translation
dict
{ "en": "They have also filed an application with the United Nations Working Group Against Arbitrary Detention.", "eng": null, "yor": "Wọ́n tún ti kọ̀wé sí Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé Tó Ń Gbógun Ti Fífini Sátìmọ́lé Lọ́nà Tí Kò Bójú Mu." }
{ "en": "As persecution increases in places like Russia, we are “in no way being frightened” by our opponents.", "eng": null, "yor": "Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àti láwọn orílẹ̀-èdè míì ń le sí i, a ò ní jẹ́ káwọn alátakò yìí “kó jìnnìjìnnì bá wa lọ́nàkọnà.”" }
{ "en": "We trust that Jehovah will continue to give all of us what we need to endure until his great day of salvation comes.—Philippians 1:28\"", "eng": null, "yor": "Ó dá wa lójú pé Jèhófà á máa fún wa ní gbogbo ohun tá a nílò ká lè máa fara dà á títí táyé tuntun tá à ń retí fi máa dé.—Fílípì 1:28\"" }
{ "en": "\"During the month of October 2018, local and federal police raided more than 30 homes throughout western Russia.", "eng": null, "yor": "\"Nínú oṣù October 2018, àwọn ọlọ́pàá ya wọ ilé tó ju ọgbọ̀n (30) lọ káàkiri ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Rọ́ṣíà." }
{ "en": "Six brothers and two sisters were arrested and sentenced to pretrial detention for so-called extremist activity.", "eng": null, "yor": "Wọ́n mú arákùnrin mẹ́fà àti arábìnrin méjì, wọ́n sì fi wọ́n sí àtìmọ́lé kí ilé ẹjọ́ tó gbọ́ ẹjọ́ wọn lórí ẹ̀sùn pé agbawèrèmẹ́sìn ni wọ́n." }
{ "en": "Consequently, there are now 25 brothers and sisters unjustly imprisoned, and 18 others are under house arrest.", "eng": null, "yor": "Ní báyìí, àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin tí wọ́n ti rán lọ sẹ́wọ̀n láìtọ́ jẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25), wọ́n sì sọ fún àwọn méjìdínlógún (18) míì pé wọn ò gbọ́dọ̀ jáde nílé." }
{ "en": "October 7, Sychyovka, Smolensk Region—Local police and masked special forces searched four homes and arrested two sisters, 43-year-old Nataliya Sorokina and 41-year-old Mariya Troshina.", "eng": null, "yor": "October 7, ní Sychyovka, Àgbègbè Smolensk​—Àwọn ọlọ́pàá àdúgbò àtàwọn agbófinró tó fi nǹkan bojú lọ tú ilé mẹ́rin, wọ́n sì mú arábìnrin méjì, ìyẹn Nataliya Sorokina tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélógójì (43) àti Mariya Troshina tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógójì (41)." }
{ "en": "Two days after their arrest, the Leninsky District Court sentenced our sisters to pretrial detention through November 19, 2018.", "eng": null, "yor": "Lẹ́yìn ọjọ́ méjì tí wọ́n mú wọn, Ilé Ẹjọ́ Leninsky rán àwọn arábìnrin wa lọ sí àtìmọ́lé títí di November 19, 2018." }
{ "en": "Then, on November 16, 2018, the Leninsky District Court extended the sisters’ pretrial detention for an additional three months, that is, until February 19, 2019.", "eng": null, "yor": "Àmọ́ nígbà tó di November 16, 2018, Ilé Ẹjọ́ Leninsky fi oṣù mẹ́ta kún ọjọ́ táwọn arábìnrin wa máa lò látìmọ́lé, tó fi hàn pé wọ́n á wà níbẹ̀ títí di February 19, 2019 nìyẹn." }
{ "en": "October 9, Kirov, Kirov Region—At least 19 homes were raided.", "eng": null, "yor": "October 9, ní Kirov, Àgbègbè Kirov​—Ó kéré tán, ilé mọ́kàndínlógún (19) ni wọ́n ya wọ̀." }
{ "en": "Five congregation elders were arrested and later sentenced to pretrial detention.", "eng": null, "yor": "Wọ́n mú àwọn alàgbà ìjọ márùn-ún, wọ́n sì fi wọ́n sí àtìmọ́lé kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ wọn." }
{ "en": "Four of the brothers (Maksim Khalturin, Vladimir Korobeynikov, Andrey Suvorkov, and Evgeniy Suvorkov) are Russian nationals, and one, Andrzej Oniszczuk, is a Polish citizen.", "eng": null, "yor": "Ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà ni mẹ́rin lára wọn (ìyẹn Maksim Khalturin, Vladimir Korobeynikov, Andrey Suvorkov àti Evgeniy Suvorkov) ẹnì kan tó kù, ìyẹn Andrzej Oniszczuk, jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Poland." }
{ "en": "Brother Oniszczuk is the second foreigner, after Dennis Christensen from Denmark, to be unjustly detained in Russia for his Christian beliefs.", "eng": null, "yor": "Yàtọ̀ sí Dennis Christensen tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Denmark, Arákùnrin Oniszczuk ló máa jẹ́ ẹnì kejì tó wá láti orílẹ̀-èdè míì táwọn aláṣẹ Rọ́ṣíà máa mú sílẹ̀ ní Rọ́ṣíà torí ohun tó gbà gbọ́ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni." }
{ "en": "October 18, Dyurtyuli, Republic of Bashkortostan—Police raided at least 11 homes and seized money, bank cards, photographs, personal letters, computers, SIM cards, and cell phones.", "eng": null, "yor": "October 18, ní Dyurtyuli, Republic of Bashkortostan​—Ó kéré tán, ilé mọ́kànlá (11) làwọn ọlọ́pàá ya wọ̀, wọ́n sì gba owó, káàdì tí wọ́n fi ń gbowó ní báǹkì, fọ́tò, àwọn lẹ́tà àdáni, kọ̀ǹpútà, fóònù alágbèéká àti síìmù." }
{ "en": "Anton Lemeshev, an elder, was arrested and then sentenced to pretrial detention for two months.", "eng": null, "yor": "Wọ́n mú Anton Lemeshev tó jẹ́ alàgbà, wọ́n sì fi sí àtìmọ́lé fún oṣù méjì kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀." }
{ "en": "On October 31, 2018, he was released from prison and transferred to house arrest, where he remains at present.", "eng": null, "yor": "Nígbà tó di October 31, 2018, wọ́n dá a sílẹ̀ kó máa lọ sílé, àmọ́ wọ́n ní kò gbọ́dọ̀ jáde nílé, títí di bá a ṣe ń sọ yìí." }
{ "en": "Despite the ongoing threat of raids and unlawful seizure of their belongings, local brothers and sisters continue to pray for those imprisoned and to provide them and their families with practical help when possible.", "eng": null, "yor": "Láìka báwọn agbófinró ṣe ń ya wọ ilé àwọn ará, tí wọ́n sì ń gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ohun ìní wọn lọ́nà tí kò bófin mu, àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin láwọn àgbègbè yìí ń ṣèrànwọ́ tí wọ́n lè ṣe fáwọn tó wà látìmọ́lé àti ìdílé wọn, wọ́n sì ń gbàdúrà fún wọn." }
{ "en": "Until the situation is resolved, our international brotherhood will supplicate Jehovah in behalf of all his faithful servants in Russia, even mentioning some by name.—Ephesians 6:18.\"", "eng": null, "yor": "Títí tí ọ̀rọ̀ yìí fi máa yanjú, ẹgbẹ́ ará kárí ayé ò ní yéé bẹ Jèhófà torí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ tó wà ní Rọ́ṣíà, kódà, àá máa dárúkọ àwọn kan nínú àdúrà wa.​—Éfésù 6:18.\"" }
{ "en": "\"On Tuesday, May 7, 2019, at the Oryol Regional Court, the hearing began for Dennis Christensen to appeal the six-year prison sentence he received for practicing his faith.", "eng": null, "yor": "\"Ní Tuesday, May 7, 2019, Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Oryol bẹ̀rẹ̀ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Dennis Christensen pè torí bí wọ́n ṣe rán an lẹ́wọ̀n ọdún mẹ́fà nítorí ohun tó gbà gbọ́." }
{ "en": "Thus far, this court has continued the pattern set by other Russian courts, refusing to consider properly what the defense lawyers feel is overwhelming evidence that Dennis is innocent.", "eng": null, "yor": "Àmọ́ ohun táwọn ilé ẹjọ́ ilẹ̀ Rọ́ṣíà sábà máa ń ṣe ni ilé ẹjọ́ yìí náà ṣe, wọn ò gba àwọn ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro táwọn agbẹjọ́rò wa mú wá wọlé, wọn ò sì gbé wọn yẹ̀ wò láti rí i pé Dennis kò mọwọ́mẹsẹ̀." }
{ "en": "The three-judge panel may issue their decision on the appeal by the end of this week.", "eng": null, "yor": "Ó ṣeé ṣe kí àwọn adájọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó ń gbọ́ ẹjọ́ yìí sọ ìpinnu wọn títí ìparí ọ̀sẹ̀ yìí." }
{ "en": "On the first day of the hearing, many brothers and sisters came to the courthouse to support Dennis.", "eng": null, "yor": "Ọ̀pọ̀ àwọn ará ló wá sí ilé ẹjọ́ yìí láti wá ṣètìlẹyìn fún Dennis lọ́jọ́ tí ìgbẹ́jọ́ náà bẹ̀rẹ̀." }
{ "en": "Also in attendance were diplomats from various countries, journalists, and human rights advocates.", "eng": null, "yor": "Bákan náà, àwọn aṣojú láti oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè wá síbẹ̀ àtàwọn akọ̀ròyìn pẹ̀lú àwọn tó ń jà fẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn." }
{ "en": "The hearing began in a small room that could only hold 20 to 25 people, so that about 50 more were denied access.", "eng": null, "yor": "Inú yàrá kékeré kan tí kò lè gbà ju èèyàn ogún (20) sí mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ẹjọ́ náà, ìyẹ̀n sì mú kí nǹkan bí àádọ́ta (50) èèyàn dúró síta." }
{ "en": "However, the court granted a motion by Dennis’ attorneys to move the hearing into a larger room that could hold close to 80 people.", "eng": null, "yor": "Àmọ́ ilé ẹjọ́ náà fara mọ́ àbá táwọn agbẹjọ́rò Dennis mú wá pé kí wọ́n jẹ́ kí gbogbo àwọn tó wá fún ìgbẹ́jọ́ náà lọ sí yàrá míì tó lè gba nǹkan bí ọgọ́rin (80) èèyàn." }
{ "en": "The court adjourned after only three hours.", "eng": null, "yor": "Lẹ́yìn tí wọ́n lo wákàtí mẹ́ta péré lẹ́nu ìgbẹ́jọ́ náà, ilé ẹjọ́ sún ẹjọ́ náà síwájú." }
{ "en": "On the second day of the proceedings, the judges denied the defense’s request to re-examine a substantial amount of evidence of Dennis’ innocence.", "eng": null, "yor": "Lọ́jọ́ kejì ìgbẹ́jọ́ náà, agbẹjọ́rò Dennis béèrè pé kí ilé ejọ́ náà ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí kan tó fi hàn pé Dennis ò mọwọ́mẹsẹ̀, àmọ́ àwọn adájọ́ kọ̀." }
{ "en": "This is unfortunate, because Dennis’ lawyers are convinced the evidence would reveal that the original conviction was unjustified.", "eng": null, "yor": "Èyí ò dáa rárá torí àwọn agbẹjọ́rò Dennis gbà pé àwọn ẹ̀rí yìí máa fi hàn pé ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ àkọ́kọ́ dá kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀." }
{ "en": "At the end of the day, the court announced that the hearing will resume on Thursday, May 16, when closing arguments will begin.", "eng": null, "yor": "Lópin ọjọ́ náà, ilé ẹjọ́ sọ pé ìgbẹ́jọ́ náà máa tẹ̀ síwájú ní Thursday, May 16 káwọn agbẹjọ́rò lè fẹnu ọ̀rọ̀ wọn jóná lọ́kọ̀ọ̀kan." }
{ "en": "We continue to pray that our brothers in Russia maintain their peace and firm faith in Jehovah’s promise that ultimately he will save them from those who treat them with contempt.—Psalm 12:5.\"", "eng": null, "yor": "Àdúrà wa fáwọn ará wa ní Rọ́síà ni pé kí ọkàn wọn balẹ̀, kí ìgbàgbọ́ wọn má sì yẹ̀ nínú àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun máa gbà wọ́n pátápátá lọ́wọ́ àwọn tó kórìíra wọn.—Sáàmù 12:5.\"" }
{ "en": "\"Several international news outlets have reported that during recent searches in the Kirov region of Russia, authorities supposedly discovered “weapons” that they say belonged to Jehovah’s Witnesses.", "eng": null, "yor": "\"Àwọn ilé iṣẹ́ oníròyìn bíi mélòó kan gbé ìròyìn kan jáde pé, nígbà táwọn aláṣẹ ń wo ilé àwọn èèyàn ní agbègbè Kirov lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, wọ́n rí àwọn ohun kan tí wọ́n pè ní ohun ìjà tó jẹ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà." }
{ "en": "However, the “weapons” that the authorities found were in the home of someone who is not one of Jehovah’s Witnesses.", "eng": null, "yor": "Àmọ́ ẹni tí wọ́n rí ohun tí wọ́n pè ní ohun ìjà yìí nílé rẹ̀ kìí ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà." }
{ "en": "The “weapons” were actually three rusty, inoperable relics from World War II—two grenades and one landmine.", "eng": null, "yor": "Àwọn àdó olóró tí wọ́n lò kù nígbà Ogun Àgbáyé Kejì ni ohun ìjà tí wọ́n láwọn rí yìí, méjì nínú wọn jẹ́ èyí tí wọ́n máa ń jù, ọ̀kan tó kù sì jẹ́ èyí tí wọ́n ń rì mọ́lẹ̀, gbogbo wọn ló ti dípẹtà, tí wọn ò sì ṣeé lò mọ́." }
{ "en": "The individual’s wife, who is one of Jehovah’s Witnesses, apparently was not even aware that her husband possessed these items.", "eng": null, "yor": "Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ìyàwó onílé yìí, kódà òun gan-an ò mọ̀ pé ọkọ òun nírú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́." }
{ "en": "The owner of the relics was once a chief of one of the well-known Russian “Poisk,” or “Search,” squads that looked for the remains of soldiers killed in WWII in order to provide them a proper burial.", "eng": null, "yor": "Ọ̀gbẹ́ni tó ni àwọn nǹkan yìí ti fìgbà kan jẹ́ ọ̀gá nínú àwùjọ àwọn tó máa ń wá òkú àwọn ọmọ ogun tó kú nígbà Ogun Àgbáyé Kejì kí wọ́n lè sin wọ́n bó ṣe yẹ." }
{ "en": "This work often yielded artifacts from the war, including defunct weapons.", "eng": null, "yor": "Tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́, wọ́n sábà máa ń rí àwọn nǹkan tí wọ́n fi jagun nígbà yẹn, títí kan àwọn ohun ìjà tí kò wúlò mọ́." }
{ "en": "As Russian authorities continue to fabricate lies to discredit our reputation as peace-loving people, we recall the words of Jesus, who foretold that opposers would “lyingly say every sort of wicked thing against” his disciples.—Matthew 5:11.\"", "eng": null, "yor": "Bí àwọn aláṣẹ nílẹ̀ Rọ́ṣíà ṣe ń hùmọ̀ irọ́ kí wọ́n lè bà wá lórúkọ jẹ́ pé a kìí ṣe èèyàn àlàáfíà yìí ń rán wa létí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé àwọn alátakò máa “parọ́ oríṣiríṣi ohun burúkú mọ́” àwọn ọmọlẹ́yìn òun.—Mátíù 5:11.\"" }
{ "en": "\"Judge Ivan Belykh of the Zheleznodorozhniy District Court of Khabarovsk has scheduled the verdict in the criminal case against 52-year-old Brother Valeriy Moskalenko to be announced on September 2, 2019.", "eng": null, "yor": "\"Adájọ́ Ivan Belykh ti ilé ẹjọ́ agbègbè Zheleznodorozhniy ní Khabarovsk ti fi ìdájọ́ lórí ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi kan Arákùnrin Valeriy Moskalenko tó jẹ́ ẹni ọdún méjìléláàádọ́ta (52) sí September 2, 2019." }
{ "en": "Brother Moskalenko has been in pretrial detention since his arrest on the morning of August 2, 2018, when Federal Security Service (FSB) and riot police raided his home.", "eng": null, "yor": "August 2, 2018 ni wọ́n mú Arákùnrin Moskalenko nígbà tí àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Ìjọba àtàwọn ọlọ́pàá tó ń kó àwọn tó ń jà ìjà ìgboro ya wọ ilé rẹ̀." }
{ "en": "Agents searched Brother Moskalenko’s home for some five hours before arresting him.", "eng": null, "yor": "Àwọn agbófinró gbọn ilé Arákùnrin Moskalenko yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́ fún bíi wákàtí márùn-ún kí wọ́n tó mú un." }
{ "en": "Because he has remained in pretrial detention for over a year, there is concern that he will be convicted and sentenced to prison just as was the case with Dennis Christensen.", "eng": null, "yor": "Àtìgbà yẹn ni wọ́n ti tì í mọ́lé láì tíì gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀, pẹ̀lú bó ṣe jẹ́ pé ó ti wà lẹ́wọ̀n láì tíì gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ fún ohun tó lé ní ọdún kan báyìí, ọ̀pọ̀ ló ń ronú pé wọ́n lè dá a lẹ́bi, kí wọ́n sì fi sẹ́wọ̀n bíi ti Dennis Christensen." }
{ "en": "On December 18, 2018, a complaint, Moskalenko v. Russia, was filed with the European Court of Human Rights (ECHR).", "eng": null, "yor": "Ní December 18, 2018, a kọ̀wé sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù lórí ẹjọ́ Moskalenko v. Russia.." }
{ "en": "Over 50 applications have been filed with the ECHR against Russia, with 34 of them already communicated to the Russian government.", "eng": null, "yor": "Ẹ̀sùn tó lé ní àádọ́ta (50) ló wà níwájú ilé ẹjọ́ yìí lòdì sí ilẹ̀ Rọ́ṣíà, mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (34) nínú rẹ̀ sì ti dé etígbọ̀ọ́ ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà." }
{ "en": "We take pride in our dear Russian brothers and sisters ‘because of their endurance and faith in all their persecutions and the hardships that they are suffering.’", "eng": null, "yor": "À ń fi àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ní Rọ́ṣíà yangàn ‘nítorí ìfaradà àti ìgbàgbọ́ wọn nínú gbogbo inúnibíni àti àwọn ìṣòro tí wọ́n ń dojú kọ.’" }
{ "en": "Clearly, they have Jehovah’s support and blessing.", "eng": null, "yor": "Ó hàn gbangba pé Jèhófà ń tì wọ́n lẹ́yìn, ó sì ń bù kún wọn." }
{ "en": "We pray he continues to give Brother Moskalenko the strength needed to endure with joy, no matter the outcome of next week’s verdict.—2 Thessalonians 1:4.\"", "eng": null, "yor": "Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà máa bá a lọ láti fún Arákùnrin Moskalenko ní okun tó nílò kó lè máa fara dà á pẹ̀lú ìdùnnú, láìka ohun tó lé jẹ́ àbájáde ìdájọ́ náà.​—2 Tẹsalóníkà 1:4.\"" }
{ "en": "\"Brother Dennis Christensen has spent over 525 days in prison for practicing his faith and has appeared in court nearly 50 times.", "eng": null, "yor": "\"Arákùnrin Dennis Christensen ti lo ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (525) ọjọ́ lẹ́wọ̀n torí pé ó ń ṣe ohun tó gbà gbọ́, ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta (50) ìgbà tó ti fara hàn nílé ẹjọ́." }
{ "en": "The Zheleznodorozhniy District Court in Oryol, Russia, which is considering Dennis’ case, has scheduled hearings through mid-December.", "eng": null, "yor": "Ilé Ẹjọ́ Zheleznodorozhniy nílùú Oryol ní Rọ́ṣíà, tó ń gbọ́ ẹjọ́ Dennis, ti ṣètò ìgbẹ́jọ́ náà sí àárín oṣù December." }
{ "en": "Although his detention has dragged on for over 18 months, Dennis has never lost his positive attitude.", "eng": null, "yor": "Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé ní ọdún kan ààbọ̀ tí Dennis ti wà ní àtìmọ́lé, síbẹ̀ ó ṣì ń láyọ̀, ó sì gbà pé nǹkan á dáa." }
{ "en": "No doubt this is evidence that Jehovah is sustaining him in answer to millions of prayers by our worldwide brotherhood.", "eng": null, "yor": "Kò sí àní-àní pé Jèhófà ń gbọ́ àìmọye àdúrà tí ẹgbẹ́ ará wa kárí ayé ń gbà nítorí arákùnrin yìí, ó sì ń fún un lókun." }
{ "en": "Dennis has received hundreds of cards and drawings from fellow Witnesses in Russia and other countries expressing their loving support.", "eng": null, "yor": "Ọgọ́rọ̀ọ̀rún káàdì àtàwọn ìwé tí wọ́n yàwòrán sí ni Dennis ti rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bíi tiẹ̀ ní Rọ́ṣíà àtàwọn orílẹ̀-èdè míì, tí wọ́n ń fìyẹn sọ fún un pé àwọn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, gbágbáágbá làwọn sì wà lẹ́yìn rẹ̀." }
{ "en": "At his October 30 court hearing, Dennis displayed through the glass of his detention booth some of the cards and pictures that children have sent to him, so that all who came to support him could enjoy seeing them.", "eng": null, "yor": "Níbi ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ tí wọ́n ṣe ní October 30, Dennis fi díẹ̀ lára àwọn káàdì àtàwọn àwòrán táwọn ọmọdé fi ránṣẹ́ sí i han àwọn èèyàn látinú ẹ̀wọ̀n onígíláàsì táwọn aláṣẹ dé e mọ́, kí gbogbo àwọn tó bá wá kí i lè rí i, kó sì fún wọn níṣìírí." }
{ "en": "During a break in his court hearing on October 30, 2018, Dennis Christensen displays through the glass of his detention booth some of the letters of encouragement he has received.", "eng": null, "yor": "Lásìkò ìsinmi ní October 30, 2018, tí ilé ẹjọ́ ń gbọ́ ẹjọ́ Dennis Christensen, ó ń fi díẹ̀ lára àwọn lẹ́tà ìṣírí táwọn ará fún un han àwọn èèyàn látinú ẹ̀wọ̀n onígíláàsì tí wọ́n dé e mọ́." }
{ "en": "In addition to our worldwide brotherhood, the international community has shown great interest in Dennis’ case.", "eng": null, "yor": "Kì í ṣe ẹgbẹ́ ará wa kárí ayé nìkan lọ̀rọ̀ Dennis ń ká lára, àwọn ẹlòmíì káàkiri ayé pàápàá ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀." }
{ "en": "On July 21, 2017, the Moscow-based Memorial Human Rights Centre granted Dennis political prisoner status.", "eng": null, "yor": "Bí àpẹẹrẹ, ní July 21, 2017, Iléeṣẹ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn tó fìkàlẹ̀ sílùú Moscow kéde pé àwọn olóṣèlú ló fi Dennis sẹ́wọ̀n." }
{ "en": "On June 20, 2018, Russia’s Human Rights Council requested that the Prosecutor General’s Office verify the lawfulness of the criminal prosecution of Jehovah’s Witnesses.", "eng": null, "yor": "Ní June 20, 2018, Àjọ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ní Rọ́ṣíà sọ pé kí Ọ́fíìsì Olùpẹ̀jọ́ Ìjọba ṣèwádìí bóyá ó bófin mu láti máa fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́." }
{ "en": "On September 26, 2018, the United States Commission on International Religious Freedom formally adopted Dennis as a “religious prisoner of conscience.”", "eng": null, "yor": "Nígbà tó tún di September 26, 2018, Àjọ Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà Tó Ń Rí sí Òmìnira Ẹ̀sìn Kárí Ayé forúkọ Dennis sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ẹni tí wọ́n rán lọ sẹ́wọ̀n torí ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ gbà gbọ́.”" }
{ "en": "Russia guaranteed in open court that the ban on the legal entities of Jehovah’s Witnesses would not affect the rights of individual Witnesses to practice their faith.", "eng": null, "yor": "Gbangba ni ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti sọ ọ́ nílé ẹjọ́ pé báwọn ṣe gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ibi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe ẹ̀sìn wọn ò túmọ̀ sí pé àwọn máa dí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ kó má ṣe ohun tó gbà gbọ́." }
{ "en": "Local and federal law enforcement agencies have disregarded this guarantee and misapplied the law to justify arresting Dennis and many others, charging them with “extremist” activity.", "eng": null, "yor": "Àwọn agbófinró ìjọba ìbílẹ̀ àti ti ìjọba àpapọ̀ ò tẹ̀ lé ohun tí ìjọba sọ yẹn, wọ́n sì ti ṣi òfin lò kí wọ́n lè mú Dennis àti ọ̀pọ̀ àwọn míì, kí wọ́n sì fẹ̀sùn “agbawèrèmẹ́sìn” kàn wọ́n." }
{ "en": "This year, Russia conducted scores of raids across the Federation.", "eng": null, "yor": "Lọ́dún yìí, ọ̀pọ̀ ilé àwọn Ẹlẹ́rìí ni àwọn aláṣẹ ti ya wọ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè náà." }
{ "en": "As of this posting, 25 brothers and sisters are in prison, 18 are under house arrest, and more than 40 are under a variety of other restrictions.", "eng": null, "yor": "Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ló wà lẹ́wọ̀n, àwọn méjìdínlógún (18) wà nílé, wọ́n ní wọn ò gbọ́dọ̀ jáde nílé, àwọn míì tó sì lé ní ogójì (40) ni wọn ò jẹ́ kó lómìnira lọ́nà kan tàbí òmíì." }
{ "en": "The outcome of Dennis’ criminal trial will therefore set a precedent for the more than 90 other Jehovah’s Witnesses, in approximately 30 regions of Russia, who are awaiting the results of their criminal investigation.", "eng": null, "yor": "Ohun tó bá tẹ̀yìn ìgbẹ́jọ́ Dennis yọ ló máa pinnu ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà míì tí wọ́n lé ní àádọ́rùn-ún (90), tí wọ́n wà láwọn àgbègbè tó tó ọgbọ̀n (30) ní Rọ́ṣíà, tí wọ́n ń retí èsì ìwádìí táwọn aláṣẹ ń ṣe lórí bóyá ọ̀daràn ni wọ́n lóòótọ́." }
{ "en": "We know our international family will keep praying that Jehovah continues to strengthen and encourage our dear brothers and sisters facing criminal charges for their faith, as we eagerly look forward to the day when he will “cause justice to be done” in their behalf.—Luke 18:7.\"", "eng": null, "yor": "A mọ̀ pé àwọn ará wa kárí ayé ò ní dákẹ́ àdúrà sí Jèhófà, pé kó túbọ̀ máa pèsè okun fún àwọn ará wa tí wọ́n fẹ̀sùn kàn torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́, kó sì máa bá wa gbé wọn ró, bí gbogbo wa ṣe ń retí ọjọ́ tó máa “mú kí a dájọ́ bó ṣe tọ́” fún wọn.​—Lúùkù 18:7.\"" }
{ "en": "\"On April 9, 2019, the Surgut City Court ordered the release of Brothers Yevgeniy Fedin and Sergey Loginov from pretrial detention.", "eng": null, "yor": "\"Ní April 9, 2019, Ilé Ẹjọ́ Ìlú Surgut pàṣẹ pé kí wọ́n tú Arákùnrin Yevgeniy Fedin àti Arákùnrin Sergey Loginov sílẹ̀ ní àtìmọ́lé." }
{ "en": "This denied the request by Russian authorities to extend their detention.", "eng": null, "yor": "Ìpinnu yìí wọ́gi lé ohun táwọn aláṣẹ ní Rọ́ṣíà béèrè pé kí wọ́n fi kún àsìkò táwọn arákùnrin yìí máa lò látìmọ́lé." }
{ "en": "Although the criminal charges against both brothers are still under investigation, they were allowed to leave the detention center on April 11.", "eng": null, "yor": "Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwádìí ṣì ń lọ lọ́wọ́ lórí ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tí wọ́n fi kan àwọn arákùnrin méjèèjì, wọ́n fún wọn láyè láti kúrò látìmọ́lé ní April 11." }
{ "en": "Brothers Fedin and Loginov had been detained since February 15, 2019, when they were arrested following mass home raids in the city of Surgut.", "eng": null, "yor": "Ìgbà táwọn aláṣẹ tú ilé ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn nílùú Surgut ní February 15, 2019 ni wọ́n mú Arákùnrin Fedin àti Arákùnrin Loginov, tí wọ́n sì tì wọ́n mọ́lé." }
{ "en": "On that occasion, authorities initiated criminal cases against a total of 19 Witnesses.", "eng": null, "yor": "Lásìkò yẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí mọ́kàndínlógún (19) làwọn aláṣẹ fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kàn." }
{ "en": "Three of them, Yevgeniy and Sergey, along with Brother Artur Severinchik, were ordered to remain in pretrial detention.", "eng": null, "yor": "Wọ́n sì ju mẹ́ta lára wọn sátìmọ́lé láì tíì gbọ́ ẹjọ́ wọn, àwọn ni: Yevgeniy àti Sergey pẹ̀lú Arákùnrin Artur Severinchik." }
{ "en": "Artur was released earlier on March 15.", "eng": null, "yor": "Ní March 15, wọ́n tú Artur sílẹ̀." }
{ "en": "During the February raids, law enforcement officers tortured seven of our brothers, including Brother Loginov.", "eng": null, "yor": "Nígbà tí wọ́n ń kó àwọn èèyàn lóṣù February, àwọn agbofinró dá méje lára àwọn ará wa lóró, Arákùnrin Loginov sì wà lára àwọn tí wọ́n dá lóró náà." }
{ "en": "A complaint regarding this abusive treatment has been filed with the European Court of Human Rights.", "eng": null, "yor": "A fi ẹjọ́ bí wọ́n ṣe dá àwọn ará wa lóró yìí sùn ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù." }
{ "en": "The complaint is still under consideration.", "eng": null, "yor": "Wọ́n sì ti ń gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò." }
{ "en": "We are confident that Jehovah will continue to demonstrate that he is paying close attention to our prayers as he strengthens our faithful brothers and sisters in Russia.—Psalm 10:17.\"", "eng": null, "yor": "Ó dá wa lójú pé Jèhófà ó ní yé fi hàn pé òun ń fiyè sí gbogbo àdúrà wa, bó ṣe ń fún àwọn ará wa olóòótọ́ lókun ní Rọ́ṣíà.—Sáàmù 10:17.\"" }
{ "en": "\"On Thursday, November 14, 2019, the Ordzhonikidzevskiy District Court of Perm’ convicted Brother Aleksey Metsger and fined him 350,000 rubles (approx. $5,460 U.S.).", "eng": null, "yor": "\"Ní Thursday, November 14, 2019, ilé ẹjọ́ agbègbè Ordzhonikidzevskiy tó wà ní Perm dá Arákùnrin Aleksey Metsger lẹ́bi, kódà ó ní kó san owó ìtanràn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àtààbọ̀ Ruble (350,000 Rubles) ìyẹn sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti ọgọ́ta owó dọ́là ilẹ̀ Amẹ́ríkà ($5,460 U.S.)" }
{ "en": "He is the 12th brother in Russia to be convicted this year for so-called extremist activity for peacefully practicing or sharing his beliefs.", "eng": null, "yor": "Arákùnrin yìí ni ẹni kejìlá (12) tí wọ́n dá lẹ́bi ní Rọ́ṣíà lọ́dún yìí lórí ẹ̀sùn tí kò jẹ́ òótọ́ tí wọ́n fi kàn wọ́n pé agbawèrèmẹ́sìn ni wọ́n." }
{ "en": "Brother Metsger’s lawyer will appeal the conviction.", "eng": null, "yor": "Agbẹjọ́rò Arákùnrin Metsger máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn nítorí ìdájọ́ yìí." }
{ "en": "On April 25, 2019, a criminal case was brought against Brother Metsger based on the fact that he professed to be one of Jehovah’s Witnesses.", "eng": null, "yor": "Ní April 25, 2019, wọ́n fi ẹ̀sùn ọ̀daràn kan Arákùnrin Metsger nítorí pé ó sọ pé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun." }
{ "en": "Some of the evidence included conversations Brother Metsger had about religion with individuals who secretly recorded their discussions.", "eng": null, "yor": "Lára àwọn ẹ̀rí tí wọ́n lò lòdì sí Arákùnrin Metsger ni ọ̀rọ̀ tí òun àtàwọn kan jọ sọ nípa ẹ̀sìn táwọn yẹn sì gbohùn ẹ̀ sílẹ̀ ní bòńkẹ́lẹ́." }
{ "en": "The trial began on October 14, 2019, the city prosecutor requested that Brother Metsger be sentenced to three years in prison.", "eng": null, "yor": "October 14, 2019 ni ìgbẹ́jọ́ náà bẹ̀rẹ̀, agbẹjọ́rò ìjọba sì ní kí wọ́n fi Arákùnrin Metsger sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́ta." }
{ "en": "Although the court did not sentence Brother Metsger to prison, we are concerned that yet another brother has been convicted and that this trend will result in many more of our brothers and sisters being prosecuted for their faith.", "eng": null, "yor": "Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé ẹjọ́ kò sọ Arákùnrin Metsger sẹ́wọ̀n, wọ́n ti dá arákùnrin wa míì lẹ́bi, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n tún ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ lára àwọn ará wa torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́." }
{ "en": "While the authorities keep persecuting our brothers in Russia without just cause, we know that Jehovah will continue to comfort and strengthen them.—Psalm 119:76, 161.\"", "eng": null, "yor": "Bí àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe ń fúngun mọ́ àwọn arákùnrin wa láìnídìí, a mọ̀ pé Jèhófà máa tù wọ́n nínú, á sì máa fún wọn lókun.​—Sáàmù 119:76, 161.\"" }
{ "en": "\"The Zheleznodorozhniy District Court in Khabarovsk will announce its verdict on Friday, February 14, 2020, in the trial involving Brother Yevgeniy Aksenov.", "eng": null, "yor": "\"Ilé ẹjọ́ agbègbè Zheleznodorozhniy tó wà nílùú Khabarovsk máa dá ẹjọ́ Arákùnrin Yevgeniy Aksenov ní Friday, February 14, 2020, lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án." }
{ "en": "The prosecution has requested a three-year prison sentence.", "eng": null, "yor": "Agbẹjọ́rò ìjọba fẹ́ kí wọ́n fi arákùnrin náà sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́ta." }
{ "en": "On April 21, 2018, Brother Aksenov gathered with friends and acquaintances in a hotel conference room to discuss the Bible.", "eng": null, "yor": "Ní April 21, 2018, Arákùnrin Aksenov péjọ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ ní yàrá àpérò ní hòtẹ́ẹ̀lì kan láti sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì." }
{ "en": "On that occasion, he spoke to those assembled about how Bible principles can strengthen families.", "eng": null, "yor": "Níbi ìjíròrò yẹn, ó bá àwùjọ náà sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè mú kí ìdílé wà níṣọ̀kan." }
{ "en": "For this reason, he was accused of a “socially dangerous crime” and charged with “organizing the activities of an extremist organization.”", "eng": null, "yor": "Fún ìdí yẹn, wọ́n fẹ̀sùn “ìwà ọ̀daràn tó burú jáì” kàn án, wọ́n sì pè é lẹ́jọ́ fún “ṣíṣètò ìgbòkègbodò àwọn agbawèrèmẹ́sìn.”" }
{ "en": "The trial began on October 21, 2019.", "eng": null, "yor": "Ìgbẹ́jọ́ náà bẹ̀rẹ̀ ní October 21, 2019." }
{ "en": "As Brother Aksenov’s trial comes to a close, we pray that he and his family will continue to look to Jehovah for support, confident in Jehovah’s inspired promise that his loyal ones will “lack nothing.”—Psalm 34:9.\"", "eng": null, "yor": "Bí ìgbẹ́jọ́ Arákùnrin Aksenov ṣe ń parí lọ, àdúrà wa ni pé kí òun àti ìdílé ẹ̀ túbọ̀ gbára lé Jèhófà, kí wọ́n sì fọkàn sí ìlérí rẹ̀ pé àwọn ẹni ìdúróṣinṣin “kò ní ṣaláìní” ohunkóhun.​—Sáàmù 34:9.\"" }
{ "en": "\"As previously reported, on May 23, 2019, the Oryol Regional Court upheld the conviction of Dennis Christensen.", "eng": null, "yor": "\"Bá a ṣe sọ nínú ìròyìn tó jáde ní May 23, 2019, Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Oryol fara mọ́ ọn pé kí Dennis Christensen lọ sẹ́wọ̀n." }
{ "en": "As a result, Brother Christensen’s six-year sentence remains in place.", "eng": null, "yor": "Torí náà, ẹjọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà tí wọ́n dá fún Arákùnrin Christensen ò tíì yí pa dà." }
{ "en": "Since he has served two years in pretrial detention, which under Russian law is considered the equivalent of three years in prison, there are three years remaining on his sentence.", "eng": null, "yor": "Ó ti lo ọdún méjì látìmọ́lé kí wọ́n tó dá ẹjọ́ rẹ̀, nínú òfin orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, èyí ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ọdún mẹ́ta nínú ẹ̀wọ̀n, torí náà ọ́dún mẹ́ta ló kù tí wọ́n retí pé kó lò lẹ́wọ̀n." }
{ "en": "On the evening of June 6, 2019, Brother Christensen was transferred to a penal colony to begin his sentence.", "eng": null, "yor": "Ní ìrọ̀lẹ́ June 6, 2019, wọ́n mú Arákùnrin Christensen lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n kan táwọn ẹlẹ́wọ̀n ti ń ṣiṣẹ́, kó lè lọ ṣẹ̀wọ̀n níbẹ̀." }
{ "en": "An application regarding Brother Christensen’s criminal conviction will be filed with the European Court of Human Rights (ECHR).", "eng": null, "yor": "A máa fi ìwé tá a kọ lórí bí wọ́n ṣe rán Arákùnrin Christensen lẹ́wọ̀n láìtọ́ ránṣẹ́ sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù (ECHR)." }
{ "en": "An application contesting his pretrial detention is already pending with the ECHR.", "eng": null, "yor": "Ìwé tá a kọ ránṣẹ́ sí Ilé Ẹjọ́ ECHR lórí bí wọ́n ṣe tì í mọ́lé láì tíì gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ ṣì wà lọ́dọ̀ wọn." }
{ "en": "We admire the calm endurance of Brother Christensen in the face of this ongoing injustice.", "eng": null, "yor": "A mọyì bí Arákùnrin Christensen ṣe ń fara dà á nìṣó láìka ìdájọ́ tí kò tọ́ tí wọ́n ṣe fún un sí." }
{ "en": "We are assured that Jehovah will continue to sustain him, as well as the more than 200 Jehovah’s Witnesses in Russia facing criminal charges.—Psalm 27:1.", "eng": null, "yor": "Ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní fi í sílẹ̀, àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì (200) tí wọ́n fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kàn ní lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.​—Sáàmù 27:1." }
{ "en": "Read the transcript of Dennis Christensen’s address to the Oryol Regional Court on May 16, 2019.", "eng": null, "yor": "Ka ọ̀rọ̀ tí Dennis Christensen sọ ní Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Oryol ní May 16, 2019." }
{ "en": "Read the transcript of Dennis Christensen’s address to the Oryol Regional Court on May 23, 2019.\"", "eng": null, "yor": "Ka ọ̀rọ̀ tí Dennis Christensen sọ ní Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Oryol ní May 23, 2019.\"" }
{ "en": "\"Authorities in Omsk, Russia, sentenced a Witness couple, Sergey and Anastasia Polyakov, to pretrial detention on July 6, 2018.", "eng": null, "yor": "\"Ní July 6, 2018, àwọn aláṣẹ ní ìlú Omsk, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ju tọkọtaya kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí àtìmọ́lé láì tíì gbọ́ ẹjọ́ wọn nílé ẹjọ́, Sergey àti Anastasia Polyakov lorúkọ wọn." }