diacritcs
stringlengths
1
36.7k
no_diacritcs
stringlengths
1
35.5k
nítorí náà ẹ jẹ́ kí a bọ́ ara iṣẹ́ òkùnkùn sílẹ̀, kí a sì gbé ìhámọ́ra ìmọ́lẹ̀ wọ̀
nitori naa e je ki a bo ara ise okunkun sile, ki a si gbe ihamora imole wo
Jẹ́ kí a má rin ìrìn títọ́, bí ní ọ̀sán
Je ki a ma rin irin tito, bi ni osan
kì í ṣe ní ìréde òru àti ní ìmọ̀tipara, kì í ṣe ni ìwà èérí àti wọ̀bìà, kì íṣe ní ìjà àti ìlara
ki i se ni irede oru ati ni imotipara, ki i se ni iwa eeri ati wobia, ki ise ni ija ati ilara
Ṣùgbọ́n ẹ gbé Jésù Kírísítì Olúwa wọ̀, kí ẹ má sì pèsè fún ara, láti ma mú ìfẹ́kúfẹ rẹ̀ ṣẹ
Sugbon e gbe Jesu Kirisiti Oluwa wo, ki e ma si pese fun ara, lati ma mu ifekufe re se
Aláìlera Àti Alágbára
Alailera Ati Alagbara
Ẹ gba ẹni tí ó bá ṣe àìlera ní ìgbàgbọ́ mọ́ra, kí ẹ má se tọpinpin ìṣiyèméjì rẹ̀
E gba eni ti o ba se ailera ni igbagbo mora, ki e ma se topinpin isiyemeji re
Ìgbàgbọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan fi ààyè gbà á láti jẹ ohun gbogbo
Igbagbo enikookan fi aaye gba a lati je ohun gbogbo
sùgbọ́n ẹlòmíràn tí ó sì jẹ́ aláìlera ní ìgbàgbọ́ ń jẹ ewébẹ̀ nìkan
sugbon elomiran ti o si je alailera ni igbagbo n je ewebe nikan
Kí ẹni tí ń jẹ ohun gbogbo má ṣe kẹ́gàn ẹni tí kò jẹ
Ki eni ti n je ohun gbogbo ma se kegan eni ti ko je
kí ẹni tí kò sì jẹ ohun gbogbo kí ó má ṣe dá ẹni tí ń jẹ lẹ́bi
ki eni ti ko si je ohun gbogbo ki o ma se da eni ti n je lebi
nítorí Ọlọ́run ti gbà á
nitori Olorun ti gba a
Ta ni ìwọ láti dá ọmọ ọ̀dọ̀ tí kì í se tìrẹ lẹ́jọ́
Ta ni iwo lati da omo odo ti ki i se tire lejo
Lójú olúwa tirẹ̀ ni òun ni dúró, tàbí subú
Loju oluwa tire ni oun ni duro, tabi subu
Òun yóò sì dúró nítorí Ọlọ́run ní agbára láti mú kí òun dúró
Oun yoo si duro nitori Olorun ni agbara lati mu ki oun duro
Àwọn kan bu ọlá fún ju ọ̀kan lọ, ẹlòmíràn bu ọlá fún ọjọ́ gbogbo bákan náà
Awon kan bu ola fun ju okan lo, elomiran bu ola fun ojo gbogbo bakan naa
Kí olúkúlùkù kí ó dá ara rẹ̀ lójú nípa èyí tí ó tọ́ lọ́kàn ara rẹ̀
Ki olukuluku ki o da ara re loju nipa eyi ti o to lokan ara re
Ẹni tí ó bá ya ọjọ́ kan sí ọ̀tọ̀, ó ń yà á sọ́tọ̀ fún Olúwa
Eni ti o ba ya ojo kan si oto, o n ya a soto fun Oluwa
Ẹni tí ó ń jẹ ẹran, ó ń jẹ ẹran fún Olúwa, nítorí pé òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run
Eni ti o n je eran, o n je eran fun Oluwa, nitori pe oun naa dupe lowo Olorun
ẹni tí kò bá sì jẹ ẹran, kò jẹ ẹran fún Olúwa, òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run
eni ti ko ba si je eran, ko je eran fun Oluwa, oun naa dupe lowo Olorun
Nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láàyè fún ara rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó kú fún ara rẹ̀
Nitori ko si enikan ti o wa laaye fun ara re, bee ni ko si eni ti o ku fun ara re
Bí a bá wà láààyè, a wà láààyè fún Olúwa
Bi a ba wa laaaye, a wa laaaye fun Oluwa
bí a bá sì kú, a kú fún Olúwa
bi a ba si ku, a ku fun Oluwa
Nítorí náà, yálà ní kíkú tàbí ní yíyè, ti Olúwa ni àwá jẹ́
Nitori naa, yala ni kiku tabi ni yiye, ti Oluwa ni awa je
Nítorí ìdí èyí náà ni Kírísítì fi kú, tí ó sì tún yè, kí ó bá le jẹ́ Olúwa òkú àti alààye
Nitori idi eyi naa ni Kirisiti fi ku, ti o si tun ye, ki o ba le je Oluwa oku ati alaaye
Èése nígbà náà tí ìwọ fi ń dá arakùnrin rẹ lẹ́jọ́
Eese nigba naa ti iwo fi n da arakunrin re lejo
tàbì èése tí ìwọ sì ń fi ojú ẹ̀gàn wo arakùnrin rẹ
tabi eese ti iwo si n fi oju egan wo arakunrin re
Nítorí olúkúlùkù wa ni yóò dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run
Nitori olukuluku wa ni yoo duro niwaju ite idajo Olorun
A ti kọ ìwé rẹ̀ pé
A ti ko iwe re pe
 Níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè, ni Olúwa wí gbogbo eékún ni yóò wólẹ̀ fún mi
 Niwon igba ti mo wa laaye, ni Oluwa wi gbogbo eekun ni yoo wole fun mi
gbogbo ahọ́n ni yóò jẹ́wọ́ fún Ọlọ́run
gbogbo ahon ni yoo jewo fun Olorun
  Ǹjẹ́ nítorí náà, olúkúlùkù wa ni yóò jíyìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run
  Nje nitori naa, olukuluku wa ni yoo jiyin ara re fun Olorun
Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a yé dá ara wa lẹ́jọ́
Nitori naa, e je ki a ye da ara wa lejo
Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ pinu nínú ọkàn yín láti má se fi òkúta ìdìgbòlù kankan sí ọ̀nà arakùnrin yín
Dipo bee, e pinu ninu okan yin lati ma se fi okuta idigbolu kankan si ona arakunrin yin
Bí ẹni tí ó wà nínú Jésù Olúwa, mo mọ̀ dájú gbangba pé kò sí oùnjẹ tó jẹ́ àìmọ́ nínú ara rẹ̀
Bi eni ti o wa ninu Jesu Oluwa, mo mo daju gbangba pe ko si ounje to je aimo ninu ara re
Ṣùgbọ́n bí ẹnìkẹ́ni ba kà á sí àìmọ́, òun ni ó se àìmọ́ fún
Sugbon bi enikeni ba ka a si aimo, oun ni o se aimo fun
Bí inú arakùnrin rẹ ba bàjẹ́ nítorí ohun tí ìwọ́ jẹ, ìwọ kò rìn nínú ìfẹ́ mọ́
Bi inu arakunrin re ba baje nitori ohun ti iwo je, iwo ko rin ninu ife mo
Má se fi oúnjẹ rẹ sọ ẹni tí Kírísítì kú fún di ẹni ègbé
Ma se fi ounje re so eni ti Kirisiti ku fun di eni egbe
Má se gba kí a sọ̀rọ̀ ohun tí ó gbà sí rere ní buburu
Ma se gba ki a soro ohun ti o gba si rere ni buburu
Nítorí ìjọba ọ̀run kì í se jíjẹ àti mímu, bí kò se nípa ti òdodo, àlàáfíà àti ayọ̀ nínú Èmí Mímọ́, nítorí ẹni tí ó bá sin Kírísítì nínú nǹkan wọ̀nyí ni ó se ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì ní ìyìn lọ́dọ̀ ènìyàn
Nitori ijoba orun ki i se jije ati mimu, bi ko se nipa ti ododo, alaafia ati ayo ninu Emi Mimo, nitori eni ti o ba sin Kirisiti ninu nnkan wonyi ni o se itewogba lodo Olorun, ti o si ni iyin lodo eniyan
Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a sa gbogbo ipá wa láti máa lépa àlàáfíà, àti ohun tí àwa yóò fi gbé ara wa ró
Nitori naa, e je ki a sa gbogbo ipa wa lati maa lepa alaafia, ati ohun ti awa yoo fi gbe ara wa ro
Má se dí iṣẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́ nítorí oúnjẹ
Ma se di ise Olorun lowo nitori ounje
Gbogbo oúnjẹ ni ó mọ́, sùgbọ́n ohun búburú ni fún ẹni náà tí ó jẹ ohunkóhun tí ó le mú arákùnrin rẹ kọsẹ̀
Gbogbo ounje ni o mo, sugbon ohun buburu ni fun eni naa ti o je ohunkohun ti o le mu arakunrin re kose
Ó sàn kí a má jẹ ẹran tàbí mu wáìnì tàbí se ohunkóhun tí yóò mú arákùnrin rẹ subú
O san ki a ma je eran tabi mu waini tabi se ohunkohun ti yoo mu arakunrin re subu
Nítorí náà, ohun tí ìwọ bá gbàgbọ́ nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí, pa á mọ́ ní àárín ìwọ àti Ọlọ́run
Nitori naa, ohun ti iwo ba gbagbo nipa gbogbo nnkan wonyi, pa a mo ni aarin iwo ati Olorun
Alábùkún fún ni ẹni náà tí kò dá ara rẹ̀ lẹ́bi nípa ohun tí ohun gbà
Alabukun fun ni eni naa ti ko da ara re lebi nipa ohun ti ohun gba
Ṣùgbọ́n ẹni náà tí ó se iyèméjì ni a ti dá lẹ́bi tí ó ba jẹ ẹ́, nítorí kò wá nípa ìgbàgbọ́
Sugbon eni naa ti o se iyemeji ni a ti da lebi ti o ba je e, nitori ko wa nipa igbagbo
bẹ́ẹ̀ sì ni, ohun gbogbo tí kò bá ti ipa ìgbàgbọ́ wá, ẹ̀sẹ̀ ni
bee si ni, ohun gbogbo ti ko ba ti ipa igbagbo wa, ese ni
Pọ́ọ̀lù Wàásù Sí Àwọn Aláìkọlà
Poolu Waasu Si Awon Alaikola
Àwa tí a jẹ́ alágbára nínú ìgbàgbọ́ yẹ kí ó máa ru ẹrù àìlera àwọn aláìlera, kí a má si ṣe ohun tí ó wu ara wa
Awa ti a je alagbara ninu igbagbo ye ki o maa ru eru ailera awon alailera, ki a ma si se ohun ti o wu ara wa
Olúkúlùkù wa gbọdọ̀ máa ṣe ohun tí ó wu ọmọnìkejì rẹ̀ sí rere, láti gbé e ró
Olukuluku wa gbodo maa se ohun ti o wu omonikeji re si rere, lati gbe e ro
Nítorí Kírísítì pàápàá kò ṣe ohun tí ó wu ara rẹ̀, ṣùgbọ́n, bí a ti kọ ọ́ pé
Nitori Kirisiti paapaa ko se ohun ti o wu ara re, sugbon, bi a ti ko o pe
Àwọn ẹni tí ń tàbùkù rẹ ń tàbùkù mi pẹ̀lú
Awon eni ti n tabuku re n tabuku mi pelu
Nítorí ohun gbogbo tí a kọ nígbà àtijọ́ ni a kọ láti fi kọ́ wa, kí àwa lè ní ìrètí nípa sùúrù àti ìtùnú èyí tí ó wá láti inú ìwé mímọ́
Nitori ohun gbogbo ti a ko nigba atijo ni a ko lati fi ko wa, ki awa le ni ireti nipa suuru ati itunu eyi ti o wa lati inu iwe mimo
Kí Ọlọ́run, ẹni tí ń fún ni ní sùúrù àti ìtùnú fún yin ní ẹ̀mí ìrẹ́pọ̀ láàrin ara yín gẹ́gẹ́ bí i Jésù Kírísítì, kí ẹ̀yin kí ó lè fi ọkàn kan àti ẹnu kan fi ògo fún Ọlọ́run, Baba Olúwa wa Jésù Kírísítì
Ki Olorun, eni ti n fun ni ni suuru ati itunu fun yin ni emi irepo laarin ara yin gege bi i Jesu Kirisiti, ki eyin ki o le fi okan kan ati enu kan fi ogo fun Olorun, Baba Oluwa wa Jesu Kirisiti
Nítorí náà ẹ gba ara yín mọ́ra, gẹ́gẹ́ bí Kírísítì ti gbà wá mọ́ra fún ògo Ọlọ́run
Nitori naa e gba ara yin mora, gege bi Kirisiti ti gba wa mora fun ogo Olorun
Mo sì wí pé, a rán Kírísítì láti ṣe ìránṣẹ́ àwọn tí se Júù nítorí òtítọ́ Ọlọ́run, láti fi ìdí àwọn ìlérí tí a ti ṣe fún àwọn baba múlẹ̀, kí àwọn aláìkọlà kí ó lè yin Ọlọ́run lógo nítorí àánú rẹ̀
Mo si wi pe, a ran Kirisiti lati se iranse awon ti se Juu nitori otito Olorun, lati fi idi awon ileri ti a ti se fun awon baba mule, ki awon alaikola ki o le yin Olorun logo nitori aanu re
gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé
gege bi a ti ko o pe
Nítorí èyí ni èmi ó ṣe yìn ọ́ láàrin àwọn aláìkọlà, Èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ
Nitori eyi ni emi o se yin o laarin awon alaikola, Emi o si korin si oruko re
Ó sì tún wí pé, Ẹ̀yin aláìkọlà, ẹ ma yọ̀, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀
O si tun wi pe, Eyin alaikola, e ma yo, pelu awon eniyan re
Àti pẹ̀lú, Ẹyin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin aláìkọlà
Ati pelu, Eyin Oluwa, gbogbo eyin alaikola
ẹ kọ orin ìyìn sí, ẹ̀yin ènìyàn gbogbo
e ko orin iyin si, eyin eniyan gbogbo
Àìṣáyà sì tún wí pé, Gbòngbò Jésè kan ń bọ̀ wá, òun ni ẹni tí yóò dìde ṣe àkóso àwọn aláìkọlà
Aisaya si tun wi pe, Gbongbo Jese kan n bo wa, oun ni eni ti yoo dide se akoso awon alaikola
Àwọn aláìkọlà yóò ní ìrètí nínú rẹ̀
Awon alaikola yoo ni ireti ninu re
Njẹ́ kí Ọlọ́run ìrètí kí ó fi gbogbo ayọ̀ òun àlàáfíà kún yín bí ẹ̀yín ti gbà á gbọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè pọ̀ ní ìrétí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́
Nje ki Olorun ireti ki o fi gbogbo ayo oun alaafia kun yin bi eyin ti gba a gbo, ki eyin ki o le po ni ireti nipa agbara Emi Mimo
Ẹ̀yin ará, èmi gan alára ti ní ìdánilójú, pé ẹ̀yin pàápàá kún fún oore, è pé ní ìmọ̀, ẹ̀yin sì jáfáfá láti máa kọ́ ara yín
Eyin ara, emi gan alara ti ni idaniloju, pe eyin paapaa kun fun oore, e pe ni imo, eyin si jafafa lati maa ko ara yin
Mo ti fi ìgboyà kọ̀wé sí yín lórí àwọn kókó ọ̀rọ̀ kan, bí ẹni ti ń rán yín létí àwọn kókó ọ̀rọ̀ náà, nítorí oore-ọ̀fẹ́ tí a ti fifún mi láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti jẹ́ ìránsẹ́ Kírísìtì Jésù láàrin àwọn aláìkọlà láti polongo ìyìn rere Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ojúse àlùfáà, kí àwọn aláìkọlà lè jẹ́ ẹbọ-ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run, èyí tí a ti fi Ẹ̀mí mímọ́ yà sí mímọ́
Mo ti fi igboya kowe si yin lori awon koko oro kan, bi eni ti n ran yin leti awon koko oro naa, nitori oore-ofe ti a ti fifun mi lati odo Olorun lati je iranse Kirisiti Jesu laarin awon alaikola lati polongo iyin rere Olorun gege bi ojuse alufaa, ki awon alaikola le je ebo-ore itewogba fun Olorun, eyi ti a ti fi Emi mimo ya si mimo
Nítorí náà, mo ní ìsògo nínú Kírísítì Jésù nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi fún Ọlọ́run
Nitori naa, mo ni isogo ninu Kirisiti Jesu ninu ise iranse mi fun Olorun
Èmi kò sa à gbọdọ̀ sọ ohun kan bí kò se èyí tí Kírisítì ti ọwọ́ mi se, ní títọ́ àwọn aláìkọlà sọ́nà láti ṣe ìgbọ́ran sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe mi
Emi ko sa a gbodo so ohun kan bi ko se eyi ti Kirisiti ti owo mi se, ni tito awon alaikola sona lati se igboran si oro Olorun nipa oro ati ise mi
nípa agbára isẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu tí a se lọ́wọ́ Ẹ̀mi
nipa agbara ise ami ati ise iyanu ti a se lowo Emi
Mo ti polongo ìyìn rere Kírísítì ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ láti Jérúsálẹ́mù dé ìlú tí a ń pè ní Ílíríkónì
Mo ti polongo iyin rere Kirisiti ni ekun rere lati Jerusalemu de ilu ti a n pe ni Ilirikoni
Ó jẹ́ èrò mi ní gbogbo ìgbà láti wàásù ìyìn rere Kírísítì ní ibi gbogbo tí wọn kò tí i gbọ́ nípa rẹ̀, kí èmi kí ó má se máa mọ àmọlé lórí ìpìlẹ̀ ẹlòmíràn
O je ero mi ni gbogbo igba lati waasu iyin rere Kirisiti ni ibi gbogbo ti won ko ti i gbo nipa re, ki emi ki o ma se maa mo amole lori ipile elomiran
Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé
Sugbon, gege bi a ti ko o pe
Àwọn tí kò tí ì sọ òrọ̀ rẹ̀ fún yóò rí i, yóò sì yé àwọn tí kò tí ì gbọ́ ọ rí
Awon ti ko ti i so oro re fun yoo ri i, yoo si ye awon ti ko ti i gbo o ri
Ìdí nì yìí tí ààyè fi há pẹ́ tó bẹ́ẹ̀ fún mi kí n tó wa bẹ̀ yín wò
Idi ni yii ti aaye fi ha pe to bee fun mi ki n to wa be yin wo
Ṣùgbọ́n báyìí tí kò tún sí ibòmíràn fún mi mọ́ ní agbègbè yìí, tí èmi sì ti ń pòùngbẹ láti ọdún púpọ̀ sẹ́yìn láti tọ̀ yín wá, mo gbèrò láti se bẹ́ẹ̀ nígbà tí mo bá lọ sí orílẹ̀ èdè Sípáníà
Sugbon bayii ti ko tun si ibomiran fun mi mo ni agbegbe yii, ti emi si ti n poungbe lati odun pupo seyin lati to yin wa, mo gbero lati se bee nigba ti mo ba lo si orile ede Sipania
Èmi yóò bẹ̀ yín wò ní ọ̀nà ìrìnàjò mi, lẹ́yìn tí a bá sì gbádùn ara wa fún ìgbà díẹ̀, ẹ ó kún mi ọ́wọ́ nínú ìrìnàjò mi láti dé ibẹ̀
Emi yoo be yin wo ni ona irinajo mi, leyin ti a ba si gbadun ara wa fun igba die, e o kun mi owo ninu irinajo mi lati de ibe
Ṣùgbọ́n ní báyìí, mo ń lọ nínú ìrìnàjò sí ìlú Jérúsálẹ́mù láti sé ìránsẹ́ fún àwọn ènìyàn mímọ́ níbẹ̀
Sugbon ni bayii, mo n lo ninu irinajo si ilu Jerusalemu lati se iranse fun awon eniyan mimo nibe
Nítorí pé àwọn tí ó wà ní agbégbé Makedóníà àti agbégbé Ákáyà ti kó ẹ̀bùn jọ fún àwọn talákà tí ó wà ní àárín àwọn ènìyàn mímọ́ ní Jérúsálẹ́mù
Nitori pe awon ti o wa ni agbegbe Makedonia ati agbegbe Akaya ti ko ebun jo fun awon talaka ti o wa ni aarin awon eniyan mimo ni Jerusalemu
Pẹ̀lú ayọ̀ ni wọ́n ń se èyí, nítorí wọ́n gbà wí pé, wọ́n jẹ́ ajigbésè fún wọn
Pelu ayo ni won n se eyi, nitori won gba wi pe, won je ajigbese fun won
Nítorí bí ó bá se pé a fi àwọn aláìkọlà se alájọni nínú ohun ẹ̀mí wọn, ajigbèsè sì ni wọn láti fi ohun ti ara ta wọ́n lọ́rẹ
Nitori bi o ba se pe a fi awon alaikola se alajoni ninu ohun emi won, ajigbese si ni won lati fi ohun ti ara ta won lore
Nítorí náà, nígbà tí mo bá ti se èyí tán tí mo bá sì di ẹ̀dìdì èso náà fún wọn tán, èmi yóò gba ti ọ̀dọ̀ yín bí mo bá ń lọ sí orílẹ̀ èdè Sípáníà
Nitori naa, nigba ti mo ba ti se eyi tan ti mo ba si di edidi eso naa fun won tan, emi yoo gba ti odo yin bi mo ba n lo si orile ede Sipania
Mo sì mọ̀ pé nígbà tí mo bá dé ọ̀dọ̀ yín, èmi yóò wà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìbùkùn Kírísítì
Mo si mo pe nigba ti mo ba de odo yin, emi yoo wa ni ekunrere ibukun Kirisiti
Èmí rọ̀ yín, ẹ̀yin ará, nítorí Olúwa wa Jésù Kírísítì, àti nítorí ìfẹ́ Ẹ̀mí, kí ẹ̀yin kí ó kún mi láti bá mi làkàkà nínú àdúrà yín sí Ọlọ́run fùn mi
Emi ro yin, eyin ara, nitori Oluwa wa Jesu Kirisiti, ati nitori ife Emi, ki eyin ki o kun mi lati ba mi lakaka ninu adura yin si Olorun fun mi
Kí a lè kó mi yọ kúrò lọ́wọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ ní Jùdíà àti kí isẹ́ ìránsẹ́ tí mo ní sí Jérúsálẹ́mù le jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ níbẹ̀
Ki a le ko mi yo kuro lowo awon alaigbagbo ni Judia ati ki ise iranse ti mo ni si Jerusalemu le je itewogba lodo awon eniyan mimo nibe
Nítorí náà, nípa ìfẹ́ Ọlọ́run kí èmi le fi ayọ̀ tọ̀ yín wa, kí pọ̀ pẹ̀lú yín ní ìtura
Nitori naa, nipa ife Olorun ki emi le fi ayo to yin wa, ki po pelu yin ni itura
Kí Ọlọ́run àlàáfíà wà pẹ̀lú gbogbo yín
Ki Olorun alaafia wa pelu gbogbo yin
Àmín
Amin
Ìkíni
Ikini
Mo fi Fébè arábìnrin wa le yin lọ́wọ́, ẹni tí ó jẹ́ díaókọ́nì nínú ìjọ tí ó wà ní Kéńkíríà
Mo fi Febe arabinrin wa le yin lowo, eni ti o je diaokoni ninu ijo ti o wa ni Kenkiria
Mo rọ̀ yín kí ẹ gbà á ní orúkọ Olúwa, bí ó ti yẹ fún àwọn ẹ̀nìyàn mímọ́, kí ẹ̀yin kí ó sì ràn án lọ́wọ́ ní gbogbo ọ̀nà, nítorí pé òun jẹ́ olùìrànlọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àti fún èmi náà pẹ̀lú
Mo ro yin ki e gba a ni oruko Oluwa, bi o ti ye fun awon eniyan mimo, ki eyin ki o si ran an lowo ni gbogbo ona, nitori pe oun je oluiranlowo fun opolopo eniyan ati fun emi naa pelu
Ẹ kí Pìrìsílà àti Àkúílà, àwọn tí ó ti jẹ́ alábásiṣẹ́pọ̀ mi nínú Kírísítì Jésù
E ki Pirisila ati Akuila, awon ti o ti je alabasisepo mi ninu Kirisiti Jesu
Àwọn tí wọ́n ti fi ẹ̀mí wọn wéwu nítorí mi
Awon ti won ti fi emi won wewu nitori mi
Kì í se èmi nìkan àti gbogbo àwọn ìjọ àwọn aláìkọlà ní ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn
Ki i se emi nikan ati gbogbo awon ijo awon alaikola ni n dupe lowo won
Kí ẹ sì kí ìjọ tí ń pé jọ fún pọ̀ ní ilé wọn
Ki e si ki ijo ti n pe jo fun po ni ile won
Ẹ kí Épénétù ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, òun ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó di Kírísítẹ́nì ní orílẹ̀ èdè Ésìà
E ki Epenetu ore mi owon, oun ni eni akoko ti o di Kirisiteni ni orile ede Esia
Ẹ kí Màríà, ẹni tí ó ṣe iṣẹ́ takuntakun fún yin
E ki Maria, eni ti o se ise takuntakun fun yin
Ẹ kí Áńdíróníkúsì àti Júníásì, àwọn ìbátan mi tí wọ́n wà ní ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú mi
E ki Andironikusi ati Juniasi, awon ibatan mi ti won wa ni ewon pelu mi
Àwọn wọ̀nyí ní ìtayọ láàrin àwọn àpósítélì, wọ́n sì ti wà nínú Kírísítì sáájú mi
Awon wonyi ni itayo laarin awon apositeli, won si ti wa ninu Kirisiti saaju mi
Ẹ kí Áńpílíátúsì, ẹni tí ó jẹ́ olùfẹ́ mi nínú Olúwa
E ki Anpiliatusi, eni ti o je olufe mi ninu Oluwa
Ẹ kí Úbánúsì, alábásisẹ́ pọ̀ wa nínú Kírísítì àti olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n Sítákì
E ki Ubanusi, alabasise po wa ninu Kirisiti ati olufe mi owon Sitaki