diacritcs
stringlengths
1
36.7k
no_diacritcs
stringlengths
1
35.5k
Nítorí pé, nǹkan gbogbo tí a lè mọ nípa Ọlọ́run ni a ti fihàn fún wọn, nítorí Ọlọ́run ti fi í hàn fún wọn
Nitori pe, nnkan gbogbo ti a le mo nipa Olorun ni a ti fihan fun won, nitori Olorun ti fi i han fun won
Nítorí pé láti ìgbà dídá ayé, gbogbo ohun àìlèfojúrí rẹ̀
Nitori pe lati igba dida aye, gbogbo ohun ailefojuri re
bí agbára ayérayé àti ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ̀ ni a rí gbangba tí a sì ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n kí ènìyàn má ba à wá àwáwí
bi agbara ayeraye ati iwa-bi-Olorun re ni a ri gbangba ti a si n fi oye ohun ti a da mo on ki eniyan ma ba a wa awawi
Lóòótọ́, wọn ní òye nípa Ọlọ́run dáadáa, ṣùgbọ́n wọn kò yìn ín lógo bí Ọlọ́run, wọ́n kò sí dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀
Loooto, won ni oye nipa Olorun daadaa, sugbon won ko yin in logo bi Olorun, won ko si dupe lowo re
wọ́n ń rò èrò aṣiwèrè, ọkàn òmùgọ̀ wọn sì ṣókùnkùn
won n ro ero asiwere, okan omugo won si sokunkun
Wọ́n Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n pe ara wọn ní ọlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n wọ́n di òmùgọ̀ pátápátá
Won Bi o tile je wi pe won pe ara won ni ologbon sugbon won di omugo patapata
wọ́n sì yí ògo Ọlọ́run tí kìí díbàjẹ́ sí àwọn àwòrán ère bí i ti ènìyàn tí í díbàjẹ́ àti ti ẹyẹ, àti ti ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin àti ti ẹranko afàyàfà
won si yi ogo Olorun ti kii dibaje si awon aworan ere bi i ti eniyan ti i dibaje ati ti eye, ati ti eranko elese merin ati ti eranko afayafa
Nítorí náà Ọlọ́run fà wọ́n lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun ìríra pẹ̀lú ara wọn èyí tí kò tọ́
Nitori naa Olorun fa won le ifekufee okan won lowo lati maa se ohun irira pelu ara won eyi ti ko to
Wọ́n yí òtítọ́ Ọlọ́run sí èké, wọ́n sì ń forí balẹ̀ láti máa sin ẹ̀dá dípò ẹlẹ́dàá—ẹni tí ìyìn tọ́ sí láéláé
Won yi otito Olorun si eke, won si n fori bale lati maa sin eda dipo eledaa—eni ti iyin to si laelae
Àmín
Amin
Nítorí èyí yìí ni Ọlọ́run ṣe fi wọ́n fún ìfẹ́ ìwàkíwà
Nitori eyi yii ni Olorun se fi won fun ife iwakiwa
nítorí àwọn obìnrin wọn tilẹ̀ yí ìlò àdánidá padà sí èyí tí ó lòdì sí ti àdánidá
nitori awon obinrin won tile yi ilo adanida pada si eyi ti o lodi si ti adanida
Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin pẹ̀lú, wọn a máa fi ìlò obìnrin nípa ti ẹ̀dá sílẹ̀, wọn a máa fẹ́ ìfẹ́kúfẹ́ sí ara wọn, ọkùnrin ń bá ọkùnrin ṣe èyí tí kò yẹ, wọ́n sì ǹ jẹ èrè ìsìnà wọn nínú ara wọn bí ó ti yẹ sí
Gege bee ni awon okunrin pelu, won a maa fi ilo obinrin nipa ti eda sile, won a maa fe ifekufe si ara won, okunrin n ba okunrin se eyi ti ko ye, won si n je ere isina won ninu ara won bi o ti ye si
Àti gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ̀ láti gba Ọlọ́run nínú ìmọ̀ tí ó tọ́, Ọlọ́run fi wọ́n fún iyè ríra láti ṣe ohun tí kò tọ́ fún wọn láti ṣe
Ati gege bi won ti ko lati gba Olorun ninu imo ti o to, Olorun fi won fun iye rira lati se ohun ti ko to fun won lati se
Wọ́n kún fún onírúurú àìṣòdodo gbogbo, àgbèrè, ìkà, ojúkòkòrò, àránkan
Won kun fun oniruuru aisododo gbogbo, agbere, ika, ojukokoro, arankan
wọ́n kún fún ìlara, ìpànìyàn, ìjà, ìtànjẹ, ìwà-búburú
won kun fun ilara, ipaniyan, ija, itanje, iwa-buburu
wọ́n jẹ́ afi-ọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-banijẹ́
won je afi-oro-kele-banije
Asọ̀rọ̀-ẹni-lẹ́yìn, akóríra Ọlọ́run, aláfojúdi, agbéraga, ahalẹ̀, aláròṣe ohun búburú, aṣàìgbọ́ràn sí òbí, Aláìníyè nínú, ọ̀dàlẹ̀, aláìnígbàgọ́, ọ̀dájú, aláìláàánú
Asoro-eni-leyin, akorira Olorun, alafojudi, agberaga, ahale, alarose ohun buburu, asaigboran si obi, Alainiye ninu, odale, alainigbago, odaju, alailaaanu
Bí ó tílẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n mọ ìlànà Ọlọ́run pé, ẹni tí ó bá ṣe irú nǹkan wọ̀nyí yẹ sí ikú, wọn kò ní inú dídùn sí àwọn nǹkan wọ̀nyí nìkan ṣùgbọ́n wọ́n ní inú dídùn sí àwọn tí ń ṣe wọ́n
Bi o tile je wi pe won mo ilana Olorun pe, eni ti o ba se iru nnkan wonyi ye si iku, won ko ni inu didun si awon nnkan wonyi nikan sugbon won ni inu didun si awon ti n se won
Ẹ̀yin ará, ìfẹ́ ọkàn àti àdúrà mi ni pé, kí àwọn Júù rí ìgbàlà
Eyin ara, ife okan ati adura mi ni pe, ki awon Juu ri igbala
Mo mọ irú ìfẹ́ àti ìtara tí wọ́n ní sí ọlá àti ògo Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ọ̀nà ìsìnà ni wọn ń gbà wá Ọlọ́run
Mo mo iru ife ati itara ti won ni si ola ati ogo Olorun, sugbon ona isina ni won n gba wa Olorun
Ìdí ni pé, wọ́n ń gbìyànjú láti hu ìwà rere nípa pípa òfin àti àṣà ìbílẹ̀ àwọn Júù mọ́, kí wọn báà lè rí ojú rere Ọlọ́run
Idi ni pe, won n gbiyanju lati hu iwa rere nipa pipa ofin ati asa ibile awon Juu mo, ki won baa le ri oju rere Olorun
Kò yé wọn pé, Kírísítì ti kú láti mú wọn dọ́gba pẹ̀lú Ọlọ́run
Ko ye won pe, Kirisiti ti ku lati mu won dogba pelu Olorun
Òfin àwọn Júù àti àṣà ìbílẹ̀ wọn kì í ṣe ọ̀nà tí Ọlọ́run lè fi gba ènìyàn là
Ofin awon Juu ati asa ibile won ki i se ona ti Olorun le fi gba eniyan la
Títí ìsinsin yìí, wọn kò ì tíì mọ̀ pé, Kírísítì kú láti pèsè ohun gbogbo tí wọ́n ń fi àníyàn wá kiri nípa òfin fún àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e, ó ti fi òpin sí gbogbo rẹ̀
Titi isinsin yii, won ko i tii mo pe, Kirisiti ku lati pese ohun gbogbo ti won n fi aniyan wa kiri nipa ofin fun awon ti o gbekele e, o ti fi opin si gbogbo re
Nítorí pé Mósè kọ ọ́ pé, Kí ènìyàn tó lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àti ìgbàlà gbà, ó ní láti ja àjàṣẹ́gun nínú gbogbo ìdánwò, kí ó sì wà láì dá ẹ̀ṣẹ̀ kan soso nínú gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀
Nitori pe Mose ko o pe, Ki eniyan to le ri idariji ese ati igbala gba, o ni lati ja ajasegun ninu gbogbo idanwo, ki o si wa lai da ese kan soso ninu gbogbo ojo aye re
Ṣùgbọ́n ìgbàlà tí ó wà nípa ìgbàgbọ́ wí pé, A kò níláti lọ wá inú ọ̀run láti mú Kírísítì wá sí ayé kí ó bá à lè ràn wá lọ́wọ́
Sugbon igbala ti o wa nipa igbagbo wi pe, A ko nilati lo wa inu orun lati mu Kirisiti wa si aye ki o ba a le ran wa lowo
Bẹ́ẹ̀ ni, a kò níláti wọ ìsà òkú lọ láti jí Kírísítì dìde
Bee ni, a ko nilati wo isa oku lo lati ji Kirisiti dide
Nítorí pé, ìgbàlà tí ènìyàn ń ní nípa ìgbẹ́kẹ̀lé, nínú Kírísítì, ìgbàlà tí àwa ń wàásù rẹ̀, wà ní àrọ́wọ́tó ẹnikọ̀ọ̀kan wa
Nitori pe, igbala ti eniyan n ni nipa igbekele, ninu Kirisiti, igbala ti awa n waasu re, wa ni arowoto enikookan wa
Kódà, ó kínlẹ̀ sí wa tó bí ọkàn àti ẹnu wa ti kínlẹ̀ sí wa
Koda, o kinle si wa to bi okan ati enu wa ti kinle si wa
Nítorí pé, bí ìwọ bá gbàgbọ́ ní ọkàn rẹ pé, Olúwa ti jí dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì jẹ́wọ́ rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn pé Jésù Kírísítì ní Olúwa rẹ, a ó gbà ọ́ là
Nitori pe, bi iwo ba gbagbo ni okan re pe, Oluwa ti ji dide kuro ninu oku, ti o si jewo re fun awon elomiran pe Jesu Kirisiti ni Oluwa re, a o gba o la
Nítorí pé, nípa ìgbàgbọ́ nínú ọkàn ni ènìyàn le gbà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run
Nitori pe, nipa igbagbo ninu okan ni eniyan le gba ni alaafia pelu Olorun
Bẹ́ẹ̀ ni ẹnu ni a sì fi ń sọ fún àwọn ẹlòmíràn ní ti ìgbàgbọ́ wa
Bee ni enu ni a si fi n so fun awon elomiran ni ti igbagbo wa
Nípa bẹ́ẹ̀, a sì sọ ìgbàlà wa di ohun tí ó dájú
Nipa bee, a si so igbala wa di ohun ti o daju
Nítorí pé, ìwé Mímọ́ sọ pé, Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba Kírísítì gbọ́ kò ní kábámọ̀
Nitori pe, iwe Mimo so pe, Enikeni ti o ba gba Kirisiti gbo ko ni kabamo
ojú kò ní ti olúwa rẹ̀ láéláé
oju ko ni ti oluwa re laelae
Òtítọ́ ni èyí pé, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́, ìbáà ṣe Júù tàbí aláìkọlà
Otito ni eyi pe, enikeni ti o wu ki o je, ibaa se Juu tabi alaikola
Ọlọ́run kan ni ó wà fún gbogbo wa, ó sì ń pín ọ̀rọ̀ rẹ̀ láì ní ìwọ̀n fún ẹnikẹ́ni tí ó bá bèèrè rẹ̀
Olorun kan ni o wa fun gbogbo wa, o si n pin oro re lai ni iwon fun enikeni ti o ba beere re
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sà à ti pe orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà
Enikeni ti o ba sa a ti pe oruko Oluwa ni a o gbala
Ṣùgbọ́n báwo ni wọ́n ṣe le ké pé ẹni tí wọn kò gbàgbọ́
Sugbon bawo ni won se le ke pe eni ti won ko gbagbo
Wọn ó ha sì ti ṣe gba ẹni tí wọn kò gbúró rẹ̀ rí gbọ́
Won o ha si ti se gba eni ti won ko gburo re ri gbo
Wọn o há sì ti ṣe gbọ́ láì sí oníwàásù
Won o ha si ti se gbo lai si oniwaasu
Wọ́n ó ha sì ti ṣe wàásù, bí kò ṣe pé a rán wọn
Won o ha si ti se waasu, bi ko se pe a ran won
Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, Ẹsẹ̀ àwọn tí ń wàásù ìyìn rere àlàáfíà ti dára tó, àwọn tí ń wàásù ìhìn ìyìn àyọ̀ ohun rere! Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn ni ó gbọ́ ti ìyìn rere
Gege bi a ti ko o pe, Ese awon ti n waasu iyin rere alaafia ti dara to, awon ti n waasu ihin iyin ayo ohun rere! Sugbon ki i se gbogbo won ni o gbo ti iyin rere
Nítorí Ìsáià wí pé, Olúwa, tali ó gba ìyìn wa gbọ́
Nitori Isaia wi pe, Oluwa, tali o gba iyin wa gbo
Ǹjẹ́ nípa gbígbọ́ ni ìgbàgbọ́ ti í wá, àti gbígbọ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Nje nipa gbigbo ni igbagbo ti i wa, ati gbigbo nipa oro Olorun
Ṣùgbọ́n mo ní, wọn kò ha gbọ́ bí
Sugbon mo ni, won ko ha gbo bi
Bẹ́ẹ̀ ni nítòótọ́ Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀, àti ọ̀rọ̀ wọn sí òpin ayé
Bee ni nitooto Ohun won jade lo si gbogbo ile, ati oro won si opin aye
Ṣùgbọ́n mo wí pé, Ísírẹ́lì kò ha mọ̀ bí
Sugbon mo wi pe, Isireli ko ha mo bi
Mósè ni ó kọ́ wí pé, Èmi ó fi àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mú yín jowú
Mose ni o ko wi pe, Emi o fi awon ti ki i se eniyan mu yin jowu
Àti àwọn aláìmòye ènìyàn ni èmi ó fi bí yín nínú
Ati awon alaimoye eniyan ni emi o fi bi yin ninu
Ṣùgbọ́n Ìsáià tilẹ̀ láyà, ó wí pé, Àwọn tí kò wá mi rí mi
Sugbon Isaia tile laya, o wi pe, Awon ti ko wa mi ri mi
Àwọn tí kò béèrè mi ni a fi mí hàn fún
Awon ti ko beere mi ni a fi mi han fun
Ṣùgbọ́n nípa ti Ísírẹ́lì ni ó wí pé, Ní gbogbo ọjọ́ ni mo na ọwọ́ mi sí àwọn aláìgbọ́ràn àti aláríwísí ènìyàn
Sugbon nipa ti Isireli ni o wi pe, Ni gbogbo ojo ni mo na owo mi si awon alaigboran ati alariwisi eniyan
Ìran aláìkọlà Pín Nínú ìgbàlà Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì
Iran alaikola Pin Ninu igbala Awon Omo Isireli
Ǹjẹ́ mo ní Ọlọ́run ha ta àwọn ènìyàn rẹ̀ nù bí
Nje mo ni Olorun ha ta awon eniyan re nu bi
Kí a má ri
Ki a ma ri
Nítorí Ísírẹ́lì ni èmi pẹ̀lú, láti inú irú-ọmọ Ábúráhámù, ni ẹ̀yà Béńjámínì
Nitori Isireli ni emi pelu, lati inu iru-omo Aburahamu, ni eya Benjamini
Ọlọ́run kò ta àwọn ènìyàn rẹ̀ nù ti ó ti mọ̀ tẹ́lẹ̀
Olorun ko ta awon eniyan re nu ti o ti mo tele
Tàbí ẹ̀yin kò mọ bí ìwé-mímọ́ ti wí ní ti Èlíjà
Tabi eyin ko mo bi iwe-mimo ti wi ni ti Elija
Bí ó ti ń bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run fún Ísírẹ́lì, wí pé
Bi o ti n bebe lodo Olorun fun Isireli, wi pe
Olúwa, wọ́n ti pa àwọn wòlíì rẹ, wọn sì ti wó àwọn pẹpẹ rẹ lulẹ̀
Oluwa, won ti pa awon wolii re, won si ti wo awon pepe re lule
èmi nìkan soso ni ó sì kù, wọ́n sì ń wá ẹ̀mí mi
emi nikan soso ni o si ku, won si n wa emi mi
Ṣùgbọ́n ìdáhùn wo ni Ọlọ́run fi fún un
Sugbon idahun wo ni Olorun fi fun un
Mo ti paẹ̀ẹ́dẹ́gbàrin ènìyàn mọ́ sílẹ̀ fún ara mi, àwọn tí kò tẹ eékún ba fún Báálì
Mo ti paeedegbarin eniyan mo sile fun ara mi, awon ti ko te eekun ba fun Baali
ẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni li àkókò ìsinsin yìí pẹ̀lú, apákan wà nípa ìyànfẹ́ ti ore-ọ̀fẹ́
ege bee si ni li akoko isinsin yii pelu, apakan wa nipa iyanfe ti ore-ofe
í ó bá sì ṣe pé nípa ti ore-ọ̀fẹ́ ni, ǹjẹ́ kì í ṣe ti iṣẹ́ mọ́
i o ba si se pe nipa ti ore-ofe ni, nje ki i se ti ise mo
àyàmọ̀bí ore-ọ̀fẹ́ kì í ṣe ore-ọ̀fẹ́ mọ́
ayamobi ore-ofe ki i se ore-ofe mo
Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe pe nípa ti iṣẹ́ ni, ǹjẹ́ kì í ṣe ti ore-ọ̀fẹ́ mọ́
Sugbon bi o ba se pe nipa ti ise ni, nje ki i se ti ore-ofe mo
àyàmọ̀bí iṣẹ́ kì í ṣe iṣẹ́ mọ́
ayamobi ise ki i se ise mo
Kí ha ni
Ki ha ni
Ohun tí Isírẹ́lì ń wá kiri, òun náà ni kò rí
Ohun ti Isireli n wa kiri, oun naa ni ko ri
ṣùgbọ́n àwọn ẹni ìyànfẹ́ ti rí i, a sì ṣé àyà àwọn ìyókù le
sugbon awon eni iyanfe ti ri i, a si se aya awon iyoku le
Èyí ni ìwé Mímọ́ ń wí nígbà tí ó sọ pé
Eyi ni iwe Mimo n wi nigba ti o so pe
Ọlọ́run ti fi oorun kùn wọ́n, ó sì dí ojú àti etí wọn, wọn kò sì le ní ìmọ̀ Kírísítì nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ síwọn
Olorun ti fi oorun kun won, o si di oju ati eti won, won ko si le ni imo Kirisiti nigba ti a ba n soro re siwon
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó sì rí títí di ọjọ́ òní
Bee gege ni o si ri titi di ojo oni
Ohun kan náà yìí ni Dáfídì ọba sọ̀rọ̀ rẹ̀ wí pé
Ohun kan naa yii ni Dafidi oba soro re wi pe
Kí oúnjẹ àti àwọn nǹkan mèremère wọn tàn wọ́n, láti rò pé wọ́n rí ojú rere Ọlọ́run
Ki ounje ati awon nnkan meremere won tan won, lati ro pe won ri oju rere Olorun
Jẹ́ kí àwọn nǹkan wọ̀nyí padà dojú ìjà kọ wọ́n, kí a bá à lè fi òtítọ́ wó wọn túútúú
Je ki awon nnkan wonyi pada doju ija ko won, ki a ba a le fi otito wo won tuutuu
Jẹ́ kí ojú wọn sókùnkùn, kí wọn má sì ṣe ríran
Je ki oju won sokunkun, ki won ma si se riran
Sì jẹ́ kí ẹrù ńlá tẹ̀ wọ́n ba títí láéláé bí wọ́n ti ń rìn lọ
Si je ki eru nla te won ba titi laelae bi won ti n rin lo
Ǹjẹ́ èyí fi hàn wí pé
Nje eyi fi han wi pe
Ọlọ́run àwọn Júù rẹ ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ láéláé
Olorun awon Juu re eniyan re sile laelae
Rárá o
Rara o
Ṣe ni Ọlọ́run ń fi ìgbàlà fún àwọn aláìkọlà
Se ni Olorun n fi igbala fun awon alaikola
Nípa síṣe bẹ́ẹ̀ yóò mú kí àwọn Júù jowú, kí wọn sì béèrè ìgbàlà Ọlọ́run náà fún ara wọn
Nipa sise bee yoo mu ki awon Juu jowu, ki won si beere igbala Olorun naa fun ara won
Bí ó bá ṣe pé gbogbo ayé di ọlọ́rọ̀ nípa ìgbàlà tí Ọlọ́run fifún àwọn Júù nítorí pé wọ́n kọ ìgbàlà náà, ìbùkún tí ó tóbi jùlọ ni yóò tún jẹ́ fún wa nígbà tí àwọn Júù fúnra wọn yóò tún ní ìgbàlà náà pẹ̀lú wa
Bi o ba se pe gbogbo aye di oloro nipa igbala ti Olorun fifun awon Juu nitori pe won ko igbala naa, ibukun ti o tobi julo ni yoo tun je fun wa nigba ti awon Juu funra won yoo tun ni igbala naa pelu wa
Ṣebí ẹ̀yin náà mọ̀ pé Ọlọ́run ti yà mi sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ajíyìnrere fún àwọn aláìkọlà
Sebi eyin naa mo pe Olorun ti ya mi soto gege bi ajiyinrere fun awon alaikola
Mo ń tẹnumọ́ ọn gidigidi mo sì ń rán àwọn Júù létí nípa rẹ̀ nígbákùúgbà tí ààyè bá wà
Mo n tenumo on gidigidi mo si n ran awon Juu leti nipa re nigbakuugba ti aaye ba wa
Ìdí tí mo fi ń ṣe èyí ni láti mú kí wọn jowú nǹkan tí ẹ̀yin aláìkọlà ní, bóyá ní ọ̀nà yìí Ọlọ́run lè lò mí láti gba díẹ̀ là nínú wọn
Idi ti mo fi n se eyi ni lati mu ki won jowu nnkan ti eyin alaikola ni, boya ni ona yii Olorun le lo mi lati gba die la ninu won
Ohun ìyanu ni yóò jẹ́ nígbà tí àwọn Júù yóò di Kírísítẹ́nì
Ohun iyanu ni yoo je nigba ti awon Juu yoo di Kirisiteni
Nígbà tí Ọlọ́run yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn, ṣe ni ó yípadà sí àwọn ìyókù ní ayé láti fún wọn ní ìgbàlà
Nigba ti Olorun yipada kuro lodo won, se ni o yipada si awon iyoku ni aye lati fun won ni igbala
Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú nísinsinyí ìyanu náà ń peléke sí i ni nígbà tí àwọn Júù bá wá sọ́dọ̀ Kírísítì
Bee ni pelu nisinsinyi iyanu naa n peleke si i ni nigba ti awon Juu ba wa sodo Kirisiti
Bí ẹni pé a sọ àwọn òkú di alààyè ni yóò jẹ́
Bi eni pe a so awon oku di alaaye ni yoo je
Níwọ̀n ìgbà tí Ábúráhámù àti àwọn wòlíì jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run, àwọn ọmọ wọn yóò jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run pẹ̀lú
Niwon igba ti Aburahamu ati awon wolii je eniyan Olorun, awon omo won yoo je eniyan Olorun pelu
Ìdí ni pé, bí gbòǹgbò igi bá jẹ́ mímọ́, àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóò jẹ́ mímọ́ pẹ̀lú
Idi ni pe, bi gbongbo igi ba je mimo, awon eka re yoo je mimo pelu
Ṣùgbọ́n a ti ké díẹ̀ nínú ẹ̀ka Ábúráhámù, tí í ṣe àwọn Júù kúrò
Sugbon a ti ke die ninu eka Aburahamu, ti i se awon Juu kuro
Ẹ̀yin aláìkọlà, tí a lè wí pé ó jẹ́ ẹ̀ka igi búburú ni a fi sí ipò àwọn Júù
Eyin alaikola, ti a le wi pe o je eka igi buburu ni a fi si ipo awon Juu
Nítorí náà, nísinsinyí, í se é ṣe fún yín láti gba ìbùkún tí Ọlọ́run ṣe ìpinnu fún Ábúráhámù àti àwọn ọmọ rẹ̀, èyí ni pé, ẹ ń pín nínú oúnjẹ ọlọ́ràá tí ó jẹ́ ti igi àrà ọ̀tọ̀ fún Ọlọ́run
Nitori naa, nisinsinyi, i se e se fun yin lati gba ibukun ti Olorun se ipinnu fun Aburahamu ati awon omo re, eyi ni pe, e n pin ninu ounje oloraa ti o je ti igi ara oto fun Olorun
Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣe gbéraga nítorí pé a fi yín sí ipò àwọn ẹ̀ka tí a ké kúrò
Sugbon e kiyesara ki e ma se gberaga nitori pe a fi yin si ipo awon eka ti a ke kuro