translation
dict |
---|
{
"en": "As the Working Group explains, international law recognizes the right of all persons “to be presumed innocent until proven guilty in accordance with the law.”",
"eng": null,
"yor": "Nínú àlàyé táwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ náà ṣe, wọ́n ní òfin àwọn orílẹ̀-èdè jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀tọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan ni “pé kí wọ́n fojú aláìmọwọ́mẹsẹ̀ wò ó, títí wọ́n á fi rí i dájú pé onítọ̀hún jẹ̀bi ẹsùn tí wọ́n fi kàn án.”"
} |
{
"en": "For that reason, our sisters should not have been “shackled or kept in cages during trials or otherwise presented to the court in a manner indicating that they may be dangerous criminals.”",
"eng": null,
"yor": "Torí náà, kò yẹ kí wọ́n fi “ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sí àwọn arábìnrin wa lọ́wọ́ tàbí kí wọ́n fi wọ́n sínú àhámọ́ nígbà tí wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ wọn, torí ìyẹn á jẹ́ káwọn èèyàn máa fi ojú ọ̀daràn paraku wò wọ́n.”"
} |
{
"en": "The Working Group demands that Russia expunge the criminal records of all 18 Witnesses and compensate them in accordance with international law.",
"eng": null,
"yor": "Àwùjọ náà tún sọ pé kí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà wọ́gi lé àkọ́sílẹ̀ ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjìdínlógún (18) náà."
} |
{
"en": "Further, the country is called upon to “ensure a full and independent investigation of the circumstances surrounding the arbitrary deprivation of liberty” and “take appropriate measures against those responsible for the violation of [the Witnesses’] rights.”",
"eng": null,
"yor": "Kí wọ́n sì tún san owó gbà-má-bínú fún wọn, bí òfin àwọn orílẹ̀-èdè ṣe sọ. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ní kí ìjọba orílẹ̀-èdè náà “ṣèwádìí fínnífínní nípa ohun tó mú káwọn aláṣẹ hùwà àìtọ́ yìí,” kí wọ́n sì “gbé ìgbẹ́sẹ̀ lórí àwọn tó ń fi ẹ̀tọ́ [àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] dù wọ́n.”"
} |
{
"en": "The opinion notes that the 18 Witnesses are “part of a now ever-growing number of Jehovah’s Witnesses in Russia who have been arrested, detained, and charged with criminal activity on the basis of mere exercise of freedom of religion.”",
"eng": null,
"yor": "Wọ́n tún sọ nínú ìwé náà pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjìdínlógún (18) tí wọ́n mú wulẹ̀ jẹ́ díẹ̀ “lára ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Rọ́ṣíà, tí wọ́n fi sátìmọ́lé, tí wọ́n sì fi ẹ̀sùn kàn pé wọ́n jẹ́ ọ̀daràn, torí pé wọ́n ń lo ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti máa ṣe ìsìn wọn.”"
} |
{
"en": "A right protected by an international covenant to which Russia is a party.",
"eng": null,
"yor": "Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà wà lára àwọn tó fọwọ́ sí ẹ̀tọ́ yìí nínú àdéhùn táwọn orílẹ̀-èdè ṣe."
} |
{
"en": "Therefore, although the present opinion focuses on the 18 named brothers and sisters, the Working Group was unequivocal that the findings “apply to all others in similar situations.”",
"eng": null,
"yor": "Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹjọ́ àwọn ará wa méjìdínlógún (18) ni ìwé tí àwùjọ náà kọ dá lé, wọ́n tún jẹ́ kó ṣe kedere pé ohun tí wọ́n sọ “kan gbogbo àwọn míì tó wà nírú ipò yẹn.”"
} |
{
"en": "The Working Group’s call to action does not guarantee that our brothers and sisters in Russia will be exonerated, but there is hope that it may improve the situation.",
"eng": null,
"yor": "Kò sí ẹ̀rí tó dájú pé ìwé táwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ yìí kọ máa mú kí àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà dá àwọn ará wa sílẹ̀, àmọ́ a gbà pé ó ṣeé ṣe kó mú kí ọ̀rọ̀ náà yanjú déwọ̀n àyè kan."
} |
{
"en": "We await Russia’s response.",
"eng": null,
"yor": "À ń retí ohun táwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà máa ṣe sọ́rọ̀ yìí."
} |
{
"en": "In the meantime, as our brothers and sisters in Russia courageously endure persecution, we know our loving Father, Jehovah, will continue to fill them with joy and peace for trusting in him.—Romans 15:13.\"",
"eng": null,
"yor": "Ní báyìí ná, a mọ̀ pé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó wà ní Rọ́ṣíà á máa fara da inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sí wọn, a sì mọ̀ pé Jèhófà, Baba wa onífẹ̀ẹ́, á jẹ́ kí wọ́n máa láyọ̀, kí ọkàn wọn sì balẹ̀, torí pé òun ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé.—Róòmù 15:13.\""
} |
{
"en": "On Tuesday, June 9, 2020, the Pskov City Court convicted 61-year-old Brother Gennady Shpakovskiy and sentenced him to six and a half years in prison.",
"eng": null,
"yor": "Lọ́jọ́ Tuesday, June 9, 2020, ilé ẹjọ́ Pskov City Court dẹ́bi fún Arákùnrin Gennady Shpakovskiy tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta (61), wọ́n sì dájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà àtààbọ̀ fún un."
} |
{
"en": "He was immediately taken to prison from the courtroom.",
"eng": null,
"yor": "Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí wọ́n dájọ́ fún un tán ni wọ́n mú un lọ sínú ẹ̀wọ̀n."
} |
{
"en": "This is the longest sentence handed down to one of our brothers since the 2017 Russian Supreme Court ruling that effectively criminalized our activity.",
"eng": null,
"yor": "Iye ọdún tí wọ́n dá fún arákùnrin wa yìí ló ṣì pọ̀ jù láti ọdún 2017 tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà ti ṣòfin pé ọ̀daràn ni ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá rí tó ń ṣe ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà."
} |
{
"en": "Brother Shpakovskiy will appeal the conviction.",
"eng": null,
"yor": "Arákùnrin Shpakovskiy máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ẹjọ́ tí wọ́n dá fún un."
} |
{
"en": "\"Judge Oleg Golovashko of the Prohladniy District Court in Russia announced the verdict in the case against Brother Arkadya Akopyan on Thursday, December 27.",
"eng": null,
"yor": "\"Ní Thursday, December 27, Adájọ́ Oleg Golovashko ti Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Prohladniy ní Rọ́ṣíà sọ ìpinnu ilé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Arákùnrin Arkadya Akopyan."
} |
{
"en": "The court sentenced Brother Akopyan, a 70-year-old retired tailor, to 120 hours of community service based on the absurd accusation that he allegedly commissioned non-Witnesses to distribute extremist literature.",
"eng": null,
"yor": "Ilé ẹjọ́ sọ pé Arákùnrin Akopyan, tó jẹ́ ẹni àádọ́rin (70) ọdún tó ti fẹ̀yìn tì nídìí iṣẹ́ télọ̀, máa fi ọgọ́fà (120) wákàtí ṣe iṣẹ́ ìlú torí ẹ̀sùn èké tí wọ́n fi kàn án pé ó rán àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí wọ́n lọ máa pín ìwé àwọn agbawèrèmẹ́sìn kiri."
} |
{
"en": "While Brother Akopyan was not sentenced to prison, this conviction is a gross violation of human rights.",
"eng": null,
"yor": "Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò rán Arákùnrin Akopyan lẹ́wọ̀n, ẹjọ́ tí wọ́n dá fún un yìí ta ko ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn."
} |
{
"en": "Therefore, the ruling will be appealed to a higher court.",
"eng": null,
"yor": "Nítorí náà, a máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí ilé gíga."
} |
{
"en": "In the coming weeks, we anticipate a judgment on the case involving Dennis Christensen.",
"eng": null,
"yor": "Ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sí i, à ń retí ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ máa ṣe lórí ẹjọ́ Arákùnrin Dennis Christensen."
} |
{
"en": "We pray that Jehovah continues to support and comfort our brothers and sisters in Russia who are facing imprisonment for their faith.—2 Thessalonians 2:16, 17.\"",
"eng": null,
"yor": "Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà máa ti àwọn ará wa ní Rọ́ṣíà lẹ́yìn, kó sì máa tù wọ́n nínú torí bí wọ́n ṣe ń fi wọ́n sẹ́wọ̀n nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́.—2 Tẹsalóníkà 2:16, 17.\""
} |
{
"en": "\"The Vilyuchinsk City Court is expected to announce its verdict in the trial involving Brother Mikhail Popov and his wife, Sister Yelena Popova, on Thursday, February 13, 2020.",
"eng": null,
"yor": "\"A retí pé kí ilé ẹjọ́ Vilyuchinsk City Court sọ ìdájọ́ wọn lórí ọ̀rọ̀ Arákùnrin Mikhail Popov àti ìyàwó rẹ̀ Arábìnrin Yelena Popova lọ́jọ́ Thursday, February 13, 2020."
} |
{
"en": "The couple was arrested on July 30, 2018, in Kamchatka and were released on August 9, 2018. They have been charged with engaging in “extremist activity.”",
"eng": null,
"yor": "Wọ́n mú tọkọtaya yìí ní July 30, 2018 ní ìlú Kamchatka, àmọ́ wọ́n fi wọ́n sílẹ̀ ní August 9, 2018. Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n ni pé wọ́n ń lọ́wọ́ sí “iṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn.”"
} |
{
"en": "Mikhail and Yelena are relying on Jehovah as they face this distressing trial. We are confident that he will continue to be a “refuge and strength” for them.—Psalm 46:1.\"",
"eng": null,
"yor": "Mikhail àti Yelena gbára lé Jèhófà pátápátá bí wọ́n ṣe ń fara da ipò tó le koko yìí. Ó dá wa lójú pé Jèhófà á máa bá a lọ láti jẹ́ ‘ibi ààbò àti okun’fún wọn.—Sáàmù 46:1.\""
} |
{
"en": "\"Brother Vladimir Alushkin was released from prison and reunited with his wife on March 30, 2020.",
"eng": null,
"yor": "\"A láyọ̀ láti sọ fún yín pé wọ́n ti dá Arákùnrin Vladimir Alushkin sílẹ̀ lẹ́wọ̀n ní March 30, 2020, inú òun àti ìyàwó ẹ̀ sì dùn gan-an pé àwọn tún jọ wà pa pọ̀."
} |
{
"en": "His release was the result of the previously reported March 25 decision by the Penza Regional Court.",
"eng": null,
"yor": "Tẹ́ ò bá gbàgbé, a gbé ìròyìn kan jáde ní March 25 nípa bí Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tó wà nílùú Penza ṣe fagi lé ìpinnu tí ilé ẹjọ́ àkọ́kọ́ ṣe, tí wọ́n sì ní kí wọ́n tún ẹjọ́ náà gbọ́."
} |
{
"en": "The ruling overturned the conviction of Brothers Vladimir Alushkin, Vladimir Kulyasov, Andrey Magliv, and Denis Timoshin, as well as Sisters Tatyana Alushkina and Galiya Olkhova.",
"eng": null,
"yor": "Ìpinnu ilé ẹjọ́ kejì jẹ́ kó ṣe kedere pé Arákùnrin Vladimir Alushkin, Vladimir Kulyasov, Andrey Magliv àti Arákùnrin Denis Timoshin kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n, bákan náà lọ̀rọ̀ sì rí pẹ̀lú Arábìnrin Tatyana Alushkina àti Galiya Olkhova."
} |
{
"en": "The Penza Regional Court returned the case to the original court for consideration by a different judge.",
"eng": null,
"yor": "Nípa bẹ́ẹ̀, Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tó wà nílùú Penza ní kí ilé ẹjọ́ àkọ́kọ́ yan adájọ́ míì láti tún ẹjọ́ náà gbọ́."
} |
{
"en": "In the meantime, all six remain under travel and other restrictions.",
"eng": null,
"yor": "Kó tó di pé wọ́n tún ẹjọ́ yẹn gbọ́, wọ́n fòfin de àwọn ará wa mẹ́fẹ̀ẹ̀fà yẹn pé wọn ò gbọ́dọ̀ rìnrìn-àjò, wọ́n sì tún fi àwọn ẹ̀tọ́ míì dù wọ́n."
} |
{
"en": "Although we are pleased to hear Brother Alushkin was released, just two days later another one of our brothers was convicted for his faith in far northeastern Russia.",
"eng": null,
"yor": "Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú wa dùn gan-an pé wọ́n ti dá Arákùnrin Alushkin sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, ó ká wa lára pé lọ́jọ́ méjì lẹ́yìn náà, wọ́n tún mú ọ̀kan lára àwọn arákùnrin wa lápá àríwá orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà nítorí ohun tó gbà gbọ́."
} |
{
"en": "As long as these baseless legal attacks continue, we know that our brothers and sisters in Russia will keep close in mind the words at Nahum 1:7: “Jehovah is good, a stronghold in the day of distress. He is mindful of those seeking refuge in him.”\"",
"eng": null,
"yor": "Títí dìgbà táwọn èèyàn fi máa ṣíwọ́ àtimáa fẹ̀sùn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ kan àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ó dá wa lójú pé àwọn ará wa yìí á máa fi ọ̀rọ̀ tó wà nínú Náhúmù 1:7 sọ́kàn, èyí tó sọ pé: “Jèhófà jẹ́ ẹni rere, odi agbára ní ọjọ́ wàhálà. Ó sì mọ àwọn tó ń wá ibi ààbò lọ́dọ̀ rẹ̀.”\""
} |
{
"en": "\"The Pskov City Court will announce its verdict on June 8, 2020, in the trial involving 61-year-old Brother Gennady Shpakovskiy.",
"eng": null,
"yor": "\"Ilé ẹjọ́ ìlú Pskov máa gbé ìdájọ́ ẹ̀ kalẹ̀ ní June 8, 2020, lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Arákùnrin Gennady Shpakovskiy, ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta (61)."
} |
{
"en": "He is being accused of “extremist” activity simply for holding small Christian meetings in his home, the prosecution has asked the court to sentence Brother Shpakovskiy to seven and a half years in prison.",
"eng": null,
"yor": "Wọ́n fẹ̀sùn agbawèrèmẹ́sìn kàn-án torí ìpàdé Kristẹni tí wọn ń ṣe nílé ẹ̀. Agbẹjọ́rò ìjọba ti sọ pé kí ilé ẹjọ́ rán Arákùnrin Shpakovskiy lọ sẹ́wọ̀n ọdún méje àtààbọ̀."
} |
{
"en": "In early 2018, Federal State Security (FSB) agents wiretapped the Shpakovskiy’s apartment and monitored their activity for several months.",
"eng": null,
"yor": "Ní ìbẹ̀rẹ̀ 2018, àwọn ọ̀lọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà bẹ̀rẹ̀ sí yọ́ kẹ́lẹ́ fi ẹ̀rọ gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ nínú ilé Shpakovskiy, wọ́n sì ń ṣọ́ wọn lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀ fún ọ̀pọ̀ oṣù."
} |
{
"en": "On June 3, 2018, at 12:45 p.m., FSB agents supported by armed National Guard officers forced open the front door of their apartment, where people were gathered for a peaceful meeting, and searched the home for six hours.",
"eng": null,
"yor": "Ní June 3, 2018, ní aago kan ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ́sàn-án, àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́, papọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ orílẹ̀-èdè náà, fi tipátipá ṣí ilẹ̀kùn iwájú ilé náà, níbi tí àwọn èèyàn péjọ sí láti ṣe ìpàdé ní wọ́ọ́rọ́wọ́, wọ́n sì wá gbogbo inú ilé náà fún wákàtí mẹ́fà."
} |
{
"en": "The FSB agents confiscated tablets and cell phones and took the Witnesses away for interrogation.",
"eng": null,
"yor": "Àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ gbẹ́sẹ̀ lé tábílẹ́tì àti fóònù àwọn Ẹlẹ́rìí náà, wọ́n sì kó wọn lọ fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò."
} |
{
"en": "The interrogators insulted the Witnesses and threatened them with dismissal from work and criminal prosecution.",
"eng": null,
"yor": "Àwọn tó ń fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò bẹ̀rẹ̀ sí bú wọn, wọ́n sì ń halẹ mọ́ wọn pé wọ́n máa pàdánù iṣẹ́ wọn, wọ́n á sì lọ sẹ́wọ̀n."
} |
{
"en": "Brother Shpakovskiy’s interrogation lasted until 10 p.m.",
"eng": null,
"yor": "Ó tó aago mẹ́wàá alẹ́ kí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò Arákùnrin Shpakovskiy tó parí."
} |
{
"en": "On March 19, 2019, Brother Shpakovskiy was charged with organizing the activities of an “extremist” organization.",
"eng": null,
"yor": "Ní March 19, 2019, wọ́n fẹ̀sùn kan Arákùnrin Shpakovskiy pé ó ń ṣètò ìgbòkègbodò ẹgbẹ́ agbawèrèmẹ́sìn."
} |
{
"en": "Five months later, the accusation of “financing extremist activities” was added to the criminal charge.",
"eng": null,
"yor": "Oṣù márùn-ún lẹ́yìn náà, wọ́n fi ẹ̀sùn míì kàn-án pé ó ń fi owó ṣe ìtìlẹ́yìn fún ìgbòkègbodò ẹgbẹ́ àwọn agbawèrèmẹ́sìn."
} |
{
"en": "As the verdict approaches, we pray in full confidence that Jehovah will help the Shpakovskiy family remain strong, knowing that their faithful endurance will be rewarded.—2 Chronicles 15:7.\"",
"eng": null,
"yor": "Bí ìgbẹ́jọ́ náà ṣe ń sún mọ́lé, a gbàdúrà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún pé Jèhófà máa ran ìdílé Shpakovskiy lọ́wọ́ láti dúró gbọin, a sì mọ̀ pé èrè wà fún ìfaradà wọn.—2 Kíróníkà 15:7.\""
} |
{
"en": "\"On September 2, 2019, the Zheleznodorozhniy District Court of Khabarovsk, Russia, sentenced Brother Valeriy Moskalenko to two years and two months of community service and another six months of probation.",
"eng": null,
"yor": "\"Ní September 2, 2019, Ilé Ẹjọ́ Àgbègbè Zheleznodorozhniy ní ìlú Khabarovsk lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà dájọ́ pé kí Arákùnrin Valeriy Moskalenko lọ ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú fún ọdún méjì àti oṣù méjì."
} |
{
"en": "He will not need to spend any additional time in prison.",
"eng": null,
"yor": "Ẹ̀yìn ìyẹn ní wọ́n á wá máa ṣọ́ ọ lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀ fún oṣù mẹ́fà. Ìyẹn túmọ̀ sí pé kò ní pa dà sẹ́wọ̀n mọ́."
} |
{
"en": "After the verdict was announced, Brother Moskalenko was released from custody to the delight of his family and friends. He had been in jail since August 2, 2018.",
"eng": null,
"yor": "Lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ kéde ìdájọ́ yìí, wọ́n dá Arákùnrin Moskalenko sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, inú ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì dùn gan-an."
} |
{
"en": "Before his arrest, he worked as an assistant train conductor while caring for his sick mother.",
"eng": null,
"yor": "Láti August 2, 2018 ló ti wà lẹ́wọ̀n. Kí wọ́n tó fi í sẹ́wọ̀n, iṣẹ́ tó ń ṣe ni pé ó máa ń ran ẹni tó ń wa ọkọ̀ ojú irin lọ́wọ́, ó sì tún ń tọ́jú ìyá rẹ̀ tó ń ṣàìsàn."
} |
{
"en": "Under the terms of his probation, he cannot travel outside Khabarovsk and must report for a criminal-executive inspection every month.",
"eng": null,
"yor": "Lára àwọn ìkálọ́wọ́kò tí wọ́n fún un lásìkò tí wọ́n fi ń ṣọ́ ọ lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀ ni pé kò gbọdọ̀ jáde kúrò nílùú Khabarovsk, ó sì gbọ́dọ̀ máa lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá lóṣooṣù kí wọ́n lè rí i pé kò ṣe ohunkóhun tí kò bófin mu."
} |
{
"en": "In his closing statement to the court on August 30, Brother Moskalenko said in part: “It is completely unthinkable for me to go against the will of God that is clearly expressed in the Bible.",
"eng": null,
"yor": "Nínú ọ̀rọ̀ tí Arákùnrin Moskalenko sọ kẹ́yìn nílé ẹjọ́ ní August 30, ó sọ pé: “Mi ò ni ṣe ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run bó ṣe wà nínú Bíbélì láé."
} |
{
"en": "And regardless of how I might be pressured or punished, even if I were sentenced to death, I declare that not even then would I abandon the almighty Creator of the universe, Jehovah God.”",
"eng": null,
"yor": "Bó ti wù kí ilé ẹjọ́ yìí fìyà jẹ mí tó, kódà tí wọ́n bá dájọ́ ikú fún mi, mi ò ni fi Jèhófà, Ọlọ́run Olódùmarè àti Ẹlẹ́dàá ayé àtọ̀run sílẹ̀ láé.”"
} |
{
"en": "Yaroslav Sivulskiy, a representative from the European Association of Jehovah’s Witnesses, states: “While we do not agree with the guilty verdict, we are glad that Valeriy can return home.”",
"eng": null,
"yor": "Yaroslav Sivulskiy, tó jẹ́ aṣojú Àjọ European Association of Jehovah’s Witnesses, sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò gbà pé a jẹ̀bi ẹ̀sùn náà, àmọ́ inú wa dùn pé Valeriy máa lè pa dà sílé.”"
} |
{
"en": "In addition to Brother Moskalenko, seven more of our brothers in the Khabarovsk Territory are awaiting verdicts in their criminal cases.",
"eng": null,
"yor": "Yàtọ̀ sí Arákùnrin Moskalenko, àwọn arákùnrin wa méje míì wà ní ìlú Khabarovsk tó ń retí ìgbà tí wọ́n máa dá ẹjọ́ ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn wọ́n."
} |
{
"en": "We are thankful to Jehovah that Brother Moskalenko maintained his strong faith during his detention.",
"eng": null,
"yor": "A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé Arákùnrin Moskalenkodúró gbọin nígbà tó wà lẹ́wọ̀n."
} |
{
"en": "We pray that He will continue to supply strength to all the brothers and sisters who are enduring persecution for their Bible-based convictions.—Isaiah 40:31.\"",
"eng": null,
"yor": "Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà túbọ̀ máa fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lókun bí wọ́n ṣe ń fara da inúnibíni nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́.—Àìsáyà 40:31.\""
} |
{
"en": "\"On August 13, 2019, the appeals court in the city of Kirov ruled to release 26-year-old Brother Andrey Suvorkov from house arrest.",
"eng": null,
"yor": "Ní August 13, 2019, ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tó wà ní ìlú Kirov dájọ́ pé kí wọn jẹ́ ki Arákùnrin Andrey Suvorkov tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26) pé kò lómìnira láti jáde kúrò nílé."
} |
{
"en": "Although Brother Suvorkov has been given greater freedom, the criminal case against him remains open.",
"eng": null,
"yor": "Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fún Arákùnrin Suvorkov lómìnira tó pọ̀ si i, síbẹ̀ ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn án ṣì wà síbẹ̀."
} |
{
"en": "As previously reported, Brother Suvorkov was arrested, along with his stepfather and three other brothers, when local police and masked special forces raided 19 homes in Kirov on October 9, 2018.",
"eng": null,
"yor": "Bó ṣe wà nínú ìròyìn tá a gbé jáde ṣáájú, ní October 9, 2018 àwọn ọlọ́pàá àtàwọn agbófinró tó fi nǹkan bojú ya wọ ilé mọ́kàndínlógún (19) lára ilé àwọn ará wa, ìgbà yẹn ni wọ́n mú Arákùnrin Suvorkov, ọkọ ìyá rẹ̀ àtàwọn arákùnrin mẹ́ta míì."
} |
{
"en": "Thinking back to when his home was searched, Brother Suvorkov states: “Many of our valuable items were confiscated.",
"eng": null,
"yor": "Arákùnrin Suvorkov sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n wá tú ilé rẹ̀, ó ní: “Wọ́n kó púpọ̀ nínú àwọn ohun ìní wa."
} |
{
"en": "But my wife and I didn’t worry about it, since we always tried to keep our life simple and not get too attached to material things.",
"eng": null,
"yor": "Àmọ́, èmi àti ìyàwó mi ò ronú nípa ìyẹn torí a ti jẹ́ kí ohun díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn, a ò sì kì í ṣàníyàn púpọ̀ nípa àwọn nǹkan tara."
} |
{
"en": "The counsel from Matthew 6:21, ‘for where your treasure is, there your heart will be also,’ helped us remain calm.”",
"eng": null,
"yor": "Ìmọ̀ràn tó wà ní Mátíù 6:21 ti ràn wá lọ́wọ́ gan-an, ó sọ pé, ‘ibi tí ìṣúra yín bá wà ibẹ̀ ni ọkàn yín náà máa wà,’ ìyẹn ni kò jẹ́ ká kọ́kàn sókè.”"
} |
{
"en": "Following the raids, criminal cases were opened against Brother Suvorkov, his stepfather, and the three other brothers for singing Kingdom songs, studying religious literature, and possessing a copy of the Russian New World Translation of the Holy Scriptures.",
"eng": null,
"yor": "Lẹ́yìn tí wọ́n tú ilé àwọn arákùnrin yìí, wọ́n fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kan Arákùnrin Suvorkov, ọkọ ìyá rẹ̀ àtàwọn arákùnrin mẹ́ta míì, wọ́n ní torí pé wọ́n ń kọrin ìjọba Ọlọ́run, wọ́n ń ka àwọn ìtẹ̀jáde wa àti pé wọ́n tún ní Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Rọ́ṣíà lọ́wọ́."
} |
{
"en": "They were all detained in a temporary holding facility as they waited for a court to decide either to release them or place them in pretrial detention.",
"eng": null,
"yor": "Wọ́n fi gbogbo wọ́n sí àtìmọ́lé tó wà fún gbà díẹ̀ títí ilé ẹjọ́ á fi sọ pé kí wọn dá wọ́n sílẹ̀ tàbí kí wọ́n wà lẹ́wọ̀n títí wọ́n á fi gbọ́ ẹjọ́ wọn."
} |
{
"en": "Brother Suvorkov describes his experience: “I spent two nights in a temporary holding facility.",
"eng": null,
"yor": "Arákùnrin Suvorkov sọ ohun tójú ẹ̀ rí, ó sọ pé: “Ọjọ́ méjì ni mo lò ní àtìmọ́lé onígbà díẹ̀."
} |
{
"en": "In the beginning, I did not stop praying. I was sure that Jehovah heard me and would give me support.",
"eng": null,
"yor": "Mi ò dáwọ́ àdúrà dúró láti ìbẹ̀rẹ̀, torí ó dá mi lójú pé Jèhófà á gbọ́ mi, á sì tì mí lẹ́yìn. Mò rántí àwọn orin ìjọba Ọlọ́run kan, mo sì ń kọ wọ́n."
} |
{
"en": "I recalled melodies from the Kingdom songs and sang them. Later, I recalled more than 50 melodies with lyrics.”",
"eng": null,
"yor": "Lápapọ̀, mo rántí ohùn orin tó lé ní àádọ́ta (50) àti ọ̀rọ̀ inú wọn.”"
} |
{
"en": "The court decided to place Brother Suvorkov and the others in pretrial detention.",
"eng": null,
"yor": "Ilé ẹjọ́ wá sọ pé kí wọ́n fi Arákùnrin Suvorkov àti àwọn yòókù sẹ́wọ̀n títí wọ́n á fi gbọ́ ẹjọ́ wọn."
} |
{
"en": "During his first week in detention, Brother Suvorkov focused on helping others.",
"eng": null,
"yor": "Ní ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ tí Arákùnrin Suvorkov lò lẹ́wọ̀n, ṣé ló gbájú mọ́ bó ṣe máa ran àwọn míì lọ́wọ́."
} |
{
"en": "He recalls: “I decided to mention brothers by name in my prayers and write encouraging letters to those whose addresses I remembered.",
"eng": null,
"yor": "Ó sọ́ pé: “Mo pinnu láti máa dárúkọ àwọn ará wa nínú àdúrà mi, mo sì ń kọ lẹ́tà tó ń fúnni lókùn sí àwọn tí mo rántí àdírẹ́sì ilé wọn."
} |
{
"en": "This brought me joy.”—Acts 20:35.",
"eng": null,
"yor": "Èyí fún mi láyọ̀ gan-an.”—Ìṣe 20:35."
} |
{
"en": "As the months went by, all the brothers were eventually transferred to house arrest, except for Brother Andrzej Oniszczuk.",
"eng": null,
"yor": "Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù, wọ́n dá àwọn arákùnrin yìí padà sílé wọ́n, àmọ́ wọ́n pàṣẹ pé gbogbo wọn ò gbọdọ̀ jáde kúrò nílé, àfi Arákùnrin Andrey Oniszczuk nìkan ló lè jáde nílé."
} |
{
"en": "Brother Suvorkov is the first of the brothers from Kirov to be released from house arrest.",
"eng": null,
"yor": "Arákùnrin Suvorkov ni ẹni àkọ́kọ́ nílùú Kirov lára àwọn tí wọ́n ní wọn ò gbọdọ̀ jáde nílé tí wọ́n wá pa dà fún lómìnira láti jáde nílé."
} |
{
"en": "“Looking back,” states Brother Suvorkov, “I’m very glad that I had such an experience in prison. . . .",
"eng": null,
"yor": "Nígbà tí Arákùnrin Suvorkov rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i, ó sọ pé: “Inú mi dùn pé mo ní irú ìrírí tí mo ní lẹ́wọ̀n. . . ."
} |
{
"en": "I don’t know what the future holds or if I will be imprisoned again.",
"eng": null,
"yor": "Mi ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́la, mi ò sì mọ̀ bóyá wọ́n ṣì tún máa sọ mí sẹ́wọ̀n."
} |
{
"en": "I now have confidence that I will receive the support of Jehovah and his organization, even if I am in prison.",
"eng": null,
"yor": "Àmọ́ ní báyìí, ó ti wá dá mi lójú pé Jèhófà àti ètò rẹ̀ ò ní fi mí sílẹ̀, kódà tí mo bá wà lẹ́wọ̀n."
} |
{
"en": "What I don’t have is the fear of being imprisoned.”\"",
"eng": null,
"yor": "Ohun kan ni pé, àyà mi ò já pé wọ́n lè sọ mí sẹ́wọ̀n.”\""
} |
{
"en": "\"On September 3, 2019, Brother Andrzej Oniszczuk was released from a Russian prison.",
"eng": null,
"yor": "\"Ní September 3, 2019, wọ́n dá Arákùnrin AndrzejOniszczuk sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n kan lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà."
} |
{
"en": "He had been incarcerated since October 9, 2018, for merely practicing his faith.",
"eng": null,
"yor": "Láti October 9, 2018 ni wọ́n ti fi í sẹ́wọ̀n torí pé ó ń jọ́sìn Ọlọ́run."
} |
{
"en": "During that time, he was held in solitary confinement and was not allowed to see or speak with his wife, Anna.",
"eng": null,
"yor": "Láàárín àkókò yẹn, wọ́n fi í sínú àhámọ́, wọn ò jẹ́ kó rí Anna ìyàwó rẹ̀, wọn ò tún jẹ́ kó o bá a sọ̀rọ̀."
} |
{
"en": "Though he can return home, he remains under restrictions, which severely limit his travel.",
"eng": null,
"yor": "Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti jẹ́ kó pa dà sílé báyìí, àmọ́ àwọn aláṣẹ ò gbà á láyè láti lọ síbi tó wù ú."
} |
{
"en": "His criminal case is still in progress.",
"eng": null,
"yor": "Wọn ò sì tíì parí ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn án."
} |
{
"en": "We rejoice that Brother Andrzej Oniszczuk and his wife are maintaining strong faith during this ordeal.",
"eng": null,
"yor": "Inú wa dùn pé Arákùnrin Andrzej Oniszczuk àti ìyàwó rẹ̀ dúró gbọin lákòókò tí nǹkan le koko yìí."
} |
{
"en": "We are thankful that Jehovah responds to all the prayers in behalf of those in “prison bonds.”—Colossians 4:2, 3.\"",
"eng": null,
"yor": "A dúpẹ́ pé Jèhófà ń dáhùn àwọn àdúrà tá a gbà nítorí àwọn tó wa nínú “ìdè ẹ̀wọ̀n.”—Kólósè 4:2, 3.\""
} |
{
"en": "\"On April 1, 2019, the same Russian court that sentenced Brother Dennis Christensen to six years in prison convicted 56-year-old Sergey Skrynnikov for practicing his faith as one of Jehovah’s Witnesses.",
"eng": null,
"yor": "\"Ní April 1, 2019 ilé ẹjọ́ tó rán Arákùnrin Dennis Christensen lẹ́wọ̀n ọdún mẹ́fà tún dẹ́bi fún Sergey Skrynnikov, ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta (56) torí pé ó ń ṣe ohun tó gbà gbọ́ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni Ẹlẹ́rìí Jèhófà."
} |
{
"en": "The court imposed a large fine of $5,348.00 (RUB 350,000; EUR 4,758.95).",
"eng": null,
"yor": "Ilé ẹjọ́ bu owó ìtanràn tabua lé e lórí, wọ́n ní kó san ẹgbẹ̀rún márùn-ún àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé méjìdínláàádọ́ta owó dọ́là ($5,348.00)."
} |
{
"en": "No prison time was ordered, although the prosecution was seeking three years of detention.",
"eng": null,
"yor": "Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó fẹ̀sùn kàn án fẹ́ kí ilé ẹjọ́ ran an lẹ́wọ̀n ọdún mẹ́ta, ilé ẹjọ́ ò rán an lẹ́wọ̀n."
} |
{
"en": "Brother Skrynnikov and his wife, Nina, have one daughter.",
"eng": null,
"yor": "Arákùnrin Skrynnikov àti ìyàwó rẹ̀, Nina bí ọmọbìnrin kan."
} |
{
"en": "They assist their daughter and her husband with their five children.",
"eng": null,
"yor": "Wọ́n máa ń ran ọmọbìnrin wọn lọ́wọ́ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ láti tọ́jú ọmọ márùn-ún tí wọ́n bí."
} |
{
"en": "Additionally, the Skrynnikovs are the primary caregivers for Nina’s elderly parents.",
"eng": null,
"yor": "Yàtọ̀ síyẹn, ìdílé Skrynnikov náà ló ń tọ́jú àwọn òbí Nina, ìyàwó ọmọ wọn, torí wọ́n ti dàgbà gan-an."
} |
{
"en": "In court, Brother Skrynnikov made a respectful and compelling defense of his faith.",
"eng": null,
"yor": "Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni Arákùnrin Skrynnikov gbèjà ohun tó gbà gbọ́ nílé ẹjọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì wọni lọ́kàn."
} |
{
"en": "He said, in part: “If you look at the current situation from an unbeliever’s viewpoint, you might despair. . . .",
"eng": null,
"yor": "Lára ohun tó sọ ni pé: “Téèyàn bá fojú ẹni tí ò nígbàgbọ́ wo ọ̀rọ̀ yìí, ó máa bọkàn jẹ́. . . ."
} |
{
"en": "But as one of Jehovah’s Witnesses, I look at this situation through the eyes of faith.",
"eng": null,
"yor": "Àmọ́ torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí, ojú ìgbàgbọ́ ni mo fi wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí."
} |
{
"en": "If God permits me to be convicted, it means that I need to view these three years not as a punitive sentence but as a special assignment to serve in a new location!",
"eng": null,
"yor": "Tí Ọlọ́run bá fàyè gbà á pé kí wọ́n rán mi lẹ́wọ̀n, àfi kí n yáa gbà pé ọdún mẹ́ta yìí kì í ṣe tìyà, àmọ́ ó wà fún iṣẹ́ pàtàkì kan tí màá ṣe níbi tuntun!"
} |
{
"en": "So I do not despair. . . .",
"eng": null,
"yor": "Torí náà, mi ò bọkàn jẹ́. . . ."
} |
{
"en": "God is one and the same whether we are free or in prison.",
"eng": null,
"yor": "Ìkan náà ni Ọlọ́run, kò yí pa dà, à báà wà lómìnira tàbí a wà lẹ́wọ̀n."
} |
{
"en": "Therefore, we are not abandoned.",
"eng": null,
"yor": "Kò fi wá sílẹ̀."
} |
{
"en": "He is with us everywhere as long as we stay faithful to him.”",
"eng": null,
"yor": "Ó wà pẹ̀lú wa níbikíbi tá a bá wà, tá a bá ṣáà ti jẹ́ olóòótọ́ sí i.”"
} |
{
"en": "We are encouraged by the strong faith of our fellow believers, such as Brother Skrynnikov.",
"eng": null,
"yor": "Ìgbàgbọ́ tó lágbára táwọn ará wa ní máa ń fún wa níṣìírí bíi ti Arákùnrin Skrynnikov."
} |
{
"en": "When we think of the severe trials they are facing, we echo the apostle Paul’s prayerful words: “May the God who gives hope fill you with all joy and peace by your trusting in him, so that you may abound in hope with power of holy spirit.”—Romans 15:13.",
"eng": null,
"yor": "Tá a ba ronú nípa àwọn àdánwò lílé tí wọ́n ń kojú, àwa náà máa gba irú àdúrà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà fáwọn ará pé: “Kí Ọlọ́run tó ń fúnni ní ìrètí fi gbogbo ayọ̀ àti àlàáfíà kún inú yín nítorí ẹ̀ ń gbẹ́kẹ̀ lé e, kí ìrètí yín lè túbọ̀ dájú nípasẹ̀ agbára ẹ̀mí mímọ́.”—Róòmù 15:13."
} |
{
"en": "Translated from Russian",
"eng": null,
"yor": "A túmọ̀ rẹ̀ láti èdè Russian"
} |
{
"en": "First, I would like to express my gratitude to Presiding Judge Gleb Borisovich Noskov for not imposing [pretrial] imprisonment on me, which meant that I have been with my family the entire time.",
"eng": null,
"yor": "Lákọ̀ọ́kọ́, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Adájọ́ Àgbà Gleb Borisovich Noskov tí kò fi mí sátìmọ́lé kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ mi, èyí jẹ́ kí n lè wà pẹ̀lú ìdílé mi ní gbogbo àsìkò ìgbẹ́jọ́ yìí."
} |
{
"en": "Also I wish to thank all of the clerks for their work.",
"eng": null,
"yor": "Bákan náà, mo fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀ṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́ fún iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe."
} |
{
"en": "I offer special thanks to the prosecutor, Madam Nadezhda Gennadiyevna Naumova, because no undue pressure was exerted on me and the questioning was conducted properly.",
"eng": null,
"yor": "Mo dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ agbẹjọ́rò ìjọba, Ìyáàfin Nadezhda Gennadiyevna Naumova, torí kò ni mí lára nígbà tó ń wádìí ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu mi, ọ̀nà tó sì gbà bi mí léèrè ọ̀rọ̀ bọ́gbọ́n mu."
} |
{
"en": "I would also like to thank my lawyers, Madam Irina Aleksandrovna Krasnikova and Mr. Anton Nikolayevich Bogdanov, for the tremendous work they have done.",
"eng": null,
"yor": "Mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn agbẹjọ́rò mi, Ìyáàfin Irina Aleksandrovna Krasnikova àti Ọ̀gbẹ́ni Anton Nikolayevich Bogdanov torí iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ṣe."
} |