diacritcs
stringlengths
1
36.7k
no_diacritcs
stringlengths
1
35.5k
Ẹni tí ó ba létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń ṣọ fún àwọn ìjọ
Eni ti o ba leti, ki o gbo ohun ti Emi n so fun awon ijo
Àti sí Ańgẹ́lì Ìjọ ni Filadéfíà Kọ̀wé
Ati si Angeli Ijo ni Filadefia Kowe
Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ náà wí, ẹni tí ó ṣe olóòótọ́, ẹni tí ó ní kọ́kọ́rọ́ Dáfídì, ẹni tí ó sí, tí kò sí ẹni tí yóò tì
Oro wonyi ni eni ti o je mimo naa wi, eni ti o se oloooto, eni ti o ni kokoro Dafidi, eni ti o si, ti ko si eni ti yoo ti
ẹni tí o sì tì, tí kò sì ẹni tí yóò ṣí i
eni ti o si ti, ti ko si eni ti yoo si i
Èmi mọ iṣẹ́ rẹ̀ kíyèsí i, mo gbe ilẹ̀kùn tí ó ṣí kálẹ̀ níwájú rẹ̀, tí kò sí ẹni tí o lè tì í
Emi mo ise re kiyesi i, mo gbe ilekun ti o si kale niwaju re, ti ko si eni ti o le ti i
pé ìwọ ni agbára díẹ̀, ìwọ sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, ìwọ kò sì sẹ́ orúkọ mi
pe iwo ni agbara die, iwo si pa oro mi mo, iwo ko si se oruko mi
Kíyèsí i, èmi ó mú àwọn ti sínágógù Sàtánì, àwọn tí wọ́n ń wí pé Júù ni àwọn, tí wọn kì í sì ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọn ń ṣèké
Kiyesi i, emi o mu awon ti sinagogu Satani, awon ti won n wi pe Juu ni awon, ti won ki i si se bee, sugbon ti won n seke
kíyèsí i, èmi ó mú kí wọn wá wólẹ̀ níwájú ẹṣẹ̀ rẹ̀, kí wọn sì mọ̀ pé èmi tí fẹ́ ọ
kiyesi i, emi o mu ki won wa wole niwaju ese re, ki won si mo pe emi ti fe o
Nítorí tí ìwọ tí pa ọ̀rọ̀ sùúrù mi mọ́, èmi pẹ̀lú yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú wákàtí ìdánwò, tí ń bọ̀ wá dé bá gbogbo ayé, láti dán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé wò
Nitori ti iwo ti pa oro suuru mi mo, emi pelu yoo pa o mo kuro ninu wakati idanwo, ti n bo wa de ba gbogbo aye, lati dan awon ti n gbe ori ile aye wo
Kíyèsí i, èmi ń bọ̀ kánkán
Kiyesi i, emi n bo kankan
di èyí ti ìwọ ní mú ṣinṣin, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gba adé rẹ
di eyi ti iwo ni mu sinsin, ki enikeni ma se gba ade re
Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun, òun ni èmi ó fi ṣe ọ̀wọ́n nínú tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run mi, òun kì yóò sì jáde kúrò níbẹ̀ mọ́
Eni ti o ba segun, oun ni emi o fi se owon ninu tempili Olorun mi, oun ki yoo si jade kuro nibe mo
èmi ó sì kọ orúkọ Ọlọ́run mi sí i lára, àti orúkọ ìlú Ọlọ́run mi, tí i ṣe Jerúsálémù tuntun, tí ó ń ti ọrun sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi wá
emi o si ko oruko Olorun mi si i lara, ati oruko ilu Olorun mi, ti i se Jerusalemu tuntun, ti o n ti orun sokale lati odo Olorun mi wa
àti orúkọ tuntun ti èmi tikarámì
ati oruko tuntun ti emi tikarami
Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun ti Ẹmi ń sọ fún àwọn ìjọ
Eni ti o ba ni eti, ki o gbo ohun ti Emi n so fun awon ijo
Àti sí áńgẹ́lì ìjọ ní Láódékíá kọ̀wé
Ati si angeli ijo ni Laodekia kowe
Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ń jẹ́ Àmín wí, ẹlẹ́rìí olódodo àti olóòótọ́, olórí ìṣẹ̀dá Ọlọ́run
Oro wonyi ni eni ti n je Amin wi, elerii olododo ati oloooto, olori iseda Olorun
Èmi mọ̀ iṣẹ́ rẹ, pé ìwọ kò gbóná bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò tútù
Emi mo ise re, pe iwo ko gbona bee ni iwo ko tutu
èmi ìbá fẹ́ pé kí ìwọ kúkú tutù, tàbí kí ìwọ kúkú gbóná
emi iba fe pe ki iwo kuku tutu, tabi ki iwo kuku gbona
Ǹjẹ nítorí tí ìwọ lọ wọ́ọ́rọ́, tí o kò si gbóná, bẹ́ẹ̀ ni tí o kò tutù, èmi yóò pọ̀ ọ́ jáde kúrò ni ẹnu mi
Nje nitori ti iwo lo wooro, ti o ko si gbona, bee ni ti o ko tutu, emi yoo po o jade kuro ni enu mi
Nítorí tí ìwọ wí pé, Èmi ní ọrọ̀, èmi sì ń pọ̀ sí i ni ọrọ̀, èmi kò si ṣe aláìní ohunkóhun
Nitori ti iwo wi pe, Emi ni oro, emi si n po si i ni oro, emi ko si se alaini ohunkohun
tí ìwọ kò sì mọ̀ pé, òsì ni ìwọ, ẹni-ikáànù, tálákà, afọ́jú, àti ẹni-ìhòhò
ti iwo ko si mo pe, osi ni iwo, eni-ikaanu, talaka, afoju, ati eni-ihoho
Èmi fún ọ ni ìmọ̀ràn pé kí o ra wúrà lọ́wọ́ mi tí a ti dà nínú iná, kí ìwọ lè di ọlọ́rọ̀
Emi fun o ni imoran pe ki o ra wura lowo mi ti a ti da ninu ina, ki iwo le di oloro
àti aṣọ funfun, kí ìwọ lè fi wọ ara rẹ̀, àti kí ìtìjú ìhòòhò rẹ̀ má ba hàn kí ìwọ sì fi ohun ìkunra kun ojú rẹ̀, kí ìwọ lè ríran
ati aso funfun, ki iwo le fi wo ara re, ati ki itiju ihooho re ma ba han ki iwo si fi ohun ikunra kun oju re, ki iwo le riran
Gbogbo àwọn ti èmi bá fẹ́ ni èmi ń bá wí, tí mo sì ń nà
Gbogbo awon ti emi ba fe ni emi n ba wi, ti mo si n na
nítorí náà, ní ìtara, kì ìwọ sì ronúpìwàdà
nitori naa, ni itara, ki iwo si ronupiwada
Kíyèsí i, èmi dúró ni ẹnu ilẹ̀kùn, èmi sì ń kànkùn, bí ẹnikẹ́ni bá gbọ ohun mi, tí ó sì ṣí ilẹ̀kùn, èmi yóò sì wọlé tọ̀ ọ́ wá, èmi yóò sì máa bá a jẹun, àti òun pẹ̀lú mi
Kiyesi i, emi duro ni enu ilekun, emi si n kankun, bi enikeni ba gbo ohun mi, ti o si si ilekun, emi yoo si wole to o wa, emi yoo si maa ba a jeun, ati oun pelu mi
Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi fún láti jókòó pẹ̀lu mi lórí ìtẹ́ mi, bí èmi pẹ̀lú ti ṣẹ́gun, tí mo sì jókòó pẹ̀lú Baba mi lórí ìtẹ́ rẹ̀
Eni ti o ba segun ni emi yoo fi fun lati jokoo pelu mi lori ite mi, bi emi pelu ti segun, ti mo si jokoo pelu Baba mi lori ite re
Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń ṣọ fún àwọn Ìjọ
Eni ti o ba leti, ki o gbo ohun ti Emi n so fun awon Ijo
Ìtẹ́ Ọ̀run
Ite Orun
Lẹ́yin nǹkan wọ̀nyí èmi wò, sì kíyèsí i, ìlẹ̀kùn kan ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run
Leyin nnkan wonyi emi wo, si kiyesi i, ilekun kan si sile ni orun
Ohùn kìn-ín-ní tí mo gbọ́ bí ohùn ìpè tí ń bá mi sọ̀rọ̀, tí ó wí pé, Gòkè wá níhìn-ín, èmi ó sì fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ̀yìn èyí hàn ọ́
Ohun kin-in-ni ti mo gbo bi ohun ipe ti n ba mi soro, ti o wi pe, Goke wa nihin-in, emi o si fi ohun ti yoo sele leyin eyi han o
Lójú kan náà, mo sì wà nínú Ẹ̀mí
Loju kan naa, mo si wa ninu Emi
sì kíyèsí i, a tẹ́ ìtẹ́ kan lọ́run ẹnìkan sì jókòó lórí ìtẹ́ náà
si kiyesi i, a te ite kan lorun enikan si jokoo lori ite naa
Ẹni tí ó sì jókòó náà dàbí òkúta jásípérì àti sádíúsì lójú
Eni ti o si jokoo naa dabi okuta jasiperi ati sadiusi loju
Ni àyíká ìtẹ́ náà ni òṣùmàrè kan wà tí ó dàbí òkúta émérádì lójú
Ni ayika ite naa ni osumare kan wa ti o dabi okuta emeradi loju
Yíká ìtẹ́ náà sì ni ìtẹ́ mẹ́rínlélógún
Yika ite naa si ni ite merinlelogun
àti lórí àwọn ìtẹ́ náà mo rí àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún jókòó, tí a wọ̀ ni aṣọ àlà
ati lori awon ite naa mo ri awon agba merinlelogun jokoo, ti a wo ni aso ala
adé wúrà sì wà ni orí wọn
ade wura si wa ni ori won
Àti láti ibi ìtẹ́ náà ni ìró mọ̀nàmọ́ná àti ohùn àti àrá ti jáde wá
Ati lati ibi ite naa ni iro monamona ati ohun ati ara ti jade wa
níwájú ìtẹ́ náà ni fìtílà iná méje sì ń tàn, èyí tí ń ṣe Ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run
niwaju ite naa ni fitila ina meje si n tan, eyi ti n se Emi meje ti Olorun
Àti láti ibi ìtẹ́ náà ni òkun bi digi wà tí o dàbí Kírísítálì
Ati lati ibi ite naa ni okun bi digi wa ti o dabi Kirisitali
Àti yí ìtẹ́ náà ká ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ni ẹ̀dá alààyè mẹ́rin tí ó kún fún ojú níwájú àti lẹ̀yìn wà
Ati yi ite naa ka ni egbe kookan ni eda alaaye merin ti o kun fun oju niwaju ati leyin wa
Ẹ̀dá kínní sì dàbí kìnnìún, ẹ̀dá kéjì si dàbí ọmọ màlúù, ẹ̀dá kẹta sì ni ojú bi ti ènìyàn, ẹ̀dá kẹ́rin sì dàbí ìdì tí ń fò
Eda kinni si dabi kinniun, eda keji si dabi omo maluu, eda keta si ni oju bi ti eniyan, eda kerin si dabi idi ti n fo
Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, tí olúkúlùkù wọn ni ìyẹ́ mẹ́fà, kún fún ojú yíká ara àti nínú
Awon eda alaaye merin naa, ti olukuluku won ni iye mefa, kun fun oju yika ara ati ninu
wọn kò sì sinmi lọ́sàn-ań àti lóru, láti wí pé
won ko si sinmi losan-an ati loru, lati wi pe
Mímọ́, Mímọ́, Mímọ́, Olúwa Ọlọ́run Olódùmare, tí ó ti wà, tí ó sì ń bẹ, tí ó sì ń bọ̀ wá! Nígbà tí àwọn ẹ̀dá aláàyè náà bá sì fi ògo àti ọlá, àti ọpẹ́ fún ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, tí o ń bẹ láàyè láé àti láéláé
Mimo, Mimo, Mimo, Oluwa Olorun Olodumare, ti o ti wa, ti o si n be, ti o si n bo wa! Nigba ti awon eda alaaye naa ba si fi ogo ati ola, ati ope fun eni ti o jokoo lori ite, ti o n be laaye lae ati laelae
Àwọn àgbà mẹ́rinlélógún náà yóò sì wólẹ̀ níwájú ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, wọn yóò sì tẹríba fún ẹni tí ń bẹ láàyè láé àti láéláé, wọn yóò sì fi adé wọn lélẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wí pé
Awon agba merinlelogun naa yoo si wole niwaju eni ti o jokoo lori ite, won yoo si teriba fun eni ti n be laaye lae ati laelae, won yoo si fi ade won lele niwaju ite naa, wi pe
Olúwa, ìwọ ni o yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára
Oluwa, iwo ni o ye lati gba ogo ati ola ati agbara
nítorí pé ìwọ ni o dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ inú rẹ̀ ni wọn fi wà tí a sì dá wọn
nitori pe iwo ni o da ohun gbogbo, ati nitori ife inu re ni won fi wa ti a si da won
Ìwé Àti Ọ̀dọ́ Agùntàn
Iwe Ati Odo Aguntan
Mo sì rí i ni ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà, ìwé kan ti a kọ nínú àti lẹ̀yìn, ti a sì fi èdìdì méje dí
Mo si ri i ni owo otun eni ti o jokoo lori ite naa, iwe kan ti a ko ninu ati leyin, ti a si fi edidi meje di
Mó sì rí ańgẹ́lì alágbára kan, ó ń fi ohùn rara kéde pé, Táni ó yẹ láti ṣí ìwé náà, àti láti tu èdìdì rẹ̀
Mo si ri angeli alagbara kan, o n fi ohun rara kede pe, Tani o ye lati si iwe naa, ati lati tu edidi re
Kò sì sí ẹni kan ní ọ̀run, tàbí lórí ilẹ̀ ayé, tàbí nísàlẹ̀ ilẹ̀, tí ó le ṣí ìwé náà, tàbí ti o lè wo inú rẹ̀
Ko si si eni kan ni orun, tabi lori ile aye, tabi nisale ile, ti o le si iwe naa, tabi ti o le wo inu re
Èmi sì sọkùn gidigidi, nítorí tí a kò ri ẹnìkan tí o yẹ láti sí i àti láti ka ìwé náà, tàbí láti wo inú rẹ̀
Emi si sokun gidigidi, nitori ti a ko ri enikan ti o ye lati si i ati lati ka iwe naa, tabi lati wo inu re
Ọ̀kan nínú àwọn àgbà náà sì wí fún mi pé, Má ṣe sọkún
Okan ninu awon agba naa si wi fun mi pe, Ma se sokun
kíyèsí i, kìnnìún ẹ̀yà Júdà, Gbòǹgbò Dáfídì, tí borí láti ṣí ìwé náà, àti láti tú èdìdì rẹ̀ méjèèje
kiyesi i, kinniun eya Juda, Gbongbo Dafidi, ti bori lati si iwe naa, ati lati tu edidi re mejeeje
Mo sì rí i ni àárin ìtẹ́ náà, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti ni àárin àwọn àgbà náà, Ọ̀dọ́-Àgùntàn kan dúró bí èyí tí a ti pa, ó ní ìwo méje àti ojú méje, tí o jẹ́ Ẹ̀mi méje tí Ọlọ́run, tí a rán jáde lọ sì orí ilẹ̀ ayé gbogbo
Mo si ri i ni aarin ite naa, ati awon eda alaaye merin naa, ati ni aarin awon agba naa, Odo-Aguntan kan duro bi eyi ti a ti pa, o ni iwo meje ati oju meje, ti o je Emi meje ti Olorun, ti a ran jade lo si ori ile aye gbogbo
Ó sì wá, o sì gbà á ni ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà
O si wa, o si gba a ni owo otun eni ti o jokoo lori ite naa
Nígbà tí ó sì gba ìwé náà, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà wólẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà, olúkúlùkù wọn mú háàpù kan lọ́wọ́, àti ago wúrà tí ó kún fún tùràrí tí i ṣe àdúrà àwọn ènìyàn mímọ́
Nigba ti o si gba iwe naa, awon eda alaaye merin naa, ati awon agba merinlelogun naa wole niwaju Odo-Aguntan naa, olukuluku won mu haapu kan lowo, ati ago wura ti o kun fun turari ti i se adura awon eniyan mimo
Wọn sì ń kọ orin tuntun kan, wí pé
Won si n ko orin tuntun kan, wi pe
Ìwọ ní o yẹ láti gba ìwé náà, àti láti ṣí èdìdì rẹ̀
Iwo ni o ye lati gba iwe naa, ati lati si edidi re
nítorí tí a tí pa ọ, ìwọ sì tí fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe ìràpadà ènìyàn sí Ọlọ́run láti inú ẹ̀yà gbogbo, àti èdè gbogbo, àti inú ènìyàn gbogbo, àti orílẹ̀-èdè gbogbo wá
nitori ti a ti pa o, iwo si ti fi eje re se irapada eniyan si Olorun lati inu eya gbogbo, ati ede gbogbo, ati inu eniyan gbogbo, ati orile-ede gbogbo wa
Ìwọ sì tí ṣe wọ́n ni ọba àti àlùfáà sì Ọlọ́run wá
Iwo si ti se won ni oba ati alufaa si Olorun wa
wọ́n sì ń jọba lórí ilẹ̀ ayé
won si n joba lori ile aye
Èmi sì wò, mo sì gbọ́ ohùn àwọn ańgẹ́lì púpọ̀ yí ìtẹ́ náà ká, àti yí àwọn ẹ̀dá alààyè náà àti àwọn àgbà náà ká
Emi si wo, mo si gbo ohun awon angeli pupo yi ite naa ka, ati yi awon eda alaaye naa ati awon agba naa ka
Iye wọn sì jẹ́ ẹgbàárun ọ̀nà ẹgbàarún àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún
Iye won si je egbaarun ona egbaarun ati egbeegberun ona egbeegberun
Wọn ń wí lóhùn rara pé
Won n wi lohun rara pe
Yíyẹ ni Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà tí a tí pa, láti gba agbára, àti ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n, àti ipá, àti ọlá, àti ògo, àti ìbùkún
Yiye ni Odo-Aguntan naa ti a ti pa, lati gba agbara, ati oro ati ogbon, ati ipa, ati ola, ati ogo, ati ibukun
Gbogbo ẹ̀dá tí o sì ń bẹ ni ọ̀run, àti lórí ilẹ̀ ayé, àti nísàlẹ̀ ilẹ̀ àti irú àwọn tí ń bẹ nínú òkun, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú wọn, ni mo gbọ́ tí ń wí pé, Kí a fi ìbùkún àti ọlá, àti ògo, àti agbára, fún Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ àti fún Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà láé àti láéláé
Gbogbo eda ti o si n be ni orun, ati lori ile aye, ati nisale ile ati iru awon ti n be ninu okun, ati gbogbo awon ti n be ninu won, ni mo gbo ti n wi pe, Ki a fi ibukun ati ola, ati ogo, ati agbara, fun Eni ti o jokoo lori ite ati fun Odo-Aguntan naa lae ati laelae
Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà wí pé, Àmín! Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà wólẹ̀, wọn sì foríbalẹ̀ fún ẹni tí ń bẹ láàyè láé àti láéláé
Awon eda alaaye merin naa wi pe, Amin! Awon agba merinlelogun naa wole, won si foribale fun eni ti n be laaye lae ati laelae
Àwọn Èdìdì Ìwé Náà
Awon Edidi Iwe Naa
Èmi sì rí i nígbà tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà sí ọkàn nínú èdìdì wọ̀nyí, mo sì gbọ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ń wí bí sísán àrá pé, Wá, wò ó! Mo sì wò ó, kíyèsí i, Ẹṣin funfun kan
Emi si ri i nigba ti Odo-Aguntan naa si okan ninu edidi wonyi, mo si gbo okan ninu awon eda alaaye merin naa n wi bi sisan ara pe, Wa, wo o! Mo si wo o, kiyesi i, Esin funfun kan
ẹni tí ó sì jókòó lórí i rẹ̀ ní ọrùn kan
eni ti o si jokoo lori i re ni orun kan
a sì fi adé kan fún un
a si fi ade kan fun un
ó sì jáde lọ láti ìṣẹ́gun dé ìsẹ́gun
o si jade lo lati isegun de isegun
Nígbà tí ó sì sí èdìdì kéjì, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè wí pé, Wá, wò ó! Ẹṣin mìíràn tí ó pupa sì jáde
Nigba ti o si si edidi keji, mo gbo ohun eda alaaye wi pe, Wa, wo o! Esin miiran ti o pupa si jade
a sì fi agbára fún ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀, láti gba àlàáfíà kúrò lórí ilẹ̀ ayé, àti pé kí wọn kí ó máa pa ara wọn
a si fi agbara fun eni ti o jokoo lori re, lati gba alaafia kuro lori ile aye, ati pe ki won ki o maa pa ara won
A sì fi idà ńlá kan lé e lọ́wọ́
A si fi ida nla kan le e lowo
Nígbà tí ó sì di èdìdì kẹ́tà, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kẹta wí pé, Wá, wò ó
Nigba ti o si di edidi keta, mo gbo ohun eda alaaye keta wi pe, Wa, wo o
Mo sì wò ó, sì kíyèsí i, ẹṣin dúdú kan
Mo si wo o, si kiyesi i, esin dudu kan
ẹni tí ó jókòó lórí ni ìwọ̀n aláwẹ́ méjì ní ọwọ́ rẹ̀
eni ti o jokoo lori ni iwon alawe meji ni owo re
Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn kan ní àárin àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nì ti ń wí pé, òsùwọ̀n àlìkámà kan fún owó idẹ kan, àti òṣùwọ̀n ọkà-bálì mẹ́ta fún owó idẹ kan, sì kíyèsí i, kí ó má sì ṣe pa òróró àti ọtí wáìnì lára
Mo si gbo bi eni pe ohun kan ni aarin awon eda alaaye mereerin ni ti n wi pe, osuwon alikama kan fun owo ide kan, ati osuwon oka-bali meta fun owo ide kan, si kiyesi i, ki o ma si se pa ororo ati oti waini lara
Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹ́rin, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kan wí pé, Wá wò ó
Nigba ti o si si edidi kerin, mo gbo ohun eda alaaye kan wi pe, Wa wo o
Mo sì wò ó, kíyèsi, ẹ̀ṣin ràndànràndàn kan
Mo si wo o, kiyesi, esin randanrandan kan
orúkọ ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni ikú, àti ipò òkú sì tọ̀ ọ́ lẹ̀yìn
oruko eni ti o jokoo lori re ni iku, ati ipo oku si to o leyin
A sì fi agbára fún wọn lórí ìdá mẹ́rin ayé, láti fi idà, àti ebi, àti ikú, àti ẹranko lu orí ilẹ̀ ayé pa
A si fi agbara fun won lori ida merin aye, lati fi ida, ati ebi, ati iku, ati eranko lu ori ile aye pa
Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì karùn ún, mo rí lábẹ́ pẹpẹ, ọkàn àwọn tí a ti pa nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí tí wọ́n dìmú
Nigba ti o si si edidi karun un, mo ri labe pepe, okan awon ti a ti pa nitori oro Olorun, ati nitori eri ti won dimu
Wọ́n kígbe ní ohùn rara, wí pé, Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa, ẹ̀mí mímọ́ àti olóòótọ́ ìwọ kì yóò ṣe ìdájọ́ kí o sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa mọ́ lára àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé
Won kigbe ni ohun rara, wi pe, Yoo ti pe to, Oluwa, emi mimo ati oloooto iwo ki yoo se idajo ki o si gbesan eje wa mo lara awon ti n gbe ori ile aye
A sì fi aṣọ funfun fún gbogbo wọn
A si fi aso funfun fun gbogbo won
a sì wí fún wọn pé, kí wọn kí ó sinmi fún ìgbà díẹ̀ ná, títí iye àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn àti arákùnrin wọn tí ó ti pa bí wọn, yóò fi dé
a si wi fun won pe, ki won ki o sinmi fun igba die na, titi iye awon iranse elegbe won ati arakunrin won ti o ti pa bi won, yoo fi de
Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹfa mo sì rí i, sì kíyèsí i, ìsẹ̀lẹ̀ ńlá kan ṣẹ̀
Nigba ti o si si edidi kefa mo si ri i, si kiyesi i, isele nla kan se
ọ̀run sì dúdú bí aṣọ ọ̀fọ̀ onírun, òsùpá sì dàbí ẹ̀jẹ̀
orun si dudu bi aso ofo onirun, osupa si dabi eje
Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run sì ṣubú sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ń rẹ̀ àìgbó èso rẹ̀ dànù, nígbà tí ẹ̀fúùfù ńlá bá mì í
Awon irawo oju orun si subu sile gege bi igi opoto ti n re aigbo eso re danu, nigba ti efuufu nla ba mi i
A sì ká ọ̀run kúrò bí ìwé tí a ká, àti olúkúlùkù òkè àti erékùsù ní a sì ṣí kúrò ní ipò wọn
A si ka orun kuro bi iwe ti a ka, ati olukuluku oke ati erekusu ni a si si kuro ni ipo won
Àwọn ọba ayé àti àwọn ọlọ́lá àti àwọn olórí ogun, àti àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn alágbára, àti olókúlùkù ẹrú, àti olúkúlùkù òmìnira, sì fi ara wọn pamọ́ nínú ihò ilẹ̀, àti nínú àpáta orí òkè
Awon oba aye ati awon olola ati awon olori ogun, ati awon oloro ati awon alagbara, ati olokuluku eru, ati olukuluku ominira, si fi ara won pamo ninu iho ile, ati ninu apata ori oke
Wọ́n sì ń wí fún àwọn òkè àti àwọn àpáta náà pé, Ẹ wó lù wá, kí ẹ sì fi wá pamọ́ kúrò lójú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti kúrò nínú ìbínú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà
Won si n wi fun awon oke ati awon apata naa pe, E wo lu wa, ki e si fi wa pamo kuro loju eni ti o jokoo lori ite, ati kuro ninu ibinu Odo-Aguntan naa
Nítorí ọjọ́ ńlá ìbínú wọn dé
Nitori ojo nla ibinu won de
ta ni sì le dúró
ta ni si le duro
Ọ̀kẹ́ Méje-Ólé-Ẹgbàá-Méjì Èdìdí Ìwé
Oke Meje-Ole-Egbaa-Meji Edidi Iwe