translation
dict
{ "en": "Additionally, two members of the Portugal Branch Committee joined local circuit overseers and congregation elders as they visited our brothers and sisters to encourage them.", "eng": null, "yor": "Bákan náà, méjì lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lórílẹ̀-èdè Portugal dara pọ̀ mọ́ àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà ìjọ láti máa bẹ àwọn ará wa lọ́kùnrin lóbìnrin wò kí wọ́n lè fún wọn níṣìírí." }
{ "en": "We pray that Jehovah continues to surround our brothers in Portugal with the loving support and comfort they need to recover from the extensive fire damage.—Psalm 71:21.", "eng": null, "yor": "Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà túbọ̀ jẹ́ ká máa fìfẹ́ ti àwọn ará wa ní Portugal lẹ́yìn, kó sì máa tù wọ́n nínú kí wọ́n lè bọ́ nínú ìṣòro tí iná ọ̀gbálẹ̀-gbáràwé yìí dá sílẹ̀.—Sáàmù 71:21." }
{ "en": "Media Contacts:", "eng": null, "yor": "Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:" }
{ "en": "International: David A. Semonian, Office of Public Information, +1-845-524-3000", "eng": null, "yor": "Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000" }
{ "en": "Portugal: João Pedro Candeias, +351-214-604-339\"", "eng": null, "yor": "Portugal: João Pedro Candeias, +351-214-604-339\"" }
{ "en": "\"Dates: June 28-30, 2019", "eng": null, "yor": "\"Déètì: June 28 sí 30, 2019" }
{ "en": "Location: Sport Lisboa e Benfica Stadium in Lisbon, Portugal", "eng": null, "yor": "Ibi Tá A Ti Ṣe É: Pápá ìṣeré Sport Lisboa e Benfica Stadium ní ìlú Lisbon, Pọ́túgà" }
{ "en": "Program Languages: English, Portuguese (Portugal), Portuguese Sign Language, Spanish", "eng": null, "yor": "Èdè: Gẹ̀ẹ́sì, Èdè Potogí (Pọ́túgà), Èdè Adití ti Potogí, Sípáníìṣì" }
{ "en": "Peak Attendance: 63,390", "eng": null, "yor": "Àwọn Tó Wá: 63,390" }
{ "en": "Total Number Baptized: 451", "eng": null, "yor": "Àwọn Tó Ṣèrìbọmi: 451" }
{ "en": "Number of International Delegates: 5,300", "eng": null, "yor": "Àwọn Tó Wá Láti Ìlẹ̀ Òkèèrè: 5,300" }
{ "en": "Invited Branches: Angola, Australasia, Brazil, Canada, Central America, Ghana, India, Mozambique, Senegal, Spain, United States, Venezuela", "eng": null, "yor": "Áwọn Ẹ̀ka Ọ́fíísì Tó Wá: Àǹgólà, Ọsirélíà, Brazil, Kánádà, Central America, Gánà, Íńdíà, Mòsáńbíìkì, Sẹ̀nẹ̀gà, Sípéènì, Amẹ́ríkà, Fẹnẹsúélà" }
{ "en": "Local Experience: Mr. Santos was one of the tour bus drivers for the delegates. When the bus captain invited him to the convention, Mr. Santos stated: “I want to go.", "eng": null, "yor": "Ìrírí: Ọ̀gbẹ́ni Santos wà lára àwọn awakọ̀ tó ń gbé àwọn àlejò tó wá sí àpéjọ. Nígbà tí arákùnrin tó ń ṣètò mọ́tò pè é wá sí àpéjọ náà, Ọ̀gbẹ́ni Santos sọ pé: “Mà á wá." }
{ "en": "Ever since I’ve started working with you, I feel such a peace that I can’t describe.", "eng": null, "yor": "Látìgbà tí mo ti ń bá yín ṣiṣẹ́, mo ní ìfọ̀kànbalẹ̀ tó kojá àfẹnusọ." }
{ "en": "I don’t know where this peace comes from, but you give me peace.", "eng": null, "yor": "Mi ò mọ bí ìfọ̀kànbalẹ̀ yìí ṣe ń wá, àmọ́ ó dá mi lójú ni pé ẹ̀ ń jẹ́ kí n ní ìfọ̀kànbalẹ̀." }
{ "en": "I’ll be at the stadium all day, so I want to attend.”", "eng": null, "yor": "Pápá ìṣeré ni màá wà jálẹ̀ ọjọ́ yẹn, torí náà màá wá.”" }
{ "en": "After attending, Mr. Santos said that he really appreciated the program.", "eng": null, "yor": "Lẹ́yìn tí Ọ̀gbẹ́ni Santos wá sí àpéjọ náà, ó sọ pé òun gbádùn ẹ̀ gan-an." }
{ "en": "He is from a village outside of Lisbon.", "eng": null, "yor": "Abúlé kan níta ìlú Lisbon ló ti wá." }
{ "en": "While at the convention, he met a brother who lives in a nearby village.", "eng": null, "yor": "Nígbà tó wá sí àpéjọ, ó pàdé arákùnrin kan tó ń gbé ní tòsí abúlé ẹ̀." }
{ "en": "Mr. Santos agreed to meet with the brother when they return home.\"", "eng": null, "yor": "Ọ̀gbẹ́ni Santos gbà pé kí arákùnrin yìí máa wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n bá ti pa dà sílé.\"" }
{ "en": "\"On Thursday, September 19, 2019, six brothers from the Russian city of Saratov were convicted and sentenced to prison simply for being Jehovah’s Witnesses.", "eng": null, "yor": "\"Ní Thursday, September 19, 2019, ilé ẹjọ́ dá àwọn arákùnrin mẹ́fà láti ìlú Saratov, ní Rọ́ṣíà lẹ́bi wọ́n sì jù sẹ́wọ̀n, kìkì nítorí pé wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà." }
{ "en": "Judge Dmitry Larin of the Leninsky District Court of Saratov sentenced Brother Konstantin Bazhenov and Brother Aleksey Budenchuk to three years and six months in prison; Brother Feliks Makhammadiyev to three years; Brother Roman Gridasov, Brother Gennadiy German, and Brother Aleksey Miretskiy to two years.", "eng": null, "yor": "Adájọ́ Dmitry Larin ti ilé ẹjọ́ Leninsky District Court of Saratov dájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ fún Arákùnrin Konstantin Bazhenov àti Arákùnrin Aleksey Budenchuk; ó dá ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta fún Arákùnrin Feliks Makhammadiyev; ó sì dá ẹ̀wọ̀n ọdún méjì fún Arákùnrin Roman Gridasov, Arákùnrin Gennadiy German, àti Arákùnrin Aleksey Miretskiy." }
{ "en": "Additionally, the ruling states that after serving their time in prison, all of the brothers will be banned from holding leadership positions in public organizations for a period of five years.", "eng": null, "yor": "Yàtọ̀ síyẹn, ilé ẹjọ́ sọ pé lẹ́yìn tí gbogbo wọn bá ṣẹ̀wọ̀n tán, wọn ò ní lé mú ipò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba èyíkéyìí fún odindi ọdún márùn-ún." }
{ "en": "The defense intends to appeal the verdict.", "eng": null, "yor": "Àwọn arákùnrin náà máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ìdájọ́ yìí." }
{ "en": "Criminal charges were first initiated against the six brothers after Russian authorities raided seven homes of Witnesses in Saratov on June 12, 2018.", "eng": null, "yor": "Ìgbà táwọn aláṣẹ ya wọ ilé méje táwọn Ẹlẹ́rìí ń gbé nílùú Saratov ní June 12, 2018 ni ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n fi ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kan àwọn arákùnrin mẹ́fà yìí." }
{ "en": "All of the brothers have families, but Brother Budenchuk has two children who are still in school.", "eng": null, "yor": "Gbogbo àwọn arákùnrin wọ̀nyí ló ní ìdílé, àmọ́ Arákùnrin Budenchuk ní tiẹ̀ ní ọmọ méjì tí wọ́n ṣì wà ní ilé ìwé." }
{ "en": "Brother Budenchuk, along with Brother Bazhenov and Brother Makhammadiyev, spent almost a year in pretrial detention after their arrest.", "eng": null, "yor": "Arákùnrin Budenchuk, Arákùnrin Bazhenov àti Arákùnrin Makhammadiyev ti lo ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún kan látìmọ́lé lẹ́yìn tí wọ́n mú wọn kó tó wá di pé wọ́n gbọ́ ẹjọ́ wọn." }
{ "en": "In their final words to the court, the six brothers quoted several inspiring verses from the Bible and said that they did not harbor animosity toward the prosecution.", "eng": null, "yor": "Nínú ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ gbẹ̀yìn nílé ẹjọ́, àwọn arákùnrin mẹ́fà wọ̀nyí tọ́ka sí ọ̀pọ̀ àwọn ẹsẹ Bíbélì amóríyá tó sún wọn láti jẹ́ adúróṣinṣin, wọ́n sì fi kún un pé àwọn ò ní ẹ̀tanú èyíkéyìí sí ẹnikẹ́ni lára àwọn tó fẹ̀sùn kan àwọn." }
{ "en": "Russia has now convicted and sentenced seven men to prison. Over 250 brothers and sisters in Russia are facing criminal charges, with 41 in detention (pretrial or prison) and 23 under house arrest.", "eng": null, "yor": "Ní báyìí, ìjọba Rọ́ṣíà, ti dá àwọn arákùnrin wa méje lẹ́bi tí wọ́n sì ti jù wọ́n sẹ́wọ̀n. Ó ju igba ó lé àádọ́ta (250) àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wa ní Rọ́ṣíà tí wọ́n ti fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kàn. Àwọn mọ́kànlélógójì (41) wà ní àtìmọ́lé (ìyẹn àwọn tí wọ́n tì mọ́lé láì tíì gbọ́ ẹjọ́ wọn tàbí àwọn tí wọ́n ti dá lẹ́bi tí wọ́n sì ti jù sẹ́wọ̀n), wọ́n ò sì gbá àwọn mẹ́tàlélógún (23) láyè láti jáde kúrò ní ilé wọn." }
{ "en": "We pray for all of our faithful and courageous brothers and sisters in Russia that they ‘may be strengthened with all power according to [Jehovah’s] glorious might so that [they] may endure fully with patience and joy.’—Colossians 1:11.\"", "eng": null, "yor": "A gbàdúrà fún gbogbo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa olóòótọ́ àti onígboyà ní Rọ́ṣíà pé ‘kí agbára [Jèhófà] ológo fún [wọn] ní gbogbo agbára tí [wọn] nílò, kí [wọn] lè fara dà á ní kíkún pẹ̀lú sùúrù àti ìdùnnú.’​—Kólósè 1:11.\"" }
{ "en": "\"As was announced on February 6, 2019, the Zheleznodorozhniy District Court of Oryol sentenced Dennis Christensen to six years in prison for engaging in peaceful worship.", "eng": null, "yor": "\"Bá a ṣe sọ nínú ìròyìn tó jáde ní February 6, 2019, Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Zheleznodorozhniy nílùú Oryol ti rán Arákùnrin Dennis Christensen lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà torí pé ó ń jọ́sìn pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà." }
{ "en": "The verdict is in the process of being appealed to a higher court.", "eng": null, "yor": "Arákùnrin náà ti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí ilé ẹjọ́ gíga." }
{ "en": "The news of Christensen’s six-year sentence immediately provoked an international response.", "eng": null, "yor": "Ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ló kọminú sí ẹjọ́ tí wọ́n dá fún arákùnrin wa yìí. Bí àpẹẹrẹ, Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù." }
{ "en": "Bodies within the Council of Europe, the European Union, the United States Commission on International Religious Freedom, the Office of the United Nations High Commissioner for Human Rights, and other organizations have decried Russia’s unjust and unwarranted prosecution of Dennis Christensen.", "eng": null, "yor": "Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù, Àjọ Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà Tó Ń Rí sí Òmìnira Ẹ̀sìn Kárí Ayé, Ọ́fíìsì Ọ̀gá Àgbà Àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn àti onírúurú àwọn àjọ míì ló ti kéde pé ohun tí ìjọba Rọ́ṣíà ṣe fún Christensen kò bẹ́tọ̀ọ́ mu rárá àti pé wọ́n kàn ń fìyà jẹ aláìṣẹ̀ ni." }
{ "en": "The U.N. High Commissioner for Human Rights, Michelle Bachelet, issued a statement that said, in part: “The harsh sentence imposed on Christensen creates a dangerous precedent, and effectively criminalizes the right to freedom of religion or belief for Jehovah’s Witnesses in Russia.”", "eng": null, "yor": "Ọ̀gá Àgbà Àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ìyẹn Michelle Bachelet sọ pé: “Ẹjọ́ tí wọ́n dá fún Christensen lè dá wàhálà sílẹ̀ torí pé láti ìsinsìnyí lọ, ilé ẹjọ́ lè fẹ̀sùn ọ̀daràn kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìjọba sọ pé gbogbo èèyàn lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n.”" }
{ "en": "She urged the Russian government “to revise the Federal Law on Combating Extremist Activity with a view to clarifying the vague and open-ended definition of ‘extremist activity,’ and ensuring that the definition requires an element of violence or hatred.”", "eng": null, "yor": "Ó wá gba ìjọba Rọ́ṣíà níyànjú pé kí wọ́n “ṣàyẹ̀wò òfin tó dá lórí Bí Wọ́n Ṣe Lè Gbéjà Ko Àwọn Agbawèrèmẹ́sìn kí wọ́n lè ṣàtúnṣe sí ìtumọ̀ tí wọ́n fún ọ̀rọ̀ náà ‘agbawèrèmẹ́sìn,’ kí wọ́n sì rí i dájú pé àwọn alákatakítí tó ń hùwà jàgídíjàgan ni wọ́n kà sí agbawèrèmẹ́sìn.”" }
{ "en": "Ms. Bachelet concluded by calling on the authorities “to drop charges against and to release all those detained for exercising their rights to freedom of religion or belief, the freedom of opinion and expression, and the right to freedom of peaceful assembly and association.”", "eng": null, "yor": "Bachelet wá sọ ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kí àwọn aláṣẹ “wọ́gi lé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn tó ń lo òmìnira tí wọ́n ní láti ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n, àwọn tó lómìnira láti gba ohun tó wù wọ́n gbọ́ àti láti pé jọ ní àlàáfíà, kí wọ́n sì dá àwọn tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n sílẹ̀ lómìnira.”" }
{ "en": "Two days after the sentencing of Brother Christensen, four well-known Russian human rights experts organized a press conference in Moscow.", "eng": null, "yor": "Ọjọ́ méjì lẹ́yìn tí wọ́n dájọ́ Arákùnrin Christensen, àwọn gbajúgbajà mẹ́rin tí wọ́n jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́-ọmọnìyàn ní Rọ́ṣíà ṣètò ìpàdé kan pẹ̀lú àwọn oníròyìn nílùú Moscow." }
{ "en": "The venue was filled to capacity, and over 6,000 people followed the hour-long program that was streamed online.", "eng": null, "yor": "Èrò kún fọ́fọ́ níbi tí wọ́n ti ṣèpàdé náà, àwọn tó sì lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ló ń wo ètò náà bí wọ́n ṣe ń ṣe é látorí íńtánẹ́ẹ̀tì." }
{ "en": "All on the panel defended Jehovah’s Witnesses as a peaceful people who pose no threat to society.", "eng": null, "yor": "Gbogbo àwọn tó sọ̀rọ̀ níbi ìpàdé náà ló gbèjà àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sọ pé èèyàn àlàáfíà ni wọ́n, wọn kì í sì í dá wàhálà sílẹ̀ nílùú." }
{ "en": "Press conference held in Moscow on February 8, 2019.", "eng": null, "yor": "Ìpàdé àwọn oníròyìn nílùú Moscow ní February 8, 2019." }
{ "en": "Also participating in the press conference were Brother Christensen’s wife, Irina; his lawyer, Mr. Anton Bogdanov; and a representative from the European Association of Jehovah’s Witnesses, Yaroslav Sivulskiy.", "eng": null, "yor": "Lára àwọn tó wà níbi ìpàdé náà ni ìyàwó Arákùnrin Christensen, ìyẹn Irina; agbẹjọ́rò rẹ̀, Ọ̀gbẹ́ni Anton Bogdanov; àti aṣojú Àjọ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Yúróòpù, ìyẹn Yaroslav Sivulskiy." }
{ "en": "They made statements regarding the unjust verdict and responded to questions from the press.", "eng": null, "yor": "Gbogbo wọn ló sọ̀rọ̀ nípa ẹjọ́ àìtọ́ tí wọ́n dá fún Arákùnrin Christensen, wọ́n sì dáhùn ìbéèrè àwọn oníròyìn." }
{ "en": "Despite being in prison for almost two years, Brother Christensen continues to maintain his joy and his resolve to trust in Jehovah.", "eng": null, "yor": "Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Arákùnrin Christensen ti fẹ́rẹ̀ẹ́ lo ọdún méjì lẹ́wọ̀n, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó sì ń láyọ̀." }
{ "en": "Just days before the final verdict, while delivering his final statement to the court, Brother Christensen noted: “The truth sooner or later becomes obvious, and it will be the case in this matter.”", "eng": null, "yor": "Nínú ọ̀rọ̀ àsọkẹ́yìn tó sọ nílé ẹjọ́ ní ọjọ́ díẹ̀ ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n dájọ́ rẹ̀, Arákùnrin Christensen sọ pé: “Bópẹ́ bóyá, ohun tó jẹ́ òótọ́ máa hàn kedere, bó sì ṣe máa rí nínú ẹjọ́ yìí náà nìyẹn.”" }
{ "en": "After reading Revelation 21:3-5, he concluded with full conviction: “These words . . . describe the time when God will take care of justice and true freedom for all people.", "eng": null, "yor": "Lẹ́yìn tó ka Ìfihàn 21:3-5, ó fi ìdánilójú sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ yìí . . . sọ nípa ìgbà tí Ọlọ́run máa ṣèdájọ́ òdodo, tá a sì fún gbogbo èèyàn ní òmìnira tòótọ́." }
{ "en": "Freedom and justice are closely related to each other.", "eng": null, "yor": "Ìdájọ́ òdodo ló ń mú kéèyàn ní òmìnira tòótọ́." }
{ "en": "God will make sure that all of this will be fulfilled.”", "eng": null, "yor": "Ọlọ́run á sì rí i dájú pé gbogbo èèyàn rí ìdájọ́ òdodo gbà.”" }
{ "en": "Brother Christensen must await the appeal ruling while in Detention Facility No. 1 in the Oryol Region—where he has been imprisoned for the past 20 months.", "eng": null, "yor": "Títí dìgbà tí wọ́n máa bẹ̀rẹ̀ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, Arákùnrin Christensen ṣì máa wà ní àtìmọ́lé nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n kan ní ìpínlẹ̀ Oryol, níbi tó ti wà láti nǹkan bí ọdún kan àti oṣù mẹ́jọ." }
{ "en": "We will continue to pray that Jehovah give his unfailing support to Dennis Christensen, his wife, and all of our fellow worshippers throughout Russia.—1 Peter 3:12.", "eng": null, "yor": "Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà wà pẹ̀lú Arákùnrin Dennis Christensen àti ìyàwó rẹ̀. Kó sì tún dúró ti gbogbo àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.—1 Pétérù 3:12." }
{ "en": "Sorry, the media player failed to load.", "eng": null, "yor": "Máà bínú, ètò tó o fi ń wo fídíò kò ṣiṣẹ́." }
{ "en": "Download This Video", "eng": null, "yor": "Wa Fídíò Yìí Jáde" }
{ "en": "The video Russian Trial Called ‘A Litmus Test For Religious Freedom’ was produced by the international media outlet RFE/RL just days before the verdict was announced.\"", "eng": null, "yor": "Nígbà tó ku ọjọ́ díẹ̀ tí wọ́n máa dájọ́ arákùnrin náà, ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde kan, ìyẹn RFE/RL ṣe fídíò kan tí wọ́n pè ní Russian Trial Called ‘A Litmus Test For Religious Freedom’ (ìyẹn, Ìgbẹ́jọ́ Kan ní Rọ́ṣíà Tó Máa Jẹ́ ‘Ìlànà Fáwọn Ẹjọ́ Míì Nípa Òmìnira Ẹ̀sìn’).\"" }
{ "en": "\"Since April 20, 2017, when the Russian Supreme Court effectively banned the worship of Jehovah’s Witnesses in the country, our brothers and sisters have faced relentless persecution and imprisonment.", "eng": null, "yor": "\"Látìgbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà ti fòfin de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní April 20, 2017, ni wọ́n ti ń ṣenúnibíni sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, tí wọ́n sì ń fi wọ́n sẹ́wọ̀n." }
{ "en": "Authorities have also progressively seized 131 of the properties owned by Jehovah’s Witnesses, with an additional 60 properties subject to confiscation.", "eng": null, "yor": "Àtìgbà náà làwọn aláṣẹ ti gbẹ́sẹ̀ lé dúkìá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí iye rẹ̀ tó mọ́kànléláàádóje (131)." }
{ "en": "The total value of the properties is estimated to be over $57 million.", "eng": null, "yor": "Wọ́n sì tún ń sapá láti gbẹ́sẹ̀ lé ọgọ́ta (60) dúkìá míì. Àròpọ̀ gbogbo dúkìá náà ju mílíọ̀nù mẹ́tàdínlọ́gọ́ta (57) owó dọ́là lọ." }
{ "en": "One of the seized properties was the former Russia branch complex in Solnechnoye—a property that was owned by the Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania.", "eng": null, "yor": "Ọ̀kan lára ohun ìní tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé ni ilé Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania tó wà ní Solnechnoye, ìyẹn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Rọ́ṣíà tẹ́lẹ̀." }
{ "en": "(See picture above on left.)", "eng": null, "yor": "(wo àwòrán tó wà lókè lápá òsì.)" }
{ "en": "This property alone is valued at about $30 million. An additional 43 of the properties that were seized belong to foreign legal entities existing in Austria, Denmark, Finland, the Netherlands, Norway, Portugal, Spain, Sweden, and the United States.", "eng": null, "yor": "Tá a bá ṣírò iye tí ilé yìí nìkan jẹ́, ó tó ọgbọ̀n (30) mílíọ̀nù owó dọ́là. Dúkìá mẹ́tàlélógójì (43) míì tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé jẹ́ ti àjọ ilẹ̀ òkèèrè tá a gbé kalẹ̀ lábẹ́ òfin tó wà ní Austria, Denmark, Finland, Netherlands, Nọ́wè, Pọ́túgà, Sípéènì, Sweden, àti Amẹ́ríkà." }
{ "en": "The seizures are illegal, since the Supreme Court decision banning Jehovah’s Witnesses did not give the government a legal basis for taking foreign-owned properties.", "eng": null, "yor": "Òótọ́ ni pé Ilé Ẹjọ́ Gíga ti fòfin dé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ ìyẹn ò fún ìjọba láṣẹ láti gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ohun ìní wa tó jẹ́ ti ilẹ̀ òkèèrè, torí náà bí wọ́n ṣe gba àwọn dúkìá náà kò bófin mu." }
{ "en": "Jehovah’s Witnesses have filed a claim with the European Court of Human Rights (ECHR) concerning the illegal seizure of the former Russia branch property.", "eng": null, "yor": "Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kọ̀wé sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù (ECHR) lórí bí ìjọba ṣe gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀ka ọ́fíìsì tá à ń lò ní Rọ́ṣíà tẹ́lẹ̀." }
{ "en": "Regardless of how the ECHR rules, our trust and confidence are in Jehovah.", "eng": null, "yor": "Ìpinnu yòówù kí ECHR ṣe, Jèhófà la fọkàn tán, òun la sì gbára lé." }
{ "en": "We pray that our brothers and sisters in Russia continue to be courageous as they refuse to let raids, arrests, or confiscation of meeting places stop them from worshipping Jehovah “with spirit and truth.”—John 4:23.\"", "eng": null, "yor": "Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà fún àwọn ará wa ní Rọ́ṣíà lókun kí wọ́n lè máa fìgboyà sin Jèhófà “ní ẹ̀mí àti òtítọ́” láìka bí ìjọba ṣe ń dà wọ́n láàmù, tí wọ́n ń mú wọ́n, tí wọ́n sì ń gbẹ́sẹ̀ lé àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa.​—Jòhánù 4:23.\"" }
{ "en": "\"On November 5, 2019, the Oktyabrsky District Court of Tomsk sentenced Brother Sergey Klimov to six years in prison.", "eng": null, "yor": "\"Ní November 5, 2019, ilé ẹjọ́ àgbègbè Oktyabrsky nílùú Tomsk ju Arákùnrin Sergy Klimov sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́fà." }
{ "en": "Dennis Christensen is the only other brother in Russia to have received a sentence of this length.", "eng": null, "yor": "Dennis Christensen ni arákùnrin tí wọ́n kọ́kọ́ dá ẹ̀wọ̀n ọlọ́jọ́ gbọọrọ bẹ́ẹ̀ fún." }
{ "en": "However, in Brother Klimov’s case, the court imposed several additional restrictions, making his the harshest sentence imposed on one of our brothers since the 2017 Supreme Court ban.", "eng": null, "yor": "Àmọ́, ọ̀rọ̀ arákùnrin Klimov tún wá burú sí i torí pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni ilé ẹjọ́ ká a lọ́wọ́ kò pé kò ní lè ṣe, èyí ló mú kí ìdájọ́ tiẹ̀ jẹ́ èyí tó le jù lọ tó tíì wáyé látìgbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti fòfin de iṣẹ́ wa lọ́dún 2017." }
{ "en": "Brother Klimov was arrested on June 3, 2018, after law enforcement, including special forces, invaded two homes of Jehovah’s Witnesses.", "eng": null, "yor": "Wọ́n mú arákùnrin Klimov ní June 3, 2018, nígbà táwọn agbófinró àtàwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ya wọ ilé àwọn Elẹ́rìí Jèhófà méjì." }
{ "en": "Some 30 brothers and sisters, including an 83-year-old sister, were taken away for questioning.", "eng": null, "yor": "Nǹkan bí ọgbọ̀n (30) àwọn ará wa ni wọ́n mú kí wọ́n lè fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò. Kódà wọ́n mú arábìnrin kan tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin (83)." }
{ "en": "All but Brother Klimov were released. Criminal charges were brought against him, and a court ordered that he be placed in pretrial detention for two months.", "eng": null, "yor": "Wọ́n dá àwọn tó kù sílẹ̀, àfi arákùnrin Klimov. Wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn án, ilé ẹjọ́ sì pàṣẹ pé kó ṣì wà látìmọ́lé fún oṣú méjì kí wọ́n tó dá ẹjọ́ rẹ̀." }
{ "en": "His term was extended seven times, meaning that even before beginning his six-year prison sentence, he has been incarcerated—separated from his wife and family—for a year and five months.", "eng": null, "yor": "Ẹ̀ẹ̀méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n sún ẹjọ́ rẹ̀ síwájú, tó túmọ̀ sí pé kó tó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà tí wọ́n dá fún un, ó ti lo ọdún kan àti oṣù márùn-ún ní àtìmọ́lé láìfojú kan ìyàwó àti ìdílé rẹ̀." }
{ "en": "Lawyers for Brother Klimov will appeal his conviction.", "eng": null, "yor": "Àwọn agbẹjọ́rò tó ń ṣojú fún arákùnrin Klimov máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ẹjọ́ náà." }
{ "en": "Additionally, on August 20, 2018, the complaint Klimov v. Russia was filed with the European Court of Human Rights regarding his pretrial detention.", "eng": null, "yor": "Yàtọ̀ síyẹn, ní August 20, 2018, wọ́n gbé ẹjọ́ nípa Klimov àti ilẹ̀ Rọ́ṣíà lọ síwájú Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù lórí bí wọ́n ṣe ń sún àsìkò tí wọ́n fẹ́ fi gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ síwájú." }
{ "en": "Throughout 2019, we have seen an increase in raids, arrests, and detentions in Russia.", "eng": null, "yor": "Jálẹ̀ ọdún 2019, iye ilé àwọn ará wa táwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà lọ fọ́ túbọ̀ pọ̀ sí i, tó fi mọ́ iye àwọn tí wọ́n mú àtàwọn tí wọ́n ń fi sí àtìmọ́lé. Síbẹ̀, ìgbàgbọ́ àwọn ará wa ò mì rárá." }
{ "en": "Yet, our brothers remain undeterred. We are encouraged by the evidence that Jehovah is blessing our brothers’ full confidence in him.—Psalm 56:1-5, 9.\"", "eng": null, "yor": "A ń rí ẹ̀rí tó fi hàn pé Jèhófà ń bù kún àwọn ará wa bí wọ́n ṣe gbẹ́kẹ̀ lé e, ìyẹn sì túbọ̀ ń fún wa níṣìírí.—Sáàmù 56:1-5, 9.\"" }
{ "en": "\"On Thursday, May 16, 2019, the appeal hearing for Dennis Christensen resumed as scheduled.", "eng": null, "yor": "\"Ní Thursday, May 16, 2019, ìgbẹ́jọ́ Dennis Christensen tẹ̀ síwájú gẹ́gẹ́ bí ilé ẹjọ ṣe sọ tẹ́lẹ̀." }
{ "en": "The prosecutors and defense attorneys delivered their closing arguments, and Dennis was able to speak in his defense for nearly an hour.", "eng": null, "yor": "Àwọn agbẹjọ́rò ìjọba àtàwọn tó ń gbèjà Dennis fẹnu ọ̀rọ̀ wọn jóná lọ́kọ̀ọ̀kan, wọ́n sì gba Dennis láyè pé kóun náà fi nǹkan bíi wákàtí kan gbèjà ara rẹ̀." }
{ "en": "Foreign diplomats and journalists were again present—an encouraging indication that, even though it has been two years since Dennis’ arrest made international news, the world remains keenly interested in his case.", "eng": null, "yor": "Àwọn aṣojú láti ilẹ̀ òkèèrè àtàwọn akọ̀ròyìn lóríṣiríṣi wà níbẹ̀, èyí fi hàn pé bó tiẹ̀ ti pọ́dún méjì báyìí tórọ̀ Dennis ti jáde nínú ìròyìn kárí ayé pé wọ́n tì í mọ́lé, àwọn èèyàn káàkiri ayé ṣì fẹ́ mọbi tọ́rọ̀ ẹjọ́ ẹ̀ máa já sí." }
{ "en": "Originally, the hearing was scheduled to last through Friday, May 17. However, the judges announced they would adjourn until Thursday, May 23 at 10 a.m.", "eng": null, "yor": "Ètò tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe ni pé kí wọ́n parí ìgbẹ́jọ́ náà ní Friday, May 17. Àmọ́, àwọn adájọ́ sún ẹjọ́ náà sí aago mẹ́wàá àárọ̀ Thursday, May 23." }
{ "en": "Dennis will then be granted his last opportunity to appeal to the court before the judges break to deliberate.", "eng": null, "yor": "Wọ́n á fún Dennis láyè láti gbèjà ara rẹ̀ níwájú àwọn adájọ́, lẹ́yìn ìyẹn, àwọn adájọ́ náà á foríkorí kí wọ́n lè ṣèpinnu." }
{ "en": "It is difficult to project whether a decision will be announced by the end of the day on May 23, or if the court will schedule a future date to do so.", "eng": null, "yor": "A ò tíì lè sọ bóyá May 23 yẹn náà ni ilé ẹjọ́ máa sọ ìpinnu rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí àbí wọ́n máa mú ọjọ́ míì tí wọ́n á sọ ìpinnu tí ilé ẹjọ́ bá ṣe." }
{ "en": "We take courage when we see our brothers, such as Dennis Christensen and Sergey Skrynnikov, maintain a positive disposition and express their sincere desire to remain faithful.", "eng": null, "yor": "Bá a ṣe ń rí àwọn ará bíi Dennis Christensen àti Sergey Skrynnikov, tí wọn ò bọkàn jẹ́, tí wọ́n sì ń fi hàn pé àwọn ò ní yẹhùn, àpẹẹrẹ wọn ń fún wa nígboyà." }
{ "en": "We feel the same way about our fellow Witnesses in Russia as the apostle Paul felt about the Thessalonians when he was inspired to write: “We ourselves take pride in you among the congregations of God because of your endurance and faith in all your persecutions and the hardships that you are suffering.”—2 Thessalonians 1:4.\"", "eng": null, "yor": "Ńṣe lohun tá à ń rò nípa àwọn ará wa ní Rọ́síà ṣọ̀kan pẹ̀lú ohun tí àpọ́síltélì Pọ́ọ̀lù sọ nipa àwọn ará Tẹsalóníkà, ó ní: “À ń fi yín yangàn láàárín ìjọ Ọlọ́run nítorí ìfaradà àti ìgbàgbọ́ yín nínú gbogbo inúnibíni àti àwọn ìṣòro tí ẹ̀ ń dojú kọ.”—2 Tẹsalóníkà 1:4.\"" }
{ "en": "\"On March 1, 2019, the Supreme Court of the Republic of Kabardino-Balkaria overturned a lower court’s conviction of Brother Arkadya Akopyan.", "eng": null, "yor": "\"Ní March 1, 2019, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Republic of Kabardino-Balkaria wọ́gi lé ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ kan fi dẹ́bi fún Arákùnrin Arkadya Akopyan." }
{ "en": "He had been on trial for over a year, wrongfully accused of distributing “extremist” literature and ‘inciting religious hatred.’", "eng": null, "yor": "Ó ti lé lọ́dún kan tí wọ́n ti ń gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀, wọ́n fẹ̀sùn èké kàn án pé ó ń pín ìwé “àwọn agbawèrèmẹ́sìn,” ó sì ń ‘rúná sí ìkórìíra ẹ̀sìn.’" }
{ "en": "Previously, a lower court sentenced 70-year-old Brother Akopyan to perform community service. This recent Supreme Court ruling dismissed the lower court’s sentence.", "eng": null, "yor": "Ilé ẹjọ́ kan ti kọ́kọ́ sọ pé kí Arákùnrin Akopyan, ẹni àádọ́rin (70) ọdún lọ ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú. Àmọ́ ìdájọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ṣe yìí wọ́gi lé ìdájọ́ ti tẹ́lẹ̀." }
{ "en": "We thank Jehovah for this victory as we rejoice with Brother Akopyan. We continue to pray that our brothers will faithfully endure.—2 Thessalonians 1:4.\"", "eng": null, "yor": "A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó mú ká borí nínú ẹjọ́ yìí, a sì bá Arákùnrin Akopyan yọ̀. Àdúrà wa ni pé kí àwọn ará wa máa fi ìṣòtítọ́ fara dà á nìṣó.—2 Tẹsalóníkà 1:4.\"" }
{ "en": "On December 13, 2019, Brother Vladimir Alushkin was convicted and sentenced to six years in prison.", "eng": null, "yor": "Ní December 13, 2019, ilé ẹjọ́ dá ẹjọ́ Arákùnrin Vladimir Alushkin, wọ́n sì rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà." }
{ "en": "He was immediately handcuffed and taken into custody.", "eng": null, "yor": "Ojú ẹsẹ̀ níbẹ̀ ni wọ́n ti fí ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sí i lọ́wọ́ tí wọ́n sì mú un lọ." }
{ "en": "Brother Alushkin will appeal the conviction.", "eng": null, "yor": "Arákùnrin Alushkin máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ìdájọ́ yìí." }
{ "en": "\"As of today, Brother Dennis Christensen has endured three years of unjust imprisonment in Russia.", "eng": null, "yor": "\"Bá a se ń sọ̀rọ̀ yìí, ó ti tó ọdún mẹ́ta tí wọ́n ti fi Arákùnrin Dennis Christensen sẹ́wọ̀n lọ́nà àìtọ́ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà." }
{ "en": "Since his arrest on May 25, 2017, some friends have asked Brother Christensen how this tribulation has affected his faith.", "eng": null, "yor": "Láti May 25, 2017 ni wọ́n ti mú Arákùnrin Christensen, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa bí gbogbo wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀ sí i yìí ṣe ń nípa lórí ìgbàgbọ́ rẹ̀." }
{ "en": "His answer has remained the same: “My faith has become only stronger.”", "eng": null, "yor": "Ohun kan náà ló ṣì fi ń dáhùn látìgbà yẹn: “Ṣe ni ìgbàgbọ́ mi ń lágbára sí i.”" }
{ "en": "Brother Christensen relates: “I have experienced what is written in the Bible book of James chapter 1, verses 2 to 3: ‘Consider it all joy, my brothers, when you meet with various trials, knowing as you do that this tested quality of your faith produces endurance.’”", "eng": null, "yor": "Arákùnrin Christensen sọ pé: “Ohun tó wà nínú ìwé Jémíìsì orí kìíní ẹsẹ kejì sí ìkẹta ti ṣẹ sí mi lára, èyí tó sọ pé: ‘Ẹ̀yin ará mi, tí oríṣiríṣi àdánwò bá dé bá yín, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìgbàgbọ́ yín tí a dán wò ní ti bó ṣe jẹ́ ojúlówó tó máa mú kí ẹ ní ìfaradà.’ ”" }
{ "en": "Remarkably, Brother Christensen’s faith, and even his joy, has grown amidst increasing hardships and disappointments.", "eng": null, "yor": "Ó wú wa lórí láti mọ̀ pé láìka gbogbo ìṣòro àti ìjákulẹ̀ tí Arákùnrin Christensen ti kojú sí, ńṣe ni ìgbàgbọ́ rẹ̀ ń lágbára sí i, tí inú rẹ̀ sì ń dùn." }
{ "en": "Immediately after his arrest, Brother Christensen was placed in a pretrial detention facility not far from his home in Oryol.", "eng": null, "yor": "Lẹ́yìn tí ìjọba mú Arákùnrin Christensen, kó tó di pé wọ́n mú un lọ sílé ẹjọ́, wọ́n fi sí àtìmọ́lé níbì kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí ilé rẹ̀ ní ìlú Oryol." }
{ "en": "In time, his wife, Irina, was granted permission to visit.", "eng": null, "yor": "Kò pẹ́ sígbà yẹn, wọ́n gbà Irina ìyàwó rẹ̀ láyè láti máa wá bẹ̀ ẹ́ wò." }
{ "en": "Brother Christensen remained in pretrial detention for just over two years.", "eng": null, "yor": "Ó lé ní ọdún méjì tí wọ́n fi ti Arákùnrin Christensen mọ́lé láì tíì gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀." }
{ "en": "In February 2019, Brother Christensen was sentenced to six years in prison. Three months later, his appeal was denied.", "eng": null, "yor": "Ní February 2019, wọ́n dájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà fún Arákùnrin Christensen. Oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà, ó pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, àmọ́ wọn ò gbà á láyè." }
{ "en": "He was subsequently transferred to a prison some 200 kilometers (124 mi) away from Oryol, further distancing him from Irina.", "eng": null, "yor": "Lẹ́yìn náà wọ́n gbé e lọ sí ẹ̀wọ̀n míì tó jìnnà tó máìlì mẹ́rìnlélọ́gọ́fà [124] (200km) sí ìlú Oryol tí ìyàwó rẹ̀ wà, èyí sì mú kí ibi táwọn méjèèjì wà túbọ̀ jìnnà síra." }
{ "en": "For almost a year now, Brother Christensen has qualified to apply for early release, three of his four applications have been denied.", "eng": null, "yor": "Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún kan báyìí tí Arákùnrin Christensen ti lẹ́tọ̀ọ́ láti béèrè pé kí wọ́n dá òun sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, ó sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àmọ́ ẹ̀ẹ̀mẹta ni ìjọba ti dá a lóhùn pé kò ṣeé ṣe." }