diacritcs
stringlengths 1
36.7k
| no_diacritcs
stringlengths 1
35.5k
|
---|---|
Bábílónì ńlá sì wá sí ìrántí níwájú Ọlọ́run, láti fi ago ọtí wáìnì ti ìrunú ìbínú rẹ̀ fún un | Babiloni nla si wa si iranti niwaju Olorun, lati fi ago oti waini ti irunu ibinu re fun un |
Olúkúlùkù erekúṣu sì sálọ, a kò sì ri àwọn òkè ńlá mọ́ | Olukuluku erekusu si salo, a ko si ri awon oke nla mo |
Yìnyín ńlá, tí ọkọkan rẹ̀ tó talẹ́ntì ní ìwọ̀n, sì bọ́ lù àwọn ènìyàn láti ọ̀run wà | Yinyin nla, ti okokan re to talenti ni iwon, si bo lu awon eniyan lati orun wa |
Àwọn ènìyàn sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run nítorí ìyọnu yìnyín náà | Awon eniyan si soro odi si Olorun nitori iyonu yinyin naa |
nítorí tí ìyọnu rẹ̀ náà pọ̀ gidigidi | nitori ti iyonu re naa po gidigidi |
Obìnrin Àti Ẹranko | Obinrin Ati Eranko |
Ọ̀kan nínú àwọn ańgẹ́lì méje náà tí ó ní ìgò méje wọ̀n-ọn-nì sì wá, ó sì ba mi sọ̀rọ̀ wí pé, Wá níhìn-ín | Okan ninu awon angeli meje naa ti o ni igo meje won-on-ni si wa, o si ba mi soro wi pe, Wa nihin-in |
èmi ó sì fi ìdájọ́ àgbèrè ńlá ní tí ó jókòó lórí omi púpọ̀ han ọ | emi o si fi idajo agbere nla ni ti o jokoo lori omi pupo han o |
Ẹni tí àwọn ọba ayé bá ṣe àgbèrè, tí a sì fi ọtí wáìnì àgbèrè rẹ̀ pá àwọn tí ń gbé inú ayé | Eni ti awon oba aye ba se agbere, ti a si fi oti waini agbere re pa awon ti n gbe inu aye |
Ó sì gbé mi nínú ẹ̀mí lọ sí ihà | O si gbe mi ninu emi lo si iha |
mo sì rí obìnrin kan ó jòkòó lórí ẹranko aláwọ̀ òdòdó kan tí ó kún fún orúkọ ọ̀rọ̀ òdì, ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá | mo si ri obinrin kan o jokoo lori eranko alawo ododo kan ti o kun fun oruko oro odi, o ni ori meje ati iwo mewaa |
A sì fi aṣọ elése àlùkò àti aṣọ odòdó wọ obìnrin náà, a sì fi wúrà àti òkúta iyebíye àti pérílì ṣe é lọ́sọ̀ọ́, ó ní ago wúrà kan ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó kún fún ìríra àti fún ẹ̀gbin àgbérè rẹ̀ | A si fi aso elese aluko ati aso ododo wo obinrin naa, a si fi wura ati okuta iyebiye ati perili se e losoo, o ni ago wura kan ni owo re, ti o kun fun irira ati fun egbin agbere re |
Àti níwájú rẹ̀ ni orúkọ kan tí a kọ | Ati niwaju re ni oruko kan ti a ko |
OHUN ÌJÌNLẸ̀ BÁBÍLÓNÌ ŃLÁ ÌYÁ ÀWỌN PANṢÁGÀ ÀTI ÀWỌN OHUN ÌRÍRA AYÉ | OHUN IJINLE BABILONI NLA IYA AWON PANSAGA ATI AWON OHUN IRIRA AYE |
Mo sì rí obìnrin náà mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, àti ẹ̀jẹ̀ àwọn ajẹ́rìí ikú Jésù ní àmuyó | Mo si ri obinrin naa mu eje awon eniyan mimo, ati eje awon ajerii iku Jesu ni amuyo |
Nígbà tí mo sì rí i, ẹnu yà mi gidigidi | Nigba ti mo si ri i, enu ya mi gidigidi |
Ańgẹ́lì sì wí fún mi pé, Nítorí kí ni ẹnu ṣe yà ọ́ | Angeli si wi fun mi pe, Nitori ki ni enu se ya o |
Èmi ó sọ ti ìjìnlẹ̀ obìnrin náà fún ọ, àti ti ẹranko tí ó gùn, ti ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá | Emi o so ti ijinle obinrin naa fun o, ati ti eranko ti o gun, ti o ni ori meje ati iwo mewaa |
Ẹranko tí ìwọ ri nì, o ti wà, kò sì sí mọ́ | Eranko ti iwo ri ni, o ti wa, ko si si mo |
Yóò sì ti inú ọ̀gbun gòkè wá, yóò sì lọ sínú ìwé iye láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, nígbà tí wọn ń wò ẹranko tí o ti wà, tí kò sì sí mọ́, tí ó sì ń bọ̀ wá | Yoo si ti inu ogbun goke wa, yoo si lo sinu iwe iye lati ipilese aye, nigba ti won n wo eranko ti o ti wa, ti ko si si mo, ti o si n bo wa |
Níhìn-ín ni ìtumọ̀ tí o ní ọgbọ́n wà | Nihin-in ni itumo ti o ni ogbon wa |
Orí méje ni òkè ńlá méje ni, lórí èyí tí obìnrin náà jókòó | Ori meje ni oke nla meje ni, lori eyi ti obinrin naa jokoo |
Ọba méje sì ní wọn | Oba meje si ni won |
àwọn márùn-ún ṣubú, ọ̀kan ń bẹ, ọ̀kan ìyókù kò sì tí ì dé | awon marun-un subu, okan n be, okan iyoku ko si ti i de |
nígbà tí ó bá sì dé, yóò dúró fún ìgbà kúkurú | nigba ti o ba si de, yoo duro fun igba kukuru |
Ẹranko tí ó sì ti wà, tí kò sì sí, òun náà sì ni ìkẹjọ, ó sì ti inú àwọn méje náà wá, ó sì lọ sí ìparun | Eranko ti o si ti wa, ti ko si si, oun naa si ni ikejo, o si ti inu awon meje naa wa, o si lo si iparun |
Ìwo mẹ́wáà tí ìwọ sì rí ni ọba mẹ́wàá ni wọn, tí wọn kò ì ti gba ìjọba | Iwo mewaa ti iwo si ri ni oba mewaa ni won, ti won ko i ti gba ijoba |
ṣùgbọ́n wọn gba ọlá bí ọba pẹ̀lú ẹranko náà fún wákàtí kan | sugbon won gba ola bi oba pelu eranko naa fun wakati kan |
Àwọn wọ̀nyí ní inú kan, wọ́n ò sì fi agbára àti ọlá wọn fún ẹranko náà | Awon wonyi ni inu kan, won o si fi agbara ati ola won fun eranko naa |
Àwọn wọ̀nyí ni yóò si máa bá Ọ̀dọ́ Àgùntàn jagun, Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà yóò sì ṣẹ́gun wọn | Awon wonyi ni yoo si maa ba Odo Aguntan jagun, Odo Aguntan naa yoo si segun won |
nítorí òun ni Olúwa àwọn Olúwa, àti Ọba àwọn ọba | nitori oun ni Oluwa awon Oluwa, ati Oba awon oba |
Àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú rẹ̀, tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olóòtọ́ yóò sì sẹ́gun pẹ̀lú | Awon ti o si wa pelu re, ti a pe, ti a yan, ti won si je olooto yoo si segun pelu |
Ó sì wí fún mi pé, Àwọn omi tí ìwọ ti rí ni, níbi tí àgbèrè náà jókòó, àwọn ènìyàn àti ẹ̀yà àti orílẹ̀ àti oníruru èdè ni wọ́n | O si wi fun mi pe, Awon omi ti iwo ti ri ni, nibi ti agbere naa jokoo, awon eniyan ati eya ati orile ati oniruru ede ni won |
Àti ìwo mẹ́wàá tí ìwọ rí, àti ẹranko náà, àwọn wọ̀nyí ni yóò koríra àgbèrè náà, wọn ó sì sọ ọ́ di ahoro àti ẹni ìhòòhò, wọn ó sì jẹ ẹran ara rẹ̀, wọn ó sì fi iná sun ún pátapáta | Ati iwo mewaa ti iwo ri, ati eranko naa, awon wonyi ni yoo korira agbere naa, won o si so o di ahoro ati eni ihooho, won o si je eran ara re, won o si fi ina sun un patapata |
Nítorí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn wọn láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, láti ní inú kan, àti láti fi ìjọba wọn fún ẹranko náà, títí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò fi ṣẹ Obìnrin tí ìwọ rí ní ìlú ńlá ni, tí ń jọba lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé | Nitori Olorun ti fi sinu okan won lati mu ife re se, lati ni inu kan, ati lati fi ijoba won fun eranko naa, titi oro Olorun yoo fi se Obinrin ti iwo ri ni ilu nla ni, ti n joba lori awon oba ile aye |
Ìṣubú Bábílónì | Isubu Babiloni |
Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo sì rí ańgẹ́lì mìíràn, ó ń ti ọ̀run sọkalẹ̀ wá ti òun ti agbára ńlá | Leyin nnkan wonyi mo si ri angeli miiran, o n ti orun sokale wa ti oun ti agbara nla |
ilẹ̀ ayé sì ti ipa ògo rẹ̀ mọ́lẹ̀ | ile aye si ti ipa ogo re mole |
Ó sì kígbe ní ohùn rara, wí pé | O si kigbe ni ohun rara, wi pe |
Bábílónì ńlá ṣubú! Ó ṣubú! Ó sì di ibùjókòó àwọn ẹ̀mí ẹ̀ṣù, àti ihò ẹ̀mí àìmọ́ gbogbo, àti ilé ẹyẹ àìmọ́ gbogbo, àti ti ẹyẹ ìríra | Babiloni nla subu! O subu! O si di ibujokoo awon emi esu, ati iho emi aimo gbogbo, ati ile eye aimo gbogbo, ati ti eye irira |
Nítorí nípa ọtí wáìnì ìrunú àgbèrè rẹ̀ ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú | Nitori nipa oti waini irunu agbere re ni gbogbo awon orile-ede subu |
Àwọn ọba ayé sì ti bá a ṣe àgbèrè, àti àwọn oníṣòwò ayé sì di ọlọ́rọ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọ̀bìà rẹ̀ | Awon oba aye si ti ba a se agbere, ati awon onisowo aye si di oloro nipa opolopo wobia re |
Mo sì gbọ́ ohùn mìíràn láti ọ̀run wá, wí pé | Mo si gbo ohun miiran lati orun wa, wi pe |
Ẹ ti inú rẹ̀ jáde, ẹ̀yin ènìyàn mi, kí ẹ ma bàá ṣe alábàápín nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ẹ ma bàá si ṣe gbà nínú ìyọnu rẹ̀ | E ti inu re jade, eyin eniyan mi, ki e ma baa se alabaapin ninu ese re, ki e ma baa si se gba ninu iyonu re |
Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga títí dé ọ̀run, Ọlọ́run sì ti rántí àìsedédé rẹ̀ | Nitori awon ese re ga titi de orun, Olorun si ti ranti aisedede re |
San an fún un, àní bí òun tí san án fún ní, kí ó sì ṣe e ni ìlọ́po méjì fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ Nínú ago náà tí o ti kún, òun ni kí ẹ sì kún fún un ni méjì | San an fun un, ani bi oun ti san an fun ni, ki o si se e ni ilopo meji fun un gege bi ise re Ninu ago naa ti o ti kun, oun ni ki e si kun fun un ni meji |
Níwọ̀n bí o ti yin ara rẹ̀ lógo tó, tí ó sì hùwà wọ̀bìà, níwọ̀n bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ dá a lóró kí ẹ sì fún un ní ìbànújẹ́ | Niwon bi o ti yin ara re logo to, ti o si huwa wobia, niwon bee ni ki e da a loro ki e si fun un ni ibanuje |
nítorí tí ó wí ní ọkàn rẹ̀ pé, Mo jókòó bí ọbabìnrin, èmi kì sì í ṣe opó, èmí kì yóò sì rí ìbànújẹ́ láé | nitori ti o wi ni okan re pe, Mo jokoo bi obabinrin, emi ki si i se opo, emi ki yoo si ri ibanuje lae |
Nítorí náà, ní ìjọ kan ni ìyọnu rẹ̀ yóò dé, ìkú, àti ìbìnújẹ́, àti ìyàn | Nitori naa, ni ijo kan ni iyonu re yoo de, iku, ati ibinuje, ati iyan |
a ó sì fi iná sun ún pátapáta | a o si fi ina sun un patapata |
nítorí pé alágbára ni Olúwa Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀ | nitori pe alagbara ni Oluwa Olorun ti n se idajo re |
Àti àwọn ọba ayé, tí ó ti ń bá a ṣe àgbérè, ti wọn sì ń hùwà wọ̀bìà, yóò sì pohùnréré ẹkún lé e lórí, nígbà tí wọn bá wo èéfín ìjóná rẹ̀ | Ati awon oba aye, ti o ti n ba a se agbere, ti won si n huwa wobia, yoo si pohunrere ekun le e lori, nigba ti won ba wo eefin ijona re |
Wọ́n ó dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn ó máa wí pé | Won o duro ni okere rere nitori iberu ise oro re, won o maa wi pe |
Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà, Bábílónì ìlú alágbára nì! Nítorí ní wákàtí kan ni ìdájọ́ rẹ dé! Àwọn oníṣòwò ayé sì ń sọkún, wọn sì ń sọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, nítorí pé ẹnikẹ́ni kò rà ọjà wọn mọ́ | Egbe! Egbe, ni fun ilu nla naa, Babiloni ilu alagbara ni! Nitori ni wakati kan ni idajo re de! Awon onisowo aye si n sokun, won si n sofo lori re, nitori pe enikeni ko ra oja won mo |
Ọjà wúrà, àti ti fàdákà, àti ti òkúta iyebíye, àti ti pẹ́rílì, àti ti aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, àti tí elése àlùkò, àti ti sẹ́dà, àti ti òdòdó, àti ti gbogbo igi olóòórùn dídùn, àti ti olúkúlùkù ohun èlò tí a fi igi iyebíye ṣe, àti ti idẹ, àti ti irin, àti ti òkúta mabílì | Oja wura, ati ti fadaka, ati ti okuta iyebiye, ati ti perili, ati ti aso ogbo wiwe, ati ti elese aluko, ati ti seda, ati ti ododo, ati ti gbogbo igi olooorun didun, ati ti olukuluku ohun elo ti a fi igi iyebiye se, ati ti ide, ati ti irin, ati ti okuta mabili |
Àti ti Kínamónì, àti ti onírúurú ohun olóòórun dídùn, àti ti ohun ìkunra, àti tí tùràrí, àti ti ọtí wáìnì, àti ti oróro, àti ti ìyẹ̀fun dáradára, àti ti àlìkámà, àti ti ẹran ńlá, àti ti àgùntàn, àti ti ẹ̀sin, àti ti kẹ̀kẹ́, àti ti ẹrú, àti ti ọkàn ènìyàn | Ati ti Kinamoni, ati ti oniruuru ohun olooorun didun, ati ti ohun ikunra, ati ti turari, ati ti oti waini, ati ti ororo, ati ti iyefun daradara, ati ti alikama, ati ti eran nla, ati ti aguntan, ati ti esin, ati ti keke, ati ti eru, ati ti okan eniyan |
Àti àwọn èso tí ọkàn rẹ̀ ń ṣe | Ati awon eso ti okan re n se |
Ìfẹ́kufẹ̀ẹ́ sí, si lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ, àti ohun gbogbo tí ó dùn tí ó sì dára ṣègbé mọ́ ọ lójú, kì yóò sì tún rí wọn mọ́ láé | Ifekufee si, si lo kuro lodo re, ati ohun gbogbo ti o dun ti o si dara segbe mo o loju, ki yoo si tun ri won mo lae |
Àwọn oníṣòwò nǹkan wọ̀nyí, tí a ti ipa rẹ̀ sọ di ọlọ́rọ̀, yóò dúró ní òkèrè rére nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ oró rẹ̀, wọn o máa sọ́kún, wọ́n ó sì máa ṣọ̀fọ̀, Wí pé | Awon onisowo nnkan wonyi, ti a ti ipa re so di oloro, yoo duro ni okere rere nitori iberu ise oro re, won o maa sokun, won o si maa sofo, Wi pe |
Ẹ̀gbẹ́! Ẹ̀gbé, ni fún ìlú ńlá nì, tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, àti ti elése àlùkò, àti ti òdòdó, àti ti a sì fi wúrà ṣe lọ́sọ̀ọ́, pẹ̀lú òkúta iyebíye àti pẹrílì! Nítorí pé ní wákàtí kan ni ọrọ̀ ti o pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ di asán! Àti olúkulùkù ẹni tí ń rin ojú omi lọ sí ìbikíbí, àti àwọn ti ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ àwọn ti ń ṣòwò ojú òkun dúró ní òkèrè réré, Wọ́n sì kígbe nígbà tí wọ́n rí èéfín jíjóná rẹ́, wí pé, Ìlú wo ni o dàbí ìlú yìí | Egbe! Egbe, ni fun ilu nla ni, ti a wo ni aso ogbo wiwe, ati ti elese aluko, ati ti ododo, ati ti a si fi wura se losoo, pelu okuta iyebiye ati perili! Nitori pe ni wakati kan ni oro ti o po to bee di asan! Ati olukuluku eni ti n rin oju omi lo si ibikibi, ati awon ti n sise ninu oko awon ti n sowo oju okun duro ni okere rere, Won si kigbe nigba ti won ri eefin jijona re, wi pe, Ilu wo ni o dabi ilu yii |
Wọ́n sì kú ekuru sí orí wọn, wọ́n kígbe, wọ́n sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀, wí pé | Won si ku ekuru si ori won, won kigbe, won sokun, won si n sofo, wi pe |
Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà, nínú èyí tí a sọ gbogbo àwọn tí ó ni ọkọ̀ ní òkun di ọlọ́rọ̀ nípa ohun iyebíye rẹ̀! Nítorí pé ni wákàtí kan, a sọ ọ́ di ahoro | Egbe! Egbe, ni fun ilu nla naa, ninu eyi ti a so gbogbo awon ti o ni oko ni okun di oloro nipa ohun iyebiye re! Nitori pe ni wakati kan, a so o di ahoro |
Yọ̀ lórí rẹ̀, ìwọ ọ̀run! Àti ẹ̀yin Àpósítélì mímọ́ àti wòlíì! Nítorí Ọlọ́run ti gbẹ̀san yín lára rẹ̀ | Yo lori re, iwo orun! Ati eyin Apositeli mimo ati wolii! Nitori Olorun ti gbesan yin lara re |
Ańgẹ́lì alágbára kan sì gbé òkúta kan sókè, ó dàbí ọlọ ńlá, ó sì jù ú sínú òkun, wí pé | Angeli alagbara kan si gbe okuta kan soke, o dabi olo nla, o si ju u sinu okun, wi pe |
Báyìí ní a ó fi agbára ńlá bíi Bábílónì ìlú ńlá ni wó, a kì yóò sì rí i mọ́ láé | Bayii ni a o fi agbara nla bii Babiloni ilu nla ni wo, a ki yoo si ri i mo lae |
Àti ohùn àwọn aludùùrù, àti ti àwọn olórin, àti ti àwọn afọnrèrè, àti ti àwọn afọ̀npè, ni a kì yóò sì gbọ́ nínú rẹ mọ́ rara | Ati ohun awon aluduuru, ati ti awon olorin, ati ti awon afonrere, ati ti awon afonpe, ni a ki yoo si gbo ninu re mo rara |
àti olukulùkù oníṣọ̀nà ohunkóhun ni a kì yóò sì rí nínú rẹ mọ́ láé | ati olukuluku onisona ohunkohun ni a ki yoo si ri ninu re mo lae |
Àti ìró ọlọ ní a kì yóò sì gbọ́ mọ̀ nínú rẹ láé | Ati iro olo ni a ki yoo si gbo mo ninu re lae |
Àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà ni kì yóò sì tàn nínú rẹ̀ mọ́ láé | Ati imole fitila ni ki yoo si tan ninu re mo lae |
a kì yóò sì gbọ́ ohùn ọkọ ìyàwó àti ti ìyàwó nínú rẹ mọ́ láé | a ki yoo si gbo ohun oko iyawo ati ti iyawo ninu re mo lae |
nítorí pé àwọn oníṣòwò rẹ̀ ni àwọn ẹni ńlá ayé | nitori pe awon onisowo re ni awon eni nla aye |
nítorí pé nípa ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ní a fi tàn orílẹ̀ èdè gbogbo jẹ | nitori pe nipa oso re ni a fi tan orile ede gbogbo je |
Àti nínú rẹ̀ ní a gbé ri ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì, àti ti àwọn ènìyàn mímọ́, àti ti gbogbo àwọn tí a pa lórí ilẹ̀ ayé | Ati ninu re ni a gbe ri eje awon wolii, ati ti awon eniyan mimo, ati ti gbogbo awon ti a pa lori ile aye |
Halelúyà | Haleluya |
Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo gbọ́ ohùn ńlá ní ọ̀run bí ẹni pé tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, ń wí pé | Leyin nnkan wonyi mo gbo ohun nla ni orun bi eni pe ti opolopo eniyan, n wi pe |
Halelúyà! Ti Olúwa Ọlọ́run wa ni ìgbàlà, àti ọlá agbára, nítorí òtítọ́ àti òdodo ni ìdájọ́ rẹ̀ | Haleluya! Ti Oluwa Olorun wa ni igbala, ati ola agbara, nitori otito ati ododo ni idajo re |
Nítorí o ti ṣe ìdájọ́ àgbèrè ńlá a nì, tí o fi àgbèrè rẹ̀ ba ilẹ́ ayé jẹ́, ó sì ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ náà | Nitori o ti se idajo agbere nla a ni, ti o fi agbere re ba ile aye je, o si ti gbesan eje awon iranse re lowo re naa |
Àti lẹ́ẹ̀kejì wọ́n wí pé | Ati leekeji won wi pe |
Halelúyà! Èéfín rẹ̀ sì gòkè lọ láé àti láéláé | Haleluya! Eefin re si goke lo lae ati laelae |
Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún nì, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin nì sì wólẹ, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wí pé | Awon agba merinlelogun ni, ati awon eda alaaye merin ni si wole, won si foribale fun Olorun ti o jokoo lori ite, wi pe |
Àmín, Halelúyà! Ohùn kan sì ti ibi ìtẹ́ náà jáde wá, wí pé | Amin, Haleluya! Ohun kan si ti ibi ite naa jade wa, wi pe |
Ẹ máa yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo, ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àti èwe àti àgbà! Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti bí ìró omi púpọ̀, àti bí ìró àrá ńláńlá, ń wí pé | E maa yin Olorun wa, eyin iranse re gbogbo, eyin ti o beru re, ati ewe ati agba! Mo si gbo bi eni pe ohun opolopo eniyan, ati bi iro omi pupo, ati bi iro ara nlanla, n wi pe |
Halelúyà! Nítorí Olúwa Ọlọ́run wa, Olódùmarè ń jọba | Haleluya! Nitori Oluwa Olorun wa, Olodumare n joba |
Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí inú wa kí ó sì dùn gidigidi, kí a sì fi ògo fún un | E je ki a yo, ki inu wa ki o si dun gidigidi, ki a si fi ogo fun un |
Nítorí pé ìgbéyàwó Ọ̀dọ́-Àgùntàn dé, aya rẹ̀ sì ti múra tán | Nitori pe igbeyawo Odo-Aguntan de, aya re si ti mura tan |
Òun ni a sì fi fún pé kí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́ tí ó funfun gbòò | Oun ni a si fi fun pe ki o wo aso ogbo wiwe ti o funfun gboo |
Ó sì wí fún mi pé, Kọ̀wé rẹ̀, Ìbùkún ni fún àwọn tí a pè sí àsè-alẹ́ ìgbéyàwó ọ̀dọ́-àgùntàn | O si wi fun mi pe, Kowe re, Ibukun ni fun awon ti a pe si ase-ale igbeyawo odo-aguntan |
Ó sì wí fún mi pé | O si wi fun mi pe |
Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run | Iwonyi ni oro otito Olorun |
Mo sì wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ láti foríbalẹ̀ fún un | Mo si wole ni ese re lati foribale fun un |
Ó sì wí fún mi pé, Wò ó, má ṣe bẹ́ẹ̀ | O si wi fun mi pe, Wo o, ma se bee |
ìránṣẹ́ ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n di ẹ̀rí Jésù mú | iranse elegbe re ni emi, ati ti awon arakunrin re ti won di eri Jesu mu |
foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run nítorí pé ẹ̀rí Jésù ni ìsọtẹ́lẹ̀ | foribale fun Olorun nitori pe eri Jesu ni isotele |
Mo sì rí ọ̀run sí sílẹ̀, sì wò ó, ẹsin funfun kan | Mo si ri orun si sile, si wo o, esin funfun kan |
ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni à ń pè ní Olódodo àti Olóòótọ́, nínú òdodo ni ó sì ń ṣe ìdájọ́, tí ó ń jagun | eni ti o jokoo lori re ni a n pe ni Olododo ati Oloooto, ninu ododo ni o si n se idajo, ti o n jagun |
Ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́ iná, àti ní orí rẹ̀ ni adé púpọ̀ wà | Oju re dabi owo ina, ati ni ori re ni ade pupo wa |
ó sì ní orúkọ kan tí a kọ, tí ẹnikẹ́ni kò mọ́, bí kò ṣe òun tìkárarẹ̀ | o si ni oruko kan ti a ko, ti enikeni ko mo, bi ko se oun tikarare |
A sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ tí a tẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ | A si wo o ni aso ti a te bo inu eje |
a sì ń pe orúkọ rẹ̀ ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run | a si n pe oruko re ni Oro Olorun |
Àwọn ogun tí ń bẹ ní ọrùn tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, funfun àti mímọ́, sì ń tọ̀ ọ́ lẹ̀yìn lórí ẹ̀sin funfun | Awon ogun ti n be ni orun ti a wo ni aso ogbo wiwe, funfun ati mimo, si n to o leyin lori esin funfun |