translation
dict
{ "en": "This marks the first time one of our sisters has been imprisoned in Russia since the Supreme Court decision banning the activity of Jehovah’s Witnesses.", "eng": null, "yor": "Èyí nìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ju Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ obìnrin sí ẹ̀wọ̀n ní Rọ́ṣíà látìgbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti sọ pé kí wọ́n fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà." }
{ "en": "The Moscow-based SOVA Center for Information and Analysis stated concerning this recent imprisonment:", "eng": null, "yor": "Nígbà tí Ilé iṣẹ́ kan tó máa ń ṣèwádìí, tí wọ́n ń pè ní SOVA Center for Information and Analysis ní ìlú Moscow, ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ó ní:" }
{ "en": "“We believe that this decision, like the persecution of Jehovah’s Witnesses as a whole, had no legal basis, and we consider it as a manifestation of religious discrimination.”", "eng": null, "yor": "“A gbà pé ìpinnu tí wọ́n ṣe yìí, irú bí wọ́n ṣe ń fìyà jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lápapọ̀, kò bófin mu, ẹ̀tanú ẹ̀sìn gbáà ló jẹ́.”" }
{ "en": "There are now 21 brothers and 1 sister imprisoned for their faith in Russia.", "eng": null, "yor": "Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àwọn mọ́kànlélógún (21) ọkùnrin àti obìnrin kan ló wà lẹ́wọ̀n lára àwọn ará wa ní Rọ́ṣíà torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́." }
{ "en": "We continue to pray that they have courage, knowing that Jehovah is their ultimate Helper.—Hebrews 13:6.\"", "eng": null, "yor": "Àdúrà wa ni pé kí wọ́n nígboyà, kó sì dá wọn lójú pé Jèhófà ni Olùrànlọ́wọ́ wọn gíga jù lọ.​—Hébérù 13:6.\"" }
{ "en": "\"On March 7, 2019, the Appeals Court in Khanty-Mansiysk, Russia, overturned the decision of the Surgut City Trial Court to detain Brother Artur Severinchik.", "eng": null, "yor": "\"Ní March 7, 2019, Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tó wà ní ìlú Khanty-Mansiysk, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà wọ́gi lé ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ Ìlú Surgut ṣe pé kí wọ́n ti Arákùnrin Artur Severinchik mọ́lé." }
{ "en": "He was subsequently released from pretrial detention on March 15.", "eng": null, "yor": "Wọ́n sì tú u sílẹ̀ nínu àtìmọ́lé ní March 15." }
{ "en": "Brother Severinchik is one of three brothers who was placed in pretrial detention on February 17, following raids in the cities of Surgut and Lyantor.", "eng": null, "yor": "Arákùnrin Severinchik wà lára àwọn arákùnrin mẹ́ta tí wọ́n jù sí àtìmọ́lé ní February 17, lẹ́yìn táwọn aláṣẹ ya wọlé àwọn èèyàn ní ìlú Surgut àti Lyantor." }
{ "en": "The court has denied the release of the two other brothers, Yevgeniy Fedin and Sergey Loginov.", "eng": null, "yor": "Ilé ẹjọ́ ò fọwọ́ sí i pé kí wọ́n tú àwọn arákùnrin méjì tó kù sílẹ̀, ìyẹn Yevgeniy Fedin àti Sergey Loginov." }
{ "en": "The situation has garnered international attention.", "eng": null, "yor": "Ọ̀pọ̀ ìjọba àtàwọn oníròyìn kárí ayé ló ti gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ yìí." }
{ "en": "The European Court of Human Rights ordered an independent medical examination of Brother Loginov, who was subjected to physical abuse while he was detained.", "eng": null, "yor": "Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù pàṣẹ pé kí wọ́n jẹ́ káwọn dókítà ṣàyẹ̀wò ìlera Arákùnrin Loginov, torí bí wọ́n ṣe lù ú lálùbami nígbà tí wọ́n tì í mọ́lé." }
{ "en": "We are grateful that Brother Severinchik was released.", "eng": null, "yor": "A dúpẹ́ pé wọ́n tú Arákùnrin Severinchik sílẹ̀." }
{ "en": "We continue to pray that our imprisoned brothers in Russia trust in Jehovah, remembering that with his support they “will never be shaken.”—Psalm 16:8.\"", "eng": null, "yor": "Àdúrà wa ni pé kí àwọn ará wa tó wà lẹ́wọ̀n ní Rọ́ṣíà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí wọ́n sì máa rántí pé bó ṣe ń ràn wọ́n lọ́wọ́, ‘mìmì kan ò ní mì wọ́n.’​—Sáàmù 16:8.\"" }
{ "en": "\"Over the past 18 months, local police and Federal Security Service (FSB) agents in Russia have raided a total of 613 homes of our brothers and sisters.", "eng": null, "yor": "\"Láàárín oṣù méjìdínlógún (18) tó kọjá, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti mẹ́tàlá (613) ilé àwọn arákùnrin wa ni àwọn ọlọ́pàá àti ẹ̀ṣọ́ aláàbò orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, ìyẹn Federal Security Service (FSB) ti lọ gbọ̀n yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́." }
{ "en": "Since January 2019, authorities have raided 332 homes—already exceeding the 281 that were invaded in all of 2018.", "eng": null, "yor": "Nígbà tó fi máa di January 2019, ilé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti méjìlélọ́gbọ̀n (332) ni àwọn aláṣẹ ti lọ tú, èyí sì ju àpapọ̀ ilé tí wọ́n tú ní 2018 lọ, tó jẹ́ ọgọ́rùn-ún méjì àti mọ́kànlélọ́gọ́rin (281)." }
{ "en": "Authorities have been especially active against our brothers and sisters in recent months.", "eng": null, "yor": "Ṣe ni iye ilé àwọn ará wa táwọn agbófinró ń ya wọ̀ láwọn oṣù díẹ̀ sẹ́yìn túbọ̀ ń pọ̀ sí i." }
{ "en": "In June there were 71 raids, and in July there were 68—a significant increase compared to the 23.4 average number of raids per month in 2018.", "eng": null, "yor": "Bí àpẹẹrẹ, ilé mọ́kànléláàádọ́rin (71) ni wọ́n ya wọ̀ lóṣù June, nígbà tí ti July jẹ́ méjìdínláàádọ́rin (68), èyí sì lọ sókè gan-an ní ìfiwéra pẹ̀lú iye ilé mẹ́tàlélógún àti ẹ̀sún mẹ́rin (23.4) ní ìpíndọ́gba tí wọ́n ya wọ̀ lóṣooṣù lọ́dún 2018." }
{ "en": "Russian authorities raiding a home in Nizhniy Novgorod", "eng": null, "yor": "Àwọn ọlọ́pàá orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ń fipá wọ ilé kan ní Nizhniy Novgorod" }
{ "en": "In a typical raid, masked and heavily armed security forces converge on a house or apartment.", "eng": null, "yor": "Lọ́pọ̀ Ìgbà, ṣe ni ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n dira ogun tí wọ́n sì fi nǹkan bojú máa ya wọ ilé kan ṣoṣo." }
{ "en": "Once inside the home, agents have at times pointed guns in the faces of Witnesses, including children and the elderly, as if they are hardened and dangerous criminals.", "eng": null, "yor": "Bí wọ́n bá ti rọ́nà wọlé, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọn máa ń na ìbọn sí àwọn ará wa títí kan àwọn àgbàlagbà àti àwọn ọmọdé bí i pé ògbólógbòó ọ̀daràn ni wọ́n wá mú." }
{ "en": "It stands to reason, then, that several experts agree with Dr. Derek H. Davis.", "eng": null, "yor": "Abájọ tí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n fi gbà pẹ̀lú ohun tí Dókítà Derek H. Davis sọ." }
{ "en": "The former director of Baylor University’s J.M. Dawson Institute of Church-State Studies, who states:", "eng": null, "yor": "Òun ni ọ̀gá tẹ́lẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ J.M. Dawson Institute of Church-State Studies ní Baylor University níbi tí wọ́n ti ń kọ́ Ẹ̀kọ́ Nípa Àjọṣe Tó Wà Láàárín Ìsìn àti Ìjọba, ó sọ pé:" }
{ "en": "“Russia’s aggressive persecution of a peaceful group like the Jehovah’s Witnesses is patently ‘extreme.’”", "eng": null, "yor": "“Inúnibíni tó rorò tí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ń ṣe sí àwọn èèyàn alálàáfíà bí i ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti jẹ́ ká rí i pé ìjọba gan-an ni ‘agbawèrèmẹ́sìn.’”" }
{ "en": "Unfortunately, as the raids have increased, so have the criminal cases against our brothers.", "eng": null, "yor": "Ó ṣeni láàánú pé, bí iye ilé tàwọn aláṣẹ ń ya wọ̀ ṣe ń pọ̀ sí i bẹ́ẹ̀ ni iye ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n ń fi kan àwọn ará wa túbọ̀ ń pọ̀ sí i." }
{ "en": "There are now 244 brothers and sisters facing criminal charges in Russia and Crimea.", "eng": null, "yor": "Àwọn ará wa tí iye wọn jẹ́ igba ó lé mẹ́rìnlélógójì (244) ni wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àti ní ilẹ̀ Crimea báyìí." }
{ "en": "This number has more than doubled since December 2018, when there were 110 open criminal cases.", "eng": null, "yor": "Èyí sì ju ìlọ́po méjì ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn wọ́n ní December 2018 lọ, èyí tó jẹ́ àádọ́fà (110) nígbà yẹn." }
{ "en": "Of the 244 brothers and sisters facing prosecution, 39 are in detention, 27 are under house arrest, and over 100 are under a variety of restrictions.", "eng": null, "yor": "Nínú àwọn igba ó lé mẹ́rìnlélógójì (244) ará wa tó ń jẹ́jọ́, mọ́kàndínlógójì [39] nínú wọn ló wà ní àtìmọ́lé, wọ́n fòfin de àwọn mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) pé wọn ò gbọ́dọ̀ jáde nílé, nígbà tí wọ́n fún àwọn tó lé ní ọgọ́rùn-ún kan (100) ni onírúurú ìkálọ́wọ́kò." }
{ "en": "Although our brothers and sisters continue to be targeted by Russian authorities, we are ‘not shaken by these tribulations.’", "eng": null, "yor": "Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣì ń bá a lọ láti máa ṣe inúnibíni sáwọn ará wa, síbẹ̀ ‘àwọn ìpọ́njú yìí ò ní mú ká yẹsẹ̀.’" }
{ "en": "Rather, we are encouraged by reports that our fellow believers are remaining loyal and enduring.", "eng": null, "yor": "Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ìròyìn tá à ń gbọ́ nípa bí àwọn ará wa ṣe jẹ́ adúróṣinṣin tí wọ́n sì ń lo ìfaradà túbọ̀ ń fún wa níṣìírí." }
{ "en": "We thus praise and thank Jehovah for answering our many prayers in their behalf, and we remain ever confident that he will continue to do so.—1 Thessalonians 3:3, 7.\"", "eng": null, "yor": "Torí náà, a dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún bó ṣe ń dáhùn àdúrà tá à ń gbà nítorí àwọn ará wa yìí, ó sì dá wa lójú pé á túbọ̀ máa gbọ́ àdúrà wa.​—1 Tẹsalóníkà 3:​3, 7.\"" }
{ "en": "\"One of the 19 individuals being baptized", "eng": null, "yor": "\"Ọ̀kan lára àwọn mọ́kàndínlógún (19) tó ṣèrìbọmi" }
{ "en": "Our brothers hosted the first Romany-language regional convention in Slovakia, from July 20 to 21, 2019, at the Winter Stadium in Michalovce.", "eng": null, "yor": "Ní July 20 sí 21, 2019, àwọn ará wa ṣe àpéjọ àgbègbè àkọ́kọ́ ní èdè Rómánì ní Slovakia nínú pápá ìṣeré tí wọ́n ń pè ní Winter Stadium ní Michalovce." }
{ "en": "The abbreviated program had a peak attendance of 1,276. A total of 19 were baptized.", "eng": null, "yor": "Ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún méjì àti mẹ́rìndínlọ́gọ́rin (1,276) ló pésẹ̀ sí àpéjọ ọlọ́jọ́ méjì yìí, nígbà tí àwọn mọ́kàndínlógún (19) sì ṣèrìbọmi." }
{ "en": "In attendance were brothers and sisters visiting from four lands: Belgium, Czech Republic, Great Britain, and Ukraine.", "eng": null, "yor": "Àwọn ará láti orílẹ̀-èdè mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló pésẹ̀ sí àpéjọ yìí, ìyẹn Belgium, Czech Republic, Great Britain àti Ukraine." }
{ "en": "A highlight for the attendees was being able to enjoy the feature film, The Story of Josiah: Love Jehovah; Hate What Is Bad, in their mother tongue.", "eng": null, "yor": "Ohun tó wú àwọn tó wá síbẹ̀ lórí jù ni bí wọ́n ṣe wo fíìmù Ìtàn Jòsáyà: Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà; Kórìíra Ohun Búburú, ní èdè ìbílẹ̀ wọn." }
{ "en": "The convention comes just five years after the first Romany congregation was formed in Slovakia in November 2014.", "eng": null, "yor": "November 2014 ni wọ́n dá ìjọ àkọ́kọ́ lédè Rómánì sílẹ̀ ní Slovakia, ọdún márùn-ún péré lẹ́yìn náà ni àpéjọ yìí sì wáyé." }
{ "en": "Currently, there are 9 Romany congregations, 10 groups, and 14 pregroups in the Czech-Slovak branch territory.", "eng": null, "yor": "Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ìjọ mẹ́sàn-án, àwùjọ mẹ́wàá àti àwọn tó fẹ́ di àwùjọ mẹ́rìnlá (14) tó ń sọ èdè Rómánì ni ẹ̀ka ọ́fíìsì Czech-Slovak ń bójú tó." }
{ "en": "Peter Tirpak, the Winter Stadium manager, stated:", "eng": null, "yor": "Peter Tirpak, alábòójútó pápá ìṣeré náà sọ pé:" }
{ "en": "“The cooperation from Jehovah’s Witnesses has been excellent.", "eng": null, "yor": "“Bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wa wú wa lórí gan-an." }
{ "en": "You have always kept your word.", "eng": null, "yor": "Ẹ máa ń dúró lórí ọ̀rọ̀ yín." }
{ "en": "We will be happy if you come again.”", "eng": null, "yor": "Inú wa máa dùn tẹ́ ẹ bá tún pa dà wá.”" }
{ "en": "Peter Varga, who served as the convention program overseer, said: “I’ve never experienced such a convention.", "eng": null, "yor": "Peter Varga, tó jẹ́ alábòójútó àpéjọ sọ pé: “Mí ò tíì ṣe irú àpéjọ yìí rí." }
{ "en": "For our dear Romany-speaking brothers and sisters, this was a truly historic theocratic milestone.", "eng": null, "yor": "Mánigbàgbé ni àpéjọ yìí jẹ́ fún àwọn ará wa tó ń sọ èdè Rómánì." }
{ "en": "After the final song, they began to hug each other, although they had never met each other before.", "eng": null, "yor": "Lẹ́yìn orin ìparí, ṣé ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í dì mọ́ra wọn bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò mọ ara wọn rí." }
{ "en": "Many had tears in their eyes.”", "eng": null, "yor": "Ọ̀pọ̀ ló ń da omijé ayọ̀ lójú.”" }
{ "en": "We rejoice with the 1,010 publishers who speak Romany in Slovakia. These conventions highlight the genuine brotherly love among Jehovah’s people.—John 13:34, 35.\"", "eng": null, "yor": "A bá àwọn ẹgbẹ̀rún kan àti mẹ́wàá (1,010) akéde tó ń sọ èdè Rómánì ní Slovakia yọ̀. Àpéjọ yìí jẹ́ ká rí ojúlówó ìfẹ́ ará tó wà láàárín àwọn èèyàn Jèhófà.​—Jòhánù 13:34,35.\"" }
{ "en": "\"On Friday, July 19, 2019, the opening day of the “Love Never Fails”! International Convention in Madrid, Spain, Jehovah’s Witnesses released the much-anticipated revised New World Translation of the Holy Scriptures in Spanish.", "eng": null, "yor": "\"Ní Friday, July 19, 2019, lọ́jọ́ àkọ́kọ́ Àpéjọ Àgbáyé tá a pe àkọlé rẹ̀ ní, “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! tá a ṣe ní Madrid, lórílẹ̀-èdè Spain, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe jáde lédè Sípáníìṣì." }
{ "en": "The revised Bible is now available on jw.org® to read and download by the over 2.5 million Spanish-speaking brothers and sisters worldwide.", "eng": null, "yor": "Ọjọ́ pẹ́ tá a ti ń retí ẹ̀! Bíbélì tá a tún ṣe yìí ti wà lórí ìkànnì jw.org®, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa kárí ayé tó lé ní mílíọ̀nù méjì àtààbọ̀ tó ń sọ èdè Spanish lè kà á níbẹ̀ tàbí wà á jáde." }
{ "en": "People that speak the language are the largest language group among Jehovah’s Witnesses. *", "eng": null, "yor": "Àwọn tó ń sọ èdè yìí ló pọ̀ jù lọ nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. *" }
{ "en": "Brother Gerrit Lösch, a member of the Governing Body, released the Bible in a prerecorded video presented at the Wanda Metropolitano Stadium in Madrid, the site of the international convention.", "eng": null, "yor": "Arákùnrin Gerrit Lösch, tó jẹ́ ọkàn lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí mú Bíbélì yìí jáde nínú fídíò tí a ti gbà ohùn àti àwòrán rẹ̀ sílẹ̀ ní àpéjọ àgbáyé tó wáyé ní pápá Ìṣeré Wanda Metropolitano nílùú Madrid." }
{ "en": "The video was simultaneously streamed to 11 other venues throughout Spain.", "eng": null, "yor": "A ṣe àtagbà fídíò yìí sí ibi mọ́kànlá (11) míì ní orílẹ̀-èdè Spain." }
{ "en": "Shortly after the release, the video was posted on JW Broadcasting®.", "eng": null, "yor": "Kété lẹ́yìn náà, a gbé fídíò náà sórí ètò JW Broadcasting®." }
{ "en": "Attendees react to the release of the revised Spanish Bible", "eng": null, "yor": "Inú àwọn tó pé jọ dùn nígbà tí a mú Bíbélì tí a tún ṣe jáde lédè Sípáníìṣì" }
{ "en": "At the international convention venue, special arrangements were made so that attendees could download the Bible—as an EPUB, a JWPUB, or a PDF—by navigating to a webpage on jw.org.", "eng": null, "yor": "Níbi àpéjọ náà, a ṣe àkànṣe ètò tó máa jẹ́ kí àwọn tó wà níbẹ̀ lè wa Bíbélì yìí jáde ní ẹ̀dà EPUB, JWPUB tàbí PDF lórí ìkànnì jw.org." }
{ "en": "Brothers and sisters tied in at the other 11 venues in Spain were also able to download electronic copies of the Bible by connecting their devices to JW Box, a customized Wi-Fi hot spot created by Jehovah’s Witnesses.", "eng": null, "yor": "Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà láwọn ibi mọ́kànlá yòókù ní orílẹ̀-èdè Spain níbi tá a ṣe àtagbà ètò yìí sí ní àǹfààní láti wa ẹ̀dà Bíbélì yìí sórí fóònú tàbí ẹ̀rọ alágbèéká wọn nípa lílo ètò ìṣiṣẹ́ íńtánẹ́ẹ̀tì JW Box tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dìídì ṣe." }
{ "en": "Over 1,200 volunteers were on hand at the international convention venue and satellite locations to help the audience download the revised Bible.", "eng": null, "yor": "Ó lé ní ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún méjì (1,200) àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn tó ti wà ní sẹpẹ́ níbi àpéjọ àgbáyé yìí àti láwọn ibòmíì tá a ṣètò láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tó wá kí wọ́n lè wa Bíbélì sórí fóònù wọn." }
{ "en": "Brothers and sisters download the revised New World Translation in Spanish onto their devices", "eng": null, "yor": "Àwọn arákùnrin àti arábìnrin ń wa Bíbélì tuntun tá a mú jáde ní èdè Sípáníìṣì sí orí ẹ̀rọ alágbèéká wọn" }
{ "en": "The translation of the Bible into Spanish presented a unique challenge, since there is a diverse field of Spanish-speaking Witnesses throughout the world.", "eng": null, "yor": "Ìpèníjà ńlá ni iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì ní èdè Sípáníìṣì jẹ́, torí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń sọ èdè Sípáníìṣì kárí ayé yàtọ̀ síra." }
{ "en": "Brother Pedro Gil, a member of the Spain Branch Committee, explains: “Globally, there are an estimated 577 million Spanish speakers, and from country to country individual words, as well as expressions, vary in meaning.", "eng": null, "yor": "Arákùnrin Pedro Gil, ọkàn lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ní orílẹ̀-èdè Spain sọ pé: “Kárí ayé, nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (577) mílíọ̀nù èèyàn ló ń sọ èdè Spanish, àmọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àtàwọn àgbékalẹ̀ wọn ní ìtumọ̀ tó yàtọ̀ síra láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn." }
{ "en": "Additionally, the Spanish language has changed significantly in recent decades.”", "eng": null, "yor": "Yàtọ̀ sí ìyẹn, èdè Sípáníìṣì tí à ń sọ báyìí ti yàtọ̀ pátápátá sí bí àwọn èèyàn ṣe ń sọ ọ́ lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn.”" }
{ "en": "A young volunteer helps a sister download an electronic copy of the released Bible", "eng": null, "yor": "Ọ̀dọ́ kan tó yọ̀ǹda ara rẹ̀, ń ran arábìnrin kan lọ́wọ́ láti wa Bíbélì tuntun yìí jáde." }
{ "en": "In order to assist the translation team in producing an accurate and easy-to-read text, some 100 brothers and sisters in various countries were consulted.", "eng": null, "yor": "Ká lè ran àwọn atúmọ̀ èdè lọ́wọ́ láti ṣe ìtumọ̀ tó péye tó sì rọrùn láti kà, a kàn sí nǹkan bí ọgọ́rùn-ún kan (100) àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà ní orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti ràn wá lọ́wọ́." }
{ "en": "The entire project took about four and a half years to complete.", "eng": null, "yor": "Gbogbo ẹ̀ gba nǹkan bí ọdún mẹ́rin àtààbọ̀ kó tó parí." }
{ "en": "Brother Gil states: “The updated language used in this revised Spanish New World Translation employs a vocabulary that everyone will understand.", "eng": null, "yor": "Arákùnrin Gil sọ pé: “Èdè tó bágbà mu tá a lò nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe lédè Sípáníìṣì yìí máa tètè yé àwọn tó bá kà á." }
{ "en": "As a result, publishers will find it easy to use in the field service or at the meetings.", "eng": null, "yor": "Nípa bẹ́ẹ̀, á rọrùn fún àwọn akéde láti lò lóde ẹ̀rí àti ní ìpàdé." }
{ "en": "We are very happy that this revision will also help Spanish-speaking brothers and sisters draw closer to Jehovah.”", "eng": null, "yor": "Inú wa dùn pé àtúnṣe yìí á jẹ́ kí àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin tó ń sọ èdè Sípáníìṣì sún mọ́ Jèhófà sí i.”" }
{ "en": "We thank Jehovah for the recent translation that honors his name.", "eng": null, "yor": "A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìtumọ̀ tuntun tó ń mú ìyìn bá orúkọ rẹ̀." }
{ "en": "We trust that this revised Bible will help Jehovah’s Witnesses continue preaching “to the most distant part of the earth.”—Acts 1:8.", "eng": null, "yor": "A nígbàgbọ́ pé Bíbélì tá a tún ṣe yìí máa ran àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ láti máa bá a lọ láti wàásù “dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.”​—Ìṣe 1:8." }
{ "en": "^ par. 2 Because of the unprecedented volume of Bibles required for this release, no printed copies were distributed at the venues.", "eng": null, "yor": "ìpínrọ̀ 2 Iye Bíbélì tá a fẹ́ tẹ̀ jáde lédè yìí pọ̀ gan-an, torí náà, a ò pín ẹ̀dà Bíbélì tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ mú jáde ní àpéjọ yìí." }
{ "en": "However, Spanish congregations worldwide will receive printed copies as soon as they are available.", "eng": null, "yor": "Àmọ́, àwọn ìjọ tó ń sọ èdè Sípáníìṣì máa rí ẹ̀dà Bíbélì yìí gbà ní kété tó bá ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó." }
{ "en": "The Spanish revised Bible will also be available in JW Library® after Monday, July 22.\"", "eng": null, "yor": "A máa gbé e sí orí JW Library® lẹ́yìn ọjọ́ Monday, July 22.\"" }
{ "en": "\"Dates: July 19-21, 2019", "eng": null, "yor": "\"Ọjọ́ Àpéjọ: July 19-21, 2019" }
{ "en": "Location: Wanda Metropolitano Stadium in Madrid, Spain", "eng": null, "yor": "Ibi Àpéjọ: Pápá Ìṣeré Wanda Metropolitano nílùú Madrid lórílẹ̀ èdè Spain" }
{ "en": "Program Languages: English, Spanish, Spanish Sign Language", "eng": null, "yor": "Àwọn Èdè Tí A Lò Fún Ìtòlẹ́sẹẹsẹ: Gẹ̀ẹ́sì, Sípáníìṣì, Èdè Adití Lọ́nà Ti Sípáníìṣì" }
{ "en": "Peak Attendance: 52,516", "eng": null, "yor": "Iye Àwọn Tó Wá: Ẹgbẹ̀rún méjìléláàdọ́ta, ọgọ́rùn-ún márùn-un àti mẹ́rìndínlógún (52,516)" }
{ "en": "Total Number Baptized: 434", "eng": null, "yor": "Iye Àwọn Tó Ṣe Ìrìbọmi: Ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (434)" }
{ "en": "Number of International Delegates: 6,300", "eng": null, "yor": "Iye Àwọn Tó Wá Láti Orílẹ̀-Èdè Míì: Ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (6,300)" }
{ "en": "Invited Branches: Albania, Argentina, Bulgaria, Canada, Central America, Dominican Republic, Ghana, Hungary, Korea, the Netherlands, Peru, Slovenia, Taiwan, Turkey, United States", "eng": null, "yor": "Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tí Àlejò Ti Wá: Albania, Argentina, Bulgaria, Kánádà, Amẹ́ríkà Àárín, Dominican Republic, Gánà, Hungary, Kòríà, Netherlands, Peru, Slovenia, Taiwan, Tọ́kì àti Amẹ́ríkà" }
{ "en": "Local Experience: César López, the resident director of one of the hotels that delegates stayed in, stated: “We have lived through an extraordinary experience.", "eng": null, "yor": "Ìrírí Tó Ṣẹlẹ̀ Lágbègbè Náà: César López, tó jẹ́ olùdarí òtẹ́ẹ̀lì tàwọn àlejò dé sí sọ pé: “Ìrírí àrà ọ̀tọ̀ lèyí jẹ́ fún wa." }
{ "en": "One of the things our staff could not stop talking about was the type of delegates who attended this event—their smiles, their good behavior and their friendliness.", "eng": null, "yor": "Ọ̀kan lára àwọn nǹkan tàwọn òṣìṣẹ́ wa ò lè ṣe kí wọ́n má sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ ni irú ẹni tàwọn àlejò tó wá síbi ayẹyẹ yìí jẹ́, wọ́n ń rẹ́rìn-ín músẹ́, wọ́n nìwà ọmọlúàbí, wọ́n sì ṣeé sún mọ́." }
{ "en": "I think your message [“Love Never Fails”] is one that these delegates had already learned before coming here.", "eng": null, "yor": "Mo gbà pé àwọn àlejò yìí ti kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa àkòrí àpéjọ yín, ìyẹn “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé” kí wọ́n tó wá síbí." }
{ "en": "It was transmitted by everyone who stayed in our hotel.", "eng": null, "yor": "Gbogbo àwọn tó dé sí òtẹ́ẹ̀lì wa ni wọ́n fìfẹ́ hàn sí wa." }
{ "en": "We would love to have your delegates here again.”\"", "eng": null, "yor": "Inú wa máa dùn láti rí àwọn àlejò yín nígbà míì.”\"" }
{ "en": "\"Several rounds of heavy rain caused widespread destruction in eastern Spain during the months of September and October 2019.", "eng": null, "yor": "\"Òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá ba nǹkan jẹ́ gan-an ní apá ìlà oòrùn Sípéènì láàárín oṣù September sí October 2019." }
{ "en": "The most serious of these occurred on October 23 in the province of Tarragona when the Francolí River turned into a raging flood.", "eng": null, "yor": "Èyí tó ṣọṣẹ́ jù ni èyí tó wáyé ní October 23 lágbègbè Tarragona nígbà tí Odò Francoli kún àkúnya." }
{ "en": "Sadly, five people lost their lives in this flood.", "eng": null, "yor": "Ó bani nínú jẹ́ pé èèyàn márùn-ún ló kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Àwọn arákùnrin méjì tí wọ́n ń bọ̀ láti ìpàdé wà lára wọn." }
{ "en": "Among these were two of our brothers who were crossing a bridge on the way home from a congregation meeting when their car was suddenly swept away.", "eng": null, "yor": "Ṣe ni omi ṣàdédé gbé mọ́tò wọn lọ nígbà tí wọ́n fẹ́ kọjá lórí afárá kan." }
{ "en": "The elders are comforting the local congregation as they mourn this tragedy.", "eng": null, "yor": "Àwọn alàgbà ń tu àwọn ará nínú torí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi tó ṣẹlẹ̀ sáwọn arákùnrin wa wọ̀nyìí." }
{ "en": "A member of the Spain Branch Committee has visited the congregation to provide additional shepherding.", "eng": null, "yor": "Arákùnrin kan tó wà lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Sípéènì náà ti ṣèbẹ̀wò sí ìjọ yẹn kó lè túbọ̀ tù wọ́n nínú." }
{ "en": "We pray that Jehovah continues to comfort our brothers and sisters during this trial.—2 Corinthians 1:3, 4.\"", "eng": null, "yor": "Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà máa tu àwọn ará wa nínú lásìkò àdánwò yìí.—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.\"" }
{ "en": "\"Since January 1, 2000, the Swedish government has offered state funding to faith-based organizations under the Support for Religious Communities Act.", "eng": null, "yor": "\"Láti January 1, ọdún 2000, ni ìjọba orílẹ̀-èdè Sweden ti ń lo Òfin Tó Wà fún Ṣíṣe Ìtìlẹ́yìn fún Ẹ̀sìn láti máa fowó ìjọba ṣètìlẹ́yìn fun àwọn ẹlẹ́sìn." }
{ "en": "Funding is only given to a religious group that “contributes to maintaining and strengthening the fundamental values upon which society is based” and “is stable and plays an active role in the community.”", "eng": null, "yor": "Àwọn ẹ̀sìn tí wọ́n ń fi owó tì lẹ́yìn láwọn ẹ̀sìn tó ń “fi ìlànà táá jẹ́ káwọn èèyàn máa gbé ní ìrẹ́pọ̀ kọ́ni, tí kì í jẹ́ kí irú ìlànà bẹ́ẹ̀ pa rẹ́” àti ẹ̀sìn“tó ṣeé gbára lé tó sì ń nípa rere lórí àwọn èèyàn.”" }
{ "en": "Although Sweden approved State grants for most religions, beginning in 2007, it repeatedly refused to give funding to Jehovah’s Witnesses, criticizing our religious beliefs on political neutrality.", "eng": null, "yor": "Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù nínú ẹ̀sìn tó wà ní Sweden nìjọba ń fowó tì lẹ́yìn, láti ọdún 2007 ló ti kọ̀ láti máa fowó ṣètìlẹ́yìn fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, torí pé wọ́n kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú." }
{ "en": "Having no other recourse, our brothers brought the Swedish government to court three separate times.", "eng": null, "yor": "Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìsapá, àwọn ará gbé ìjọba orílẹ̀-èdè Sweden lọ sílé ẹjọ́ nígbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀." }
{ "en": "Each time, the Supreme Administrative Court declared that the government’s decision to deny our organization State grants was unlawful and should be reconsidered.", "eng": null, "yor": "Ìgbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni Ilé Ẹjọ́ Gíga dẹ́bi fún ìjọba orílẹ̀-èdè Sweden pé ohun tí wọ́n ṣe ò bófin mu bí wọ́n ṣe kọ̀ láti fi owó ìjọba ṣètìlẹ́yìn fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àti pé wọ́n gbọ́dọ̀ yí ìpinnu náà pa dà." }
{ "en": "Finally, on October 24, 2019, the Swedish government reversed its decision and concluded that Jehovah’s Witnesses “fulfill all legal requirements” for State grants.", "eng": null, "yor": "Níkẹyìn, ìjọba orílẹ̀-èdè Sweden yí ìpinnu wọn pa dà ní October 24, ọdún 2019, wọ́n sì gbà pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà “kúnjú ìwọ̀n gbogbo ohun tí òfin béèrè fún” láti rí owó ìtìlẹ́yìn ìjọba gbà." }
{ "en": "The same issue was recently raised in Norway, where the government has routinely provided State grants to all religions, including Jehovah’s Witnesses.", "eng": null, "yor": "Irú ẹ̀ tún ṣẹlẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí ní orílẹ̀-èdè Norway, níbi tí ìjọba ti máa ń fún gbogbo ẹ̀sìn, tó fi mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ní owó ìtìlẹ́yìn lóòrèkóòrè." }
{ "en": "However, in recent months the government was asked to reevaluate the basis for providing State grants to Jehovah’s Witnesses because of our political neutrality.", "eng": null, "yor": "Ṣùgbọ́n, ní àwọn oṣù mélòó kan sẹ́yìn, wọ́n ní kí ìjọba tún yẹ̀ ẹ́ wò dáadáa bóyá ó yẹ kí wọ́n máa fi owó ìjọba ṣètìlẹ́yìn fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí pé wọn kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú." }
{ "en": "In response, our brothers provided the Norwegian officials with accurate information concerning our views on political neutrality.", "eng": null, "yor": "Èyí wá mú kí àwọn ará wa fún àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Norway ní ìsọfúnni tó péye nípa ojú tá a fi ń wo ọ̀rọ̀ òṣèlú." }
{ "en": "They also supplied the government with copies of the favorable rulings by the Supreme Administrative Court of Sweden, as well as favorable rulings in similar issues by courts and administrative bodies in Germany and Italy.", "eng": null, "yor": "Wọ́n tún fún ìjọba ní ẹ̀dà àwọn ìwé tó ṣàlàyé bí Ilé Ẹjọ́ Ìṣàkóso Gíga Jù Lọ Lórílẹ̀-Èdè Sweden ṣe dá wa láre àti bí àwọn ilé ẹjọ́ míì ṣe dá wa láre ní orílẹ̀-èdè Jámánì àti Ítálì." }