí ò ń lò, bí o bá fẹ́ tẹ ìsopọ̀. |
|
Ṣùgbọ́n a lè díbọ́n ìsopọ̀ kí ó jọ ara, tàbí lílo orúkọ ibùdó ìtàkùn tí ọmọ-ọ̀rọ̀ kan ti dín àti ó lè daríi rẹ̀ lọ sí ojúuwé ìtàkùn àgbáyé tó jọ èyí tí ó ti máa ń lò, bíi Gmail tàbí Dropbox. |
|
Àwọn ojú ìwé ìfiwọlé wọ̀nyí sábà máa ń rí bí òótọ́ tí yóò tàn ọ́ láti fi orúkọ-ìdanimọ̀ àti ọ̀rọ̀-ìfiwọléẹ rẹ sílẹ̀. |
|
Bí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o ó fi ohun-ẹ̀rí ìfiwọléẹ rẹ ránṣẹ́ sí ìdojúkọni. |
|
Torí ìdí èyí, kí o tó tẹ ọ̀rọ̀-ìfiwọlé, yẹ pátákó àdírẹ́ẹ̀sì orí ibùdó-ìtàkùn aṣàwáríkiriì rẹ wò. |
|
Yóò fi ògidì orúkọ agbègbè-ìkápá ojú ìwé náà hàn gbangba. |
|
Bí kò bá jọ ibùdó tí o mọ̀ tẹ́lẹ̀, máa tẹ̀síwájú! |
|
Ṣèrántí wípé àwòrán ilé-iṣẹ́ tí ó rí lójú ìwé ayédèrú kò fi hàn wípé ojúlówó ni. |
|
Ẹnikẹ́ni lè gbé ẹ̀dà àwòrán-ìdánmọ̀ sí orí ojú ìwé tí wọ́n láti fi tàn ọ́ jẹ. |
|
Àwọn onífíìmù míì máa ń lo ibùdó tó fojú jọ ojúlé-ìtàkùn àgbáyé láti tàn ọ́: https://wwwpaypal.com/ yàtọ̀ sí, https://www.paypal.com/. |
|
Ẹ̀wẹ̀wẹ̀, https://www.paypaI.com/ (tí ó ní "i" nílà dípò "L" kékeré yàtọ̀ sí https://www.paypal.com/. |
|
Ọ̀pọ̀ ènìyàn máa ń lo àyí-àtóka-ìbùdó-ìtàkùn di kúkúrú URL kí URL gígùn ba rọrùn fún kíkà tàbí tẹ̀, ṣùgbọ́n a lè fi èyí ṣe ìpamọ́ ibùdó burúkú. |
|
Bí o bá gba URL kúkúrú bíi ìsopọ̀-adaríẹni t.co lórí Twitter, gbìyànjú kí o ṣe àyẹ̀wò ìdánilójú https://www.checkshorturl.com/ láti tú àṣìírí ibi tí ó ń lọ gan-an. |
|
Rántí, ó rọrùn láti ṣe ayédèrú ímeèlì kí ó bá han ojúlé ìdápadà ímeèlì ẹ̀tàn. |
|
Èyí túmọ̀ sí wípé ìṣàyẹ̀wò ojúlé ímeèlì àfiṣe-ìjẹ́-ránṣẹ́ kò tó láti mọ̀ bóyá olóòótọ́ ni ẹni tó rí iṣẹ́-ìjẹ́ ránṣẹ́ tàbí ìdá kejì. |
|
Àwọn fífẹ́ ni oríṣìíríṣìí sábà máa ń lọ fi ṣiṣẹ́ láabi wọn. |
|
Adojúkọni lè fi ímeèlì ránṣẹ́ sí ọgọ́ọ̀rún-ún tàbí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn láti tẹ àwòrán fídíò alárinrin, ìwé tó ṣe pàtàkì, tàbí àríyànjiyàn ìṣúná kan. |
|
Àmọ́ nígbà mìíràn a máa ń daríi ìdojúkọ físíìsì sí ẹni tí a mọ kíní kan nípa rẹ̀. |
|
Èyí ni a pè ní "Fíṣíìnì ọkọ̀." Rò ó wípé ó gba ímeèlì kan láti ọ̀dọ̀ ẹ̀gbọ́n Boris tí ó ní àwòrán ọmọọ̀ rẹ̀ nínú. |
|
Níwọ́n ìgbà tí Boris ní ọmọ àti pé ìjẹ́rìí sí ojúlé ímeèlìi rẹ̀ jọ èyí tí ó mọ̀ tẹ́lẹ̀, ó ṣí i. |
|
Nígbà tí ó ṣí i, ó rí fáìlì àgbásílẹ̀ kékeré PDF tí a fi mọ̀ ọ́n. |
|
Bí o bá ṣí PDF náà, o lè fi àwòrán ọmọ Boris hàn, ṣùgbọ́n o ti ṣe kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ gbé iṣẹ́-àìrídìmú àìdara sórí ẹ̀rọ-ayárabíàṣáa rẹ tí yóò máa ṣe alámì ohun tí o bá ń ṣe wò. |
|
Ẹ̀gbọ́n Boris kọ́ ló fi ímeèlì yẹn ránṣẹ́, ṣùgbọ́n ẹni tí ó mọ̀ wípé ó ní ẹ̀gbọ́n kan tó ń jẹ́ Boris (tí ó ní ọmọ wẹ́wẹ́). |
|
PDF tí ò síra tẹ̀, tí àká PDF ń ṣí lọ́wọ́, ni iṣẹ́-àìrídìmú àìdara yìí yá ló fi fọ́n odùu rẹ̀ ká sórí ẹ̀rọọ rẹ̀. |
|
Láfikún sí PDF tí ó rí, ó ti ṣe àgbásílẹ̀ ẹ̀dá iṣẹ́-àìrídìmú àìdára sórí ẹ̀rọ ayárabíàṣáa rẹ̀. |
|
Iṣẹ́-àìrídìmú àìdara yẹn sì lè jí ẹnimimọ̀ àti ka àwòrán tí ayàwòrán àti gbohùngbohùn rẹ̀ gbọ́ sílẹ̀. |
|
Ọ̀nà tó dára jù fún ìdáààbòbò araa rẹ lọ́wọ́ ìdojúkọ físíìsì ni láti máa tẹ ìsopọ̀ adarí ẹni tàbí sí àfimọ́ tí a fi mọ ímeèlì. |
|
Ṣùgbọ́n àmọ̀ràn yìí kò jẹ́ nǹkankan fún ọ̀pọ̀ ènìyàn. Àwọn ọ̀nà tó yanrantí fún ààbò físíìsì wà nísàlẹ̀. |
|
Ìrànwọ́ bí o ṣe lè gbógunti Ìdojúkọ Mòsáńbíìkì |
|
Fi àfikún fún iṣẹ́-àìrídìmú rẹ |
|
Ìdojúkọ Fisíìnì àlo iṣẹ́-àìrídìmú àìdara sábà máa ń gbójúlé odù-aṣàṣiṣẹ́ iṣẹ́-àìrídìmú láti gbé iṣẹ́-àìrídìmú àìdara sóríi ẹ̀rọọ rẹ̀. |
|
Lọ́pọ̀ ìgbà bí a bá ṣ'àkíyèsí odù-aṣàṣiṣẹ́, oníṣọ̀nà iṣẹ́-àìrídìmú yóò gbé àfikún àtúnṣe jáde. |
|
Èyí túmọ̀ sí wípé iṣẹ́-àìrídìmúu ti tẹ́lẹ̀ ni odù-aṣàṣiṣẹ́ tó pọ̀ tí a lè lò fi gbé iṣẹ́-àìrídìmú àìdára sórí ẹ̀rọ. |
|
Gbígba àfikún iṣẹ́-àìrídìmúu rẹ lóòrèkóòrè yóò dín ewu iṣẹ́-àìrídìmú àìdara kù. |
|
Lo àkóso ọ̀rọ̀-ìfiwọlé àṣìṣefúnrarẹ. |
|
Ìṣàkóso ọ̀rọ̀-ìfiwọlé àṣìṣefúnrarẹ̀ yóò ṣe àpamọ́ ibùdó tí ó ti ń lo ọ̀rọ̀-ìfiwọlé ọ̀hún. |
|
Bí ó ṣe rọrùn fún ènìyàn tó láti bọ́ sí páńpẹ́ ojú ìwé ìfiwọlé ayédèrú, ìṣàkóso ọ̀rọ̀-ìfiwọlé ò le è lùgbàdì irú ẹ̀tàn bẹ́ẹ̀. |
|
Bí o bá ń lo ìṣàkóso ọ̀rọ̀-ìfiwọlé (títí kan ìṣàkóso ọ̀rọ̀-ìfiwọlé tó bá aṣàwáríkiriì rẹ wá), tí o kọ̀ láti ṣiṣẹ́ kíkọ́ ọ̀rọ̀-ìfiwọlé fúnra rẹ, ó yẹ kí o ṣe iyèméjì, kí o ṣe àtúnyẹ̀wò ibùdó tí ó wà. |
|
Síbẹ̀, lo ọ̀rọ̀-ìfiwọlé alágbára tí ìṣàkóso ọ̀rọ̀-ìfiwọlé lè kọ fúnra rẹ lórí ojú ìwé ìfiwọlé ayédèrú dípò kí o fi ọwọ́ọ rẹ̀ tẹ̀ ẹ́. |
|
Jẹ́ríkò ṣí ímeèlì pẹ̀lú àfiṣe-ìjẹ́ ránṣẹ́ |
|
Ọ̀nà kan láti mọ̀ bí ímeèlì kan bá jẹ́ ìdojúkọ Fisíìsì ní wíwòó ní ìkànnì mìíràn láti yẹ ẹni tó fi ránṣẹ́ wò. |
|
Bí ímeèlì náà bá wá láti ilé-ìfowópamọ́ọ rẹ, máa tẹ ìsopọ̀ adarí ẹni sí ojú ìwé mìíràn tí a fi sí inú ímeèlì náà. |
|
Kàkà bẹ́ẹ̀, pe ilé-ìfowópamọ́ọ rẹ tàbí kí o ṣí aṣàwáríkiriì rẹ kí o sì tẹ URL ilé-ìfowópamọ́ọ rẹ sí i. |
|
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí ẹ̀gbọ́n Boris bá fi ímeèlì tí ó ní àfimọ́ nínú, pè é lórí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ọ kí o béèrè bóyá ó fi àwòrán ọmọ rẹ ránṣẹ́ kí ó tó o sí i. |
|
Ṣí ìwé afurasí nínú Google Drive |
|
Àwọn ènìyàn ń fojú sọ́nà fún ìfimọ́ láti ọwọ́ ẹni tí o kò mọ̀. |
|
Fún àpẹẹrẹ, oníròyìn sábà máa ń gba ìwé láti ibi pàtàkì oríṣiríṣi. |
|
Ṣùgbọ́n ó lè nira láti ṣe ìjẹ́rìísí bóyá ìwé Word, àtẹ̀jáde Excel, tàbí fáìlì PDF kì í ṣe ti búburú. |
|
Bí èyí bá wáyé, o kò gbọdọ̀ síra tẹ fótò tí o gba ẹ̀dàa rẹ sílẹ̀ lẹ́rìnméjì. |
|
Kàkà bẹ́ẹ̀, gbé e sóríi Google Drive tàbí àkàwé mìíràn lórí ayélujára. |
|
Èyí yóò yí ìwé náà padà sí àwòrán tàbí sí HTML, tí yóò di gbígbé iṣẹ́-àìrídìmú àìdara lọ́wọ́ lórí ẹ̀rọọ rẹ̀. |
|
Bí ó bá hùn ọ́ láti kọ́ ìmọ̀ iṣẹ́-àìrídìmú tuntun fún kíka ímeèlì tàbí kíka ìwé ilẹ̀ òkèèrè, o ní ẹ̀rọ ìṣiṣẹ́ tí yóò dín ipa iṣẹ́-àìrídìmú àìdara kù. |
|
TAILS jẹ́ ti ẹ̀rọ ìṣiṣẹ́ ti Linux tó máa ń pa araa rẹ̀ rẹ́ lẹ́yìn tí a bá lò ó tán. |
|
Qubes jẹ́ ẹ̀rọ ìṣiṣẹ́ mìíràn lórí Linux tí máa ń ṣe jẹ́jẹ́ ya iṣẹ́ s'ótòótọ́ kí wọ́n ba máa dí ara wọn lọ́wọ́, tí yóò dín ipa iṣẹ́-àìrídìmú àìdara kù. |
|
Méjèèjì ló ń ṣiṣẹ́ lóríi ẹ̀rọ-ayárabíàṣá àgbélétan àti àgbélétètè. |
|
O kò le è fi ìsopọ̀ àti fáìlì tí o kò fọkàn tán sí VirusTotal, iṣẹ́ orí ayélujára ayé fáìlì àti ìsopọ̀ wọ̀ láti lòdì s'onírúurú agbogunti-odù-àgùntàn-àgùntàn-àgùntàn-ayárabíàṣájẹ́ tí yóò sì jíhìn àbájáde rẹ̀. |
|
Èyí kò dájú - antivirus sábà máa ń kùnà láti rí iṣẹ́-àìdara tuntun tàbí ìdojúkọ - ṣùgbọ́n ó dára ju àìsíi rẹ̀ lọ. |
|
Ìpelekínípìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpìpì |
|
Bí ìwífún inúu fáìlì náà bá jẹ́ èyí tí ẹnìkejì ò gbọdọ̀ rí, ó lè fẹ́ lo òmíràn. |
|
Ṣọ́ra fún àlàyé inú ímeèlì |
|
Àwọn ímeèlì Fisííìnì kan máa ń parọ́ wípé àjọ alátìlẹyìn fún ilé iṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ ni àwọn ń ṣe, wọ́n á sì ní kí ó fi ọ̀rọ̀-ìfiwọlée rẹ̀ ṣòwò, tàbí f'ààyè gba "àtẹ́wọ́ ayárabíàṣá ṣe" láti wo ẹ̀rọ ayárabíàṣáa rẹ̀, tàbí yọ ààbọ̀ orí ẹ̀rọọ rẹ̀ kúrò. |
|
rò nípa ìdí tí ó yẹ kí o fi gbọ́ sí wọn lẹ́nu ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ni ohùninú ímeèlì náà yóò jẹ́, fún àpẹẹrẹ, wípé àpótí ímeèlì rẹ ti kún tàbí wípé olè ti wọ inú ẹ̀rọọ rẹ |
|
Láìbọ̀sírere, gbígbọ́ sí àwọn ọ̀daràn wọ̀nyí lẹ́nu lè ṣe àkóbá fún ààbò rẹ. |
|
Ṣọ́ra kí ó tó fún ẹnikẹ́ni ní ìwífún tó lè kọ ọ́ síta bí ọmọ ọjọ́ mẹ́ta àyàfi bí ó bá dáa lójú wípé ibi dáadáa ni aṣebéèrè náà ti wá. |
|
Bí ìfura bá ṣe ọ́ nípa ímeèlì tàbí ìsopọ̀ tí ẹnìkan fi ránṣẹ́ sí ọ, máa ṣí i tàbí síra tẹ̀ ẹ́ àfi ìgbà tí o bá ti gbìyànjú àwọn ìmọ̀ràn tí a kà sókè wọ̀nyí àti bí o bá rí àrídájú wípé kì í ṣe ti aburú. |
|
Bí a ṣe lè: f'ààyègba ìfẹ̀yìntì Olona-méjì |
|
Ìfọkànsìn olókùn-méjì (tàbí 2FA) ni ìgbésẹ̀ ìdánimọ̀ òǹlò nípa lílo àkójọpọ̀ ìfọkànládì oríṣi méjì láti lo iṣẹ́ apèsè. |
|
Èyí lè jẹ́ ohun tí òǹlò mọ̀ (bíi ọ̀rọ̀-ìfiwọlé tàbí PIN), ohun tí òǹlò ní (bíi àmì iṣẹ́-àrídìmú tàbí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ọ), tàbí nǹkan tí a fimọ́ tàbí tí kò ṣe é yà s'ọ́tọ́ lára òǹlò (bíi ìtẹ̀ka wọn). |
|
O ò ti máa lo 2FA nínú ìgbé ayéẹ rẹ. |
|
Bí o bá lo ATM láti gbówójáde, o gbọdọ̀ ní ike pẹlẹbẹ ilé-ìfowópamọ́ọ rẹ (ohun tí o ní) àti PIN rẹ̀ (ohun tí o mọ̀) |
|
Ní báyìí, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ orí ayélujára a máa lo ìdánimọ̀ kan ṣoṣo fún òǹlò wọn gẹ́gẹ́ bíi ààtààbáwá - ọ̀rọ̀-ìfiwọlé. |
|
Báwo ni 2FA ṣe ń ṣiṣẹ́ lórí ayélujára? |
|
Àìmọye iṣẹ́ orí ayélujára - títí kan Facebook, Google, àti Twitter - ń pèsèe 2FA gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà mìíràn fún ìfigagbága ọ̀rọ̀-ìfiwọlé nìkan. |
|
Bí o bá f'ààyègba iṣẹ́ yìí, wà á fi ọ̀rọ̀-ìfiwọlé àti ọ̀nà mìíràn ṣe ìfọkànbalẹ̀. |
|
Ọ̀nà kejì ni ọ̀kan nínúu SMS tàbí odu alòlẹ́ẹ̀kan tí aàpù ẹ̀rọ alágbèéká afohunikọ̀kọ̀ pamọ́ gẹ́gẹ́ bíi Aferiladi Google, Duo Mobile, aapu Facebook, tàbí Clef) tí a yà s'ótọ́ fún iṣẹ́ yìí yóò gbà jáde. |
|
Èyíkéyìí, ọ̀nà kejì ni ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ọ alágbèékáa rẹ, ohun tí o sábà máa ń ní. |
|
Ibùdó-ìtàkùn-àgbáyé (títí kan Google) náà nítìlẹ́yìn ìpamọ́ odù alálòlẹ́ẹ̀kan, tí ẹ̀dà rẹ̀ ṣe é gbà sórí ẹ̀rọọ rẹ̀, ṣe é tẹ̀ sórí ìwé, àti fi pamọ́ sí ibìkan. |
|
Ní kété tí o bá ti f'ọwọ́ sí i láti máa lo 2FA, o nílò ọ̀rọ̀-ìfiwọléẹ rẹ àti odù alálòlẹ́ẹ̀kan láti orí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ọ alágbèékáa rẹ kí o tó o r'ààyè wo ìṣàmúlòọ rẹ. |
|
Kí ló dé tí mo fi gbọdọ̀ f'ààyègba 2FA? |
|
2FA ń fún ìṣàmúlòọ rẹ̀ ní ààbò tó péye nípa mímú ó fi ẹ̀rí làdí ìdánimọ̀ọ rẹ̀ ju ọ̀nà kan lọ. |
|
Èyí túmọ̀ sí wípé, bí ẹnikẹ́ni bá ti ẹ gbá ọ̀rọ̀-ìfiwọléẹ rẹ̀ mú nípò kínínní, wọn kò ní le è r'ọ̀nà wo ìṣàmúlòo rẹ àyàfi bí wọ́n bá ní ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ọ alágbèékáa rẹ tàbí r'ọ̀nà ipò-kejì lo ìfẹ̀rílí mìíràn. |
|
Ǹjẹ́ 2FA ní àléébù? |
|
Láyépé 2FA ń fún ni ní ààbò tó péye fún ìfọkànládi, ewu àtimọlé ìṣàmúlòo rẹ lè è wáyé, fún àpẹẹrẹ, o kò mọ ibi tí o ṣ'owóo ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ rẹ sí tàbí o ti pàdánùu rẹ, tàbí pààrọ̀ ike pẹlẹbẹ SIM rẹ, tàbí rìnrìn àjò sí ìlú mìíràn láì tan ìrìn-káàkiri orí ẹ̀rọọ rẹ. |
|
[Ìròyìn tó tẹ̀wá lọ́wọ́] Luz Mely Reyes tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe ojúu rẹ̀, fi tó wa létí nípa bí àwọn Ológun SEBIN ṣe yẹ ilée Diaz pẹ̀lú ilée Soto náà wò. |
|
Ìṣọ̀kan àwọn Oníròyìn náà fẹ́ ọ̀rọ̀ náà lójú: |
|
NÍ KIAKIA Ní dédé àsìkò yìí, ní dédé agogo 3:00 òwúrọ̀ kùtùkùtù, ìgbìmọ̀ láti àjọ Amúninípa dé ilé oníròyìn àti ajá-fún- ẹ̀tọ́ọ ọmọ ènìyàn Luis Carlos Díaz, tí ó ti di ẹni àwátì láti agogo 5:30 ìrọ̀lẹ́ #NiboNiLuisCarlosWa. |
|
Àwọn ajàfúnẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti àjọ òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ náà darapọ̀ mọ́ ìpolongo yìí pẹ̀lú #DondeEstaLuisCarlos (Níbo ni Luis Carlos wà?), tí ó jẹ́ pé, ní báyìí, ni àkọlé tí ó gbajúmọ̀ ní orí ìkànnì ayélujára Twitter ti Orílẹ̀ Èdè Venezuela. |
|
Diaz jẹ́ ajábọ̀ ìròyìn àti a-jà-fún-ẹ̀tọ́-ọmọ ènìyàn tí ó jẹ́ ògbólógbòó àjàfúnẹ̀tọ́ òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ tí wọ́n sì mọ iṣẹ́ rẹ̀ fún un l'órílẹ̀ èdè Venezuela àti òkè òkun fún ìdásọ̀rọ̀ àti ìtako ìjọba Nicholas Maduro. |
|
Ó ti tó ìgbà díẹ̀ kan tí ó ti ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ àti olùdárò òṣèlú tí ó gbajúmọ̀ ń nì, Naky Soto, tí wọ́n sì ń ṣe ìgbéjáde àwọn fídíò àti ètò Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ lórí ayélujára èyí tí ó dá lórí ìṣèlú àti ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn ní Venezuela. |
|
Ó ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí akọni àti olùgbé-lárugẹ ìdásílẹ̀ ayé ọ̀tọ̀ fún àwọn ará ìlú àti àwọn àkànṣe ètò ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ tí kò lọ́wọ́ ìjọba nínú. |
|
Diaz tún jẹ́ olùkópa nínú ẹgbẹ́ Ohùn Àgbáyé fún ọdún mẹ́wàá. |
|
Lọ́dọ̀ tèmi, Luis Carlos jẹ́ onílàákàyè ẹ̀dá kan, ó gbọ́njú nínú ìròyìn gbígbà àti ìkansí-ara-ẹni nínú Venezuela tí wà yìí tí kò fara rọ. |
|
Ó ti ṣe àwárí ìjápọ̀ nínú ìlú (láti ìtako sí ibi ìṣẹ̀ṣe) #NiboniLuisCarlosWa. |
|
Láàárín ọjọ́ pẹ́réte tó síwájú ipòoraa rẹ̀, ètò ìkan-sára- ẹni tí ìjọba Con el Mazo Dando ṣàfihàn fídíò tí Díaz sọ̀rọ̀ nínúu rẹ̀. |
|
Adarí ètò ọ̀hún, olóṣèlú Diosdado Cabello, rò kan pé Diaz lọ́wọ́ sí ìfẹ̀hónú hàn àìsí ináá mọ̀nàmọ́ná tí ó lọ jákèjádò orílẹ̀ èdè èyí tí ó mú kí àwọn ọmọ Venezuela máa gbé nínú òkùnkùn fún ó lé ní wákàtí mẹ́rin lé lógún lọ́jọ́ 7 àti 8 Oṣù Ẹrẹ́nà |
|
Kò sí ẹ̀rí tí ó fi ẹsẹ̀ rinlẹ̀. |
|
Wákàtí méje ti ré kọjá lọ tí Luis Carlos Díaz ti di àwátì. |
|
[Diaz] jẹ́ oníròyìn fún ilé iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Union Radio Noticias, ó sì tún jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn. |
|
Àwa ni olú ilé iṣẹ́ẹ SEBIN headquarters àti pé wọ́n ní àwọn kò ní i [ní àhámọ́ àwọn] #NiboNiLuisCarlosWa. |
|
[Ìròyìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́: they wọ́n pàpà jẹ́wọ́ wípé [Diaz wà ní akólóọ wọn] |
|
Akọ̀ròyìn Vladimir Villegas sọ wípé kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́ wípé ìjọba ni ó fi ọwọ́ agbára mú u: |
|
radionet Luis Carlos Díaz, ti wà nínú àtìmọ́lé agbófinró Ìlú. |
|
A bá a kẹ́dùn ipò tí ó wà. |
|
A béèrè fún ìtọ́sọ́nà nípa mímọ ibi tí ó wà, àti ìbọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn-an rẹ̀. |
|
Ẹgbẹ́ Ohùn Àgbáyé dúró ṣinṣin pẹ̀lú Luis Carlos, ẹbíi rẹ̀, àti oníròyìn aládàáṣiṣẹ́ gbogbo àwọn tí ó ń mú ìjọba ṣe bí ó ti yẹ ní Venezuela. |
|
À ń retíi rẹ̀ kí ó dé kíákíá ní àlàáfíà ara àti ẹ̀mí, a ó máa gbé àwọn ìròyìn síta nípa ìròyìn yìí bí ó bá ṣe ń tẹ̀ wá lọ́wọ́. |
|
Ìwé àbádòfin ìlò ẹ̀rọ alátagbà yóò pa òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ lórí ayélujára ní Nàìjíríà |
|
Ìwé àbádòfin náà yóò fi àṣẹ fún ìsúnpa ẹ̀rọ ayélujára ní Nàìjíríàj |
|
Aṣojú Mohammed Sani Musa ni agbátẹrùu ìwé àbádòfin ìlò ẹ̀rọ alátagbà. Àwòrán àgékù láti ibùdó Channel Television You Tube. |
|
Lọ́jọ́ 20 oṣù Belu, Ìwé Àbádòfin tí ó fi Ààbò fún Irọ́ àti Makaruru tí ó rọ̀ mọ́ ọn ti ọdún-un 2019, tí a mọ̀ sí "ìwé àbádòfin ìlò ẹ̀rọ alátagbà", tí Aṣojú kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mohammed Sani Musa ṣe agbátẹrùu rẹ̀, ti di kíkà nínú ìgbìmọ̀ fún ìgbà kejì. |
|
Èròǹgbà ìwé àbádòfin ìlò ẹ̀rọ alátagbà náà ni láti dẹ́kun àwọn àhesọ àti gbólóhùn tí kì í ṣe òtítọ́ lórí ẹ̀rọ ayélukára bí àjẹ́. |
|
Bí-ó-ti-lẹ̀-jẹ́-pé, kì í ṣe láti fi òfin de ìlò ẹ̀rọ alátagbà ni ìwé àbádòfin náà dá lé lórí, àmọ́ ṣá, ó máa pa òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ lórí ayélujára, ìṣọ́ alátakò ìjọba di ọ̀daràn àti fífi àtipa ẹ̀rọ ayélujára fúngbà díẹ̀ sínú ìwé òfin. |
|
Àtẹ̀pá bí erin bá tẹ koríko ni àwọn ọmọ Nàìjíríà tẹ irú ìwé àbádòfin báyìí pa ní ọdún-un 2016. |
|
Ẹ̀ṣẹ̀ ni bí ó bá gbọ́ ìjọba lẹ́nu (tako ìjọba) |
|
Gẹ́gẹ́ bí Abala 1A ti ṣe ṣàlàyé, èròǹgbà ìwé àbádòfin yìí ni láti "[máa jẹ́] kí ìgbéjáde ọ̀rọ̀ tí kò ní òtítọ́ kan nínú tàbí èyí tí ẹ̀ríi rẹ kò f'ẹsẹ̀ rinlẹ̀ tó o jáde ní Nàìjíríà". |
|
Yóò yọ ọwọ́ kíláńkọ àwọn àtẹ̀jáde irọ́ tí ó lè kọ orílẹ̀ èdèe Nàìjíríà sí "ìkorò", lawọ́ láì gbàgbée àwọn ọ̀ràn bíi ètò ìlera gbogboògbò, ààbòo gbogboògbò, "ìyọ̀ǹda-ọkàn-an gbogboogbo tàbí ìṣúná owóo gbogboògbò" àti "àwọn ìbáṣepọ̀ orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà pẹ̀lú àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn". |
|
Abala 1c sọ bí ìwé àbádòfin náà yóò ṣe "mú, ṣàkóso àti fi ààbò bo ìlọ́nilọ́kulò àwọn ìṣàmúlò àti ẹ̀rọ àdánikanṣiṣẹ́ orí ẹ̀rọ ayélujára". |
|
Ní àlàyé síwájú sí i, kò sí ohun tí ojú òfin tuntun náà kò leè tó bí ó bá ti jẹ́ lórí ayélujára — lábẹ́ aburada à ń gbógun ti àhesọ àti irọ́ pọ́ńbélé. |
|
Ọ̀run ń ya bọ̀ ní ìwé àbádòfin ìlò ẹ̀rọ alátagbà náà, kò yọ ẹnìkan sílẹ̀, gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdèe Nàìjíríà ni yóò bá, kò kan agbègbè tàbí ibi tí ènìyàn fi ṣe ibùgbé, máa ṣe é l'óògùn máà mọ̀, ọwọ́ àwọn ọlọ́gọ̀gọ̀ ojú tólé ojú tọ́kọ ni "gbọ́lóhùn irọ́ tí kò ní ẹ̀rí" tí ó bá gba òpópónà ẹ̀rọ ayélukára bí ajẹre Nàìjíríà yóò bọ́ sí. |
|
Abala 3a sì b(i) tí ìwé àbádòfin ìlò ẹ̀rọ alátagbà sọ wípé: |
|
Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wu ìwà kíwà kan nínú tàbí lẹ́yìn odi Nàìjíríà láti tari gbólóhùn tí kò ní òtítọ́ kan tí a kò leè fi ẹ̀ríi rẹ̀ múlẹ̀ síta; àti àgbésórí afẹ́fẹ́ ayélujára gbólóhùn t'ó lè kó orílẹ̀ èdèe Nàìjíríà síta bí ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ nípa ti ààbò ìlú. |
|
Ọ̀ràn-an ti "ààbò orílẹ̀-èdè" ni orí Èṣù tí òfin náà dúró lé láti pa ẹ̀tọ́ sí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ mọ́. |
|
Àmọ́ kò tán síbẹ̀, kò sí ẹni tó lè tako ìjọba Nàìjíríà tàbí gbọ́ ọ lẹ́nu nítorí kì í ṣ'àṣìṣe. |
|
Ní Abala 3b(vi), gbólóhùn tí ó bá yẹpẹrẹ “ojúṣe tàbí iṣẹ́, tí ó jẹ́ ti ìjọba lójú ará ìlú” kò leè la orí ayélujára kọjá. |
|
Gẹ́gẹ́ bí Abala 3b(v) ti ṣe fi hàn, èyí ní í ṣe pẹ̀lú gbólóhùn tí ó: "fa ìmúlòtàá, tí a sọ sí ẹnìkan tàbí ìtara láàárín àwọn ènìyàn". |
|
Èyí léwu nítorí ó fi àyè gba àwọn onípò àṣẹ láti lo agbára nílòkulò. |
|
Ta ní í sọ bóyá gbólóhùn kan lè fa rògbòdìyàn? |
|
Ìyẹn túmọ̀ sí wípé lílo inú kan tàbí mímú àwọn olóṣèlúú mú ìléríi wọn ṣẹ lè já sí ìkórìíra lójúu wọn. |
|
Owó ìtanràn fún ẹni tí ilé ẹjọ́ bá dá lẹ́bi tó láàárín ẹgbẹ̀rún 200 àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún 10 owó náírà [tí ó tó $556 sí $28,000 owó orílẹ̀ èdèe United States], ìtìmọ́ fún ọdún mẹ́ta tàbí méjèèjì. |
|
Àṣẹ fún Àjọ Ológun láti san ẹ̀rọ ayélujára pa fúngbà díẹ̀ |
|
Ìwé àbádòfin ìlò ẹ̀rọ alátagbà náà fún ìjọba lágbára bí ó ṣe hù wọ́n láti san ẹ̀rọ ayélukára bí ajẹre pa nígbàkúùgbà tí ó bá lérò wípé ó tọ́, nípasẹ̀ "Àṣẹ Ìdígàgá Ìráyè" láti lo ayélujára bí ó ti ṣe wà ní Abala 12, òǹkàye 3: |
|
Ẹ̀ka Ológun leè fi àṣẹ fún Àjọ Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Nàìjíríà NCC [Nigerian Communications Commission – tí ó ń ṣe bòńkárí ìtàkùrọ̀sọ orí ẹ̀rọ ayárabíàṣá] láti pa á láṣẹ fún apèsè àyè sí ìlò ẹ̀rọ ayélujára kí ó gbé ìgbésẹ̀ lójú ẹsẹ̀ tí ò ní mú àwọn òǹlò rí àyè lò ayélujára ní Nàìjíríà. |
|
Àwọn apèsè ayélujára gbọdọ̀ tẹ̀lé òfin ìdígàgá yìí tàbí kí wọn ó sanwó ìtanràn tí ó tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún 5 sí 10 owó náírà [$14,000-28,000 USD]. |
|
Ní àfikún, ìwé àbádòfin náà fi àrídájú ààbò bo àwọn apèsè iṣẹ́ ẹ̀rọ ayélujára tí kò ní mú wàhálà "ara ìlú tàbí bẹ́ẹ̀ " tí kò bá à lè jáde láti ìdájọ́ kan tí ẹnikẹ́ni kò bá pè wọ́n fúnòpè "wọ́n tẹ̀lé òfin ìdígàgá ìsíwájú" sí ayélujára, ìyẹn bí abala 12, òǹkàye 5 ṣe fi lélẹ̀. |
|
Ìtẹ̀sí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn náà ṣ'ókùnkùn sí i nítorí wípé òfin náà gba àwọn ọlọ́pàá láyè lábẹ́ òfin láti pa àṣẹ ìdígàgá-ayé bí ó ti ṣe hù wọ́n. |
|
Abala 15a sọ wípé “iṣẹ́ ọpọlọ” ọlọ́pàá ní àsìkò "ìwádìí ẹ̀rí tó dájú" jẹ́ kókó láti fagilé ìsúná ẹ̀rọ ayélujára ní orílẹ̀ èdè náà. |
|
Ní ìparí, “kò sí àyè fún ẹjọ́ó kò tẹ̀mí lọ́rùn ní Ilé-ẹjọ́ Gíga” [Abala 13(2)] tí ẹnikẹ́ni lè fi yẹ ìdígàgá sílẹ̀ láì máa kọ́kọ́ tọ ọlọ́pàá lọ láti fagilé òfin ìdígàgá náà. |
|
Ipa èyí hàn gbagada — ẹnikẹ́ni kò ní leè gba ilé ẹjọ́ lọ fún ìgbèjà ìfètò ẹni dunni yìí tí ìdígàgá náà sì wà. |
|
Àwọn aṣojú-ṣòfin tí ó wà lẹ́yìn ìwé àbádòfin ẹ̀rọ alátagbà náà |
|
Àwọn aṣojú-ṣòfin mẹ́ta kan ni ó gbé ìwé àbádòfin náà sórí nínú ìgbìmọ̀, ilé ìgbìmọ̀ àgbà: Mohammed Sani Musa (adaríu ìwé àbádòfin), Abba Moro àti Elisha Abbo. |
|
Ilé-iṣẹ́ẹ Mohammed Sani Musa, Activate Technologies Limited, ni ó kọ ẹ̀rọ Ìwé-pélébé Ìdìbò Aláàbọ̀ (PVCs) tí a lò fún ìbò ọdún-un 2019, nígbà tí ó jẹ́ òǹdíjedupò lábẹ́ ẹgbẹ́ olóṣèlúu tí ó ń tukọ̀ ètò ìṣèlú lọ́wọ́ All Progressives Congress (APC) fún Aṣojú Ìlà-Oòrùn Niger, ìyẹn gẹ́gẹ́ bí ilé iṣẹ́ aṣèwádìí, Premium Times ṣe tẹ̀ ẹ́ jáde. |
|
Àjọ Eleto (INEC) gbá ẹ̀sùn náà mọ́ra. |
|
Ọ̀ràn yìí fi hàn pé àwọn alákòóso ìbò tí ó kọjá kò ṣiṣẹ́ láì lọ́wọ́ àwọn alágbára ń'nú. |
|
Ishaku Elisha Abbo ti ẹgbẹ́ alátakò People’s Democratic Party (PDP) jẹ́ aṣojú tí ó ń ṣojú Ẹkùn-ún Àríwá Adamawa ní Ìpínlẹ̀ Adamawa, ní ìlà-oòrùn àríwá orílẹ̀ èdèe Nàìjíríà. |
|
Nínú oṣù Agẹmọ 2019, ní ìṣojú ọlọ́pàá, Abbo ṣe àṣemáṣe pẹ̀lú òṣìṣẹ́bìnrin kan nínú ìṣọ́ ohun ìbálòpọ̀ ní olú-ìlú Nàìjíríà ní Àbújá. |
|
Lẹ́yìn tí àwòrán casemase náà fọ́n ká sórí ẹ̀rọ alátagbà, Abbo offered mọ́ ìwàa rẹ̀ lẹ́bi, ó sì bẹ̀bẹ̀. |
|
Abba Moro, tí í ṣe ọmọ ẹgbẹ́ẹ PDP, ni aṣojú fún ẹ̀ka Gúúsù Benue, àárín gbùngbùn àríwá Nàìjíríà. |
|
Ní ọjọ́ 15, oṣù Ẹrẹ́nà, ọdún-un 2014, Moro, tí í ṣe ọ̀gá pátápátá ètò abẹ́lé, ló wà nídìí ìṣẹ̀lẹ̀ abanilọ́kànjẹ́ Igbaniṣiṣẹ́ Ẹ̀ṣọ́ aṣọ́bodè Nàìjíríà tí àwọn ọ̀dọ́langba tí ó tó bíi ẹgbẹẹgbẹ̀rún 6 tó fẹ́ àyè iṣẹ́ ẹgbẹ̀rún 4 tí ó ṣí sílẹ̀ nínú iléeṣẹ́ Ẹ̀ṣọ́ Aṣọ́bodè Nàìjíríà tí wọ́n kóra jọ níbi oríṣìíríṣìí jákèjádò orílẹ̀ èdè náà. |
|
Ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó burúkú jáì náà tí ó ṣekú pa ogún ènìyàn àti ìpalára fún ọ̀pọ̀ èèyàn. |
|
Moro gbà nínú of owó ìwáṣẹ̀ tí àwọn awaṣẹ́ san tí ó ń lọ bíi ẹgbẹẹgbẹ̀rún 675 owóo náírà [ $1.8 USD]. |
|
Moro kó owó sápòo rẹ̀ bẹ́ẹ̀ náà ó fọ òfin ìgbànǹkan Aṣọ́bodè dà. |
|
"Kò nílò ìdákẹ́ jẹ́jẹ́, ìbẹ̀rù bojo tàbí ìkáàánú-araẹni" – #SayNoToSocialMediaBill! |
|
Nípa lílo àmì #SayNoToSocialMediaBill, àwọn ọmọ orí ayélujára orílẹ̀ èdèe Nàìjíríà bọ́ sóríi Twitter láti sọ èrò ọkàn-an wọn: |
|
Nínú gbólóhùn kan, Amnesty International fajúro sí lílo "àwọn òfin tí ó ń fìdíi ìfi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn gbolẹ̀ múlẹ̀ " nítorí pé kò ní pa àwọn ọmọ Nàíjíríà lẹ́nu mọ́ "láti máa sọ èrò ọkàn-an wọn" tí yóò sì tún "ràn wọ́n lọ s'ẹ̀wọ̀n fún wípé wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ ". |
|
Lábẹ́ aburada à ń dẹ́kun gbólóhùn irọ́ àti ọ̀rọ̀ àhesọ, ń gbèrò ìṣòfin tí kò ní ìfẹ́ ará ìlú lọ́kàn. |
|
Ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu, àwọn olóṣèlúu ló léwájú níbi ká gbé gbólóhùn irọ́ sórí ayélujára. |
|
Ẹgbẹ́ olóṣèlúu tí ó ń jẹ lọ́wọ́ àti ẹgbẹ́ alátakò gbòógì sọ Twitter di pápá ogun fa ọ̀rọ̀ ìkórìíra ẹlẹ́yàmẹ̀yà, ìròyìn tí kò pọ̀jù òṣùwọ̀n àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn lásìkò ìdìbò ààrẹ ọdún-un 2019. |
|
Kà síwájú sí i: |
|
Ẹ̀rọ alátagbà fa ọ̀rọ̀ ìkórìíra ẹlẹ́yàmẹ̀yà, ìròyìn tí kò pọ̀jù òṣùwọ̀n àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn lásìkò ìdìbò ààrẹ ọdún-un 2019 |
|
Twitter di pápá ogun fún gbólóhùn irọ́ lásìkò ìdìbò orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà ọdún-un 2019 |
|
Ní àkókò bíi ti òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ní Nàìjíríà tí a wà yìí, ọ̀rọ̀ ọlọ́pọlọ láti ẹnu òǹkọ̀wé orílẹ̀-èdèe Amẹ́ríkà Toni Morrison tí ó mú ìrètí dání: |
|
Èyí ni ìgbà tí àwọn ayàwòrán ń ṣiṣẹ́. Kò sáyè fún ìṣàníyàn, kò sáyè fún ìkáàánú-ara, kò nílò ìdákẹ́ jẹ́jẹ́, kò sí àyè fún ìbẹ̀rù bojo. |
|
A sọ, a kọ̀, a p'èdè. |
|
Ìwé àbádòfin ìlò ẹ̀rọ alátagbà náà ti jẹ́ kíkà ní igbá kejì nínú ìgbìmọ̀ Aṣojú-ṣòfin. |
|
Kí ó tó di òfin, ó gbọdọ̀ gba ìgbìmọ̀ kan tí àwọn aṣojú-ṣòfin yóò yẹ̀ ẹ́ wò. Ìgbìmọ̀ọ̀tẹ̀ẹ̀ka náà yóò sì jábọ̀ àbájáde àyẹ̀wòọ rẹ̀ fún Ìgbìmọ̀ àgbà, láti gbé e yẹ̀ wò, tí wọn yóò tẹ òmíràn jáde fún àyẹ̀wò tí ó kẹ́yìn, kí ààrẹ ó tó bu ọwọ́ lù ú. |
|
A gbọdọ̀ fajú ro sí ìgbésẹ̀ Ìgbìmọ̀ kí wọ́n ba ju ìwé àbádòfin ìlò ẹ̀rọ alátagbà náà dànù sígbó. |
|
Nítorí orílẹ̀ èdèe tí ó gbajúmọ̀ jù lọ nílẹ̀ Adúláwọ̀ yóò yẹ gẹ̀dẹ̀ sí ìjọba ìfipámúnisìn ní kété tí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ bá di títẹ̀ bọlẹ̀. |
|
Ilé ẹjọ́ gíga Tanzania pa á láṣẹ fún ìpalẹ̀mọ́ ìṣọ̀tẹ̀ láàárín àgbàlagbà àti ọmọdé láì wo ti ìgbésẹ̀ ìmúpadàà rẹ̀ |
|
"Èyí ni ìpinnu tí ó dára jù lọ tí ilé-ẹjọ́ yóò ṣe" |
|
Àwọn Ọmọiléèwé ọmọdébìnrin ní Tanzania dúró fún àwòrán lọ́jọ́ 10 oṣù Agẹmọ ọdún-un, 2007. Fanny Schertzer ni ó ya àwòrán, a lò ó pẹ̀lú àṣẹ láti Wikimedia Commons, CC BY 2.0. |
|
Nínú oṣù Ọ̀wàrà 2019, ilé ẹjọ́ gíga Tanzania ṣe ìdìtẹ̀ ṣinṣin ìdájọ́ ọdún-un 2016 tí ó pàṣẹ ó kéré jù, ọmọbìnrin àti ọmọkùnrin gbọdọ̀ pé ọmọ ọdún méjìdínlógún kí ó tó ṣe ìgbéyàwó. |
|
Àjọ ọba orílẹ̀ èdèe Tanzania fọwọ́sowọ́pọ̀ láti ṣe ìmúpadà ìpinnu yìí, nítorí wípé àwọn ọmọdébìnrin ń yára bàlágà àti wípé ààbò ni ìgbéyàwó jẹ́ fún ọ̀dọ́bìnrin aláboyún. |
|
Àmọ́ ní ọjọ́ 23 oṣù Ọ̀wàrà ọdún-un 2019, ìjọba orílẹ̀ èdèe Tanzania pàdánù ẹjọ́ọ kòtẹ́milọ́rùnun rẹ̀ tí àṣẹ ilé ẹjọ́ gíga sì dúró: akọ àtàbọ̀ gbọdọ̀ pé ọjọ́ orí méjìdínlógún kí wọn ó tó ṣe ìgbéyàwó, tí èyí sì ń fi agbára kún ìgbésẹ̀ ìṣọ̀tẹ̀ ọmọdé ní Tanzania. |
|
Gẹ́gẹ́ bí United Nations Population Fund (UNFPA) ti ṣe wí, Tanzania ni ìṣọ̀tẹ̀ ọmọdé pọ̀ sí jù lọ lágbàáyé. |
|
Àwọn ọmọ orí ayélujára síra láti fi ìdùnnúu wọn hàn lóríi ìdájọ́ náà. |
|
Àwọn kan kí Rebeca Z. Gyumi, aláfisùn àti ẹni tí ó léwájú nínú ọ̀ràn ìṣọ̀tẹ̀ àwọn ọmọdé náà. |
|
Gyumi ni olùdásílẹ̀ àti alákòóso àgbà Msichana Initiative (Ètò fún àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin), iléeṣẹ́ tí kì í ṣe tìjọba tí ó ń ro àwọn ọmọdébìnrin lágbára nípasẹ̀ ti ẹ̀kọ́ ìwé. |
|
Ìgbésẹ̀ láti fòpin sí ìṣọ̀tẹ̀ ọmọdé ní Tanzania |
|
Lọ́dún-un 2016, Gyumi na ọwọ́ ìka àbùkù sí agbára Òfin Ìgbéyàwó; Law of Marriage Act, 2002 (LMA) tí ó gba obìnrin tí kò tó ọmọ ọdún méjìdínlógún láyè láti ṣe ìgbéyàwó. |
|
Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí nípa ìlera Tanzania Demographic and Health Survey (TDHS) ṣe ti ṣàlàyé, ìdá 36 obìnrin tí ọjọ́ oríi wọn wà ní 25-49 ní í ṣe ìgbéyàwó kí wọn ó tó pé ọmọ ọdún méjìdínlógún, tí àwọn akẹgbẹ́ẹ wọn lọ́kùnrin sì jẹ́ ìdá 5. |
|
Òfin LMA fi àyè gba ọmọdébìnrin tí ọjọ́ oríi wọn kò ju ọdún mẹ́rìnlá lọ láti ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ìṣọwọ́sí ilé-ẹjọ́, ìṣọwọ́sí òbí fún ọmọ ọdún márùn-ún-dínlógún, nígbà tí ọdún méjìdínlógún jẹ́ ọjọ́ orí tí ó kéré jù lọ fún ọmọkùnrin. |
|
Nípasẹ̀ àwọn aṣojú rẹ̀, Gyumi ṣàlàyé wípé alaalẹ́ LMA kó ìyàn obìnrin kéré nítorí pé ó fún àwọn ọkùnrin ní àǹfààní ju àwọn obìnrin lọ. |
|
Nítẹ̀síwájú, wọ́n sọ wípé alaalẹ́ náà fi ẹ̀tọ́ dídọ́gba ọmọ ènìyàn yí ẹrẹ̀fọ̀ àti pé wọ́n fi ẹ̀tọ́ àǹfààní sí ẹ̀kọ́ ìwé dun àwọn ọmọdébìnrin. |
|
Gyumi rọ Ilé-ẹjọ́ Gíga láti gbé alaalẹ́ LMA tì sẹ́gbẹ̀ẹ́. |
|
Ilé-ẹjọ́ Gíga kò ṣe bẹ́ẹ̀. |
|
Àmọ́ wọ́n rí i lóòótọ́ wípé kò bá òfin mu wọ́n sì fún ìjọba lọ́dún kan láti ṣe àtúnṣe sí ohun tí kò tọ̀nà nínú alaalẹ́ LMA. |
|
Nípasẹ̀ aṣojú àgbà àwọn adájọ́, a pa ìjọba láṣẹ láti gbé ọjọ́ orí ìgbéyàwó sí ọdún méjìdínlógún fún obìnrin àti ọkùnrin. |
|
Síbẹ̀, aṣojú àgbà àná banújẹ́ sí ìdájọ́ náà ó sì kọ ìwé àtúnpè-ẹjọ́ sí Ilé-ẹjọ́ Gíga náà: |
|
Pẹ̀lú àṣẹ ìjọba: mo ti gba ìwé àtúnpè-ẹjọ́ lóríi ẹjọ́ #childmarriage. Ẹjọ́ òǹkà 204 ti oṣù Ọ̀wẹwẹ̀ ọdún-un 2017. |
|
Kà síwájú sí i: Mozambique sọ ìsọkúsọ ọmọdé di ìwà ọ̀daràn |
|
Àyè fún àtúnpè-ẹjọ́ |
|
Láàárín oṣù mẹ́rin ìgbẹ́jọ́, ìjọba gbèrò láti ṣe àtúnpè-ẹjọ́ ọdún-un 2016 tí yó ṣe àtúnṣe sí alaalẹ́ LMA èyí tí ó fi àyè gba ọmọdébìnrin ọlọ́jọ́-orí márùn-úndínlógún gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti bàlágà fún ìgbéyàwó. |
|
Àtẹ̀jọ̀pè, tí ó jẹ́ aṣojú àwọn adájọ́ ìpínlẹ̀, Mark Mulwambo àti Alesia Mbuya, ṣe àgbékalẹ̀ ìyàtọ̀ ìwà ẹ̀dá obìnrin àti ọkùnrin tí wọ́n sì fi àṣà ìbílẹ̀ àti òfin ẹ̀sìn Imale gba àtúnpè-ẹjọ́ náà nídìí. |
|
Ms. Mbuya sọ wípé ìyàtọ̀ ìwà ẹ̀dá fi ọmọdékùnrin àti ọmọdébìnrin sí "ìsórí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ " àti pé, òfin fi ojú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wò wọ́n. |
|
Ó sọ síwájú sí i wípé nítorí àwọn ọmọdébìnrin máa ń tètè bàlágà ju ọmọdékùnrin lọ ni òfin fi lá àláálẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ó sọ wípé ìgbéyàwó lè fi ààbò bo ọmọdébìnrin tí kò sí nílé ọkọ tí ó ti di èèwọ̀méjì láì tó ọjọ́ orí tí ó tọ́. |
|
Ó sọ síwájú sí i wípé ilé ẹjọ́ kùnà bí ó ṣe “ṣe ìmúdọ́gbandọ́gba ọjọ́ orí ọmọ àti ọjọ́ orí tí ó yẹ fún ìgbéyàwó”, èyí tí ó túmọ̀ sí wípé ọ̀tọ̀ ni ti tọ̀lú ọ̀tọ̀ ní ti tọ̀lú wọ̀, ọ̀tọ̀ ni ó yẹ kí ilé ẹjọ́ ó là kalẹ̀ fún ọjọ́ orí ìgbéyàwó ọkùnrin àti obìnrin. |
|
Àwọn ọmọ orí ayélujára ti yára bu ẹnu àtẹ́ lu ìdí tí àtẹ́wọ́ fi sílẹ̀ nínú ìgbẹ́jọ́. |
|
Kà síwájú sí i: Mozambique, Côte d'Ivoire gbé ìgbésẹ̀ akọni fún ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin àti ọmọdé |
|
Dídọ́gba àbọ̀ àtakò |
|
Ìdájọ́ ilé ẹjọ́ náà jẹ́ atọ́ka sí ìpalẹ̀mọ́ àwọn àṣà tí ó ń mú ìpalára bá àwọn ọmọdébìnrin àti onírúurú ẹlẹ́yàmẹ̀yà tòun ìfọwọ́ṣọwọ́yin àwọn ọmọdébìnrin ní Tanzania. |
|
Ní ti àjọ United Nations, kí a tó lè yege níbi tí dídọ́gba àbọ̀ àtakò ní ọdún-un 2030, ìjọba ní láti ṣe àyípadà òfin ìyàsọ́tọ̀ọ̀tọ̀ àti ṣíṣe àmúlò òfin tí yóò mú ìmúdọ́gba tí à ń sọ wáyé. |
|
Àbájáde ìwádìí ṣe àfihàn-an rẹ̀ wípé ọjọ́ orí tí ó tọ́ láti ṣe ìgbéyàwó bá ìpele ìwé tí ènìyàn kà àti ọ̀rọ̀ tí ènìyàn ti kó jọ (TDHS 201) tan. |
|
Ní Tanzania, ó ní ìyàtọ̀ ọdún mẹ́fà tí ó wà láàárín ọmọdébìnrin tí kò lọ sí ilé ìwé àti àwọn tí ó ka ìwé gíga tàbí ìwé gíga jù lọ. |
|
Ní Tanzania, ohun tí kò bá òfin mu ni kí a fẹ́ tàbí fún akẹ́kọ̀ọ́bìnrin lóyún, ẹ̀wọ̀n ọgbọ̀n ọdún ni ẹní bá tàsé àgẹ̀rẹ̀ sófin yóò fi gbára. |
|
Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin tí ó bá lóyún kì í padà sí ilé ìwé pàápàá tí ó bá bímọ tán. |
|
Ìfòfindè ìṣọ̀tẹ̀ pẹ̀lú ọmọdé máa ń fi ààbò fún àwọn ọmọdébìnrin, láì ro bí wọ́n ṣe wọ ilé ìwé. |
|
Ní Tanzania, ìgbéyàwó ọmọdébìnrin kì í jẹ́ kí ọmọdébìnrin ó kàwé tí wọn kò sì ní àǹfààní láti parí ẹ̀kọ́ọ wọn, gẹ́gẹ́ bí èsì ìwádìí láti Tanzania National Survey, 2017 ṣe ní i lákọsílẹ̀. |
|
Ìfòfindè ìṣọ̀tẹ̀ yìí ṣe àgbékalẹ̀ ìgbé ayé tó dára fún akẹ́kọ̀ọ́bìnrin láti parí ẹ̀kọ́ọ wọn láì sí ìdádúró. |
|
Pẹ̀lú bẹ́ẹ̀, akẹ́kọ̀ọ́bìnrin tí ó bá fẹ́rakú ṣì ń kojú òfin tí ó ní wọn kò gbọdọ̀ padà wá sílé ìwé. |
|
Àmì ìdánimọ̀ orílẹ̀ èdèe Jamaica ti Kanye West ló di awuyewuye tí ó dá fìrìgbagbòó lórí ‘ìsààmì’ |
|
Ẹrú ọjà pẹ̀lú àkòrí nípa Jamaica di títà lórí ayélujára |
|
Kanye West ń kọrin níbi ayẹyẹ ọlọ́dọọdún Ilé-ọ̀nà ti Ọ̀nà Ìgbàlode ní Garden benefit, New York City, ọjọ́ 10, oṣù karùn-ún, 2011. Àwòrán láti ọwọ́ọ Jason Persse, CC BY-SA 2.0. |
|
Ọkọ̀rin tàkasúfèé tí ó jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdèe Amẹ́ríkà Kanye West gbé àríyá "Ìsìn Ọjọ́ Ọ̀sẹ̀ " pop-up concert wá sí Kingston, Jamaica, ní kété tí ìsinmi ọjọ́ ọ̀sẹ̀ fún Àyájọ́ Ọjọ́ Àwọn Malegbagbe Ọmọ Orílẹ̀-èdè náà (19-21, oṣù Ọ̀wàrà ọdún-un 2019) yóò bẹ̀rẹ̀. |
|
Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí ọkùnrin náà yóò kó ẹgbẹ́ akọrin ìyìnrere rẹ̀ kúrò ní Amẹ́ríkà, ní ìjẹ́pípée tí àgbẹ̀ fún ìjọba orílẹ̀ èdèe kan tí ó Já kí ó gbé ètò náà wá sílùú òun. |
|
Síbẹ̀, àríyá náà ti rí ìtako láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, tí ó Ho forí sọlẹ̀ pẹ̀lú àmì ìdánimọ̀ọ orílẹ̀-èdèe Jamaica ti West wé lórí ọjà tí ó ń tà lóríi ibùdó ìtàkùn àgbáyée rẹ̀ láì gba àṣẹ láti lò ó. |
|
Láàárín ọjọ́ méjì ni ìkéde fi lọ síta, inúu gbàgede Emancipation Park tó wà ní Kingston, olú ìlú orílẹ̀ èdè náà ni bẹ̀bẹ̀ ti wáyé — ojú ibi tí ó mú àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ kan wí tẹnu wọn látàrí àwọn ọ̀rọ̀ tó mú àríyànjiyàn dání tí West sọ nípa òwò ẹrú nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan báyìí lóṣù karùn-ún ọdún-un 2018. |
|
Ọdún-un 2002 ni gbàgede náà di lílò ní ìbọ̀wọ̀ fún "omìnira dójú àmì" fún àwọn ẹrú 300,000 ní Jamaica lọ́jọ́ 1, oṣù kẹjọ ọdún-un 1838. |
|
Ó lè jẹ́ èyí gan-an ni òun àkọ́kọ́ nípa àríyá orin náà, ṣùgbọ́n òun kọ́ ni ó gbẹ́yìn. |
|
Pàápàá jù lọ bí Olóòtú Ètò Àṣà Olivia "Babsy" Grange ṣe bẹnu-ẹtẹ lu àwọn alátakò nígbà tí ó sọ wípé orílẹ̀ èdè náà ṣe àbápín nínú eré àríyá náà, ní èyí tí akópa orin kan lérò wípé àríyá náà tí ó ṣe é wò lójú ẹsẹ̀ bí ó ṣe ń lọ lóríi ìtàkùn àgbáyée Ìsìn Ọjọ́ Ọ̀sẹ̀, "gbà" àwọn ètò tí ó rọ̀ mọ́ àṣà ìbílẹ̀ tí ó jẹ́ ti Ìsinmi àwọn Malegbagbe Ọmọ orílẹ̀ èdè sẹ́gbẹ̀ẹ́. |
|
Láfikún, àwọn olùgbée Kingston, tí ó bá súnkẹrẹ fàkẹrẹ kọfo lọ́sẹ̀ yẹn, fọ àfọ̀tẹ́lẹ̀ làásìgbò àti rọ́tọ̀mùtí bí àwọn tó ṣíwọ́ iṣẹ́ bá ń darí lọ sílé nírọ̀lẹ́. |
|
Láì sí àní-àní, àríyá náà ló ní ìrọwọ́-ìrọsẹ̀, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún àwọn Nev orílẹ̀-èdèe Jamaica gbádùn-un àríyá náà tí àwọn iléeṣẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ orílẹ̀ èdèe Jamaica náà gba ìgbóríyìn fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ṣe: |
|
Ìròyìn àrọ́wọ́ ìgboro ni wípé ó ṣeé ṣe kí ìgbésẹ̀ wà láti (Ìsìn Ọjọ́-aìkú) láti gba àṣẹ ẹ̀mí-ní-mọ́ni/ètò olùpèsè ààmì ìdánimọ̀ọ Kingston, orílẹ̀ èdè Jamaica àti ti ẹyẹ afárá onígun gígùn. |
|
Mo ti ṣe àwọn ìwádìí kan lórí ayélujára tí mo sì ṣe àwárí láti fi ti ẹ̀rí lẹ́yìn àmọ́ kádàrá kò ṣe mí lóore, mo ṣalábàápàdé ọjàà wọn tí wọ́n ń tà lórí ayélujára tó ní àwọn ààmì ìdánimọ̀ wọ̀nyí, tí ó sì ṣe dọ́gba-n-dọ́gba pẹ̀lú àríyá náà... |
|
Òtítọ́ orílẹ̀ èdèe Jamaica ni wípé àwọn ìjọba àná kò fi ìgbàkan kọbiara sí ìpinnu ètò ọ̀rọ̀ Ajée ‘Jamaica’ tàbí àwọn ààmì ìdánimọ̀ tó jẹ́ ti wọn bíi àsíá àti àsíá àpáta. |
|
Bákannáà ni ó rí fún orin wa àti ohun tí ó rọ̀ mọ́, Ska, Mento, Rock Steady, Reggae àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. |
|
Ilẹ̀ Jamaica kò tètè lajú sí òwò aṣọ ṣíṣe tí ó ní ààmì pàtàkì erékùṣù tí yóò mú àwọn ènìyàn rà á wìtìwìtì. |
|
Bí a bá fi ètò àríyá ṣe ìgbélárugẹ àwọn ọjà wọ̀nyí nínúu gbàgede Emancipation Park tí ó mú ìlọsíwájú bá ohun tí ó ju aṣọ lọ láti ọ̀dọ̀ ìjọba àti àwọn ọmọ orílẹ̀ èdèe Jamaica náà, pẹ̀lú lílo àwọn ààmìi orílẹ̀ èdè náà ní ọ̀nà àrà. |
|
Mo ti ṣe àkíyèsí wípé Iléeṣẹ́ Ètò Àṣà àti Olùdarí ìlúu Kingston ti ń gbé ìgbésẹ̀e pàjáwìrì láti ra nǹkan padà. Kí àwọn méjèèjì mọ̀ pé àtúnṣe kì í ṣe nǹkan tó má yá kíákíá. |
|
Mo lérò wípé ìjọba ní àwọn agbẹjọ́rò tó ka ojú òṣùwọ̀n. |
|
Lóòótọ́, àwọn agbẹjọ́rò ṣì níṣẹ́ láti ṣe láti tú kókó awuyewuye etí aṣọ ti lílo àsíá orílẹ̀ èdèe Jamaica. |
|
Ìrọ́lù ọlọ́pàá tí í mú ikú bá ‘ni ní Guinea bí Ààrẹ Alpha Conde ṣe kọ̀ láì gbé’ jọba sílẹ̀ |
|
"Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú ti kọyìn síjọba lórí ìgbésẹ̀ yìí" |
|
Àṣèkù ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní Guinea láti ìròyìn ráńpẹ́ France 24 kan. |
|
Ìwà ipá bẹ́ sílẹ̀ ní Guinea lọ́jọ́ 14 oṣù Ọ̀wàrà, tí ó ti fa ikú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí wọ́n sì ń kó àwọn ènìyàn kiri lẹ́yìn ìyíde ìfẹ̀hónúhàn tí ó tako ìjọba ààrẹ tí ó wà lórí oyè ìyẹn Alpha Conde, ẹni tí ó ń gbèrò láti yí ìwé-òfin padà kí ó ba fi ààyè gba òun láti lọ fún ìgbà kẹta. |
|
Ojúu pópó olú ìlú náà, Conakry, àti àwọn ìlú tó kù ti di ojú ogun láàárín àjọ agbófinró àti àwọn ọmọ ìlú tó ń fi ẹ̀hónú hàn. |
|
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti lo àǹfààní tuntun tí ó fún wọn láṣẹ láti lo ohun ìjà aṣekúpani bí ó bá dé ojú ẹ̀. |
|
Àwọn afẹ̀hónúhàn ti rán ẹni mẹ́fà sí ọrùn àjàntọ́, ní èyí tí ó jẹ́ pé ọlọ́pàá kan wà nínúu àwọn tí ó jẹ Ògún nípè, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì fi ara pa. |
|
Kà síwájú sí i: Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ní Guinea ti ní àṣẹ láti lo ohun ìjà aṣekúpani |
|
Àwọn afẹ̀hónúhàn kò lọ́wọ́ sí kíláńkò àyípadà sí ìwé-òfin tí wọ́n rí gẹ́gẹ́ bí ìgbésẹ̀ ààrẹ láti wà lórí ipò fún ẹlẹ́ẹ̀kẹta. |
|
Ní tòótọ́, ìwé-òfin náà fi ààyè ọdún méjì gba ẹni tí ó bá wà ní ipò ààrẹ láti ṣèjọba. Conde, ẹni ọdún 81, yẹ kí sáà rẹ̀ ó parí ní oṣù Ọ̀wàrà ọdún-un 2020. |
|
Àwọn afẹ̀hónúhàn ni a lè sá lọ́gbẹ́ jù lọ nítorí wípé wọ́n tàsé àgẹ̀rẹ̀ sí òfin náà bí Human Rights Watch ṣe pè fún àkíyèsí: |
|
Ìtúmọ̀ Ìtúnwí-ọ̀rọ̀ Ọlọ́rọ̀ gan-an |
|
Human Rights Watch sọ lónìí wípé, ìjọba orílẹ̀-èdèe Guinea ti gbẹ́sẹ̀ lé ìfẹ̀hónúhàn l'ójúu pópó fún ọdún kan, ó tọ́ka sí ìdójú-ìjà-ko ààbò ìlú. |
|
Àwọn aláṣẹ ìjọba ìbílẹ̀ ti fọ́n ó tó bíi ogun ìfẹ̀hónúhàn ẹgbẹ́ òṣèlú àti àwọn mìíràn ká yángá. |
|
Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ti sọ tajútajú sí àárín àwọn tí kò gbọ́ràn láti tú wọn ká, wọ́n sì kó àìmọye ènìyàn. |
|
Ní ti ìṣẹ̀lẹ̀ òṣèlú náà, àjọ ọba náà ń kéde iṣẹ́-ìjẹ́ tí ó ń tako ara wọn: Ní ọjọ́ 13, oṣù Ọ̀wàrà Ààrẹ Conde fẹ́ ìṣòro-ní-túnbí-n-nùbí: |
|
Ìtúmọ̀ Ìtúnwí-ọ̀rọ̀ Ọlọ́rọ̀ gan-an |
|
Alpha Conde ti pẹ́ fún ìṣòro ní tunbinnubi ó sì fẹ́ kí ìjókòó gẹ́gẹ́ bí tọ́mọtíyà tí yóò fi pẹ̀lẹ́tù yanjú gbọ́nmi-sii-omi-ò-tóó tí ó ń ṣẹlẹ̀ àti ọ̀nà àbáyọ sí àwọn ìpèníjà tí ó ń kojú orílẹ̀-èdè náà. |
|
Síbẹ̀, Ahmed Tidiane Traore, olùdámọ̀ràn ipò ààrẹ, sọ lọ́jọ́ tí ó tẹ̀lé e, ìyẹn ní ọjọ́ 12 oṣù Ọ̀wàrà, — ọjọ́ méjì kí ìwọ́de ó tó bẹ̀rẹ̀, — fún àwọn èrò tó jẹ́ ọ̀dọ́ langba RPG ẹgbẹ́ olóṣèlúu [ruling Reunion of the People of Guinea]: |
|
Ìtúmọ̀ Ìtúnwí-ọ̀rọ̀ Ọlọ́rọ̀ gan-an |
|
A rọ àwọn ọ̀dọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú náà láti kún fún ìṣọ́ra ní ojúù pópó. |
|
Àwọn [tí àwọn jẹ́ ajìjàǹgbara alátakò] ti fa ìṣòro, a pe àwọn ìpèèrè láti inú ẹgbẹ́ náà láti wá ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro tó wà nílẹ̀, àmọ́ kí ẹ máa dojú ìjà kọ ẹnikẹ́ni, kí ẹ máa ba dúkìá kankan jẹ́, ju ìdáàbò bo ara yín lọ. |
|
Gbogbo àwọn oníṣẹ́-ibi ni ó di àwárí tí a ó fi ojúu wọn hàn f'áráyé rí. |
|
Ẹnu méjì àwọn tí ó ń tukọ̀ ìlú ti túbọ̀ mú inú bí ẹgbẹ́ alátakò àti àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn, ó ní bí ìtàkùn globalguinee.info ṣe sọ: |
|
Ìtúmọ̀ Ìtúnwí-ọ̀rọ̀ Ọlọ́rọ̀ gan-an |
|
Ọjọ́ 14 oṣù Ọ̀wàrà ọdún-un 2019 jẹ́ ọjọ́ Ajé burúkú Èṣù gbomi mu, ní ti ìfèsì sí ìpè àjọ FNDC [Àwọn tí ó ń léwájú ń'nú Ìdáàbò bo Ìwé-òfin Orílẹ̀-èdè], àwọn ọmọ Guinea tú yàyà tú yàyà sí ojúu títì láti tako ìgbésẹ̀ àtúnṣe sí ìwé-òfin. |
|
Ìkọlù wáyé ní àwọn agbègbè tí ó wà ní àárín olú ìlú orílẹ̀-èdè náà. |
|
Karakata dẹnu kọlẹ̀ ní àárín gbùngbùn ibi ìṣàkóso ìlú ní Kalou. |
|
Àwọn tí ó wà ní Àárín àti Odò orílẹ̀ èdè Guinea náà gbọ́ ìpè, wọ́n sì darapọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ìlú tó kù. |
|
Ènìyàn díẹ̀ ni ó jáde ní ìgbèríko àti Òkèe Guinea. |
|
Àmọ́ ṣá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú ti kọyìn síjọba lórí ìgbésẹ̀ yìí. |
|
Ní oríi benbere.org, gbàgede ìtàkùrọ̀sọ fún àwọn ọ̀dọ́ ní Mali, akọ̀ròyìn búlọ́ọ̀gù Adam Thiam kọ: |
|
Ìtúmọ̀ Ìtúnwí-ọ̀rọ̀ Ọlọ́rọ̀ gan-an |
|
Nǹkan kàyéfì ń lọ lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí ní Guinea, pẹ̀lú ìròkurò tí ó ń wáyé, ọta ìbọn ti fọ́ sí ara àwọn afẹ̀hónúhàn tí ó sì ti ṣekú pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ọ̀ wọn, ẹ̀jẹ̀ ní ojúu pópó, ìdígàgá ní gbogbo, iná ẹsẹ̀ ọkọ̀ọ̀ sísun àti tajútajú nínú afẹ́fẹ́. |
|
Àwọn ọmọ ìlú orí ayélujára fajúro sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà lórí ẹ̀rọ alátagbà: |
|
Bíi ti Blaise Compaore [oṣèlúu Burkinabé] Alpha Conde ń forí lé ibi ìparun, ǹjẹ́ yó leè gbóhùn inúbíbí àwọn aráa rẹ̀ bí? |
|
Ó di ọjọ́ iwájú kí a tó mọ̀. Ní báyìí ṣá, ọkọ̀ ojú omi ti ń rẹ̀. |
|
Lọ́jọ́ 15 oṣù Ọ̀wàrà, akọ̀ròyìn Guinea Bhiye Bary kọ: |
|
Ilé ìtoògùn Hamdallaye (#Conakry): àwọn ọlọ́pàá ló jí àwọn ọmọ ìlú kan lójú oorun ní òwúrọ̀ yìí. |
|
Gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ti ṣe sọ, àwọn ọlọ́pàá ń jalèkún tí wọ́n sì ń kó ẹrù nílé onílé. |
|
S. Nkola Matamba, òǹkọ̀wé àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn tí ó jẹ́ ọmọ Ìlú Olómìnira Ìjọba ará wa ti Congo, fi ìbànújẹ́ ọkàn hàn: |
|
Ọmọ ẹgbẹ́ alátakò ìgbàkan, tí ó wá fẹ́ yí òfin padà nítorí ìfẹ́ ara rẹ̀ kí ó bá ṣèjọba fún ìgbà kẹta, bóyá kí ó bá jẹ gàba títí tí Ọlọ́jọ́ yóò fi dé, Alpha Conde gan-an ni àpẹẹrẹ ibi tí ó ń fa ìfàsẹ́yìn fún Ilẹ̀-Adúláwọ̀! |
|
Ẹ̀yin aráa Guinea, ẹ mú ọkàn le! |
|
#GUINEE – ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu. Ìfèhónúhàn ìtako ìṣèjọba Conde fún ìgbà kẹta ọjọ́ kan ṣoṣo ti mú ẹ̀mí àwọn ènìyàn lọ. |
|
Sísíwín àwọn olóṣèlú tí ó fẹ́ kú sórí ipò ààrẹ yìí ti ń pọ̀ ju Amoulanfe— Cheikh FallTM (@cypher007) ọjọ́ 14, oṣù Ọ̀wàrà 2019 |
|
Adarí Guinea Macky Darsalam sọ ti ìgbésẹ̀ láti tọwọ́ bọ èròǹgbà àwọn ará ìlú lójú: |
|
Ẹgbẹ́ alátakò Guinea náà kò ní ààbò tí ó lè fi bọ́ araa rẹ̀ lásìkò ìkọlù: àwọn aṣojú aláṣẹ ẹgbẹ́ alátakò gbogbo kò dá sí àríyànjiyàn ìgbìmọ̀ ìjọba mọ́ láti ọjọ́ 11, oṣù Ọ̀wàrà 2019. |
|
Ìwà ipá sí àwọn ẹgbẹ́ olóṣèlú wọ̀nyí ti gba ọ̀nà àrà, bẹ́ẹ̀ ni ibùdó ìtàkùn mediaguinee.org ṣe kọ: |
|
Ìtúmọ̀ Ìtúnwí-ọ̀rọ̀ Ọlọ́rọ̀ gan-an |
|
...ní olú iléeṣẹ́ Union of Republican Forces (URF) ti agbègbè Sidya Toure, ìjà wáyé láàárín àwọn ọmọ ẹgbẹ́ alátakò kan àti àwọn tí ó ń fẹ́ ti ìjọba tí ó ti ṣètò tí kò ní jẹ́ kí ìyíde ìfẹ̀hónúhàn náà ó wáyé lọ́jọ́ kan sí ọjọ́ ìfẹ̀hónúhàn ní àwọn agbègbè tí wọ́n ti lẹ́nu. |
|
Ìkọlù náà wá sí òpin lẹ́yìn-in ìkólọ iléeṣẹ́ URF náà ti àwọn ènìyàn mẹ́fà tí kò sí ẹni tó mọ orúkọ àti ẹgbẹ́ olóṣèlú tí wọ́n ń bá ṣe di ẹ̀rọ àtìmọ́lé. |
|
#SexForGrades: Ẹ̀tọ́ Alalaye-aferihan tú aṣírí ìwà ìyọlẹ́nu ìbálòpọ̀ ní àwọn Ìforítìi Ìwọ̀-oòrùn Ilẹ̀-Adúláwọ̀ |
|
Ìtìjú mú àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí máa leè sọ |
|
Boniface Igbeneghu, ọ̀jọ̀gbọ́n Ifásitìi Èkó, Nàìjíríà ti bá ẹni tí ó wo ìbòjú yìí ṣe erée gẹ́lẹ́ ní àìmọye ìgbà (Àwòrán láti BBC #SexForGrades) |
|
#SexForGrades, ètò alálàyé apanilẹ́rìn-án BBC kan tí ó dá fìrìgbagbòó lóríi àṣemáṣe eré ìfẹ́ tí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ìfisítì pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́birin ní Nàìjíríà àti Ghana ti rán bíi pápá inú òye ní orí ayélujára tí ó sì ti fa àwọn ìbéèrè ọlọ́kanòjọ̀kan nípa ọ̀nà tí a leè gbà dẹ́kun àṣemáṣe ọ̀hún láwùjọ: |
|
Àgbà iṣẹ́ ìwádìí náà, tí ó di gbígbé jáde ní ọjọ́ keje oṣù Ọ̀wàrà 2019, tí akọ̀ròyìn Kiki Mordi tí kò parí ẹ̀kọ́ọ rẹ̀ látàríi wípé kò fẹ́ ṣe àṣemáṣe pẹ̀lú olùkọ́ni ìfití rẹ̀ tí ó ń fi ìdíi rẹ̀ rẹmi nínú ìdánwò nítorí wípé kò fún un ṣe ṣe atọ́kùn-un rẹ̀: |
|
Boniface Igbeneghu, Ifásitì Èkó, tí a ka ìwà àṣemáṣe pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́birin nínú ìwádìí abẹ́lé tí BBC ṣe. |
|
Àwòrán láti BBC #SexForGrades. |
|
Ìwádìí tí ó pé wákàtí kan tú àṣìírí ìwà àṣemáṣe ti “ère ìfẹ́ fún ojú-àmì ẹ̀kọ́” ní ìfisítì Ìwọ̀-oòrùn Ilẹ̀ Adúláwọ̀ méjì: University of Lagos (UNILAG) ti Nàìjíríà àti University of Ghana. |
|
Boniface Igbeneghu, tí í ṣe kọfesọ ní ẹ̀ka iṣẹ́ ọnà ti UNILAG, tí ó sì tún jẹ́ àlùfáà Ìjọ Foursquare Gospel, ní Èkó, ń bẹ nínú àwọn olùkọ́ tí òkété bòrù mọ́ lọ́wọ́. |
|
A rí Igbeneghu nínúu ètòo BBC náà tí ó kọ ẹnu ìfẹ́ sí ọmọdébìnrin tí ó díbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọmọ ọlọ́jọ́ orí mẹ́tàdínlógún tí ó ń wá ìgbànisílẹ̀ ẹ̀kọ́ láì fura wípé ajábọ̀ ìròyìn tí ó ń ṣe iṣẹ́ ìwádìí abẹ́lẹ̀ fún BBC ni ó ń ṣe. Igbeneghu sọ báyìí wípé: |
|
Ṣé o kò mọ̀ wípé ọmọbìnrin arẹwà ni ọ́? |
|
Ǹjẹ́ o mọ̀ wípé àlùfáà ìjọ ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ ni mo jẹ́, àti pé mo tó ẹni àádọ́ta ọdún ṣùgbọ́n bí mo bá fẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ọ̀rọ̀ dídùn àti ọwọ́ ni ó máa jẹ́... |
|
Níbi ìpàdé kan láàárín àwọn méjèèjì, Igbeneghu ṣe iná pa, ó sì ní kí ọmọdébìnrin náà ó fẹnu ko ọ̀hún lẹ́nu, tí ó sì tún dì mọ́ ọn baálẹ̀dí nínúu iyàráa iṣẹ́ẹ rẹ̀ tí ó wà ní títì pa. |
|
Ìjọ Ajíhìnrere Foursquare ti dá Igbeneghu dúró "lẹ́nu iṣẹ́ ìhìn rere". |
|
Bákan náà, Ifásitì Èkó ti lé Igbeneghu kúrò ní ilé ìwé wọ́n sì ti sun ìpẹ́rẹ́ sí ẹ̀hìn ìlẹ̀kùn ilé òṣìṣẹ́ tí wọ́n ń pè ní "yàrá tútù", tí àwọn ọ̀gá olùkọ́ni ti máa ń ṣe àríyá níbi tí wọ́n ti máa ń gba àwọn òsọ̀rọ̀ ọmọge lálejò. |
|
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìbànújẹ́ ọdún sẹ́yìn |
|
Àkàrà tí ó tú jáde yìí ti fi gòjé ọ̀rọ̀ jáde lẹ́nu ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ọmọ orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà ní orí ayélujára pẹ̀lú àmìi #SexForGrades ní oríi Twitter. |
|
Púpọ̀ nínú àwọn òǹlò tí ó jẹ́ abo ní oríi Twitter fi ẹ̀dùn ọkàn-an wọn hàn nípa ìríríi wọn lóríi ìwà erée gẹ́lẹ́ ti ìbálòpọ̀: |
|
Lọ́la Sónẹ̀yìn, alátinudáa àjọ̀dún ìwé àti òǹkọ̀wé, ṣàlàyé "ìtìjú ńlá" tí ọ̀hún rí nígbà tí amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀gá pátápátá ìfisítì kan (DVC) fọwọ́ kan ibi tí kò yẹ kí ó fọwọ́ kàn lára òun: |
|
Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n onísìn ilẹ̀ ẹ̀kọ́ gíga Nàìjíríà ti ba ti àwọn obìnrin jẹ́. |
|
Síbẹ̀síbẹ̀, nítorí ìtìjú àwọn tí ó fi ara pa kì í leè sọ̀rọ̀ síta èyí kò sì jẹ́ kí ó rọrùn láti dá sẹ̀ríà fún àwọn àdàwà ìbàjẹ́. |
|
Ní ọdún-un 2016, Ìgbìmọ̀ Aṣòfin mú àbá ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún wá fún olùkọ́ni tí ilé ẹjọ́ bá dá lẹ́bi àṣemáṣe pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ nínú "Ìwé àbádòfin Ìfòpin sí ìwà ìbàjẹ́ ìbálòpọ̀ ní Ilé Ìwé Gíga". |
|
Síbẹ̀, Àjọ Olùkọ́ni Ifásitìi Nàìjíríà kọ ẹ̀yìn sí ìwé àbá yìí, wọ́n ní ó kó ìyàn àwọn kéré, nítorí ó kọjú ìjà sí àwọn olùkọ́ àti wípé ó yẹpẹrẹ àṣẹ àti agbára ilé ẹ̀kọ́ gíga. |
|
Ìṣọ̀tàsí ìwé àbá náà pa òfin náà ní àpakù fínfínfín — èyí kò sì jẹ́ kí ààrẹ ó bu ọwọ́ lù ú. |
|
Ṣé Eré ìfẹ́ fún ojú-àmì Èkó #SexForGrades ni ìjìjàgbara ilé ìjọsìn #ChurchToo tuntun? |
|
Nínú oṣù keje ọdún yìí, gbajúgbajà ayàwòrán-an nì, Busola Dakolo, fi ẹ̀sùn kan Bíọ́dún Fatolú, àlùfáà àgbà ìjọ Commonwealth of Zion Assembly (COZA), wípé ó fi ipá bá òun ní àjọṣepọ̀ nígbà tí òhun wà ní ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún. |
|
Kà síwájú sí i: Àlùfáà tàbí apanijẹ bí ẹ̀pà? |
|
Ajíhìnrere Oníwàásù nínúu wàhálà ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ |
|
Fún ọdún mẹ́fà tí ó ré kọjá lọ, Fáyòòdẹ́ ti rí ìfẹ̀sùnkan ìfipábánilòpọ̀ ọ̀kan-ò-jọ̀kan. |
|
Síbẹ̀, ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí Dalma ti fẹ̀sùn kan Fáṣọlá dá awuyewuye sílẹ̀ lórí ayélukára bí àjẹ́. |
|
Fún ọjọ́ díẹ̀, ilé ìjọsìn náà; #ChurchToo — tí í ṣe àpẹẹrẹ èmi náà ní àgbáyé #MeToo — gba ayélujára kan ní Nàìjíríà. |
|
Ẹ̀sùn yìí fọ́ fèrè láti orí ayélujára sí ìfẹ̀hónúhàn lóríi òpópónà ní àwọn ìlú ńlá ní Nàìjíríà bíi Èkó àti Àbújá. |
|
Ìpẹ̀sí àkíyèsí ilé ìjọsìn náà #ChurchToo movement rọ ìjọba láti dá “ọ̀ràn-an ìjìyà obìnrin àti ọmọdébìnrin dúró.” |
|
Ilé ìjọsìn náà #ChurchToo ṣípaya ìdákẹ́ rọ́rọ́ àmọ́ "ìbàjẹ́ àṣà ìfipábánilòpọ̀ tí ó ń gbèrú, pàápàá jù lọ ní agbo ìjọsìn" ní Nàìjíríà. |
|
Ó fún àwọn obìnrin ní àǹfààní láti wí ti ẹnu wọn. |
|
Bíi ti #ChurchToo, ike tàntàn eré ìfẹ́ fún ojú-àmì ẹ̀kọ́ #SexForGrades ti fẹ́ ìdí ìlòkulò agbára tí ó bí ìwà àṣemáṣe ti ìbánilẹ́gbẹ́pọ̀ tí àwọn obìnrin kò fi tọkàntọkàn fẹ́ síta gbangba. |
|
Ǹjẹ́ àmì orí ayélujára yìí yóò ṣe amọ̀nàà ìgbèsè ètò tí kì í ṣe ti orí ayélujára tí yóò béèrè fún àtúnṣe tí yóò sọ ilé ẹ̀kọ́ gíga ìmìtìtì di ibi ààbò fún àwọn obìnrin bí? |
|
Ìgbà àti àkókò nìkan ni yóò sọ. |
|
Ilé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ orin kíkọ kan ṣoṣo ní Zanzibar ti fẹ́ di títì pa |
|
Ilé-ẹ̀kọ́ Orin Kíkọ Àwọn Orílẹ̀-èdè Dhow f'orin s'árugẹ àṣàa Swahili |
|
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti Iléèwé Orin kíkọ́ Àwọn Orílẹ̀-èdèe Dhow (DCMA) ń fi qanún, fèrè, ìlù àti duru ní Ilé Àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aṣọ́bodè Àtijọ́, ní Stone Town, Zanzibar, 2019. DCMA ló ní àwòrán. |
|
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àlejò tí ó ń rọ́ wìtìwìtì wá sí ìlú Stone Town, Zanzibar tí ó kún fún ìṣẹ̀lẹ̀ àtẹ̀yìnwá, ti tẹ̀lé ìró orin Iléèwé Orin kíkọ Àwọn Orílẹ̀-èdèe Dhow (DCMA), ilé ẹ̀kọ́ orin kíkọ tí ó ń ṣe ìgbélárugẹ àti ìpamọ́ àwọn àṣà orin erékùṣù náà tí ó sún mọ́ Swahili ní ẹ̀báà Omi Òkun Íńdíà. |
|
Láti ọdún-un 2002, ilé ẹ̀kọ́ náà ti ṣe ìgbélárugẹ àti ìpamọ́ àkójọpọ̀ orin Lárúbáwá, India àti Ilẹ̀ Adúláwọ̀ tí kò lélẹ́gbẹ́. |
|
Lẹ́yìn-in ọdún kẹtàdínlógún, iléèwé náà kò rí owó tí ó tọwọ́ nínú àpò ìkówó sí tí ó sì leè fa kí iléèwé náà ó di títì pa. |
|
Nínú ìwé ìgbéròyìnjáde tí àwọn aláṣẹ DCMA tẹ̀ jáde, ìdá àádọ́rin nínú àwọn ọgọ́rin akẹ́kọ̀ọ́ ni kò rí owó iléèwé wọn tí ó tó bíi $13 USD lóṣù san. |
|
Pẹ̀lú àtìlẹ́yìn àwọn onínúure tí ó ti dáwọ́ fún iléèwé náà, owó tí ó kù ní sísan sì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ wípé, ó ṣe é ṣe kí ìlẹ̀kùn-un iléèwé náà tí ó wà nínú Ilé Àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aṣọ́bodè Àtijọ́. |
|
Láìsí owó tí ó tówó nílẹ̀ láti tẹ̀síwájú, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ DCMA àti òṣìṣẹ́ ń fòyà kí ìró amọ́kànbalẹ̀ tí ó ń sun jáde láti inúu gbọ̀ngàn olókìkí ilé ẹ̀kọ́ yìí tí ó mú erékùṣù yìí kọrin — leè wọ òkùnkùn. |
|
Orin àti ìgbélárugẹ àṣà àti àjogúnbá nìkan kọ́ ni ilé ẹ̀kọ́ náà fi gbajúmọ̀, àmọ́ ó jẹ́ ilé fún àwọn ọ̀dọ́ tí ó ń wá ibi tí wọn yóò ti fi ìmọ̀ kún ìmọ̀. |
|
Akẹ́kọ̀ọ́ DCMA kan ń kọ qanún, ohun èlò orin ayédaade orin taarab. Àwòrán láti iléèwé DCMA. |
|
"A [ti bẹ̀rẹ̀] sí í ní rí ìdojúkọ ìgbà tí ó nira", alákòóso àgbàá DCMA, Alessia Lombardo sọ, nínúu àwòrán fídíò DCMA kan. |
|
Láti ìsinsìnyí lọ títí di oṣù mẹ́fà sí àsìkò yìí, a kò rí àrídájú tí ó rinlẹ̀ wípé a ò leè san owó oṣù àwọn olùkọ́ni àti òṣìṣẹ́ẹ". |
|
Ní àkókò tí a wà yìí, àwọn àkàwé-dàgbà olùkọ́ 19 àti àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn ti ṣiṣẹ́ fún oṣù mẹ́ta gbáko láì gba owó lọ sílé nítorí àìsí owó nínúu kọ́lọ iléèwé. |
|
Gẹ́gẹ́ bí Ilé Ìfowópamọ́ Àgbáyé ṣe ti ṣàlàyé wípé, pẹ̀lú bí a ti ṣe mọ agbègbè tí iléèwé náà wà fún ibi ìrìn-àjò ìgbafẹ́ nítorí àwọn etíkun àtijọ́ àti ilé ìtura olówó ńláńlá tí ó kángun síbẹ̀, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ló ń bá àìníṣẹ́ lọ́wọ́ pọ̀ ọ́ pàápàá bí iṣẹ́ ṣe ti gbé fúkẹ́ ju ti ìgbà kan lọ. |
|
Fún ọdún mẹ́tàdínlógún, DCMA ti ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó nípa lílo orin ṣe ìgbélárugẹ tòun ìpamọ́ ọ̀rọ̀ àjogúnbá àti àṣà Zanzibar. |
|
Orírun àwọn olóhùn-iyọ̀ akọrin taarab, Siti Binti Saad àti Fatuma Binti Baraka, tí a tún mọ̀ sí Bi. Kidude, Zanzibar ni ilé èyí-ò-jọ̀kan orin tí ó ti inúu ìbákẹ́gbẹ́papọ̀ àṣà àti àjọṣe ọlọ́dún gbogboró tí ó wà láàárín àwọn àdúgbò ẹ̀ka Swahili. |
|
Láyé òde òní, akẹ́kọ̀ọ́ leè kọ orin ìbílẹ̀ bíi taarab, ngoma àti kidumbak, pẹ̀lú àfikún àwọn ohun èlò ìkọrin bíi ìlú ní onírananran, qanun àti oud, gẹ́gẹ́ bí alápamọ́ — àti ongbifo — àṣà àti ìṣe. |
|
Neema Surri, a ta violin ní DCMA, tí ń kọ́ bí a ti ṣe ń ta ohun èlòọ̀ violin láti ọmọdún mẹ́sàn-án mẹ́nu lé ọ̀rọ̀ nínú àwòrán fídíò DCMA náà. |
|
"Mo mọ àwọn ọ̀dọ́mọdé tí ó máa nífẹ̀ẹ́ sí kíkọ orin ṣùgbọ́n wọn kò leè san owó ìmẹ̀kọ́ tí ó jẹ́ owó iléèwé nítorí wípé wọ́n kúṣẹ̀ẹ́ wọn kò sì ní iṣẹ́ lọ́wọ́ ". |
|
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́o DCMA ń fi ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín kọrin kọrin nínú Ilé Àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aṣọ́bodè Àtijọ́, níbití ìiléèwé náà fi ìkálẹ̀ sí, ní Stone Town, Zanzibar, lọ́dún-un 2019. Àwòrán jẹ́ ti iléèwée DCMA. |
|
Ní ìparí àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ọ DCMA, tí wọ́n ti gba ìwé ẹ̀rí àti ní òpin ẹ̀kọ́ ọlọ́dún kan, púpọ̀ nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ọ DCMA ni ó ti di àgbà ọ̀jẹ̀ tí wọ́n sì í ṣeré lórí ìtàgé kárí ayé. |
|
Ọmọ bíbíi Zanzibar, tí ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ DCMA nígbà kan rí, tí ó jẹ́ olùkọ́ni ní iléèwé kan náà báyìí, Amina Omar Juma tóun ti ìlú mọ̀ọ́kà ẹgbẹ́ akọrin rẹ̀, tí ó ń "fi àṣà ìró orin ìbílẹ̀ " taarab papọ̀ mọ́ ti ìgbàlódélọ kọrin, ìyẹn "Siti àti Ẹgbẹ́ ", ṣẹ̀ṣẹ̀ padà wọ̀lú láti ìrìnàjò orin kíkọ kan ní orílẹ̀-èdèe South Africa. |
|
Òun, àwọn díẹ̀ nínú ẹgbẹ́ akọrin rẹ̀ àti àpapọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ DCMA ní ìgbà kan rí ṣe àgbéjáde àwo orin wọn àkọ́kọ́, "Fusing the Roots", ní ọdún-un 2018, tí ó mú wọn óì ńg o òǹwòran lára yá ní Sauti za Busara, tí í ṣe àjọ̀dún orin kíkọ tí ó gbáradì jù lọ ní Ìlà-oòrùn Ilẹ̀ Adúláwọ̀. |
|
Hihayin ni orin Siti àti Ẹgbẹ́ “Níèwé” (“Gbọ́ mi yeke”) àti àwòrán orin náà, tí ó ṣe àfihàn-an àwòrán-an, tí ó sọ ìtàn obìnrin kan tí ó ń rí ìdojúkọ abẹ́-ilẹ̀, tí ó sì ń dárò ara rẹ̀. Ìtàn náà jọ ti Omar Juma fúnra rẹ̀: |
|
Kà síwájú sí i: Àwọn akọrin lóbìnrin Ìlà-Oòrùn Ilẹ̀ Adúláwọ̀ kọrin tako àìfàyè gba obìnrin àwọn ọkùnrin. |
|
Ìtàn nípa àyálò àṣà àti àjọṣepọ̀ |
|
Ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àlejò ni ó ti wo eré, gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti bá àwọn akọrin lóríṣìírí ọjọ́ ọ̀la ní iléèwé olókìkí náà ní gbólóhùn rí. |
|
Iléèwé náà ti ṣe àyálò àti àmúpapọ̀ ọ̀kan-ò-jọ̀kan àṣà "àwọn orílẹ̀-èdè dhow", tí ó wà ní ìtòsíi Òkun Íńdíà àti Ọ̀gbun-un Persia. |
|
Àgbègbèe Omani Sultanate, tí ó jẹ́ " ibi gbòógì àwọn alágbára atukọ̀ orí omi ní ọgọ́rùn-ún Ọdún-un kẹtàdínlógún sí kọkàndínlógún sẹ́yìn", gbé àga agbára rẹ̀ láti Muscat sí Zanzibar ní ọdún-un 1840. |
|
Láti Stone Town, àwọn ọba Omani ń tukọ̀ okòwò orí omi ìgbà náà tí ó fẹjú, títí kan kànàfù, wúrà, àti aṣọ, látàrí àwọn ìjì líle tí ń tú àwọn ọkọ̀ ìbílẹ̀e Lárúbáwá — dhows — ní oríi Òkun Indian, láti India sí Oman títí lọ dé Ìlà-Oòrùn Ilẹ̀ Adúláwọ̀. |
|
Àwọn ọ̀dọ́ ní Zanzibar mọ ríi ìṣẹ̀lẹ̀ àtẹ̀yìnwá tí ó ní ohun ńlá ní í ṣe fún ọjọ́ ọ̀la wọn, ni wọ́n fi ń ṣe àdàlù èyí tí a rí nínú àwọn orin òde òní tí wọ́n ń gbé jáde. |
|
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ni DCMA ṣe ìdásílẹ̀ẹ "TaraJazz" láì pẹ́ yìí, èyí tí ó jẹ́ àdàlù orin ìbílẹ̀ taarab àti orin Jazz òde òní. |
|
Ata violin, Felician Mussa, ọmọ ogún ọdún, ti ń kó ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín náà fún ọdún mẹ́ta àtààbọ̀; TaraJazz jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹgbẹ́ akọrin tí ó àwọn ènìyàn máa ń pé sí òde jù lọ ní àwọn erékùṣù náà, ni ó wà nínú àwòrán tí ayàwòrán tí Aline Coquelle yà: |
|
Àgbègbèe Swahili sọ ìtàn pàṣípààrọ̀ àṣà ìbílẹ̀ tí DCMA sì ń tẹ̀síwájú nínúu rẹ̀ pẹ̀lú àjọṣepọ̀ àwọn orin-in rẹ̀. |
|
Lọ́dọọdún, iléèwé náà máa ń gbàlejò fún ètò tí a pè ní "Ìkọ̀lù Swahili", tí ó mú akójọpọ̀ àgbà akọrin láti Ilẹ̀-Adúláwọ̀, Ìlú Abẹ́-àgbáyé Lárúbáwá, Ilẹ̀ Èròòpù àti Àríwá Amẹ́ríkà pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ DCMA láti ṣe orin láàárín ọ̀sẹ̀ kan. |
|
Ní ìgbẹ̀yìngbẹ́yín "ìkọlù" náà, akójọpọ̀ tuntun náà yóò ta bí ẹlẹgbẹ́ ní Sauti za Busara, tí àjọṣepọ̀ wọ̀nyí yóò sì di ìbáṣepọ̀ ọlọ́jọ́ pípẹ́ tí kò mọ ìyàtọ̀ èdè àti àṣà, tí ó fi hàn gbangba walia wípé èdè kan náà tí gbogbo ayé gbọ́ ni orin. |
|
DCMA máa ń ṣe àgbékalẹ̀ ètò orin kíkọ tí ó ń ṣe ìgbélárugẹ ẹ̀bùn orin kíkọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti àfihàn àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ọ̀kọrin àlejò hàn ní, Stone Town, Zanzibar, 2019. DCMA ni ó ní àwòrán. |
|
DCMA mọ rírì orin gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó leè ro àwọn ènìyàn lágbára àti gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó lè mú ìṣọ̀kan àti ìrẹ́pọ̀ bá àwọn ènìyàn láì wo ti àṣà — ó sì tún ń pèsè àǹfààní iṣẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́ tí ó ní ẹ̀bùn àmọ́ tí ó ń tiraka láti jẹ. |
|
Fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 1,800 tí ó ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní DCMA, èyí nìkan ni ibi ilé orin tí wọ́n mọ̀, níbi tí wọ́n ti ń kọ́ ẹ̀kọ́ tí wọ́n sì ti ń ní àlékún ìmọ̀ nípa iṣẹ́ orin kíkọ àti bí a ṣe ń di òǹkọrin. |
|
Arìnrìn-àjò kan láti Spain, tó bẹ DCMA wò ni kò pé yìí, kò sí oríi TripAdvisor: "Ní tèmi, ìsálàbàápàdée àwọn akọrin ní ìgbà tí ó meet jù lọ fún mi ní erékùṣù yìí". |
|
Bí ẹ̀ka ìrìn-àjò afẹ́ẹ̀ Zanzibar ṣe ń gbèrò sí i, DCMA nígbàgbọ́ wípé orin ní ipa kan gbòógì ní í ṣe nínú àjọyọ̀, ìpamọ́ àti ìgbélárugẹ tòun ìpolongo àṣà, àjogúnbá àti ìṣẹ̀lẹ̀ àtẹ̀yìnwá Swahili. |
|
Zanzibar ju àwọn etíkun àti ilé ìtura olówó iyebíye rẹ̀ lọ — ó jẹ́ ibi tí ó kún fún àwọn ènìyàn ọlọ́pọlọ tí ó ní ẹ̀bùn ní gbáàtúù orí wọn látàrí àjọṣepọ̀ ọlọ́jọ́ pípẹ́ tí ó mú àgbègbè náà dá yàtọ̀ gédégbé. |
|
Ìfiyèsí Alákòóso Ìwé Títẹ̀: Òǹkọ̀wé àtẹ̀jáde yìí ti ṣiṣẹ́ ọ̀fẹ́ pẹ̀lú DCMA. |
|
Ìṣọ̀de-ajé sì ń gba ẹ̀mí àwọn ènìyàn ní ìgbèríko Íńdíà |
|
Superstition and lack of awareness behind witch-hunting in India |
|
Ilétó kan ní ẹ̀báà Jamshedpur ní Jharkhand. Àwòrán láti ọwọ́ọ Anumeha Verma |
|
Ní ọjọ́ 20 oṣù Agẹmọ, àgbájọ àwọn ènìyànkénìá gba ẹ̀mí àwọn àgbàlagbà mẹ́rin kan láì dá wọn lẹ́jọ́ ní agbègbèe Gumla ní Jharkhand, India lẹ́yìn tí a fi ẹ̀sùn-un àjẹ́ kàn wọ́n. |
|
Gẹ́gẹ́ bí ìjábọ̀ ìròyìn, àwọn àgbàlagbà wọ̀nyí ṣe ikú pa ọkùnrin kan, ni ìgbìmọ̀ abúlée Panchayat ṣe dá wọn lẹ́bi. |
|
Wọ́n wó àwọn àgbàlagbà mẹ́rin wọ̀nyí jáde síta ilée wọn, àwọn ọkùnrin tí ó bojú sì fi igi lù wọ́n títí tí èmi fi bọ́ lára wọn. |
|
Mẹ́jọ nínú àwọn ènìyànkénìá wọ̀nyí ti wà ní akóló ọlọ́pàá. |
|
Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ọlọ́pàá ti Times of India tẹ̀jáde, ìṣọ̀tẹ̀-ajé ní Jharkhand ti rán àwọn ènìyàn 123 sọ́rùn apapandodo ní àárín-in oṣù Èbìbí ọdún-un 2016 sí oṣù Èbìbí ọdún-un 2019. |
|
Jákèjádò, ènìyàn 134 di ẹni ebora-ń-bá-jẹun látàrí ẹ̀sùn-un lílo “ogún” ní ọdún-un 2016, ìyẹn gẹ́gẹ́ bí Àjọ Àṣàkọ̀sílẹ̀ Ẹsẹ̀ Orílẹ̀-èdè náà ṣe kọ̀ ọ́ sílẹ̀. |
|
Àrùn T’ó Ń Peléke Sí i |
|
"Ìsòde-ajé kò jẹ́ tuntun ní Jharkhand", Prem Chand, Olùdásílẹ̀ àti Alága Free Legal Aid Committee (FLAC) ní Jharkhand, sọ nínúu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò orí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ kan. |
|
FLAC ti ń ṣe atọ́nàà ìṣòfin tí ó tako ìṣode-ajé ní Jharkhand. |
|
Iléeṣẹ́ náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní agbègbè yìí ní ọdún-un 1991 nígbà tí àwọn aládùúgbò fi ẹ̀sùn kan obìnrin kan pé ó lọ́wọ́ nínú ikú ọmọdékùnrin kan. |
|
Àgbájọ àwọn ènìyànkénìá kan dìgbò lù ú, wọ́n sì pa ọkọ àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin. |
|
Òun fi ara pa. |
|
Nígbàtí Prem Chand àti àwọn ẹlẹgbẹ́ẹ rẹ̀ ṣe ìbẹ̀wò sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wọ̀nyí nínúu túbú, wọ́n bá ìpèníjà: |
|
Wọ́n sọ fún wọn wípé àwọn dúró lé oríi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn. |
|
Wọ́n sì tún gbàgbọ́ wípé bí ẹ̀jẹ̀ẹ̀ ẹni tí a pè ní àjẹ́ bá kan ilẹ̀ ọ̀gbẹlẹ̀, yóò pàdánù agbára elése rẹ̀. |
|
Prem Chand sọ wípé ó kan apá kan nínú àwọn ọmọ ìlú: |
|
Nísinsìnyí, àwọn obìnrin tí kò lára tí ò tálákà ní í máa ń fi ara káàsà. |
|
Bí ìkùgbù bá fẹ́ tẹ̀, a ní kí lọba ó ṣe? |
|
Bí iná bá dún ọbẹ̀, a da ọ̀rọ̀ sọ. |
|
Bí kò sí àkópọ̀, kí leère wá dé ìṣọ́ adìẹ? |
|
Bí kò sí tàánú èèyàn, ta ni ìbá jí lówùúrọ̀ tí kò bójú ṣàṣà? |
|
Bí mo bá torí ọkọ̀ kú n ò ro fàlàlà; bí mo bá torí ọ̀gẹ̀dẹ̀ kú n ò ro fodo; bí mo bá torí alábàájà òkìkí kú, n ò ro foríi mi. |
|
Bí ó di ọdún mẹ́ta tí ẹ̀kún-ún ti ń ṣe òjòjò, olùgbé la ó ha rán lọ bẹ̀ ẹ́ wò? |
|
Bí ọ̀fọ̀ ti ń fò la ti ń mọ̀ ọ́ akọ ẹyẹ. |
|
Bí òkú fẹ́, bí kò fẹ́, ká bi ọmọ ọlọ́kùú léèrè. |
|
Bí ojú bá rí, ẹnu á dákẹ́. |
|
Bí ojú kò bá rí, ẹnu kì í sọ nǹkan. |
|
Bí ojú kò bá ti olè, a ti ará ilé ẹ̀. |
|
Bí ojú onílé bá mọ tintin, tí ojú àlejòó tó gbòǹgbò, onílé ní ń ṣe ọkọ̀ àlejò. |
|
Bí olóde ò kú, ọ̀dẹ̀dẹ̀ rẹ̀ kì í hu gàgá. |
|
Bí olóògùn bá rọ́jú á fi àìjẹ́ tẹ́ ẹ. |
|
Bí ọdún bá dún, bonnonnon á pawọ́ dà. |
|
Bí ọjàa bá tú tán, a kú olóríi pàtẹ́wọ́, a kú àgbààgbà sá-ńkọ́ sá-ńkọ́ lọ́jà; bIfá bá pàdí tán, ìwọ-n-wọ á dìde. |
|
Bí ọjọ́ ewúrẹ́ bá pé, á ní kò sí ohun tí aládànù lè fi òun ṣe. |
|
Bí olè ò lè jà, a lè kú túẹ́. |
|
Bí Ọlọ́run ò ṣe ẹni ní baba, a fi ìyànjú ṣe bí àgbà. |
|
Bí ọmọdé bá fẹ́ ṣiṣẹ́ àgbà, ọjọ́ oríi rẹ̀ ò níí jẹ́. |
|
Bí ọmọdé bá gun òkè àgbà, ó níláti gbọ́n. |
|
Bí ọmọdé bá ń ṣe ọmọdé, àgbà a máa ṣe bí àgbà. |
|
Bí ọmọdé ń lérí bẹ̀bẹ̀, tí kò ní baba, ti bàbá là ń ṣe. |
|
Bí Ọ̀ya ń kọ́ lọ́rùn, bí Ṣàngó ń jó láyé, kò níí burú fún bàbá kó ní ó dọwọ́ ọmọ òun lọ́rùn. |
|
Dígbòlùgì-gàgáùyàn ò jẹ́ ká mọ ajá tòótọ́. |
|
Dídákẹ́ lẹ́rìn dákẹ́; àjànàkú ló lẹ́gàn. |
|
Egungun ju eegun; òrìṣà ju òrìṣà; Paaka lé onísàngó wọ̀gbẹ́. |
|
Eegun ó na obìnrin lágo; obìnrin tú kijipa ìdíi rẹ̀, ó fi na eegun. |
|
Ẹ̀gún pẹ́ lóde, ó fọ́tẹ̀ òkè dáhùn; wọ́n ní, “Baba kú abo,” ó ní, “Hi ìì.” |
|
Eegun wọlé, ó ní òun ò rí Ejonto; Ejonto ni, “Àkísà ni, àbí kíni wọlé?” |
|
Ẹ̀gún àjànàkú: ó há ìkòkò lẹ́nu. |
|
Ẹ̀ẹ̀gbọ̀n so mọ́ ayínrin lẹ́nu, a ní kí adìẹ wá yàn án jẹ; adìẹ mọ̀ pé òun náà oúnjẹ àyínrìn. |
|
Ẹjọ́ kì í ti ojú Ààrẹ gun ọgbà lọ. |
|
Èmi dáko okoò, ìwọ dáko okoò, ó ń pèmi ní múkọ́-múkọ́. |
|
Èmi ìwọ̀fà, ìwọ ìwọ̀fà, ó ní baba ní ká gbọ́wọ́ wa; ó dá tìrẹ sílẹ̀ ná? |
|
Epo ni mo rù; oníyangi má ba tèmi jẹ́. |
|
Ẹ̀rín kì í fọn kọ́mọọ rẹ̀ ò fọn. |
|
Èrò ọ̀nà ni yó ròyìn ọkà tó gbó. |
|
Èṣùrù ṣe fujà ò tẹ̀ lọ́wọ́ oníyàn; aláǹgbá ṣe fujà ò tẹ̀ lọ́wọ́ ògiri; Ọlámọ̀nrín àjàpà ṣe fujà ò tẹ̀ lọ́wọ́-ọ mi. |
|
Etí lobìnrin fi ń gbọ́ ohùn ọ̀rọ̀. |
|
Èwo ló tọ́ ẹ̀kọ́ọ́ gbà nínú ewé ìrùgbàá? |
|
Èwo ni ti Sikira nílùú Ìwọ. |
|
Ewujú tí yóò tú ọpẹ́: gbogbo ẹ̀yin ẹ̀ ni yóò kàn tán. |
|
Ewúrẹ́ ò wí pé òun ò sọ́mọ àgùntàn; àgùntàn ló wí pé òun ò sọ́mọ ewúrẹ́. |
|
Ewúrẹ́ kì í bíni ká lo sísọ àgùntàn ló jẹ́. |
|
Èèyàn bí ọ̀bọ lọ̀bọ̀ ń ya láṣo. |
|
Èèyàn ò ríbi sùn, ajá ń hanrun. |
|
Èèyàn tí ò nítìjú ojú kan ni ìbá ní; a gbọ́rin a tó tẹ̀rín. |
|
“Ẹ fà á wọlé” ló yẹ ẹlẹ́sìn. |
|
Ẹ jẹ́ ká mí, ẹ jẹ́ ká simi; èèyàn ní ń fìdí èèyàn jókòó; èèyàn ìbá ṣe bí Ọlọ́run kò níí jẹ́ ká mí. |
|
“Ẹ kúúlé” ò yé ará ilé; “Ẹ kú àtibá” ò yéni tí ń tẹ̀dó bọ̀; ẹni tí ó kí ẹni, “Kú àtibá”-á pàdánù “Ẹ kúúlé.” |
|
Ẹ̀jẹ̀tí ẹnu ò tàsé. |
|
Ẹgbẹ́ ẹni là ń gúnyán ewúrẹ́ dé. |
|
Ègbérí ò mọ̀ pé arẹwà kì í gbé eku; gbogbo ẹ̀yìn kìn-kìn-kín lábẹ́ aṣọ. |
|
Ẹ̀gbọ́n síwájú ó so aṣọ kọ́; àbúrò kẹ́yìn ó wéwu; bí a ó mọ́lẹ̀, olè ò mọ araa rẹ̀? |
|
Eléèébù ń lo èébù, ó ní “Èébùgbẹ́ta ni àbí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà?”; èwo ló gbé níbẹ̀? |
|
Elédè ń pàfọ̀, ó rò pé òun ń ṣògì. |
|
Elédè ò mẹ́yẹ. |
|
Eleefa kì í lo eéfàá rẹ̀ ká sọ pé ó di ìjẹfà tí a ti jẹun. |
|
Ẹni a bá fi sọ̀kò kó dáparò, ó ní òun ẹni ilẹ̀. |
|
Ẹni a bá ta ká fowóọ rẹ̀ ra àdá: ó ní ìyà àdá ń jẹ òun. |
|
Ẹni a bá ta ká fowóọ rẹ̀ ra àtùpà: ó ní òun a-jí-ìmọ́lẹ̀-wò-lóru. |
|
Ẹni a bá ta ká fowóọ rẹ̀ ra ègé: ó ní ègé òun kó ọ̀ọ́dúnrún. |
|
Ẹni à ń gbé gẹ̀gẹ̀ ni yó ba araa rẹ̀ jẹ́. |
|
Ẹní bá dẹ ojúu rẹ̀ sílẹ̀ á rímúú rẹ̀. |
|
Ẹní dádé ti kúrò lọ́mọdé. |
|
Ẹni tí a bá ń dáṣọ fún kì í ka èèwọ̀. |
|
Ẹni tí a fẹ́ yàtọ̀ sí ẹni tó ní kò sí irú òun. |
|
Ẹni tí a gbé gun ẹlẹ́dẹ̀, ìwọ̀n ni kò yọ̀ mọ́; ẹni tó gẹṣin, ilẹ̀ ló ń bọ̀. |
|
Ẹni tí a lè gbé kì í dáwọ́. |
|
Ẹni tí a ń wò láwò-sunkùn ń wo araa rẹ̀ láwò-rẹ́rìn-ín. |
|
Ẹni tí a ò fẹ́, àlọ́ ò kàn án. |
|
Ẹni tí a ò fẹ́ nílùú kì í jọ lójú agbo. |
|
Ẹni tí ìbá hùwà ipá ò hùwà ipá; ẹni tí ìbá hùwà èlé ò hu èlé; okùn tó nígbà ọwọ́, tó nígbà ẹ̀ṣẹ̀ ń hùwà pẹ̀lẹ́. |
|
Ẹni tí kò lè gbé èèrà, tí ń kúṣá sí ẹ̀rín, títẹ̀ ní ń tẹ̀. |
|
Ẹni tí kò rí ayé rí ní ń sọ pé kò sẹ́ni tó gbọ́n bí òun. |
|
Ẹni tó tan araa rẹ̀ lórìṣà òkè ń tàn: àpọ́n tí ò láya nílé, tó ní kí òrìṣà ó pọ́n un lọ́mọ. |
|
Ẹni tí kò tó gẹlẹtẹ kì í mí fín-ín. |
|
Ẹni tó tijú tì í fún araa rẹ̀. |
|
Ẹnìkan kì í jẹ́ “Àwa dé.” |
|
Ẹran kí la ó jẹ rí? Ọpọlọ báni lábàtà ò bá burúburu. |
|
Ẹrúkò ń ṣe bí ọkọ̀. |
|
Èso kì í gba ọfà lẹ́yìn; iwájú gangan ní ń fií gba ọgbẹ́. |
|
Ẹ̀wọ̀n tó tó ọ̀pẹ ó tóó dá ẹ̀rín dúró; ìtàkùn tó ní kí erin má ròkè ọ̀dàn, tóun tẹ̀rín ní ń lọ. |
|
Ẹ̀yà ló bí mi, ẹkún ló wò mí dàgbà, ọlọ́gọ̀gọ̀ gbá mi tọ́; bí kò ṣèràn lọ́bẹ n kò jẹ. |
|
Ẹyẹ àkọ́kọ́ó ní òun lè gbé odò; ta ní jẹ́ fi odò àkọ́kọ́ gúnyán jẹ? |
|
Ẹyẹ ò lè rí omi inú àgbọn bù mu. |
|
Ẹyẹ tó fi ara wé igún, ẹ̀yìn igbá ní ń sun. |
|
Falana gbọ́ tirẹ̀, tara ẹni là ń gbọ́. |
|
Faari ọ̀bọ ò ju inú ìgbẹ́ lọ. |
|
Ganran-ganran ò yé ẹni á bíirè. |
|
“Gbà jẹ” ò yé àgbà. |
|
“Gbà mí, gbà mí!” ó yẹ àgbà; àgbà kì í ṣe ohun àlémú. |
|
“Gbà mí, gbà mí!” ò yé eégún; “ẹ̀ran ń lémi bọ̀” ò yé ọdẹ. |
|
“Gba wèrè,” “N ò gba wèrè” lọjà fi ń hó. |
|
Gbogbo èèyàn ní ń sunkún-un Banjo; ṣùgbọ́n Banjo ò sunkún ara ẹ̀. |
|
Gbogbo ẹgbẹ́ ń jẹ́ Ma-yẹ-lóyè, ó ń jẹ́ Sare-pegbe. |
|
Gbogbo ọ̀rọ̀ ní ń ṣojú èké. |
|
Gbọ́n-ọn-gbọ̀n-ọ́n kàn ò sí, àfi ẹni tó bá ń ti ara ẹ̀. |
|
Ìbàjẹ́ ọjọ́ kan ò tán bọ̀rọ̀. |
|
Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé tí a bá gbajúmọ̀ ẹ̀kọ́ àwọn obìnrin, a máa mú ìyàtọ̀ bá ìgbéayé wọn gidi gan, bákan náà ni àlàáfíà àwùjọ wọn. |
|
Ìdí nìyí tí mo fi jọ̀wọ́ ayé mi fún ètò-ẹ̀kọ́. |
|
Èyí wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìrònú mi nípa ìdọ́gba àti lílé dẹ̀dẹ̀ àwùjọ, nítorí tí ẹ bá fẹ́ ṣe àfikún ànfàní sí ètò-ìlera, ẹ nílò láti kọ́kọ́ ṣe àfikún ànfàní sí ìmọ̀ ìlera. |
|
Pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn alájọṣe, à ń kọ́ fásitì tó rẹwà ní ìgbèríko àríwá orílẹ̀-èdè Rwanda. |
|
À ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa láti pèsè ojúlówó, adọ́gba, ìtọ́jú àpapọ̀ fún gbogbo ènìyàn, láìyọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀, gbígbájúmọ́ àwọn tó kógun séwu, pàápàá jùlọ àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, tó ṣe pé nínú ìtàn àwọn ni ẹni ìgbẹ̀yìn láti gba ìtọ́jú. |
|
A ṣe àyípadà wọn sí aṣíwájú a sì fún wọn ní ìmọ̀ọ́ṣe ìṣàmójútó àti ìmọ̀ọ́ṣe ìjẹ agbẹnusọ kí wọ́n lè ṣe àyípadà tó dán mọ́rán ní àwùjọ tí wọ́n máa wà, kí wọ́n lè pèsè ètò ìlera tí yóò gbà wọ́n láyè láti ṣètọ́jú àwọn tó kógun séwu níbi tí wọ́n wà. |
|
Ó sì ti mú àyípadà wá. |
|
Torí lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí, ètò-ẹ̀kọ́ ìmọ̀-ìṣẹ́gun, fún àpẹẹrẹ, ni wọ́n ń kọ́ ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ tó wà nígboro, tó gbajúmọ̀ ojúlówó ètò-ìlera àti ìmọ̀ọ́ṣe, ìmọ̀ọ́ṣe ajẹ́mọ́-ìtọ́jú, tí yóò di gbígbà ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́. |
|
A tún gbajúmọ̀ ojúlówó ìmọ̀ọ́ṣe ajẹmọ́-ìtọ́jú ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọ̀nà-ìmúṣe àjọṣepọ̀ ìwà àti àwùjọ sí ipò-ìlera àwọn aláìsàn, láti lè ṣe ìtọ́jú ní àwùjọ tí àwọn ènìyàn ń gbé, pẹ̀lú gbígbé lọ sí ilé ìwòsàn nígbà tó bá pọn dandan nìkan. |
|
Bákan náà, lẹ́yìn ọdún mẹ́rin sí méje ètò-ẹ̀kọ́ ajẹmọ́-ìwòsàn nígboro, àwọn ọ̀dọ́ akẹ́kọ̀ọ́ jáde ó fẹ́ padà sí àwọn ìgbèríko. |
|
Ìdí nìyí tí a fi kọ́ Fásitì Ìdọ́gba Ètò-Ìlera Àgbáyé, ìgbésẹ̀ àwọn alájọṣepọ̀ nínú ètò-ìlera, tí wọ́n pè ní UGHE, ní ìgbèríko àríwá orílẹ̀-èdè Rwanda. |
|
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa wá láti mú àyípadà bá àgbáyé. |
|
Wọn yóò wá láti ibi gbogbo -- fásitì àgbáyé ní -- wọn yóò sì gba ètò-ẹ̀kọ́ ìmọ̀-ìṣègùn lọ́fẹ̀ẹ́ lábẹ́ àdéhùn kan: wọ́n ní láti ṣe ìtọ́jú àwọn tó kógun séwu jákèjádò àgbáyé láàrín ọdún mẹ́fà sí mẹ́sàn-án. |
|
Wọn yóò tọ́jú owó iṣẹ́ náà fún ara wọn àti àwọn ẹbí wọn ṣùgbọ́n wọn yóò yí ẹ̀kọ́ tí a fún wọn padà sí ojúlówó iṣẹ́ ajẹmọ́-ìwòsàn, pàápàá jùlọ fún àwọn akógun-séwu. |
|
Ṣíṣe èyí, wọn yóò tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn ní ìbéèrè pẹpẹ pé wọn yóò ṣe ìyẹn, àdéhùn òfin ni. |
|
A ò fẹ́ owó. |
|
A ní láti lọ pín owó náà yíká. |
|
Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ èyí di ìjábọ̀ iṣẹ́ fún gbogbo ènìyàn. |
|
Fún èyí, bẹ́ẹ̀ ni, a nílò ètò ìdọ́gba láàrín ọkùnrin àti obìnrin tó lágbára. |
|
Ní gbogbo yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ wa, abala ẹ̀kọ́ òye ìjìnlẹ̀, ó kéré ju ìdá àádọ́ta àwọn obìnrin. |
|
Inú mi dùn láti sọ pé fún ilé-ẹ̀kọ́ ìmọ̀-ìṣègùn tó bẹ̀rẹ̀ ní oṣù márùn-ún sẹ́yìn, a ti gba ìdá àádọ́rin àwọn ọmọdébìnrin. |
|
Èyí jẹ́ èsì tako àìdọ́gba lọ́wọ́lọ́wọ́ fún àwọn obìnrin láti ní ànfàní sí ètò-ẹ̀kọ́ ìmọ̀-ìṣègùn ní ẹkùn wa. |
|
Mo nígbàgbọ́ nínú ètò-ẹ̀kọ́ àwọn obìnrin. |
|
Ìdí nìyí tí mo fi gbóríyìn fún àwọn obìnrin nílẹ̀ Adúláwọ̀ tí wọ́n ń lọ káàkiri àgbáyé láti ṣe àfikún sí ẹ̀kọ́ wọn, ìmọ̀ọ́ṣe wọn àti ìmọ̀ wọn. |
|
Ṣùgbọ́n mo lérò wí pé wọn yóò mú ìyẹn padà wá sílẹ̀ Adúláwọ̀ láti jẹ́ kí ẹkùn náà gbòòrò kí wọ́n sì sọ ẹkùn náà di agbègbè alágbára, nítorí ó dámi lójú pé ilẹ̀ Adúláwọ̀ tó lágbára yóò sọ orílẹ̀-èdè àgbáyé di alágbára. |
|
Ọdún mẹ́tà-lé-lógún sẹ́yìn, mo padà lọ sí orílẹ̀-ède Rwanda, sí orílẹ̀-ède Rwanda tó ti túká, tó sì jẹ́ orílẹ̀-èdè tó kùṣẹ̀ẹ́ ṣùgbọ́n tó ń tàn pẹ̀lú ọjọ́-ìwájú rere. |
|
Mo kún fún ayọ̀ láti padà wá, kódà tí àwọn ọjọ́ kan bá le koko, tó sì jẹ́ wí pé àwọn ọjọ́ kan mo ní ìrẹ̀wẹ̀sì, nítorí mi ò rí ọ̀nà àbáyọ àwọn ènìyàn ṣì ń kú, tàbí ǹkan ò lọ dáadáa. |
|
Ṣùgbọ́n inú mi dùn láti lọ́wọ́ sí àyípadà àwùjọ mi. |
|
Èyí sì ń jẹ́ kí n kún fáyọ̀. |
|
Nítorí náà, àwọn obìnrin ilẹ̀ Adúláwọ̀ láti ilẹ̀-adúláwọ̀, tí ẹ bá ń gbomi, má gbàgbé ilẹ̀ẹ rẹ. |
|
Tí ẹ bá ti ṣetán, ẹ padà wálé. |
|
Mo ṣe bẹ́ẹ̀. |
|
Ó ti jẹ́ kí ayé mi ní àṣeyọrí. |
|
Nítorí náà, ẹ padà wálé. |
|
Ẹ ṣeun. |
|
Bí ìpéjọpọ̀ tí àwùjọ léwájú rẹ̀ ṣe lè dóòlà àwọn ẹranko igbó. |
|
Mo jẹ́ olùkọ́pamọ́ kinníhun. |
|
Ó dùn-ún gbọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? |
|
Àwọn ènìyàn kan lè má ní òye ǹkan tí èyí túmọ̀ sí. |
|
Ṣùgbọ́n ó dámi lójú wí pé gbogbo yín lẹ ti gbọ́ nípa Cecil kíníhun náà. |
|
[Cecil kinníhun náà (2002-2015)]. |
|
(kínihun tó ń bú ramúramù-ramu). |
|
Kò bú ramúramù-rókè mọ́ |
|
Ní ọjọ́ kejì oṣù Agẹmọ, ọdún 2015, wọ́n dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò nígbà tí ọdẹ apẹranko igbó kan pa á. |
|
Wọ́n sọ wí pé ẹ lè fẹ́ràn ẹranko tí ẹ̀ ń kọ́ nípa rẹ̀. |
|
Bí ó ṣe rí fúnmi àti Cecil kíníhùn náà nìyẹn, lẹ́yìn tí mo ti mọ̀ ọ́ tí mo sì ti mọwà rẹ̀ fún ọdún mẹ́ta ní ààyè-ìgbafẹ́ àpapọ̀ Hwange. |
|
Ikúu rẹ̀ bàmí lọ́kàn jẹ́. |
|
Ṣùgbọ́n ǹkan rere kan tó jáde láti ibi àjálù burúkú yìí ni àkíyèsí tí ìtàn yìí múwá nípa ẹ̀hónú àwọn ẹranko igbó tí wọ́n wà nínú ewu. |
|
Lẹ́yìn ikú Cecil, mo bẹ̀rẹ̀ síní bi ara mi ní àwọn ìbéèrè wọ̀nyí: tí ó bá jẹ́ wí pé àwùjọ tí wọ́n ń gbé lẹ́gbẹ́ kínihùn náà lọ́wọ́ sí ààbò rẹ̀ ńkọ́? |
|
Tó bá ṣe wí pé mo ti mọ Cecil nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, yàtọ̀ sí ọmọ ọdún mọ́kàn-dín-lọ́gbọ̀n ńkọ́? |
|
Ǹjẹ́ èmi tàbí àwọn akẹgbẹ́ẹ mi ní yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ ìbá ti yí àyànmọ́ rẹ padà bí? |
|
Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ń ṣiṣẹ́ láti dẹ́kun kí kíkíhùn ó má pòórá mọ́, ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni wọ́n jẹ́ ọmọ onílù sí àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí tàbí láti àwùjọ tí ọ̀rọ̀ kàn jù. |
|
Ṣùgbọ́n àwọn àwùjọ tí wọ́n ń gbé pẹ̀lú àwọn kiníhùn náà ni wọ́n wà ní ipò tó dára jù láti ran àwọn kiníhùn náà lọ́wọ́. |
|
Àwọn ọmọ onílù ló yẹ kí wọ́n léwájúu wíwá ìyànjú sí àwọn ìpèníjà tó ń kojú àwọn ẹranko igbó. |
|
Nígbà míràn, àyípadà yóò wáyé nígbà tí àwọn ènìyàn tí ọ̀rọ̀ kàn tó sì nípa lára wọn jùlọ bá gbà á. |
|
Àwọn àwùjọ ìgbèríko ń kópa pàtàkì láti kojú pípa àti ọ̀wọ́ ẹranko igbó lọ́nà àìbófinmu, tí wọ́n jẹ́ olórí ewu tó ń dámú àwọn kiníhun àti àwọn ẹranko igbó mìíràn. |
|
Pé mo jẹ́ obìnrin aláwọ̀-dúdú ọmọ ilẹ̀ Adúláwọ̀ nínú ìmọ̀-ìjìnlẹ̀, àwọn ènìyàn tí mo máa ń padà máa ń nífẹ̀ẹ́ láti mọ̀ bóyá ó dára láti jẹ́ olùkọ́ pamọ́ ni, nítorí wọn kìí pàdé àwọn olùkọ́pamọ́ tí wọ́n jomi lọ́pọ̀lọpọ̀. |
|
Nígbà tí mò ń dàgbà, mi ò tiẹ̀ mọ̀ wí pé iṣẹ́-iṣẹ́ ni ìpéjọpọ̀ àwọn ẹranko igbó. |
|
Ìgbà àkọ́kọ́ tí mo rí ẹranko igbó ní orílẹ̀-èdè mi nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n, bó tilẹ̀ jẹ́ wí pé kiníhun àti àwọn ajá igbó ilẹ̀ Adúláwọ̀ ń gbé ní ibùsọ̀ díẹ̀ sí ilé mi. |
|
Èyí wọ́pọ̀ ní orílẹ̀-ède Zimbabwe, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ò lajú sí ẹranko igbó, bó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ó wà lára àṣà wa. |
|
Nígbà tí mò ń dàgbà, mi ò tilẹ̀ mọ̀ wí pé kiníhun ń gbé lẹ́yìn ilé mi. |
|
Nígbà tí mo dáṣẹ́ wo Save Valley Conservancy ní àárọ̀ olókìkìtì kan ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ajá igbó ilẹ̀ Adúláwọ̀ fún iṣẹ́ ìwádìí òye ìjìnlẹ̀ mi, ẹwà àti ìdábùú tó yími ká fàmí mọ́ra. |
|
Ó dàbí ẹni pé mo ti rí ohun tí mo nífẹ̀ẹ́ sí àti àyànmọ́ mi nílé ayé. |
|
Mo ṣe ìpinnu lọ́jọ́ náà pé màá fi gbogbo ayé mi dáàbò bo àwọn ẹranko. |
|
Mo ronú nípa àwọn ìgbà tí mo wà ní ilé-ẹ̀kọ́ èwe ní orílẹ̀-ède Zimbabwe àti àwọn ọmọ tókù tí a jọ wà ní ilé-ẹ̀kọ́. |
|
Bóyá tí a bá ti ní ànfàní láti farakínra pẹ̀lú ẹranko igbó ni, ọ̀pọ̀ nínú àwọn akẹgbẹ́ mi ní yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ ni a ó jọ máa ṣiṣẹ́ báyìí. |
|
Àyàfi tí àwọn àwùjọ ìgbèríko bá fẹ́ dáàbòbò tí wọ́n sì fẹ́ gbé pẹ̀lú ẹranko igbó, gbogbo ìgbìyànjú olùkọ́pamọ́ lè já sásán. |
|
Àwọn wọ̀nyí ni àwùjọ tí wọ́n ń gbé pẹ̀lú àwọn ẹranko igbó náà ní àyíká kan náà tí wọ́n sì ń fara gbá ṣíṣe bẹ́ẹ̀. |
|
Tí wọn ò bá ní àjọṣepọ̀ tààrà tàbí ànfàní látara àwọn ẹranko náà, wọn ò ní ìdí kankan láti dáàbò bò wọ́n. |
|
Tí àwọn àwùjọ ìgbèríko ò bá dáàbò bo ẹranko igbó wọn, kò sí iye ìdásí láti ìta tí yóò ṣiṣẹ́. |
|
Nítorí náà kí la nílò láti ṣe? |
|
Àwọn olùkọ́pamọ́ gbọdọ̀ mú ètò-ẹ̀kọ́ agbègbè lọ́kúnkúndùn kí wọ́n sì ṣe ìrànlọ́wọ́ láti gbọ̀ọ̀rọ̀gbọ̀ọ́ṣe àwùjọ láti ṣe ìpamọ́ àwọn ẹranko igbó wọn. |
|
Àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ àti àwùjọ gbọdọ̀ di mímú lọ sí àwọn àyè-ìgbafẹ́ àpapọ̀, kí wọ́n lè ní ànfàní láti ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ẹranko igbó. |
|
Fún gbogbo ìgbìyànjú àti gbogbo ìpele, ìpéjọpọ̀ gbọdọ̀ pẹ̀lú ọrọ̀-ajé àwọn ènìyàn tí wọ́n jíjó ń pín ilẹ̀ lọ pẹ̀lú àwọn ẹranko igbó. |
|
Ó tún ṣe pàtàkì pé kí àwọn olùkọ́pamọ́ agbègbè wà lára gbogbo ìgbìyànjú ìkópamọ́, tí a bá fẹ́ kí wọ́n gbà wá gbọ́ tí a sì fẹ́ fi ìkópamọ́ rinlẹ̀ sí àwùjọ lóòtọ́. |
|
Gẹ́gẹ́ bí olùkọ́pamọ́ agbègbè, a máa ń kojú ìṣòro tó pọ̀, láti ibi ẹlẹ́yàmẹ̀yà sí àwọn ìṣòro nítorí àṣà àti ìṣe. |
|
Ṣùgbọ́n mi ò ní jáwọ́ ìgbìyànjú mi láti mú àwọn ènìyàn àwùjọ wọlé láti ja ìjà yìí fún ìgbógunti àgbáyé wa. |
|
Mò ń pè yín láti wá darapọ̀ pẹ̀lú mi. |
|
A gbọdọ̀ jọ tú àwọn ìṣòro tí a ti ṣẹ̀dá ká, tó ń yọwọ́ àwọn ọmọ-ìlú kúrò nínú ìgbìyànjú ìpéjọpọ̀. |
|
Mo ti jọ̀wọ́ ayé mi fún ìdáàbò bo kiníhùn. |
|
Mo dẹ̀ mọ̀ pé àwọn alájọgbé mi yóò ṣe bẹ́ẹ̀, bákan náà, ìbá ṣe wí pé wọ́n mọ àwọn ẹranko tí ó ń gbé ní ẹ̀gbẹ́ wọn ni. |
|
Ẹ ṣeun. |
|
Bí àwọn hòrò àìsàn jẹjẹrẹ ṣe ń sọ̀rọ̀ - àti bí a ṣẹlẹ̀ mú wọn wálé. |
|
Ààrùn tó ń bani láyé jẹ́ ni tó sì ń bani lọ́kàn jẹ́. |
|
Kìí ṣe fún aláìsàn nìkan, ṣùgbọ́n àwọn olólùfẹ́ aláìsàn náà, bákan náà. |
|
Ogun tí ìran ọmọ ènìyàn ti ń jà fún àìmọye ọ̀rún-ọdún ni. |
|
Nígbà tí a ti ṣe àwọn ìtẹ̀síwájú kan, a ò tíì ṣẹ́gun rẹ̀. |
|
Méjì nínú ènìyàn márùn-ún ní orílẹ̀-ède US ni yóò ní àìsàn jẹjẹrẹ ní ìṣẹ́mi wọn. |
|
Nínú àwọn wọ̀nyí, ìdá àádọ́rùn (90%) yóò juwọlé fún ààrùn yìí nítorí ìtànká rẹ̀. |
|
Ìtànká jẹ́ ìfọ́nká àìsàn jẹjẹrẹ láti ayé ìpìlẹ̀ sí ayé míràn, nípasẹ̀ ètò ìṣàn-ẹ̀jẹ̀ tàbí ètò omi-ara. |
|
Fún àpẹẹrẹ, obìnrin aláìsàn pẹ̀lú àìsàn jẹjẹrẹ ọyàn kìí júwọlé fún ààrùn náà nítorí ó pọ̀ lórí ọyàn rẹ̀. |
|
Ó juwọlé fún ààrùn náà nítorí ó ń tàn lọ sí ẹ̀dọ̀-fóró, ẹ̀dọ̀, àṣẹ omi-ara, ọpọlọ, egungun, níbi tí kò ní ṣe é fi iṣẹ́ abẹ yọ tàbí ṣeé tọ́jú. |
|
Ìtànká jẹ́ ìgbésẹ̀ àmúdijú. |
|
Èyí tí mo ti ń kọ́ nípa rẹ̀ fún àìmọye ọdún báyìí. |
|
Nkan tí èmi àti ikọ̀ mi ṣàwárí láìpẹ́ yìí ni wí pé àwọn hòrò àìsàn jẹjẹrẹ máa ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ wọ́n sì máa ń darí ètò ìgbésẹ̀ wọn, lórí bí wọ́n ṣe súnmọ́ra wọn nínú agbègbè-àìfojúrí kókó. |
|
Wọ́n máa ń bára wọn sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ mọlékù afúnilọ́wọ́ méjì tí wọ́n ń pè ní Interleukin-6 àti Interleukin-8. |
|
Ní báyìí, bí ǹkan mìíràn nínú ẹ̀dà, tí ǹkan bá fún díẹ̀, ó máa ń ran àmì náà lọ́wọ́, tí yóò sì mú kí àwọn hòrò àìsàn jẹjẹrẹ náà yára sún kúrò láti ayé-ìpìlẹ̀ kí wọ́n sì fọ́nká sí ayé tuntun. |
|
Nítorí náà, tí a bá di àmì yìí, pẹ̀lú lílo ogun kan tí a pèsè, a lè dá ìbánisọ̀rọ̀ láàrín àwọn hòrò àìsàn jẹjẹrẹ dúró ká sì mú àdínkù bá ìfọ́nká àìsàn jẹjẹrẹ. |
|
Ẹ jẹ́ kí n dánu dúró díẹ̀ fún ìṣẹ́jú àyà kan kí n sì mú yín padà sí ìgbà tí gbogbo èyí bẹ̀rẹ̀ fún mi ní ọdún 2010, nígbà tí mo jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ọdún kejì ní ilé-ìwé gíga. |
|
Mo ṣe bẹ̀rẹ̀ síní ṣiṣẹ́ ní àyè fún àyẹ̀wò ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ omimọ́ ìṣègùn Danny Wirtz ní fásitì John Hopkins ni. |
|
Màá dé ṣe òótọ́: mo jẹ́ ọ̀dọ́, aláìmọ̀kan, ọmọdébìnrin Sri Lankan, tí ó ní ìrírí ìwádìí àtẹ̀yìnwá Kankan. |
|
Iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún mi ni láti wo bí àwọn hóró ààrùn jẹjẹrẹ ṣe ń rìn ní 3D collagen I matrix tó máa ń ṣàfihàn, nínú àbọ̀ kan, ipò tí àwọn hóró ààrùn jẹjẹrẹ ń kojú lára wa. |
|
Èyí jẹ́ tuntun ó sì ń fún mi láyọ̀, nítorí àwọn iṣẹ́ àtẹ̀yìnwá ni wọ́n ti ṣe lórí 2D, pẹlẹbẹ, abo oníke tí wọn kìí fi bẹ́ẹ̀ ṣe àgbéjáde ǹkan tí àwọn hòrò ààrùn jẹjẹrẹ ń kojú lára wa. |
|
Nítorí, ẹ jẹ́ ká dojú kọ ọ́, àwọn hòrò ààrùn jẹjẹrẹ nínú ara wa kìí dúró lórí àwọn abo oníke. |
|
Ní àsìkò yìí ni mo lọ sí ṣèmina tí Oníṣègùn-òyìnbó Bonnie Bassler láti fásitì Princeton gbé kalẹ̀, níbi tó ti sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn hòrò alámọ̀ ṣe ń bára wọn sọ̀rọ̀, lórí iye agbáríjọpọ̀ wọn, tí wọ́n sì ń ṣe àwọn iṣẹ́ kan pàtó. |
|
Àsìkò yìí ni iná kan dédé kú lórí mi, mo wá rò ó, "Wọw, mo máa ń rí èyí nínú hóró ààrùn jẹjẹrẹ mi lójoojúmọ́, tí a bá ń sọ nípa ìgbésẹ̀ wọn. |
|
Èrò iṣẹ́-àgbéṣe mi bá di bíbí. |
|
Mo ṣe àròsọ pé àwọn hòrò ààrùn jẹjẹrẹ máa ń bára wọn sọ̀rọ̀ wọ́n sì máa ń darí ìgbésẹ̀ wọn, lórí bí wọ́n ṣe jọ wà papọ̀ ní àwùjọ-àìfojúrí kókó. |
|
Mo bẹ̀rẹ̀ síní ronú pẹ̀lú ìṣísẹ̀ tó àròsọ yìí. |
|
Orí bámi ṣe, mò ń ṣiṣẹ́ fún ẹnìkan tó ṣetán láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ẹ̀rọ tó ń sìn mí níwín. |
|
Nítorí náà, mo jura mi sínú iṣẹ́-akanse yìí. |
|
Síbẹ̀, mi ò lè dáṣẹ́ ẹ fúnra mi. |
|
Mo nílò ìrànlọ́wọ́. |
|
Mo nílò ìrànlọ́wọ́ lóòtọ́. |
|
A gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọn ò tíì kẹ́kọ̀ọ́ jáde, àwọn akẹ́kọ̀ọ́-jáde, àwọn ọ̀mọ̀wé àti àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n láti ilé-ẹ̀kọ́ lóríṣiríṣi àti oríṣiríṣi ẹ̀ka láti parapọ̀ ṣiṣẹ́ lórí ẹ̀rọ yìí tí mo lóyún rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkekèo ọdún kejì nílé-ẹ̀kọ́ gíga. |
|
Lẹ́yìn àìmọye ọdún tí a ti ń ṣe ìdánwò papọ̀ tí a sì ń pa oríṣiríṣi èrò àti òye pọ̀, a ṣàwárí orípá ìṣàmì tuntun tó ń daríi bí àwọn hòrò |
|
Àwọn kan nínú yín lè ti gbọ́ èyí, nítorí ọ̀pọ̀ àwọn ìkàni ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ mọ̀ ọ́ sí ipa Hasini. |
|
A ò dẹ̀ tíì ṣetán. |
|
A wá pinnu wí pé a fẹ́ di orípá ìṣàmì ká wá wò ó bóyá a lè mú àdínkù bá ìfọ́nká ààrùn jẹjẹrẹ. |
|
Tí a dé ṣe, ní àwòṣe ìtọ́jú síwájú àyẹ̀wò lára ẹranko. |
|
A pèsè oògùn alágbàlu kan tó ní tocilizumab, tí à ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́ láti tọ́jú làkúrègbé, àti reparixin, tí à ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́ fún ìwádìí ajẹmọ́-ìtọ́jú ààrùn jẹjẹrẹ ọ̀yàn. |
|
Pẹ̀lú ìdùnnú, ǹkan tí a rí ni wí pé oògùn alágbàlu yìí kò fi bẹ́ẹ̀ nípa lára ìdàgbàsókè kókó, ṣùgbọ́n ó dojúkọ ìtànká tààrà. |
|
Èyí jẹ́ àbájáde tó ṣe pàtàkì, torí lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí, kò sí oògùn FDA kankan tó gbaṣẹ́ tó ń kojú ìtànká ààrùn jẹjẹrẹ tààrà. |
|
Lóòtọ́, ìtànká ààrùn jẹjẹrẹ, títànká, ni wọ́n ń rí gẹ́gẹ́ bí èròjà ìdàgbàsókè kókó. |
|
Níbi tí ẹ̀rọ náà wà, tí a bá lè dènà ìdàgbàsókè kókó, a lè dènà ìtànká kókó. |
|
Síbẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa mọ̀ wí pé èyí kìí ṣe òótọ́. |
|
Àwa, nìdá kejì, pèsè ogun olómi kan tó ń kojú ìtànká tí kìí ṣe pẹ̀lú ìdojúkọ ìdàgbàsókè kókó, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìdojúkọ ìṣẹ̀dá tó gbòòrò tó ń darí rẹ̀, nípasẹ̀ kíkojú ipa Hasini. |
|
Wọ́n ṣe àtẹ̀jáde iṣẹ́ yìí láìpẹ́ yìí nínú "Nature Communications," èmi àti àwọn ikọ̀ mi dé gba èsì tó pọ̀ káàkiri àgbáyé. |
|
Kò sí ẹnikẹ́ni nínú ikọ̀ mi tó lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ irú àwọn èsì yìí. |
|
Ó jọ bí ẹni pé a ti kan ǹkan. |
|
Wíwo ẹ̀yìn, mo ń dúpẹ́ gidi gan fún àwọn èsì gidi tí mo rí gbà, kìí ṣe láti ẹ̀ka ètò-ẹ̀kọ́ nìkan, ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ àwọn aláìsàn, àti àwọn ènìyàn káàkiri àgbáyé tí ààrùn burúkú yìí ń bájà. |
|
Bí mo ṣe ń nípa lórí àṣeyọrí tí mo bá pàdé pẹ̀lú ipa Hasini, mo tún padà wá bá àwọn ènìyàn tí mo ní àǹfààní láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú. |
|
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọn ò tíì kẹ́kọ̀ọ́ jáde tí wọ́n fi agbára àkàndá ènìyàn hàn nípasẹ̀ iṣẹ́ takun-takun àti ìfọkànsìn wọn. |
|
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́-jáde àti àwọn ọ̀mọ̀wé, àwọn akẹgbẹ́ mi olùkọ́yà, tí wọ́n kọ́ mi ní àwọn ọgbọ́n tuntun tí wọ́n sì ríi dájú pé mo wà lójú ọ̀nà. |
|
Àwọn ọjọ́ọ̀gọ̀n, àwọn Yoda àti Obi-Wan Kenobid mi, tí wọ́n mú ìmọ̀ ọ́síjìn wọn wá láti jẹ́ kí iṣẹ́ yìí di ǹkan tó dà lónì. |
|
Àwọn òṣìṣẹ́ alátìlẹyìn, àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí, àwọn ènìyàn tí wọ́n gbé orí mi sókè, tí wọn ò jẹ́ ká jákàn lórí ìgbìyànjú ìpinnu wa. |
|
Àwọn kẹ́sẹ́ tó dára jù tí a lè bẹ̀rẹ̀ fún. |
|
Ó gba abúlé kan láti bá mi ṣàyẹ̀wò ìtànká. |
|
Ẹ gbamigbọ́, láìsí abúlé mi, mi ò ní sí níbí. |
|
Lónì, ikọ̀ wa ti dàgbà, a sì ń lo ipa Hasini láti pèsè àkójọpọ̀ oògùn tó máa kojú ìdàgbàsókè kókó àti ìtànká. |
|
À ń ṣe ètò oògùn àtakò-jẹjẹrẹ, láti ṣe àdínkù ọ̀rọ̀ àti láti mú àdínkù bá ìtako oògùn. |
|
À ń ṣe àwọn ètò tí yóò nípa tí yóò sì ṣe ìrànwọ́ fún ìdàgbàsókè ìwádìí ajẹmọ́-ìtọ́jú lára ènìyàn dáadáa. |
|
Ó múnú mi dùn láti ronú wí pé gbogbo èyí, iṣẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ tí mò ń ṣiṣẹ́ tó – àti ìjẹ òótọ́ pé mo dúró níbí, báa yín sọ̀rọ̀ lóní -- gbogbo rẹ̀ wá látara èrò kékeré tí mo ní nígbà tí mo jókòó lẹ́yìn ní ṣèmínà nígbà tí mo wà lọ́mọ ogún ọdún. |
|
Mo mọ ìyẹn nísìnyí, mo wà lórí ìrìn-àjò aláìlẹ́gbẹ́ yìí tó fún mi ní ànfàní láti ṣiṣẹ́ tó iṣẹ́ tí mo nífẹ̀ẹ́ sí, àti ǹkan tó máa ń bọ́ ìmọ̀ mi lójoojúmọ́. |
|
Ṣùgbọ́n mo gbọdọ̀ sọ pé, èyí tí mo fẹ́ràn jù nínú gbogbo èyíi -- yàtọ̀ sí, bẹ́ẹ̀ ni, wíwà níbí, bí báa yín sọ̀rọ̀, lónì -- ni pé mo ṣiṣẹ́ pẹ̀lú oríṣiríṣi ẹ̀yà ènìyàn, tí wọ́n jẹ́ kí iṣẹ́ mi lágbára, kò dára kò sì rọrùn púpọ̀. |
|
Torí eléyìí, mo ní láti sọ wí pé àjọṣepọ̀ ni agbára àkàndá-ènìyàn tí mo fẹ́ràn jù. |
|
Nkan tí mo sì fẹ́ràn nípa agbára yìí ni wí pé èmi nìkan kọ́ ni mo ní i. |
|
Ó wà nínú gbogbo wa. |
|
Iṣẹ́ mi fi hàn pé kódà àwọn hòrò ààrùn jẹjẹrẹ má ń lo àjọṣepọ̀ láti kógun ja àgọ́-ara wa àti láti fọ́n ìbínú wọn ká. |
|
Fún àwa ènìyàn, agbára-akàndá náà ti pèsè àwọn àwárí aláìlẹ́gbẹ́ ní ẹ̀ka ìmọ̀-ìṣègùn àti ìmọ̀-ìjìnlẹ̀. |
|
Agbára-akàndá náà ni gbogbo wa lè kọjú sí láti ṣe kóríyá fún wa láti ṣe nǹkan tó tóbi ju àwa fúnra wa lọ, ìyẹn yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti sọ ilẹ̀-ayé di ayé tó dára. |
|
Àjọṣepọ̀ ni agbára-akàndá tí mo kọjú sí, láti bá mi jagun ààrùn jẹjẹrẹ. |
|
Mo dé ní ìdánilójú pé pẹ̀lú àjọṣepọ̀ tó tọ́, a máa ṣẹ́gun ààrùn burúkú yìí. |
|
Ẹ ṣeun. |
|
Ẹ lè máa dókòwò sí àwọn ilé-iṣẹ́ sìgá láìmọ̀. |
|
Ní ọdún 2001, mo jẹ́ oníṣégùn-òyìnbó tuntun ayọ́rán, tó ń dán, tó ń gbèrò láti gba ayé là. |
|
Iṣẹ́ mi àkọ́kọ́ ni ṣíṣe iṣẹ́ fún oṣù mẹ́ta ní ẹ̀ka ààrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró. |
|
Ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ wí pé gbogbo aláìsàn mi ni wọ́n ń mu sìgá tàbí ti mu sìgá rí, ọ̀pọ̀ wọn sì ti bẹ̀rẹ̀ sí mu sìgá nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé tàbí láti bíi ọmọdún mẹ́tàlá. |
|
Pẹ̀lú pé wọ́n ń gbé ní orílẹ̀-èdè tó rẹwà, tó rorò, pẹ̀lú ànfàní sí àwọn oògùn tó lágbára jù, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ wí pé ìkankan gbogbo àwọn aláìsàn mi ni wọ́n kú tán. |
|
Gbogbo ènìyàn ló mọ̀ wí pé kùkùyẹ̀ ò dára, ṣùgbọ́n tí ẹ bá rí ipa rẹ̀ tààrà, tọ́jọ́ ń gorí ọjọ́, ó máa ń fi ipa tó kẹ́nu sílẹ̀. |
|
Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá, onímọ̀ nípa ìtàn ìkọ̀kọ̀ ni mí, tó mọ̀ nípa ìnira tí kúkúyé ń fà. |
|
Mo jókòó sí ilé-oúnjẹ ilé-ìwòsàn, mo ń ṣe ìpàdé mi àkọ́kọ́ pẹ̀lú aṣojú kan láti ilé-iṣẹ́ owó-ìfẹ̀yìntì mi. |
|
Ó múnú mi dùn, ó dámi lójú pé ẹ lè wòye rẹ̀. |
|
Ó sọ fún mi pé mo wà ní èèyàn ìpìlẹ̀. |
|
Mo ní, "Èyàn? |
|
Ṣé ìyẹn túmọ̀ sí wí pé àwọn ànfàní yíyàn míràn tún wà? |
|
Ó wò mí, ó yí ojú rẹ̀, ó sì wí pé, "káràn ìdáàbò bo àwùjọ kan báyìí wà fún àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ìṣòro ìdókòwò nínú ìwà-kusa, ọtí-líle tàbí kùkúté. |
|
Mo ní, "Ǹjẹ́ o dárúkọ kúkúye? |
|
Ó ní, bẹ́ẹ̀ ni. |
|
Mo ní, "báyìí, ṣé ò ń sọ fúnmi wí pé mò ń dókòwò nínú kùkùyé lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí? |
|
Ó ní, "oh, bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo ènìyàn sì ni. |
|
Tí o bá dókòwò ní ilé-iṣẹ́ kan, o ti ní díẹ̀ lára ilé-iṣẹ́ yẹn. |
|
Ó fẹ́ kí ilé-iṣẹ́ yẹn gbòòrò kó ṣe àṣeyọrí kó sì gbèrú. |
|
Ó fẹ́ kí ilé-iṣẹ́ yẹn fa ojú àwọn oníbàárà tuntun mọ́ra, ó fẹ́ kí ilé-iṣẹ́ yẹn ta ọ̀pọ̀ nínú àwọn èròjà rẹ̀. |
|
Tí ó bá sì jẹ́ ti kùkùyẹ̀, mi ò lè ronú ǹkan tí mo fẹ́ tó yàtọ̀. |
|
Ní báyìí, mo mọ̀ wí pé ẹnìkan tó dúró lórí àmì pupa yìí nìkan ni ẹ̀ ń rí, lórí ìtàgé ńlá yìí. |
|
Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, màá fẹ́ kí ẹ rò ó wí pé ẹ ń wo mílíọ̀nù méje ènìyàn tí wọ́n díje ní ẹgbẹ́ mi níbí lónì. |
|
Mílíọ̀nù méje ènìyàn káàkiri àgbáyé ti kú nítorí kúkúye ní ọdún tó kọjá nìkan. |
|
Ẹ kò rò ó wò, tí wọ́n bá ṣe ìfilọ́lẹ̀ ilé-iṣẹ́ tuntun àyáǹran kan lónì, ní ìparí oṣù Òkúdù tó ń bọ̀, àwọn èròjà ilé-iṣẹ́ yẹn ti pa mílíọ̀nù méje ènìyàn. |
|
Ṣé ìkankan nínú wa máa dókòwò ní ilé-iṣẹ́ tuntun, aṣekúpani yẹn? |
|
Kúkúye jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fẹ́ àmójútó jù ní àsìkò wa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa sì lọ́wọ́ nínú wàhálà náà ju bóṣe yémi lọ. |
|
Nítorí náà, aṣojú owó ńlá ṣàlàyé fún mi wí pé màá rí àwọn ilé-iṣẹ́ kúkúye ní àyè ìpín-ìdókòwò ilé-okere mi. |
|
Mo bi í léèrè, "ó dáa, ìpín-ìkówójọ ilé-okere wo ni mo ní? |
|
" Ó kàn sí mi lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì pẹ̀lú ìwé yìí: ìdókòwò mi àkọ́kọ́ nínú ìpín ìdókòwò ilẹ̀-okere jẹ́ ti British America Tobacco. |
|
Ẹ̀ẹ̀kejì, Imperial Tobacco. |
|
Ẹlẹ́ẹ̀kẹrin, Philip Morris. |
|
Elééékàrùn, ilé-iṣẹ́ Swedish Match. |
|
Mẹ́rin nínú àwọn ilé-iṣẹ́ márùn tó wà lókè téńté jẹ́ ilé-iṣẹ́ kúkúye, ìdókòwò tèmi, onímọ̀ nípa ààrùn jẹjẹrẹ. |
|
Nígbà náà ni mo mọ̀ wí pé kìí ṣe èmi nìkan. |
|
Gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ọwọ́ ńlá mi ni. |
|
Nígbà náà ni mo mọ̀ wí pé kìí ṣe ọwọ́ ńlá mi nìkan, gbogbo wọn ni. |
|
Nígbà náà ni mo mọ̀, kìí ṣe ilé-iṣẹ́ owó ìfẹ̀yìntì nìkan, àwọn ilé-ìfowópamọ́, abánidáàbòbò àti àwọn alámójútó owó. |
|
Mo wá mọ̀ wí pé kìí ṣe orílẹ̀-ède Australia nìkan. |
|
Gbogbo ẹ̀ka òwò lágbàáyé ni, wọ́n sopọ̀ pátápátá mọ́ ilé-iṣẹ́ kúkúye. |
|
Ilé-iṣẹ́ tó ń pèsè èròjà tó ń pa mílíọ̀nù méje ènìyàn lọ́dọọdún. |
|
Mo bẹ̀rẹ̀ síní jíròrò nípa ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ owó-ìfẹ̀yìntì mi, mo dẹ̀ ti ń sọ ọ́ látìgbà náà. |
|
Àwọn adarí owó ní oríṣiríṣi ìpèníjà láti kojú, lásìkò yìí. |
|
Mo dá a lábàá pé kí wọ́n lo ètò-ìgbésẹ̀ kan tí yóò sọ ìdí tí ó fi bá ìrònú mu láti gbé ìgbésẹ̀ tó le lórí kùkùyẹ̀. |
|
Mo dá a lábàá pé kí àwọn adarí bẹ̀rẹ̀ àpapọ̀ ìbéèrè mẹ́ta nípa àwọn ilé-iṣẹ́ tí wọ́n lè ti kó owóo wá sí. |
|
Ìbéèrè àkọ́kọ́: Ǹjẹ́ èròjà tí ilé-iṣẹ́ náà ń pèsè lè di lílò láìséwu? |
|
"Rárá" ni ìdáhùn fún àwọn ilé-iṣẹ́ kúkúye. |
|
Odò nìkan ni iye àìléwu sìgá fún ọmọ ènìyàn. |
|
Kò le ju dúdú àti funfun lọ. |
|
Ìbéèrè kejì: Ǹjẹ́ wàhálà tí àwọn ilé-iṣẹ́ náà ń dá sílẹ̀ nípa ní ìpele àgbáyé débi pé ó wà lábẹ́ àdéhùn tàbí àpérò UN? |
|
"Bẹ́ẹ̀ ni" ni ìdáhùn fún kúkúyè. |
|
Lóòtọ́ àdéhùn kúkúye UN kan wà tí àwọn orílẹ̀-èdè bí ọgọ́sàn ti fọwọ́ sí. |
|
Wọ́n ṣẹ̀dá àdéhùn náà nítorí ipa ewu kúkúye lágbàyé. |
|
Àsọtẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ ni wí pé orílẹ̀-èdè àgbáyé ń wà lójú ọ̀nà fún bílíọ̀nù kan ikú tó tan mọ́ kúkúye ní ọ̀rún ọdún yìí. |
|
Bílíọ̀nù ikú kan. |
|
Bílíọ̀nù méje péré nìwà. |
|
Ìbéèrè kẹta tan mọ́ èrò ìṣòro-papọ̀. |
|
Ọ̀pọ̀ àwọn ilé-iṣẹ́ ọwọ́ ni wọ́n fẹ́ di ọmọ-ìlú gidi lóòtọ́. |
|
Wọ́n fẹ́ lo agbára ìpín-ìdókòwò wọn láti jókòó pẹ̀lú àọwn ilé-iṣẹ́, bá wọn sọ̀rọ̀, kí wọ́n sì ṣe ìwúrí fún wọn láti ṣe ǹkan gidi. |
|
Ìbéèrè náà ni wí pé: Ǹjẹ́ sísọ̀rọ̀ papọ̀ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ náà lè jẹ́ àtẹ̀gùn fún àyípadà? |
|
"Rárá" ni ìdáhùn fún àwọn ilé-iṣẹ́ kúkúye. |
|
Sísọ̀rọ̀ papọ̀ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ kùkùyé ó lè so èso rere. |
|
Àbájáde tó ṣe é gbà ni tí àwọn ilé-iṣẹ́ kúkúye bá dáwọ́ ọwọ́ ìpìlẹ̀ wọn gangan dúró. |
|
Lóòtọ́, sísọ̀rọ̀ papọ̀ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ kúkúye ò tíì yọrí sí àdínkù ikú ọmọ ènìyàn rí. |
|
Tí a bá wo ètò-ìgbésẹ̀ yẹn, ìbéèrè tó rọrùn mẹ́ta, a lè rí wí pé ó bá ìrònú mu ó sì ṣe é dúró tì láti gbé ìgbésẹ̀ alágbára ká sì yọ ìdókòwò nínú ilé-iṣẹ́ kúkúye kúrò. |
|
Ní àfikún sí àdéhùn kúkúye UN, lóòtọ́, àdéhùn àgbáyé mìíràn wà tó pè fún gbígbé ìgbésẹ̀ lórí kúkúye. |
|
Ní ọdún 2015, UN gba àwọn ìpinnu ìdàgbàsókè alábọ́dé wọlé. |
|
Ní báyìí, à ń sọ̀rọ̀ nípa kùkùyè, mo dẹ̀ mọ̀ pé ẹ máa fò tààrà sí ẹlẹ́ẹ̀kẹta ni: ìlera tó dára àti wíwà lálàáfíà. |
|
Lóòtọ́, ìrólagbara òfin tó ń darí kùkùyè ṣe pàtàkì tí a bá fẹ́ kí ìpinnu yẹn di ṣíṣe. |
|
Síbẹ̀, ẹ fi ojú inú wò ó díẹ̀ sí, ẹ ó sì rí wí pé ìpinnu mẹ́tàlá nínú mẹ́tà-dín-lógún ò lè di ṣíṣe àyàfi tí àtúntò tó lágbára bá débá ilé-iṣẹ́ kúkúye. |
|
Fún èmi, ìpinnu kẹtà-dín-lógún ni mo fẹ́ràn jù: àjọṣepọ̀ fún ìpinnu náà. |
|
Lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí, a ní gbogbo ẹ̀ka ìlera àgbáyé tí wọ́n ń ṣe gbogbo ǹkan tí wọ́n lè ṣe láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn tí wọ́n ńjẹ̀ rọra ìpadàbọ̀ kíákíá. |
|
Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí a ti sọ èyí, ní ọdún tó lò nìkan, mílíọ̀nù méje ènìyàn ti kú, kedere ni, ìyẹn ò tó. |
|
A ní àwọn ìjọba tí wọ́n tò sẹ́yìn kúkúye, ọgọ́sàn nínú wọn, tí wọ́n ń gbìyànjú láti ṣàmúlò ìpèsè àdéhùn kúkúye UN. |
|
Ṣùgbọ́n ìyẹn, bákan náà, kò tó. |
|
Tí ẹ̀ka òwò lágbàyé bá tẹ̀síwájú láti máa yá àwọn ilé-iṣẹ́ àkàyé lówó, láti dókòwò nínú àkàyé, tó sì ń gbìyànjú láti jèrè lára ilé-iṣẹ́ àkàyé, à ń ṣiṣẹ́ tako arawa ni. |
|
Ní báyìí, tí a bá fẹ́ ṣe ìdíwọ́ fún ǹkan tí àwọn oníṣègùn-òyìnbó pè ní "àjàkálẹ̀ ààrùn kùràye lágbàáyé," a nílò kí gbogbo ẹ̀ka láwùjọ dúró fẹ́gbẹ́-kẹ́gbẹ́ kí wọ́n wà lára ìyànjú náà. |
|
Mò ń pe gbogbo adarí ẹ̀ka owó láti ṣe àmúlò ètò-ìgbésẹ̀ kan láti gbógun ti ọ̀rọ̀ ńlá yìí. |
|
Mo dẹ̀ ń késí wọn láti ṣiṣẹ́ tó àwọn àpérò àgbáyé. |
|
Ṣùgbọ́n ní àfikún, ewu ìṣòwò wà níbẹ̀. |
|
Àwọn ẹ̀wù owó aláìbùlà, tó níṣe pẹ̀lú ìdókòwò ní ilé-iṣẹ́ kúkúye fún ìgbà pípẹ́, mo sì ń rọ àwọn adarí ẹ̀ka-òwò láti bojú wò wọ́n. |
|
Ewu àkọ́kọ́ ni wí pé àwọn ènìyàn díẹ̀díẹ̀ ni yóò ma mu sìgá, gẹ́gẹ́ bí àbájáde ṣíṣe àfikún òfin kúkúye. |
|
Wọ́n máa ń kéfin òfin, òfin máa ń ṣe àdínkù ìlò rẹ̀, á sì ní ọgọ́sàn (180) orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣetán láti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ òfin. |
|
Ẹ jẹ́ ká sọ nípa ìgbésẹ̀ òfin àti ewu tó lè fà. |
|
Lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí, ààtò owó ilé-iṣẹ́ kúkúye ni à ń tako. |
|
Lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí, ilé-iṣẹ́ kúkúyé ń ṣe àdínkù gbogbo ewu ìlera tó tan mọ́ kúkúyé. |
|
Ìjọba ń sàn, àwùjọ ń sàn, ìwọ ń san, èmi ń san. |
|
Ilé-iṣẹ́ kúkúye ń ṣe àtúntò gbogbo ìnáwó yìí, pẹ̀lú àpapọ̀ tírílíọ̀nù kan dọ́là orílẹ̀-ède US lọ́dún kankan. |
|
Síbẹ̀ wọ́n ń ṣe àpamọ́sílẹ̀ àti àdáni àwọn ère. |
|
Ní ọdún 2015, ní agbègbè Quebec, ilé-ẹjọ́ pinnu pé ilé-iṣẹ́ kúkúye ni wọ́n ṣe okùnfà àwọn ìnáwó ìlera wọ̀nyẹn, wọ́n sì pàṣẹ fún wọn láti san bílíọ̀nù mẹ́rìndínlógún dọ́là orílẹ̀-èdè US. |
|
Ẹjọ́ yẹn wà ní ilé-ẹjọ́ kò tẹ́milọ́rùn. |
|
Ṣùgbọ́n ó ń bẹ̀rẹ̀ ìbẹ̀rẹ̀ pé, kí ló dé tí ìkankan nínú wa, ní èyíkéyìí orílẹ̀-èdè, máa sanwó fún ewu ilé-iṣẹ́ kúkúye? |
|
Ẹ jẹ́ ká tẹ̀síwájú lọ sí okùn ìtajà àti ewu tó wà níbẹ̀. |
|
Kò fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ mímọ̀ wí pé ilé-iṣẹ́ kúkúye gbára lé fífi ọmọ ṣòwò ẹrú. |
|
Ní oṣù Ẹrẹ́nà ọdún 2017, Àjọ àwọn Òṣìṣẹ́ Lágbàáyé ṣe àgbéjáde ìjábọ̀ kan tó sọ wí pé: "Ní àwọn agbègbè tí wọ́n ti ń gbin kùkùyẹ̀, fífi ọmọ ṣòwò ẹrú wọ́pọ̀. |
|
" Ẹ̀ka òṣìṣẹ́ orílẹ̀-ède US lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí ti ka àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́rìn-dín-lógún tí wọ́n ń lo àwọn ọmọdé láti pèsè ewé kùkùté. |
|
Ṣíṣe àyẹ̀wò okùn ìtajà fínnífínní lágbára, ìyẹn ò sì lè tẹ̀síwájú láti máa fọ àkíyèsí gbogboògbò. |
|
Lákòtán, ewu ìjẹ-àkarawábí wà níbẹ̀ láti ṣàfihàn fún àwọn ènìyàn àti ilé-iṣẹ́ tí wọ́n ń tẹ̀síwájú láti máa ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ilé-iṣẹ́ kukuye. |
|
Nínú àìmọye iṣẹ́-ìwádìí, ilé-iṣẹ́ kúkúye ló gba ipò gẹ́gẹ́ bí ilé-iṣẹ́ tí ìjẹ-àwàlúwàbí rẹ̀ kéré jùlọ. |
|
Ẹ jẹ́ ká kó wo ipa rẹ̀ lára àwọn ọmọdé. |
|
Káàkiri àgbáyé, ní ọjọ́ kankan, wọ́n ṣe é wí pé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn ọmọ ni wọ́n máa ń bẹ̀rẹ̀ sí mú kùkùyè. |
|
Ìyẹn jẹ́ iye ọmọ tí yóò kún inú pápá-ìṣeré bọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá Melbourne. |
|
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ wọ̀nyẹn ni wọ́n wá láti àwọn àwùjọ tó kùṣẹ̀ẹ́ jùlọ lórí ilẹ̀-eépẹ̀. |
|
Ní orílẹ̀-ède Australia níbí, àdínkù ọjọ́-orí tí àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ síní mú kùyẹ̀ ní ọdún mẹ́rìn-dín-lógún àti oṣù méjì. |
|
Wọ́n kéré púpọ̀ lójú mi, ṣùgbọ́n ǹkan tó burú jù níbí ni wí pé a ò ní dátà láti gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà lórí ilẹ̀-adúláwọ̀, a gbàgbọ́ wí pé ọjọ́-orí tó dàgbà jùlọ nìyẹn. |
|
Ní gbogbo ayé mìíràn ó kéré. |
|
Ẹ̀wẹ̀ fún ìròyìn ayọ̀. |
|
Nkan tí ń yàtọ̀. |
|
Ẹ̀ka ọwọ́ náà ti ń darapọ̀. |
|
Lẹ́yìn bí ẹgbẹ̀rún méjì ìpàdé pẹ̀lú àwọn adarí ẹ̀ka-owó, ní ilé-ìjẹun Melbourne àti Sydney àti London àti Paris àti New York àti káàkiri àgbáyé, agbára, yíyẹ kúrò níbi ìdókòwò nínú ilé-iṣẹ́ kúkúye, ti bẹ̀rẹ̀ síní gbéra. |
|
Àwọn adarí ẹ̀ka-owó ti mọ̀ nígbà tí wọ́n pèsè ẹ̀rí fún wọn, àti lọ́pọ̀, wọ́n fẹ́ darapọ̀ mọ́ ọ̀nà-àbáyọ náà. |
|
Níbí, ní orílẹ̀-ède Australia, a ti ní mílíọ́nù mẹ́wàá lé àwọn àpò ìfowópamọ́ owó-ìfẹ̀yìntì tí kò ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. |
|
Ìyẹn ni tèmi, lápá kan. |
|
Iṣẹ́ sì pọ̀ láti ṣe, ṣùgbọ́n mo ti rí bí ọ̀rọ̀ náà ṣe ń lọ láti "ṣe kí ó má sì kúkúye mọ́ ni? "sí "kí ló dé tí a ò ṣe tíì ṣe é? |
|
" Ní ọdún tó kọjá nìkan, àwọn ìgbésẹ̀ kosi-kukuye ti di ṣíṣe ní àwọn ilé-iṣẹ́ owó tí wọ́n ń léwájú ní àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. |
|
Ní orílẹ̀-èdè Australia, New Zealand, Netherlands, Sweden, Denmark, France, Ireland àti USA. |
|
Látọ̀dọ̀ àwọn olómìnira owó ìrànwọ́, àwọn alámójútó owó, àwọn owó-ìfẹ̀yìntì, ilé-ìfowópamọ́, abáni-dáàbòbò àti àtún-báni-dáàbòfò. |
|
Láti ìgbà tí àpò-ìfowópamọ́ tí kò ní kúkúye ti bẹ̀rẹ̀, ó lé ní bílíọ̀nù mẹ́fà dọ́là ni wọ́n ti darí kúrò nínú ìdókòwò ní ilé-iṣẹ́ kúkúye. |
|
Àgbéyẹ̀wò náà dára wọ́n sì jẹ́wọ́ rẹ̀ lóòtọ́. |
|
Nígbà tí à ń ṣe ìkéde kosi-kukuye ní oṣù Ẹrẹ́nà ọdún yìí, aláṣẹ àti olùdarí AMP Capital sọ wí pé, "a ò ṣetán láti ṣe àgbékalẹ̀ àdápadà èrè ìdókòwò tí yóò pa àwùjọ lára lọ́nà kán. |
|
Ìbéèrè tí a ní láti bi ara wa nìyẹn. |
|
Ṣé kò sí gbèdéke àwòkọ́ṣe tó jẹ́ wí pé a ò ní kọjá rẹ̀ láti jèrè ni? |
|
Lójú ọ̀nà náà, mo ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrànlọ́wọ́ àti àtìlẹyìn alágbára. |
|
Ní báyìí, tí o bá ń gbìyànjú láti ṣe ǹkan, mo rọ̀ yín pé kí ẹ ní ọmọbìnrin-bìnrin nínú ìkọ́ni yín. |
|
Aláyélúwà, ọmọọba-bìnrin Dina Mired, ni aṣojú wa káàkiri àgbáyé fún iṣẹ́ yìí. |
|
A tún ni olúwa, oníbìnìínì, olórí orílẹ̀-èdè nígbà kan rí, adarí ìjọba àpapọ̀ nígbà kan rí àti agbáríjọpọ̀ àwọn aláṣẹ àti olùdarí ilé-iṣẹ́. |
|
Ṣùgbọ́n ìkápá láti yí ǹkan padà kò sí lórí àwọn ènìyàn pàtàkì wọ̀nyíi nìkan. |
|
Agbára láti ṣe ìyẹn wà lọ́dọ̀ gbogbo wa. |
|
Gbogbo wa níbí lè darapọ̀ mọ́ ìyànjú yìí. |
|
Lóòtọ́, gbogbo wa níbí ni a gbọdọ̀ darapọ̀ mọ́ ìyànjú náà. |
|
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nínú yàrá yìí ni ó ní ilé-iṣẹ́ nípasẹ̀ owó-ìfẹ̀yìntì wọn, ilé-ìfowópamọ́ wọn àti abánidáàbòbò wọn. |
|
Àsìkò ti tó láti bi wọ́n: ṣé wọ́n ń fi ọwọ́ọ wa dókòwò ní àwọn ilé-iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe èròjà tó ń pa mílíọ̀nù méje ènìyàn lọ́dọọdún? |
|
Ọwọ́ọ yín ni. |
|
Ọwọ́ mi ni, ọwọ́ọ wa ni. |
|
Ìbéèrè tó sì mú ọpọlọ dání nìyẹn. |
|
Mo fún pọ̀ níbí, pẹ̀lú mílíọ̀nù méje ènìyàn ní ẹgbẹ́ mi lónì. |
|
Ṣùgbọ́n tí a ò bá gbé ìgbésẹ̀ nísìnyí, ká sì jọ ṣiṣẹ́ papọ̀, a máa nílò láti ṣìnà fún bílíọ̀nù kan ènìyàn kí ọ̀rún ọdún yìí tó parí. |
|
Ìtage tó tóbi gan ni èyí. |
|
Ṣùgbọ́n kò sí àyè mọ́. |
|
Ẹ ṣeun. |
|
Bí fọ̀ràn ayédèrú ṣe ń ṣe ìdíwọ́ fún òtítọ́ tó sì ń dukoko mọ́ ìjọba àwarawa. |
|
[ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò yìí kún fún àwọn àkóónú fún àgbàlagbà]. |
|
Rana Ayyub jẹ́ akọ̀ròyìn ní orílẹ̀-èdè India tí iṣẹ́ rẹ̀ ti tú àṣírí ìwà-ìbàjẹ́ ìjọba àti títẹ ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn lójú mọ́lẹ̀. |
|
Fún àìmọye ọdún, àwọn èébú àti awuyewuye tí ó yí ìṣe rẹ̀ ká ti mọ́ ọ lára. |
|
Ṣùgbọ́n kò sí ìkankan nínú rẹ̀ tó ṣe ìgbáradì rẹ̀ fún ǹkan tí ojúu rẹ̀ kàn ní oṣù Igbe ọdún 2018. |
|
Ó jókòó ní ilé-ìjẹun pẹ̀lú ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan nígbà tí ó kọ́kọ́ rí i: fọ̀ràn oníṣẹ́jú méjì àti ogún ìṣẹ́jú àáyá ara rẹ̀ tó ń ní ìbálòpọ̀. |