diacritcs
stringlengths
1
36.7k
no_diacritcs
stringlengths
1
35.5k
Nǹkan tí ó mú kí ẹ ṣe pàtàkì ni pé, ẹ jẹ́ ẹ̀ka igi Ọlọ́run yìí
Nnkan ti o mu ki e se pataki ni pe, e je eka igi Olorun yii
Ẹ rántí pé, ẹ̀ka igi lásán ni yín, ẹ kì í ṣe gbòngbò
E ranti pe, eka igi lasan ni yin, e ki i se gbongbo
Ó ṣe é ṣe fún un yín kí ẹ wí pé, Níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ti ké ẹ̀ka igi wọ̀nyí kúrò, tí ó sì fi wá sí ipò wọn, a sàn jù wọ́n lọ Ẹ kíyèsára! Ẹ sì rántí pé, a ké àwọn ẹ̀ka wọ̀n ọn nì tí í ṣe Júù kúrò nítorí pé wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́
O se e se fun un yin ki e wi pe, Niwon igba ti Olorun ti ke eka igi wonyi kuro, ti o si fi wa si ipo won, a san ju won lo E kiyesara! E si ranti pe, a ke awon eka won on ni ti i se Juu kuro nitori pe won ko gba Olorun gbo
Àti pé, ẹ̀yin sì wà níbẹ̀ nítorí pé ẹ̀yin gbàgbọ́
Ati pe, eyin si wa nibe nitori pe eyin gbagbo
Ẹ má ṣe gbéraga, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀, kí ẹ sì dúpẹ́, kí ẹ sì, máa sọ́ra gidigidi
E ma se gberaga, e re ara yin sile, ki e si dupe, ki e si, maa sora gidigidi
Nítorí pé bí Ọlọ́run kò bá dá àwọn ẹ̀ka igi tí ó fi síbẹ̀ lákọ́kọ́ sí, ó dájú wí pé, kò ní dá ẹ̀yin náà sí
Nitori pe bi Olorun ko ba da awon eka igi ti o fi sibe lakoko si, o daju wi pe, ko ni da eyin naa si
Nítorí náà wo ore àti ìkáànú Ọlọ́run lórí àwọn tí ó subú, ìkàánú
Nitori naa wo ore ati ikaanu Olorun lori awon ti o subu, ikaanu
ṣùgbọ́n lórí ìwọ, ọrẹ, bi ìwọ bá dúró nínú ọrẹ rẹ̀
sugbon lori iwo, ore, bi iwo ba duro ninu ore re
kí a má bá ké ìwọ náà kúrò
ki a ma ba ke iwo naa kuro
Àti àwọn pẹ̀lú, bí wọn kò bá jókòó sínú àìgbàgbọ́, a ó lọ́ wọn sínú rẹ̀, nítorí Ọlọ́run le tún wọn lọ́ sínú rẹ̀
Ati awon pelu, bi won ko ba jokoo sinu aigbagbo, a o lo won sinu re, nitori Olorun le tun won lo sinu re
Nítorí bí a bá ti ke ìwọ kúrò lára igi ólífì ìgbẹ́ nípa ẹ̀dá rẹ̀, tí a sì gbé ìwọ lé orí igi ólífì rere lòdì sí ti ẹ̀dá
Nitori bi a ba ti ke iwo kuro lara igi olifi igbe nipa eda re, ti a si gbe iwo le ori igi olifi rere lodi si ti eda
mélòómélòó ni a ó lọ́ àwọn wọ̀nyí, tí í ṣe ẹ̀ka-ìyẹ́ka sára igi ólífì wọn
meloomeloo ni a o lo awon wonyi, ti i se eka-iyeka sara igi olifi won
Ará, èmi kò sá fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó wà ní òpè ní ti ohun ìjìnlẹ̀ yìí, kí ẹ̀yin má baá ṣe ọlọgbọ́n ní ojú ara yín, pé ìfọ́jú bá Ísírẹ̀lì ní apákan, títí kíkún àwọn aláìkọlà yóò fi dé
Ara, emi ko sa fe ki eyin ki o wa ni ope ni ti ohun ijinle yii, ki eyin ma baa se ologbon ni oju ara yin, pe ifoju ba Isireli ni apakan, titi kikun awon alaikola yoo fi de
Bẹ́ẹ̀ ni a ó sì gba gbogbo Ísírẹ́lì là, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé
Bee ni a o si gba gbogbo Isireli la, gege bi a ti ko o pe
Ní Síónì ni Olúgbàlà yóò ti jáde wá, yóò sì yìí àìwà-bí-Ọlọ́run kúrò lọ́dọ̀ Jákọ́bù
Ni Sioni ni Olugbala yoo ti jade wa, yoo si yii aiwa-bi-Olorun kuro lodo Jakobu
Èyí sì ni májẹ̀mú mi fún wọn
Eyi si ni majemu mi fun won
Nígbà tí èmi yóò mú ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò
Nigba ti emi yoo mu ese won kuro
Nípa ti ìyìn rere, ọ̀ta ni wọ́n nítorí yín
Nipa ti iyin rere, ota ni won nitori yin
bí ó sì ṣe ti ìyànfẹ́ ni, olùfẹ́ ni wọ́n nítorí ti àwọn baba
bi o si se ti iyanfe ni, olufe ni won nitori ti awon baba
Nítorí àìlábámọ̀ li ẹ̀bùn àti ìpè Ọlọ́run
Nitori ailabamo li ebun ati ipe Olorun
Nítorí gẹ̀gẹ̀ bí ẹyin kò ti gba Ọlọ́run gbọ́ rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí tí ẹ̀yin rí ànú gbà nípa àìgbàgbọ́ wọn
Nitori gege bi eyin ko ti gba Olorun gbo ri, sugbon nisinsin yii ti eyin ri anu gba nipa aigbagbo won
Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn wọ̀nyí tí ó ṣe àìgbọ́ràn nísinsin yìí, kí àwọn pẹ̀lú bá le rí àánú gbà nípa àánú tí a fi hàn yín
Gege bee ni awon wonyi ti o se aigboran nisinsin yii, ki awon pelu ba le ri aanu gba nipa aanu ti a fi han yin
Nítorí Ọlọ́run sé gbogbo wọn mọ́ pọ̀ sínú àìgbàgbọ́, kí ó le ṣàánú fún gbogbo wọn
Nitori Olorun se gbogbo won mo po sinu aigbagbo, ki o le saanu fun gbogbo won
A! Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run! Àwámáridí ìdájọ́ rẹ̀ ti rí, ọ̀nà rẹ̀ sì jù àwárí lọ! Nítorí tali ó mọ inú Olúwa
A! Ijinle oro ati ogbon ati imo Olorun! Awamaridi idajo re ti ri, ona re si ju awari lo! Nitori tali o mo inu Oluwa
Tàbí tani íṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀
Tabi tani ise igbimo re
Tàbí tani ó kọ́ fifún un, tí a kò sì san padà fún u
Tabi tani o ko fifun un, ti a ko si san pada fun u
Nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti nípa rẹ̀, àti fún un ni ohun gbogbo
Nitori lati odo re, ati nipa re, ati fun un ni ohun gbogbo
ẹni tí ògo wà fún láéláé! Àmín
eni ti ogo wa fun laelae! Amin
Èkọ́ Nípa Ìfẹ́
Eko Nipa Ife
Nítorí náà mo fi ìyọ́nú Ọlọ́run bẹ̀ yín ará, kí ẹ̀yin kí ó fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè mímọ́, ìtẹ́wọ́gbà, èyí ni iṣẹ́-ìsìn yín tí ó tọ̀nà
Nitori naa mo fi iyonu Olorun be yin ara, ki eyin ki o fi ara yin fun Olorun ni ebo aaye mimo, itewogba, eyi ni ise-isin yin ti o tona
Kí ẹ má sì da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yìí
Ki e ma si da ara yin po mo aye yii
ṣùgbọ́n kí ẹ paradà láti di titun ní ìrò-inú yín, kí ẹ̀yin kí ó lè rí ìdí ìfẹ́ Ọlọ́run, tí ó dára, tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ti ó sì pé
sugbon ki e parada lati di titun ni iro-inu yin, ki eyin ki o le ri idi ife Olorun, ti o dara, ti o si se itewogba, ti o si pe
Ǹjẹ́ mo wí fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wà nínú yín, nípa oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún mi, kí ó má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ
Nje mo wi fun olukuluku eniyan ti o wa ninu yin, nipa oore-ofe ti a fi fun mi, ki o ma se ro ara re ju bi o ti ye ni riro lo
ṣùgbọ́n kí ó le rò níwọ̀ntún-wọ̀nsì, bí Ọlọ́run ti fi ìwọ̀n ìgbàgbọ́ fún olukúkùlù
sugbon ki o le ro niwontun-wonsi, bi Olorun ti fi iwon igbagbo fun olukukulu
Nítorí gẹ́gẹ́ bí àwa ti ní ẹ̀yà pípọ̀ nínú ara kan, tí gbogbo ẹ̀yà kò sì ní iṣẹ́ kan náà
Nitori gege bi awa ti ni eya pipo ninu ara kan, ti gbogbo eya ko si ni ise kan naa
Bẹ́ẹ̀ ni àwa, tí a jẹ́ pípọ̀, a jẹ́ ara kan nínú Kírísítì, àti olukúlùkú ẹ̀yà ara ọmọnìkejì rẹ̀
Bee ni awa, ti a je pipo, a je ara kan ninu Kirisiti, ati olukuluku eya ara omonikeji re
Ǹjẹ́ bí àwa sì ti ń rí ọ̀tọ̀-ọ̀tọ̀ ẹ̀bùn gbà gẹ́gẹ́ bí ore-ọ̀fẹ́ tí a fifún wa, bí ó ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, kí a máa sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ìgbàgbọ́
Nje bi awa si ti n ri oto-oto ebun gba gege bi ore-ofe ti a fifun wa, bi o se isotele ni, ki a maa sotele gege bi iwon igbagbo
Tàbí iṣẹ́-ìránṣẹ́, kí a kọjúsí iṣẹ́-ìránṣẹ́ wa tàbí ẹni tí ń kọ́ni, kí ó kọjú sí kíkọ́
Tabi ise-iranse, ki a kojusi ise-iranse wa tabi eni ti n koni, ki o koju si kiko
Tàbí ẹni tí ó ń gbani níyànjú, sí ìgbìyànjú
Tabi eni ti o n gbani niyanju, si igbiyanju
ẹni tí ń fi fún ni kí ó máa fi inú kan ṣe é
eni ti n fi fun ni ki o maa fi inu kan se e
ẹni tí ń ṣe olórí, kí ó máa ṣe é ní ojú méjèèjì
eni ti n se olori, ki o maa se e ni oju mejeeji
ẹni tí ń sàánú, kí ó máa fi inú dídùn ṣe é
eni ti n saanu, ki o maa fi inu didun se e
Kí ìfẹ́ kí ó wà ní àìṣẹ̀tàn
Ki ife ki o wa ni aisetan
Ẹ máa takéte sí ohun tí í ṣe búrubú
E maa takete si ohun ti i se burubu
ẹ faramọ́ ohun tí í ṣe rere
e faramo ohun ti i se rere
Níti ìfẹ́ ará, ẹ máa fi ìyọ́nú fẹ́ràn ara yín
Niti ife ara, e maa fi iyonu feran ara yin
níti ọlá, ẹ máa fi ẹnìkéjì yín ṣájú
niti ola, e maa fi enikeji yin saju
Níti iṣẹ́ ṣíṣe, ẹ má ṣe ọ̀lẹ
Niti ise sise, e ma se ole
ẹ máa ní ìgbóná ọkàn
e maa ni igbona okan
ẹ máa sìn Olúwa
e maa sin Oluwa
Ẹ máa yọ̀ ni ìrètí
E maa yo ni ireti
ẹ máa mú sùúrù nínú ìpọ́njú
e maa mu suuru ninu iponju
ẹ máa dúró gangan nínú àdúrà
e maa duro gangan ninu adura
Ẹ máa pèsè fún àìní àwọn ènìyàn mímọ́
E maa pese fun aini awon eniyan mimo
ẹ fi ara yín fún àlejò íṣe
e fi ara yin fun alejo ise
Ẹ máa súre fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín
E maa sure fun awon ti n se inunibini si yin
ẹ máa súre, ẹ má sì ṣépè
e maa sure, e ma si sepe
Àwọn tí ń yọ̀, ẹ má bá wọn yọ̀, àwọn tí ń sọkùn, ẹ má bá wọn sọkún
Awon ti n yo, e ma ba won yo, awon ti n sokun, e ma ba won sokun
Ẹ má wà ní inú kan náà sí ara yín
E ma wa ni inu kan naa si ara yin
Ẹ má ṣe ronú ohun gíga, ṣùgbọ́n ẹ má tẹ̀lé onírẹ̀lẹ̀
E ma se ronu ohun giga, sugbon e ma tele onirele
Ẹ má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara yín
E ma se je ologbon ni oju ara yin
Ẹ má ṣe fi búburú san búburú fún ẹnikẹ́ni
E ma se fi buburu san buburu fun enikeni
Ẹ má pèsè ohun tí ó tọ́ níwájú gbogbo ènìyàn
E ma pese ohun ti o to niwaju gbogbo eniyan
Bí ó le ṣe, bí ó ti wà ní ipa ti yín, ẹ má wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn
Bi o le se, bi o ti wa ni ipa ti yin, e ma wa ni alaafia pelu gbogbo eniyan
Olùfẹ́, ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ṣùgbọ́n ẹ fi ààyè sílẹ̀ fún ìbínú
Olufe, e ma se gbesan ara yin, sugbon e fi aaye sile fun ibinu
nítorí a ti kọ ọ́ pé, Olúwa wí pé, Èmi ni ẹ̀san, èmi ó gbẹ̀san
nitori a ti ko o pe, Oluwa wi pe, Emi ni esan, emi o gbesan
Ṣùgbọ́n bí ebi bá ń pa ọ̀ta rẹ
Sugbon bi ebi ba n pa ota re
Fún un ní oúnjẹ
Fun un ni ounje
bí oùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu
bi oungbe ba n gbe e, fun un ni omi mu
ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ ó kó ẹ̀yín iná lé e ní orí
ni sise bee iwo o ko eyin ina le e ni ori
Má ṣe jẹ́ kí búburú ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n fi rere ṣẹ́gun búburú
Ma se je ki buburu segun re, sugbon fi rere segun buburu
Síṣe Ìgbọ́ran Sí Àwọn Aláṣẹ
Sise Igboran Si Awon Alase
Kí olúkúlùkù ọkàn kí ó foríbalẹ̀ fún àwọn aláṣẹ tí ó wà ní ipò gíga
Ki olukuluku okan ki o foribale fun awon alase ti o wa ni ipo giga
Nítorí kò sí àṣẹ kan, bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá
Nitori ko si ase kan, bi ko se lati odo Olorun wa
àwọn aláṣẹ tí ó sì wà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run li a ti lànà rẹ̀ wá
awon alase ti o si wa, lati odo Olorun li a ti lana re wa
Nítorí ẹni tí ó bá tàpá sí àṣẹ, ó tàpá sí ìlànà Ọlọ́run
Nitori eni ti o ba tapa si ase, o tapa si ilana Olorun
àwọn ẹni tí ó ba sì ń tàpá, yóò gba ẹ̀bi fún ara wọn
awon eni ti o ba si n tapa, yoo gba ebi fun ara won
Nítorí pé adájọ́ kò wá láti dẹ́rù ba àwọn ẹni tí ń se rere
Nitori pe adajo ko wa lati deru ba awon eni ti n se rere
Ṣùgbọ́n àwọn tó ń ṣe búburú yóò máa bẹ̀rù rẹ̀ nígbà gbogbo
Sugbon awon to n se buburu yoo maa beru re nigba gbogbo
Nítorí ìdí èyí, pa òfin mọ́ ìwọ kò sì ní gbé nínú ìbẹ̀rù
Nitori idi eyi, pa ofin mo iwo ko si ni gbe ninu iberu
Nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni láti ṣe ọ́ ní rere
Nitori iranse Olorun ni lati se o ni rere
Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣé nǹkan búburú, máa bẹ̀rù, nítorí kò ru idà náà lásán
Sugbon bi o ba se nnkan buburu, maa beru, nitori ko ru ida naa lasan
Nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run nííse, ìránṣẹ́ ìbínú sí ara àwọn ẹni tí ń ṣe búburú
Nitori iranse Olorun niise, iranse ibinu si ara awon eni ti n se buburu
Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì láti tẹríba fún àwọn alásẹ, kì í ṣe nítorí ìjìyà tó lé wáyé nìkan, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀rí-ọkàn pẹ̀lú
Nitori naa, o se pataki lati teriba fun awon alase, ki i se nitori ijiya to le waye nikan, sugbon nitori eri-okan pelu
San owó orí rẹ pẹ̀lú nítorí ìdí méjì pàtàkì tí a ti sọ wọ̀nyí
San owo ori re pelu nitori idi meji pataki ti a ti so wonyi
Nítorí pé ó se dandan kí a san owó oṣù fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba
Nitori pe o se dandan ki a san owo osu fun awon osise ijoba
Èyí yóò mú kí wọn tẹ̀ṣíwájú nínú iṣẹ́ Ọlọ́run náà
Eyi yoo mu ki won tesiwaju ninu ise Olorun naa
Wọn yóò sì máa tọ́jú yín
Won yoo si maa toju yin
Ẹ san ohun tí ó tọ́ fún ẹni gbogbo
E san ohun ti o to fun eni gbogbo
owó-orí fún ẹni tí owó-orí tọ́ sí
owo-ori fun eni ti owo-ori to si
owó-bodè fún ẹni tí owó-bodè tọ́ sí
owo-bode fun eni ti owo-bode to si
ẹ̀rù fún ẹni tí ẹ̀rù ń ṣe tirẹ̀
eru fun eni ti eru n se tire
ọlá fún ẹni tí ọlá ń ṣe tirẹ̀ Ẹ má ṣe jẹ ẹnikẹ́ní nígbésè, yàtọ̀ fún gbésè ìfẹ́ láti fẹ́ ọmọ ẹnìkejì ẹni, nítorí ẹni tí ó bá fẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀, ó kó òfin já
ola fun eni ti ola n se tire E ma se je enikeni nigbese, yato fun gbese ife lati fe omo enikeji eni, nitori eni ti o ba fe omonikeji re, o ko ofin ja
Àwọn òfin, Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panságà, Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè, Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké, bí òfin mìíràn bá sì wà, ni a papọ̀ sọ̀kan nínú òfin kan yìí
Awon ofin, Iwo ko gbodo se pansaga, Iwo ko gbodo paniyan, Iwo ko gbodo jale, Iwo ko gbodo jerii eke, bi ofin miiran ba si wa, ni a papo sokan ninu ofin kan yii
Fẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀
Fe omonikeji re gege bi ara re
Ìfẹ́ kì í ṣe ohun búburú sí ọmọnìkejì rẹ̀
Ife ki i se ohun buburu si omonikeji re
nítorí náà ìfẹ́ ni àkójá òfin
nitori naa ife ni akoja ofin
Àti èyí, bí ẹ ti mọ àkókò pé, ó ti tó wákàtí nísinsìnyí fún yín láti jí lójú orun
Ati eyi, bi e ti mo akoko pe, o ti to wakati nisinsinyi fun yin lati ji loju orun
nítorí nísinsìn yìí ni ìgbàlà wa súnmọ́ etílé ju ìgbà tí àwa ti gbàgbọ́ lọ
nitori nisinsin yii ni igbala wa sunmo etile ju igba ti awa ti gbagbo lo
Òru bù kọjá tan, ilẹ̀ sì fẹ́rẹ mọ́
Oru bu koja tan, ile si fere mo