diacritcs
stringlengths
1
36.7k
no_diacritcs
stringlengths
1
35.5k
Àti láti ẹnu rẹ̀ ni idà mímú ti ń jáde lọ, kí ó lè máa fi ṣá àwọn orílẹ̀-èdè
Ati lati enu re ni ida mimu ti n jade lo, ki o le maa fi sa awon orile-ede
Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn
Oun o si maa fi opa irin se akoso won
ó sì ń tẹ ìfúntí àti ìbínú Ọlọ́run Olódùmarè
o si n te ifunti ati ibinu Olorun Olodumare
Ó sì ní lára aṣọ rẹ̀ àti ni ìtàn rẹ̀ orúkọ kan tí a kọ
O si ni lara aso re ati ni itan re oruko kan ti a ko
ỌBA ÀWỌN ỌBA ÀTI Olúwa ÀWỌN Olúwa Mo sì rí ańgẹ́lì kan dúró nínú òòrùn
OBA AWON OBA ATI Oluwa AWON Oluwa Mo si ri angeli kan duro ninu oorun
ó sì fi ohùn rara kígbe, ó ń wí fún gbogbo àwọn ẹyẹ tí ń fò ní agbede-méjì ọ̀run pé
o si fi ohun rara kigbe, o n wi fun gbogbo awon eye ti n fo ni agbede-meji orun pe
Ẹ wá ẹ sì kó ara yín jọ pọ̀ sí àsè-ńlá Ọlọ́run
E wa e si ko ara yin jo po si ase-nla Olorun
Kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ ẹran-ara àwọn ọba, àti ẹran-ara àwọn olórí ogun àti ẹran-ara àwọn ènìyàn alágbára, àti ẹran àwọn ẹsin, àti ti àwọn tí ó jókòó lórí wọn, àti ẹran-ara ènìyàn gbogbo, àti ti òmìnira, àti ti ẹrù, àti ti èwe àti ti àgbà
Ki eyin ki o le je eran-ara awon oba, ati eran-ara awon olori ogun ati eran-ara awon eniyan alagbara, ati eran awon esin, ati ti awon ti o jokoo lori won, ati eran-ara eniyan gbogbo, ati ti ominira, ati ti eru, ati ti ewe ati ti agba
Mo sì rí ẹranko náà àti àwọn ọba ayé, àti àwọn ogun wọn tí a gbájọ láti bá ẹni tí ó jókòó lórí ẹsin náà àti ogun rẹ̀ jagun
Mo si ri eranko naa ati awon oba aye, ati awon ogun won ti a gbajo lati ba eni ti o jokoo lori esin naa ati ogun re jagun
A sì mú ẹranko náà, àti wòlíì èké nì pẹ̀lú rẹ̀, tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ ìyanu níwájú rẹ̀, èyí tí ó fi ń tan àwọn tí ó gba àmì ẹranko náà àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún àwòrán rẹ̀ jẹ
A si mu eranko naa, ati wolii eke ni pelu re, ti o ti n se ise iyanu niwaju re, eyi ti o fi n tan awon ti o gba ami eranko naa ati awon ti n foribale fun aworan re je
Àwọn méjèèje yìí ni a sọ láàyè sínú adágún iná tí ń fi súfúrù jó
Awon mejeeje yii ni a so laaye sinu adagun ina ti n fi sufuru jo
Àwọn ìyókù ni a sì fi idà ẹni tí ó jókòó lórí ẹsin náà pa, àní idà tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde
Awon iyoku ni a si fi ida eni ti o jokoo lori esin naa pa, ani ida ti o ti enu re jade
Gbogbo àwọn ẹyẹ sì ti ipa ẹran ara wọn yó
Gbogbo awon eye si ti ipa eran ara won yo
Sí Ìjọ Éfésù
Si Ijo Efesu
Sí Ańgẹ́lì Ní Éfésù kọ̀wé
Si Angeli Ni Efesu kowe
Nǹkan wọ̀nyí ní ẹni tí ó mú ìràwọ̀ méje náà ni ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ẹni tí ń rìn ní àárin ọ̀pá wúrà fìtílà méje
Nnkan wonyi ni eni ti o mu irawo meje naa ni owo otun re, eni ti n rin ni aarin opa wura fitila meje
Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti làálàá rẹ, àti ìfaradà rẹ, àti bí ara rẹ kò ti gba àwọn ẹni búburú
Emi mo ise re, ati laalaa re, ati ifarada re, ati bi ara re ko ti gba awon eni buburu
àti bí ìwọ sì ti dán àwọn tí ń pe ara wọn ní àpósítélì, tí wọ́n kì í sì í se bẹ́ẹ̀ wo, tí ìwọ sì rí pé èké ni wọ́n
ati bi iwo si ti dan awon ti n pe ara won ni apositeli, ti won ki i si i se bee wo, ti iwo si ri pe eke ni won
Tí ìwọ sì faradà ìyà, àti nítorí orúkọ mi tí ó sì rọjú, tí àárẹ̀ kò sì mú ọ
Ti iwo si farada iya, ati nitori oruko mi ti o si roju, ti aare ko si mu o
Ṣíbẹ̀ èyí ni mo rí wí sí ọ, pé, ìwọ ti fi ìfẹ́ ìṣáájú rẹsílẹ̀
Sibe eyi ni mo ri wi si o, pe, iwo ti fi ife isaaju resile
Rántí ibi tí ìwọ ti gbé subú! Ronúpìwàdà, kí ó sì ṣe iṣẹ́ ìsáájú
Ranti ibi ti iwo ti gbe subu! Ronupiwada, ki o si se ise isaaju
bí kò sì ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó sì tọ̀ ọ́ wá, èmi ó sì sí ọ̀pá fìtílà rẹ̀ kúrò ní ipò rẹ̀, bí kò ṣe bí ìwọ bá ronúpìwàdà
bi ko si se bee, emi o si to o wa, emi o si si opa fitila re kuro ni ipo re, bi ko se bi iwo ba ronupiwada
Ṣùgbọ́n èyí ni ìwọ ní, pé ìwọ kórìíra ìṣe àwọn Nikoláétánì, èyí tí èmi pẹ̀lú sì kórìíra
Sugbon eyi ni iwo ni, pe iwo koriira ise awon Nikolaetani, eyi ti emi pelu si koriira
Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mi ń sọ fún àwọn ìjọ
Eni ti o ba ni eti ki o gbo ohun ti Emi n so fun awon ijo
Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi èso igi ìye nì fún jẹ, tí ń bẹ láàrin Párádísè Ọlọ́run
Eni ti o ba segun ni emi yoo fi eso igi iye ni fun je, ti n be laarin Paradise Olorun
Àti sí Ańgẹ́lì Ìjọ ní Símírínà Kọ̀wé
Ati si Angeli Ijo ni Simirina Kowe
Nǹkan wọ̀nyí ni ẹni tí í ṣe ẹni-ìṣáájú àti ẹni-ìkẹyìn wí, ẹni tí ó ti kú, tí ó sì tún yè
Nnkan wonyi ni eni ti i se eni-isaaju ati eni-ikeyin wi, eni ti o ti ku, ti o si tun ye
Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti ìpọ́njú, àti àìní rẹ—ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ ni ọ́ èmi sì mọ ọ̀rọ̀-òdì tí àwọn tí ń wí pé Júù ni àwọn tìkárawọn, tí wọn kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ sínágọ́gù ti Sátánì
Emi mo ise re, ati iponju, ati aini re—sugbon oloro ni o emi si mo oro-odi ti awon ti n wi pe Juu ni awon tikarawon, ti won ki si i se bee, sugbon ti won je sinagogu ti Satani
Máṣe bẹ̀rù ohunkóhun tí ìwọ ń bọ wá jìyà rẹ̀
Mase beru ohunkohun ti iwo n bo wa jiya re
Kíyèsí i, èṣù yóò gbé nínú yín jù sínú túúbú, kí a lè dán yin wò
Kiyesi i, esu yoo gbe ninu yin ju sinu tuubu, ki a le dan yin wo
ẹ̀yin ó sì ní ìpọ́njú ní ọjọ́ mẹ́wàá
eyin o si ni iponju ni ojo mewaa
ìwọ sa se olóòtọ́ dé ojú ikú, èmi ó sì fi adé ìyè fún ọ Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ
iwo sa se olooto de oju iku, emi o si fi ade iye fun o Eni ti o ba ni eti ki o gbo ohun ti Emi n so fun awon ijo
Ẹni tí ó bá sẹ́gun kì yóò farapa nínú ikú kejì
Eni ti o ba segun ki yoo farapa ninu iku keji
Àti sì Ańgẹ́lì ìjọ ni Págámọ́sì Kọ̀wé
Ati si Angeli ijo ni Pagamosi Kowe
Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó ní ídà mímú olójú méjì, Èmí mọ̀ ibi tí ìwọ ń gbé, àní ibi tí ìtẹ́ Sàtánì wà
Oro wonyi ni eni ti o ni ida mimu oloju meji, Emi mo ibi ti iwo n gbe, ani ibi ti ite Satani wa
Síbẹ̀ ìwọ di orúkọ mi mú ṣinṣin
Sibe iwo di oruko mi mu sinsin
Ìwọ kò sì sẹ́ ìgbàgbọ́ nínú mi, pàápàá jùlọ ni ọjọ́ Áńtípà ẹlẹ́rì mi, olóòótọ́ ènìyàn, ẹni tí wọn pa láàrin yín, níbi tí Sàtánì ń gbé
Iwo ko si se igbagbo ninu mi, paapaa julo ni ojo Antipa eleri mi, oloooto eniyan, eni ti won pa laarin yin, nibi ti Satani n gbe
Ṣùgbọ́n mo ni nǹkan díẹ̀ wí sí ọ
Sugbon mo ni nnkan die wi si o
nítorí tí ìwọ ní àwọn kan tí o di ẹ̀kọ́ Báláámù mú nibẹ̀, ẹni tí ó kọ́ Bálákì láti mú ohun ìkọ̀sẹ̀ wá ṣíwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, láti máa jẹ ohun tí a pa rúbọ sí òrìṣà, àti láti máa ṣe àgbèrè
nitori ti iwo ni awon kan ti o di eko Balaamu mu nibe, eni ti o ko Balaki lati mu ohun ikose wa siwaju awon omo Isireli, lati maa je ohun ti a pa rubo si orisa, ati lati maa se agbere
Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì ní àwọn tí ó gbá ẹ̀kọ́ àwọn Nikoláétanì pẹ̀lú, ohun tí mo kórìíra
Bee ni iwo si ni awon ti o gba eko awon Nikolaetani pelu, ohun ti mo koriira
Nítorí náàonúpìwàdà
Nitori naaonupiwada
bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó tọ̀ ọ́ wá nísinsinyìí, èmí o sì fi idà ẹnu mi bá wọn jà
bi ko se bee, emi o to o wa nisinsinyii, emi o si fi ida enu mi ba won ja
Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ
Eni ti o ba leti, ki o gbo ohun ti Emi n so fun awon ijo
Ẹni tí o bá ṣẹ́gun ni èmi o fi mánà tí ó pamọ́ fún, èmi ó sì fún un ni òkúta funfun kan, àti sára òkúta náà ni a kọ orúkọ tuntun kan, tí ẹnìkan kò mọ̀ bí kò ṣe ẹni tí ó gbà á
Eni ti o ba segun ni emi o fi mana ti o pamo fun, emi o si fun un ni okuta funfun kan, ati sara okuta naa ni a ko oruko tuntun kan, ti enikan ko mo bi ko se eni ti o gba a
Àti sí Ańgẹ́lì ìjọ ní Tíátírà kọ̀wé
Ati si Angeli ijo ni Tiatira kowe
Nǹkan wọ̀nyí ni Ọmọ Ọlọ́run wí, ẹni tí ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́ iná, tí ẹṣẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára
Nnkan wonyi ni Omo Olorun wi, eni ti oju re dabi owo ina, ti ese re si dabi ide daradara
Èmi mọ̀ iṣẹ́, ìfẹ́, àti ìgbàgbọ́ àti ìsìn àti sùúrù rẹ̀
Emi mo ise, ife, ati igbagbo ati isin ati suuru re
àti pé iṣẹ́ rẹ̀ ìkẹyìn ju tí iṣàájú lọ
ati pe ise re ikeyin ju ti isaaju lo
Ṣùgbọ́n èyí ni mo rí wí sì ọ
Sugbon eyi ni mo ri wi si o
Nítorí tí ìwọ fi àyè sílẹ̀ fún obìnrin Jésébẹ́lì tí ó ń pe ara rẹ̀ ní wòlíì
Nitori ti iwo fi aye sile fun obinrin Jesebeli ti o n pe ara re ni wolii
Nípaṣ ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sì ń kọ́ àwọn ìránṣẹ́ mi, ó sì ń tàn wọ́n láti máa ṣe àgbèrè, àti láti máa jẹ ohun tí a pa rúbọ sì òrìṣà
Nipas eko re, o si n ko awon iranse mi, o si n tan won lati maa se agbere, ati lati maa je ohun ti a pa rubo si orisa
Èmi fi àkókò fún un, láti ronúpìwàdà
Emi fi akoko fun un, lati ronupiwada
ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ ronúpìwàdà àgbèrè rẹ̀
sugbon oun ko fe ronupiwada agbere re
Nítorí náà, èmi ó gbé e sọ sí orí àkéte, àti àwọn tí ń bá a ṣe panṣágà ni èmi ó fi sínú ìpọ́njú ńlá, bí kò ṣe bí wọ́n bá ronúpìwàdà iṣẹ́ wọn
Nitori naa, emi o gbe e so si ori akete, ati awon ti n ba a se pansaga ni emi o fi sinu iponju nla, bi ko se bi won ba ronupiwada ise won
Èmi o pa àwọn ọmọ rẹ̀
Emi o pa awon omo re
gbogbo ìjọ ni yóò sì mọ̀ pé, èmi ni ẹni tí ń wádìí inú àti ọkàn
gbogbo ijo ni yoo si mo pe, emi ni eni ti n wadii inu ati okan
èmi ó sì fi fún olúkúlùkù yín gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀
emi o si fi fun olukuluku yin gege bi ise re
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni mò ń sọ fún, ẹ̀yin ìyókù tí ń bẹ ní Tíátírà, gbogbo ẹ̀yin tí kò ni ẹ̀kọ́ yìí, ti kò ì tí ì mọ̀ ohun tí wọn pe ni ohun ìjìnlẹ̀ Sàtánì, èmi kò di ẹrù mìíràn rù yín
Sugbon eyin ni mo n so fun, eyin iyoku ti n be ni Tiatira, gbogbo eyin ti ko ni eko yii, ti ko i ti i mo ohun ti won pe ni ohun ijinle Satani, emi ko di eru miiran ru yin
Ṣùgbọ́n èyí tí ẹ̀yin ní, ẹ di i mú ṣinṣin títí èmi ó fi dé
Sugbon eyi ti eyin ni, e di i mu sinsin titi emi o fi de
Ẹni tí ó bá sì ṣẹ́gun, àti tí o sì ṣe ìfẹ́ mi títí dé òpin, èmi o fún un láṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè
Eni ti o ba si segun, ati ti o si se ife mi titi de opin, emi o fun un lase lori awon orile-ede
Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn
Oun o si maa fi opa irin se akoso won
gẹ́gẹ́ bí a ti ń fọ́ ohun-èlò amọ̀kòkò ni a ó fọ́ wọn túútúú, gẹ́gẹ́ bí èmi pẹ̀lú tí gbà àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Baba mi
gege bi a ti n fo ohun-elo amokoko ni a o fo won tuutuu, gege bi emi pelu ti gba ase lati odo Baba mi
Èmi yóò sì fi ìràwọ̀ òwúrọ̀ fún un
Emi yoo si fi irawo owuro fun un
Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ
Eni ti o ba leti, ki o gbo ohun ti Emi n so fun awon ijo
Ìjọba Ẹgbẹ̀rún Ọdún
Ijoba Egberun Odun
Mo sì rí ańgẹ́lì kan ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, ti òun ti kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbún, àti àwọ̀n ńlá kan ní ọwọ́ rẹ̀
Mo si ri angeli kan n ti orun sokale wa, ti oun ti kokoro ogbun, ati awon nla kan ni owo re
O sì di Dírágónì náà mú, ejò àtijọ́ nì, tí í ṣe èṣù, àti Sàtánì, ó sì dè é ní ẹgbẹ̀rún ọdún
O si di Diragoni naa mu, ejo atijo ni, ti i se esu, ati Satani, o si de e ni egberun odun
Ó sì gbé e sọ sínú ọ̀gbún náà, ó sì tì í, ó sì fi èdìdì dì í lórí rẹ̀, kí ó má ba à tan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ mọ́ títí ẹgbẹ̀rún ọdún náà yóò fi pé
O si gbe e so sinu ogbun naa, o si ti i, o si fi edidi di i lori re, ki o ma ba a tan awon orile-ede je mo titi egberun odun naa yoo fi pe
Lẹ́yìn èyí, a kò le sàì tú u sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀
Leyin eyi, a ko le sai tu u sile fun igba die
Mo sì rí àwọn ìtẹ́, wọ́n sì jókòó lórí wọn, a sì fi ìdájọ́ fún wọn
Mo si ri awon ite, won si jokoo lori won, a si fi idajo fun won
mo sì rí ọkàn àwọn tí a ti bẹ́ lórí nítorí ẹ̀rí Jésù, àti nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti àwọn tí kò sì foríbalẹ̀ fún ẹranko náà, àti fún àwòrán rẹ̀, tàbí tí kò sì gbà àmì rẹ̀ ní iwájú wọn àti ní ọwọ́ wọn
mo si ri okan awon ti a ti be lori nitori eri Jesu, ati nitori oro Olorun, ati awon ti ko si foribale fun eranko naa, ati fun aworan re, tabi ti ko si gba ami re ni iwaju won ati ni owo won
wọ́n sì wà láàyè, wọ́n sì jọba pẹ̀lú Kírísítì ní ẹgbẹ̀rún ọdún
won si wa laaye, won si joba pelu Kirisiti ni egberun odun
Àwọn òkú ìyókù kò wà láàyè mọ́ títí ẹgbẹ̀rún ọdún náà yóò fi pé
Awon oku iyoku ko wa laaye mo titi egberun odun naa yoo fi pe
Èyí ni àjíǹde èkíní
Eyi ni ajinde ekini
Olúkúlùkù àti mímọ́ ni ẹni tí ó ní ipa nínú àjíǹde èkíní náà
Olukuluku ati mimo ni eni ti o ni ipa ninu ajinde ekini naa
lórí àwọn wọ̀nyí ikú eekejì kò ní agbára, ṣùgbọ́n wọn ó jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kírísítì, wọn ó sì máa jọba pẹ̀lú rẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún ọdún
lori awon wonyi iku eekeji ko ni agbara, sugbon won o je alufaa Olorun ati ti Kirisiti, won o si maa joba pelu re ni egberun odun
Nígbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún náà bá sì pé, a ó tú Sàtánì sílẹ̀ kúrò nínú túbú rẹ̀
Nigba ti egberun odun naa ba si pe, a o tu Satani sile kuro ninu tubu re
Yóò sì jáde lọ láti máa tan àwọn orílẹ̀-èdè tí ń bẹ ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé jẹ, Gógù àti Mágógú, láti gbá wọn jọ sí ogun
Yoo si jade lo lati maa tan awon orile-ede ti n be ni igun mereerin aye je, Gogu ati Magogu, lati gba won jo si ogun
àwọn tí iyè wọn dàbí iyanrìn òkun
awon ti iye won dabi iyanrin okun
Wọ́n sì gòkè lọ la ibú ayé já, wọ́n sì yí ibùdó àwọn ènìyàn mímọ́ ká àti ìlú àyànfẹ́ náà
Won si goke lo la ibu aye ja, won si yi ibudo awon eniyan mimo ka ati ilu ayanfe naa
iná sì ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, ó sì jó wọn run
ina si ti orun sokale wa, o si jo won run
A sì wọ́ Èsù tí ó tàn wọ́n jẹ lọ sínú adágún iná àti súfúrù, níbi tí ẹranko àti wòlíì èké nì gbé wà, a ó sì máa dá wọn lóró tọ̀sán tòru láé àti láéláé
A si wo Esu ti o tan won je lo sinu adagun ina ati sufuru, nibi ti eranko ati wolii eke ni gbe wa, a o si maa da won loro tosan toru lae ati laelae
Mo sì rí ìtẹ́ funfun ńlá kan, àti ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀, níwájú ẹni tí ayé àti ọ̀run fò lọ
Mo si ri ite funfun nla kan, ati eni ti o jokoo lori re, niwaju eni ti aye ati orun fo lo
a kò sì rí àyè fún wọn mọ́
a ko si ri aye fun won mo
Mo sì rí àwọn òkú, àti èwe àti àgbà, wọn dúró níwájú ìtẹ́
Mo si ri awon oku, ati ewe ati agba, won duro niwaju ite
a sì sí àwọn ìwé sílẹ̀
a si si awon iwe sile
a sì ṣí àwọn ìwé mìíràn kan sílẹ̀ tí í ṣe ìwé ìyè
a si si awon iwe miiran kan sile ti i se iwe iye
a sì ṣe ìdájọ́ fún àwọn òkú láti inú ohun tí a ti kọ sínú àwọn ìwé náà, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn
a si se idajo fun awon oku lati inu ohun ti a ti ko sinu awon iwe naa, gege bi ise won
Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́
Okun si jowo awon oku ti n be ninu re lowo
àti òkú àti ipò-òkú sì jọ̀wọ́ òkú tí ó wà nínú wọn pẹ̀lú
ati oku ati ipo-oku si jowo oku ti o wa ninu won pelu
a sì ṣe ìdájọ́ wọn, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn
a si se idajo won, olukuluku gege bi ise won
Àti ikú àti ipò-òkú ni a sì sọ sínú adágún iná
Ati iku ati ipo-oku ni a si so sinu adagun ina
Èyí ni ikú kejì
Eyi ni iku keji
Bí a bá sì rí ẹnikẹ́ni tí a kò kọ orúkọ rẹ̀ sínú ìwé ìyè, a ó sọ ọ́ sínú adágún iná
Bi a ba si ri enikeni ti a ko ko oruko re sinu iwe iye, a o so o sinu adagun ina
Jerúsálémù Tuntun
Jerusalemu Tuntun
Mo sì rí ọ̀run titun kan àti ayé titun kan
Mo si ri orun titun kan ati aye titun kan
nítorí pé ọ̀run ti ìṣáajú àti ayé ìṣáajú ti kọjá lọ
nitori pe orun ti isaaju ati aye isaaju ti koja lo
òkun kò sì sí mọ́
okun ko si si mo
Mo sì rí ìlú mímọ́, Jerúsálémù titun ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tí a ti múra sílẹ̀ bí ìyàwó tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀
Mo si ri ilu mimo, Jerusalemu titun n ti orun sokale wa lati odo Olorun, ti a ti mura sile bi iyawo ti a se losoo fun oko re
Mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti orí ìtẹ́ náà wá, ń wí pé, Kíyèsi i, àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn, òun ó sì máa bá wọn gbé, wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀, àti Ọlọ́run tìkararẹ̀ yóò wà pẹ̀lú wọn, yóò sì máa jẹ́ Ọlọ́run wọn
Mo si gbo ohun nla kan lati ori ite naa wa, n wi pe, Kiyesi i, ago Olorun wa pelu awon eniyan, oun o si maa ba won gbe, won o si maa je eniyan re, ati Olorun tikarare yoo wa pelu won, yoo si maa je Olorun won