diacritcs
stringlengths
1
36.7k
no_diacritcs
stringlengths
1
35.5k
Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ni ojú wọn
Olorun yoo si nu omije gbogbo nu kuro ni oju won
kì yóò sì sí ikú mọ́, tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ẹkún, bẹ́ẹ̀ ni kí yóò sí ìrora mọ́
ki yoo si si iku mo, tabi ofo, tabi ekun, bee ni ki yoo si irora mo
nítorí pé ohun àtijọ́ tí kọjá lọ
nitori pe ohun atijo ti koja lo
Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà, sì wí pé, Kíyèsi i, mo sọ ohun gbogbo di ọ̀tun! Ó sì wí fún mi pé, Kọ̀wé rẹ̀
Eni ti o jokoo lori ite naa, si wi pe, Kiyesi i, mo so ohun gbogbo di otun! O si wi fun mi pe, Kowe re
Nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí òdodo àti òtítọ́ ni wọ́n
Nitori oro wonyi ododo ati otito ni won
Ó sì wí fún mi pé, Ó parí
O si wi fun mi pe, O pari
Èmi ni Álfà àti Ómégà, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin
Emi ni Alfa ati Omega, ipilese ati opin
Èmi ó sì fi omi fún ẹni tí oúngbẹ ń gbẹ láti orísun omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́
Emi o si fi omi fun eni ti oungbe n gbe lati orisun omi iye lofee
Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun ni yóò jogún nǹkan wọ̀nyí
Eni ti o ba segun ni yoo jogun nnkan wonyi
èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, òun ó sì máa jẹ ọmọ mi
emi o si maa je Olorun re, oun o si maa je omo mi
Ṣùgbọ́n àwọn ojo, àti aláìgbàgbọ́, àti ẹni ìríra, àti apànìyàn, àti àgbèrè, àti oṣó, àti abọ̀rìṣà, àti àwọn èké gbogbo, ni yóò ni ipa tiwọn nínú adágún tí ń fí iná àti súfúrù jó
Sugbon awon ojo, ati alaigbagbo, ati eni irira, ati apaniyan, ati agbere, ati oso, ati aborisa, ati awon eke gbogbo, ni yoo ni ipa tiwon ninu adagun ti n fi ina ati sufuru jo
èyí tí i ṣe ikú kéjì
eyi ti i se iku keji
Ọ̀kan nínú àwọn ańgẹ́lì méje, tí wọ́n ni ìgò méje, tí ó kún fún ìyọnu méje ìkẹyìn sì wá, ó sì ba mi sọ̀rọ̀ wí pé, Wá níhìnín, èmi ó fi ìyàwó, aya Ọ̀dọ́-Àgùntàn hàn ọ́
Okan ninu awon angeli meje, ti won ni igo meje, ti o kun fun iyonu meje ikeyin si wa, o si ba mi soro wi pe, Wa nihinin, emi o fi iyawo, aya Odo-Aguntan han o
Ó sì mu mi lọ nínú Ẹ̀mí si òkè ńlá kan tí o sì ga, ó sì fí ìlú náà hàn mi, Jerúsálémù mímọ́, tí ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Tí ó ní ògo Ọlọ́run
O si mu mi lo ninu Emi si oke nla kan ti o si ga, o si fi ilu naa han mi, Jerusalemu mimo, ti n ti orun sokale wa lati odo Olorun, Ti o ni ogo Olorun
ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ sì dàbí òkúta iyebíye gidigidi, àní bí òkúta Jasípérì, ó mọ́ bí Kírísítálì
imole re si dabi okuta iyebiye gidigidi, ani bi okuta Jasiperi, o mo bi Kirisitali
Ó sì ní odi ńlá àti gíga, ó sì ni ẹnu-bodè méjìlá, àti ní àwọn ẹnu-bodè náà áńgẹ́lì méjìlá àti orúkọ tí a kọ sára wọn tí i ṣe orúkọ àwọn ẹ̀yà méjìlá tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì
O si ni odi nla ati giga, o si ni enu-bode mejila, ati ni awon enu-bode naa angeli mejila ati oruko ti a ko sara won ti i se oruko awon eya mejila ti awon omo Isireli
Ní ìhá ìlà-oòrùn ẹnu-bodè mẹ́ta
Ni iha ila-oorun enu-bode meta
ní ìhà àríwá ẹnu-bodè mẹ́ta
ni iha ariwa enu-bode meta
ní ìhà gúsù ẹnu-bodè mẹ́ta
ni iha gusu enu-bode meta
àti ní ìhà ìwọ̀-òòrùn ẹnu-bodè mẹ́ta
ati ni iha iwo-oorun enu-bode meta
Odi ìlú náà sì ni ìpìlẹ̀ méjìlá, àti lórí wọn orúkọ àwọn Àpósítélì méjìlá tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn
Odi ilu naa si ni ipile mejila, ati lori won oruko awon Apositeli mejila ti Odo-Aguntan
Ẹni tí o sì ń bá mi sọ̀rọ̀ ní ọ̀pá-ìwọ̀n wúrà kan láti fi wọn ìlú náà àti àwọn ẹnu-bodè rẹ̀, àti odi rẹ̀
Eni ti o si n ba mi soro ni opa-iwon wura kan lati fi won ilu naa ati awon enu-bode re, ati odi re
Ìlú náà sì wà ní ibú mẹ́rin lọ́gbọọgba, gígùn rẹ̀ àti ìbú rẹ̀ sì dọ́gba
Ilu naa si wa ni ibu merin logboogba, gigun re ati ibu re si dogba
ó sì fi ọ̀pá-ìwọ̀n náà wọn ìlú náà wò, ó jẹ ẹgbàafà ibùsọ̀ gígùn rẹ̀ àti ìbú rẹ̀, àti gíga rẹ̀ sì dọ́gba
o si fi opa-iwon naa won ilu naa wo, o je egbaafa ibuso gigun re ati ibu re, ati giga re si dogba
Ó sì wọn odi rẹ̀ ó jẹ̀ ogóje ìgbọ̀nwọ́ lé mẹ́rin , gẹ́gẹ́ bí òṣùwọ̀n ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni tí ańgẹ́lì náà
O si won odi re o je ogoje igbonwo le merin , gege bi osuwon eniyan, bee ni ti angeli naa
A sì fi Jásípérì mọ odi ìlú náà
A si fi Jasiperi mo odi ilu naa
Ìlú náà sì jẹ́ kìkì wúrà, ó dàbí dígí tí o mọ́ kedere
Ilu naa si je kiki wura, o dabi digi ti o mo kedere
A fi onírúuru òkúta iyebíye ṣe ìpìlẹ̀ ògiri ìlú náà lọ́ṣọ̀ọ́
A fi oniruuru okuta iyebiye se ipile ogiri ilu naa losoo
Ìpìlẹ̀ ìkínní jẹ́ jásípérì
Ipile ikinni je jasiperi
ìkejì, sáfírù
ikeji, safiru
ìkẹta, kalíkedónì ìkẹrin, emeralídì
iketa, kalikedoni ikerin, emeralidi
Ikarun, sadonikísì
Ikarun, sadonikisi
ìkẹfà, kanelíánì
ikefa, kaneliani
ìkeje, kírisolítì
ikeje, kirisoliti
ìkẹjọ bérílì
ikejo berili
ìkẹsan, tọ́pásì
ikesan, topasi
ìkẹwàá, kírísopírasù
ikewaa, kirisopirasu
ìkọkànlá, jakinítì
ikokanla, jakiniti
ìkejìlá, ámétísítì
ikejila, ametisiti
Ẹnu-bodè méjèèjìlá jẹ́ pẹ́rílì méjìlá
Enu-bode mejeejila je perili mejila
olúkúlùkù ẹnu-bodè jẹ́ pérílì kan
olukuluku enu-bode je perili kan
ọ̀nà ìgboro ìlú náà sì jẹ́ kìkì wúrà, ó dàbí dígí dídán
ona igboro ilu naa si je kiki wura, o dabi digi didan
Èmi kò sì ri tẹḿpílì nínú rẹ̀
Emi ko si ri tempili ninu re
nítorí pé Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè ni téḿpílì rẹ̀, àti Ọ̀dọ́-Àgùntàn
nitori pe Oluwa Olorun Olodumare ni tempili re, ati Odo-Aguntan
Ìlú náà kò sì ní oòrùn, tàbí òṣùpá, láti máa tan ìmọ́lẹ̀ sí i
Ilu naa ko si ni oorun, tabi osupa, lati maa tan imole si i
nítorí pé ògo Ọlọ́run ni ó ń tàn ìmọ́lẹ̀ sí i, Ọ̀dọ́-Àgùntàn sì ni fìtílà rẹ̀
nitori pe ogo Olorun ni o n tan imole si i, Odo-Aguntan si ni fitila re
Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa rìn nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀
Awon orile-ede yoo si maa rin nipa imole re
àwọn ọba ayé sì ń mú ògo wọn wá sínú rẹ̀
awon oba aye si n mu ogo won wa sinu re
A kì yóò sì ṣé àwọn ẹnu-bodè rẹ̀ rárá ní ọ̀sán
A ki yoo si se awon enu-bode re rara ni osan
nítorí ki yóò si òru níbẹ̀
nitori ki yoo si oru nibe
Wọ́n ó sì máa mú ògo àti ọlá àwọn orílẹ̀-èdè wá sínú rẹ̀
Won o si maa mu ogo ati ola awon orile-ede wa sinu re
Ohun aláìmọ́ kan ki yóò sì wọ inú rẹ̀ rárá, tàbí ohun tí ń ṣiṣẹ́ ìríra àti èké
Ohun alaimo kan ki yoo si wo inu re rara, tabi ohun ti n sise irira ati eke
bí kò ṣe àwọn tí a kọ sínú ìwé ìyè Ọ̀dọ́-Àgùntàn
bi ko se awon ti a ko sinu iwe iye Odo-Aguntan
Omi Ìyè
Omi Iye
Ó sì fi odò omi ìyè kan hàn mi, tí ó mọ́ bí Kírísítalì, tí ń tí ibi ìtẹ́ Ọlọ́run àti tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn jáde wá, Ní àárin ìgboro rẹ̀, àti níhà ìkínní kéjì odò náà, ni igi ìyè gbé wà, tí o máa ń so oníruurú èso méjìlá, a sì máa so èso rẹ̀ ni oṣooṣù ewé igi náà sí wà fún mímú àwọn orílẹ̀-èdè láradà
O si fi odo omi iye kan han mi, ti o mo bi Kirisitali, ti n ti ibi ite Olorun ati ti Odo-Aguntan jade wa, Ni aarin igboro re, ati niha ikinni keji odo naa, ni igi iye gbe wa, ti o maa n so oniruuru eso mejila, a si maa so eso re ni osoosu ewe igi naa si wa fun mimu awon orile-ede larada
Ègún kì yóò sì sí mọ
Egun ki yoo si si mo
ìtẹ́ Ọlọ́run àti tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn ni yóò sì máa wà níbẹ̀
ite Olorun ati ti Odo-Aguntan ni yoo si maa wa nibe
àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò sì máa sìn ín
awon iranse re yoo si maa sin in
Wọ́n ó si máa rí ojú rẹ̀
Won o si maa ri oju re
orúkọ rẹ̀ yóò si máa wà ni ìwájú orí wọn
oruko re yoo si maa wa ni iwaju ori won
Òru kì yóò sí mọ́
Oru ki yoo si mo
wọn kò sì ní wa ìmọ́lè fìtílà, tàbí ìmọ́lẹ̀ oòrùn
won ko si ni wa imole fitila, tabi imole oorun
nítorí pé Olúwa Ọlọ́run ni yóò tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn
nitori pe Oluwa Olorun ni yoo tan imole fun won
wọn ó sì máa jọba láé àti láéláé
won o si maa joba lae ati laelae
Ó sì wí fún mi pé, Òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyí
O si wi fun mi pe, Ododo ati otito ni oro wonyi
Olúwa Ọlọ́run ẹ̀mí àwọn wòlíì ni ó sì ran ańgẹ́lì rẹ̀ láti fi ohun tí ó ní láti ṣẹlẹ̀ láìpẹ yìí hàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀
Oluwa Olorun emi awon wolii ni o si ran angeli re lati fi ohun ti o ni lati sele laipe yii han awon iranse re
Kíyèsí i, èmi ń bọ̀ kánkán! Ìbùkún ni fún ẹni tí ń pa ọ̀rọ̀ ìṣọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí mọ́! Èmi, Jòhánù, ni ẹni tí ó gbọ́ tí ó sì ri nǹkan wọ̀nyí
Kiyesi i, emi n bo kankan! Ibukun ni fun eni ti n pa oro isotele inu iwe yii mo! Emi, Johanu, ni eni ti o gbo ti o si ri nnkan wonyi
Nígbà tí mo sì gbọ́ tí mo sì rí, mo wólẹ̀ láti foríbalẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ ańgẹ́lì náà, tí o fí nǹkan wọ̀nyí hàn mi, Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, Wó ò, má ṣe bẹ́ẹ̀
Nigba ti mo si gbo ti mo si ri, mo wole lati foribale niwaju ese angeli naa, ti o fi nnkan wonyi han mi, Nigba naa ni o wi fun mi pe, Wo o, ma se bee
ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ wòlíì, àti ti àwọn tí ń pa ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí mọ́
iranse elegbe re ni emi, ati ti awon arakunrin re wolii, ati ti awon ti n pa oro inu iwe yii mo
foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run! Ó sì wí fún mi pé, Má ṣe fi èdìdì di ọ̀rọ̀ ìṣọtẹ́lẹ̀ tí inú ìwé yìí
foribale fun Olorun! O si wi fun mi pe, Ma se fi edidi di oro isotele ti inu iwe yii
nítorí ìgbà kù sí dẹ̀dẹ̀
nitori igba ku si dede
Ẹni tí ń ṣe aláìṣòótọ́, kí ó máa ṣe aláìṣòótọ́ nì ṣó
Eni ti n se alaisooto, ki o maa se alaisooto ni so
Àti ẹni tí ń ṣe ẹlẹ́gbin, kí ó máa ṣe ẹ̀gbin nìṣó
Ati eni ti n se elegbin, ki o maa se egbin niso
Àti ẹni tí ń ṣe olòdodo, kí ó máa ṣe òdodo nìṣó
Ati eni ti n se olododo, ki o maa se ododo niso
Àti ẹni tí ń ṣe mímọ́, kí ó máa ṣe mímọ́ nìṣó
Ati eni ti n se mimo, ki o maa se mimo niso
Kíyèsí i, èmi ń bọ̀ kánkán
Kiyesi i, emi n bo kankan
èrè mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi, láti sán fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ yóò tí rí
ere mi si n be pelu mi, lati san fun olukuluku gege bi ise re yoo ti ri
Èmi ni Álífà àti Òmégà, ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin
Emi ni Alifa ati Omega, eni isaaju ati eni ikeyin, ipilese ati opin
Ìbùkún ni fún àwọn ti ń fọ aṣọ wọn, kí wọ́n lè ni àǹfààní láti wá sí ibi igi ìyè náà, àti kí wọ́n lè gbà àwọn ẹnu-bodè wọ inú ìlú náà
Ibukun ni fun awon ti n fo aso won, ki won le ni anfaani lati wa si ibi igi iye naa, ati ki won le gba awon enu-bode wo inu ilu naa
Nítorí ni òde ni àwọn ajá gbé wà, àti àwọn oṣó, àti àwọn àgbérè, àti àwọn apànìyàn, àti àwọn abọ̀rìṣà, àti olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ràn èké tí ó sì ń hùwà èké
Nitori ni ode ni awon aja gbe wa, ati awon oso, ati awon agbere, ati awon apaniyan, ati awon aborisa, ati olukuluku eni ti o feran eke ti o si n huwa eke
Èmi, Jésù, ni ó rán ańgẹ́lì mi láti jẹ̀rìí nǹkan wọ̀nyí fún yin ní tí àwọn ìjọ
Emi, Jesu, ni o ran angeli mi lati jerii nnkan wonyi fun yin ni ti awon ijo
Èmi ni gbòngbò àti irú-ọmọ Dáfídì, àti ìràwọ̀ òwúrọ̀ tí ń tàn
Emi ni gbongbo ati iru-omo Dafidi, ati irawo owuro ti n tan
Ẹ̀mí àti ìyàwó wí pé, Máa bọ! Àti ẹni tí ó ń gbọ́ kí ó wí pé, Máa bọ̀! Àti ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ kí ó wá, àti ẹni tí o bá sì fẹ́, kí ó gba omi ìyè náà lọ́fẹ̀ẹ́
Emi ati iyawo wi pe, Maa bo! Ati eni ti o n gbo ki o wi pe, Maa bo! Ati eni ti oungbe n gbe ki o wa, ati eni ti o ba si fe, ki o gba omi iye naa lofee
Èmi kìlọ̀ fún olúkúlùkú ẹni tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí pé, bí ẹnikẹ́ni ba fi kún wọn, Ọlọ́run yóò fí kún àwọn ìyọnu tí a kọ sínú ìwé yìí fún un
Emi kilo fun olukuluku eni to n gbo oro isotele inu iwe yii pe, bi enikeni ba fi kun won, Olorun yoo fi kun awon iyonu ti a ko sinu iwe yii fun un
Bí ẹnikẹ́ni bá sì mú kúrò nínú ọ̀rọ̀ ìwé ìsọtẹ́lẹ̀ yìí, Ọlọ́run yóò sì mú ipa tirẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè, àti kúró nínu ìlú mímọ́ náà, àti kúrò nínú àwọn ohun tí a kọ sínú ìwé yìí
Bi enikeni ba si mu kuro ninu oro iwe isotele yii, Olorun yoo si mu ipa tire kuro ninu iwe iye, ati kuro ninu ilu mimo naa, ati kuro ninu awon ohun ti a ko sinu iwe yii
Ẹni tí ó jẹ̀rìí nǹkan wọ̀nyí wí pé, Nítòótọ́ èmi ń bọ̀ kánkán
Eni ti o jerii nnkan wonyi wi pe, Nitooto emi n bo kankan
Àmín, Má a bọ̀, Jésù Olúwa! Oore-ọ̀fẹ́ Jésù Olúwa kí ó wà pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn-mímọ́
Amin, Ma a bo, Jesu Oluwa! Oore-ofe Jesu Oluwa ki o wa pelu gbogbo awon eniyan-mimo
Àmín
Amin
Sí Ìjọ Ní Sádísì
Si Ijo Ni Sadisi
Àti sí Ańgẹ́lì ìjọ ni Sádísì kọ̀wé
Ati si Angeli ijo ni Sadisi kowe
Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó ni Ẹ̀mí méje Ọlọ́run, àti ìràwọ̀ méje wí pé
Oro wonyi ni eni ti o ni Emi meje Olorun, ati irawo meje wi pe
Èmi mọ̀ iṣẹ́ rẹ̀, àti pé ìwọ ni orúkọ pé ìwọ ń bẹ láàyè, ṣùgbọ́n ìwọ ti kú
Emi mo ise re, ati pe iwo ni oruko pe iwo n be laaye, sugbon iwo ti ku
Jí, kí o sì fi ẹsẹ̀ ohun tí ó kù múlẹ̀, tí ó ṣetán láti kú
Ji, ki o si fi ese ohun ti o ku mule, ti o setan lati ku
Nítorí èmi kò rí iṣẹ́ rẹ ni pípé níwájú Ọlọ́run
Nitori emi ko ri ise re ni pipe niwaju Olorun
Nítorí náà rántí bí ìwọ ti gbà, àti bí ìwọ ti gbọ́, kí o sì pa á mọ́, kí o sì ronúpìwàdà
Nitori naa ranti bi iwo ti gba, ati bi iwo ti gbo, ki o si pa a mo, ki o si ronupiwada
Ǹjẹ́, bí ìwọ kò ba ṣọ́ra, èmi yóò dé sí ọ bí olè, ìwọ kì yóò sì mọ́ wákàtí tí èmi yóò dé sí ọ
Nje, bi iwo ko ba sora, emi yoo de si o bi ole, iwo ki yoo si mo wakati ti emi yoo de si o
Ìwọ ní orúkọ díẹ̀ ní Sádísì, tí kò fi aṣọ wọn yí èérí
Iwo ni oruko die ni Sadisi, ti ko fi aso won yi eeri
wọn yóò sì máa ba mi rìn ní aṣọ funfun nítorí wọ́n yẹ
won yoo si maa ba mi rin ni aso funfun nitori won ye
Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun, òun náà ni a ó fi aṣọ funfun wọ̀
Eni ti o ba segun, oun naa ni a o fi aso funfun wo
èmi kì yóò pa orúkọ rẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè, ṣùgbọ́n èmi yóò jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀ níwájú Baba mi, àti níwájú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀
emi ki yoo pa oruko re kuro ninu iwe iye, sugbon emi yoo jewo oruko re niwaju Baba mi, ati niwaju awon angeli re