diacritcs
stringlengths
1
36.7k
no_diacritcs
stringlengths
1
35.5k
Nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin, a kì yóò dá ẹnikẹ́ni láre níwájú rẹ̀
Nitori pe nipa ise ofin, a ki yoo da enikeni lare niwaju re
nítorí nípa òfin ni ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ti wá
nitori nipa ofin ni imo ese ti wa
Ṣùgbọ́n nisinsinyìí, a ti fi òdodo Ọlọ́run hàn láìsí òfin, tí a ti ń jẹ́rí sí nípa òfin àti nípa àwọn wòlíì
Sugbon nisinsinyii, a ti fi ododo Olorun han laisi ofin, ti a ti n jeri si nipa ofin ati nipa awon wolii
Àní òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kírísítì, sí gbogbo ènìyàn àti gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́
Ani ododo Olorun nipa igbagbo ninu Jesu Kirisiti, si gbogbo eniyan ati gbogbo awon ti o gbagbo
nítorí tí kò sí ìyàtọ̀
nitori ti ko si iyato
Gbogbo ènìyàn ni ó sá ti ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọ́run
Gbogbo eniyan ni o sa ti se, ti won si kuna ogo Olorun
Àwọn ẹni tí a ń dáláre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, nípa ìdáǹdè tí ó wà nínú Kírísítì Jésù
Awon eni ti a n dalare lofee nipa oore-ofe re, nipa idande ti o wa ninu Kirisiti Jesu
Ẹni tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ láti jẹ́ ètùtù nípa ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, láti fi òdodo rẹ̀ hàn nítorí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti kọjá, nínú ìpamọ́ra Ọlọ́run
Eni ti Olorun ti gbe kale lati je etutu nipa igbagbo ninu eje re, lati fi ododo re han nitori idariji awon ese ti o ti koja, ninu ipamora Olorun
Láti fi òdodo rẹ̀ hàn ní ìgbà ìsinsìnyìí
Lati fi ododo re han ni igba isinsinyii
kí ó lè jẹ́ olódodo àti olùdáre ẹni tí ó gba Jésù gbọ́
ki o le je olododo ati oludare eni ti o gba Jesu gbo
Ọ̀nà ìṣògo dà
Ona isogo da
A ti mú un kúrò
A ti mu un kuro
Nípa òfin wo
Nipa ofin wo
Nípa iṣẹ́
Nipa ise
Bẹ́ẹ̀ kọ́ Ṣùgbọ́n nípa òfin ìgbàgbọ́
Bee ko Sugbon nipa ofin igbagbo
Nítorí náà a parí rẹ̀ sí pé nípa ìgbàgbọ́ ni a ń dá ènìyàn láre láìsí iṣẹ́ òfin
Nitori naa a pari re si pe nipa igbagbo ni a n da eniyan lare laisi ise ofin
Ọlọ́run àwọn Júù nìkan ha ni bí
Olorun awon Juu nikan ha ni bi
Kì í ha ṣe ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú
Ki i ha se ti awon alaikola pelu
Bẹ́ẹ̀ ni, ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú
Bee ni, ti awon alaikola pelu
Bí ó ti jẹ́ pé Ọlọ́run kan ni, tí yóò dá àwọn akọlà láre nípa Ìgbàgbọ́ àti àwọn aláìkọlà nítorí ìgbàgbọ́ wọn
Bi o ti je pe Olorun kan ni, ti yoo da awon akola lare nipa Igbagbo ati awon alaikola nitori igbagbo won
Àwa ha ń sọ òfin dasán nípa ìgbàgbọ́ bí
Awa ha n so ofin dasan nipa igbagbo bi
Kí a má rí i
Ki a ma ri i
ṣùgbọ́n a ń fi òfin múlẹ̀
sugbon a n fi ofin mule
Ábúráhámù Gba Ìdálòre Nípa Ìgbàgbọ́
Aburahamu Gba Idalore Nipa Igbagbo
Ǹjẹ́ kín ni àwa ó ha wí nípa Ábúráhámù, baba wa sàwárí nípa èyí
Nje kin ni awa o ha wi nipa Aburahamu, baba wa sawari nipa eyi
Májẹ̀mu láéláé jẹ́rìí si i wí pé, a gba Ábúráhámù là nípa ìgbàgbọ́
Majemu laelae jerii si i wi pe, a gba Aburahamu la nipa igbagbo
Nítorí bí a bá dá Ábúráhámù láre nípa iṣẹ́, ó ní ohun ìṣògo
Nitori bi a ba da Aburahamu lare nipa ise, o ni ohun isogo
ṣùgbọ́n kì í ṣe níwájú Ọlọ́run
sugbon ki i se niwaju Olorun
Ìwé mímọ́ ha ti wí
Iwe mimo ha ti wi
Ábúráhámù gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un
Aburahamu gba Olorun gbo, a si ka a si ododo fun un
Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ṣiṣẹ́, a kò ka èrè náà sí oore ọ̀fẹ́ bí kò ṣe sí ẹ̀tọ́ rẹ̀
Nje fun eni ti o sise, a ko ka ere naa si oore ofe bi ko se si eto re
Ṣùgbọ́n fún ẹni tí kò ṣiṣẹ́, tí ó sì ń gba ẹni tí ó ń dá ènìyàn búburú láre gbọ́, a ka ìgbàgbọ́ rẹ̀ sí òdodo
Sugbon fun eni ti ko sise, ti o si n gba eni ti o n da eniyan buburu lare gbo, a ka igbagbo re si ododo
Gẹ́gẹ́ bí Dáfídì pẹ̀lú ti pe olúwa rẹ̀ náà ní ẹni ìbùkún, ẹni tí Ọlọ́run ka òdodo fún láìsí ti iṣẹ́
Gege bi Dafidi pelu ti pe oluwa re naa ni eni ibukun, eni ti Olorun ka ododo fun laisi ti ise
Wí pé, Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí a dárí ìrékọjá wọn jì, tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀
Wi pe, Ibukun ni fun awon eni ti a dari irekoja won ji, ti a si bo ese won mole
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà ẹni tí Olúwa kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí lọ́rùn
Ibukun ni fun okunrin naa eni ti Oluwa ko ka ese si lorun
Ìbùkún yìí ha jẹ́ ti àwọn akọlà nìkan, tàbí ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú
Ibukun yii ha je ti awon akola nikan, tabi ti awon alaikola pelu
Nítorí tí a wí pé, a ka ìgbàgbọ́ fún Ábúráhámù sí òdodo
Nitori ti a wi pe, a ka igbagbo fun Aburahamu si ododo
Báwo ni a ṣe kà á sí i
Bawo ni a se ka a si i
Nígbà tí ó wà ní ìkọlà tàbí ní àìkọlà
Nigba ti o wa ni ikola tabi ni aikola
Kì í ṣe ni ìkọlà, ṣùgbọ́n ní àìkọlà ni
Ki i se ni ikola, sugbon ni aikola ni
Ó sì gbé àmì ìkọlà, èdìdì òdodo ìgbàgbọ́ tí ó ní nígbà tí ó wà ní àìkọlà kí ó lè ṣe baba gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́, bí a kò tilẹ̀ kọ wọ́n ní ilà kí a lè ka òdodo sí wọn pẹ̀lú
O si gbe ami ikola, edidi ododo igbagbo ti o ni nigba ti o wa ni aikola ki o le se baba gbogbo awon ti o gbagbo, bi a ko tile ko won ni ila ki a le ka ododo si won pelu
Àti baba àwọn tí ìkọlà tí kì í ṣe pé a kàn kọlà fún ṣá, ṣùgbọ́n ti wọn ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tí baba wa Ábúráhámù ní, kí a tó kọ ọ́ nílà
Ati baba awon ti ikola ti ki i se pe a kan kola fun sa, sugbon ti won n tele apeere igbagbo ti baba wa Aburahamu ni, ki a to ko o nila
Ìlérí fún Ábúráhámù àti fún irú ọmọ rẹ̀, pé, wọn ó jogún ayé, kì í ṣe nípa òfin bí kò ṣe nípa òdodo ti ìgbàgbọ́
Ileri fun Aburahamu ati fun iru omo re, pe, won o jogun aye, ki i se nipa ofin bi ko se nipa ododo ti igbagbo
Nítorí bí àwọn tí ń ṣe ti òfin bá ṣe ajogún, ìgbàgbọ́ di asán, ìlérí sì di aláìlágbára
Nitori bi awon ti n se ti ofin ba se ajogun, igbagbo di asan, ileri si di alailagbara
Nítorí òfin ń ṣiṣẹ́ ìbínú
Nitori ofin n sise ibinu
Ṣùgbọ́n ní ibi tí òfin kò bá sí, ìrúfin kò sí níbẹ̀
Sugbon ni ibi ti ofin ko ba si, irufin ko si nibe
Nítorí náà ni ó ṣe gbé e karí ìgbàgbọ́, kí ìlérí náà bá a lè sinmi lé oore-òfẹ́, kí a sì lè mú un dá gbogbo irú ọmọ lójú, kì í ṣe fún àwọn tí ń pa òfin mọ́ nìkan, ṣùgbọ́n bí kò ṣe pẹ̀lú fún àwọn ti ó pín nínú ìgbàgbọ́ Ábúráhámù, ẹni tí í se baba gbogbo wa pátapáta, Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, Mo ti fi ọ́ se baba orílẹ̀ èdè púpọ̀
Nitori naa ni o se gbe e kari igbagbo, ki ileri naa ba a le sinmi le oore-ofe, ki a si le mu un da gbogbo iru omo loju, ki i se fun awon ti n pa ofin mo nikan, sugbon bi ko se pelu fun awon ti o pin ninu igbagbo Aburahamu, eni ti i se baba gbogbo wa patapata, Gege bi a ti ko o pe, Mo ti fi o se baba orile ede pupo
Níwájú Ọlọ́run ẹni tí òun gbàgbọ́, ẹni tí ó sọ òkú di ààyè, tí ó sì pè àwọn ohun tí kò sí bí ẹni pé wọ́n wà
Niwaju Olorun eni ti oun gbagbo, eni ti o so oku di aaye, ti o si pe awon ohun ti ko si bi eni pe won wa
Nígbà tí ìrètí kò sí mọ́, Ábúráhámù gbàgbọ́ nínú ìrètí bẹ́ẹ̀ ni ó sì di baba orílẹ̀ èdè púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí èyi tí a wí fún un pé, Báyìí ni irú ọmọ rẹ̀ yóò rí
Nigba ti ireti ko si mo, Aburahamu gbagbo ninu ireti bee ni o si di baba orile ede pupo, gege bi eyi ti a wi fun un pe, Bayii ni iru omo re yoo ri
Ẹni tí kò rẹ̀wẹ̀sì nínú ìgbàgbọ́, nígbà tí ó ro ti ara òun tìkarárẹ̀ tí ó ti kú tan, nítorí tí ó tó bí ẹni ìwọ̀n ọgọ́rún-ún ọdún, àti nígbà tí ó ro ti yíyàgàn inú Sárà
Eni ti ko rewesi ninu igbagbo, nigba ti o ro ti ara oun tikarare ti o ti ku tan, nitori ti o to bi eni iwon ogorun-un odun, ati nigba ti o ro ti yiyagan inu Sara
Kò fi àìgbàgbọ́ ṣiyèméjì nípa ìlérí Ọlọ́run
Ko fi aigbagbo siyemeji nipa ileri Olorun
ṣùgbọ́n ó lágbára sí i nínú ìgbàgbọ́ bí ó ti fi ògo fún Ọlọ́run
sugbon o lagbara si i ninu igbagbo bi o ti fi ogo fun Olorun
Pẹ̀lú ìdánilójú kíkún pé, Ọlọ́run lè ṣe ohun tí ó ti ṣe ìlérí rẹ̀
Pelu idaniloju kikun pe, Olorun le se ohun ti o ti se ileri re
Nítorí náà ni a sì ṣe kà á sí òdodo fún un
Nitori naa ni a si se ka a si ododo fun un
Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà, A kà á sí òdodo fún un, ni a kọ kì í ṣe kìkì nítorí tirẹ̀ nìkan
Sugbon oro naa, A ka a si ododo fun un, ni a ko ki i se kiki nitori tire nikan
Ṣùgbọ́n nítorí tiwa pẹ̀lú
Sugbon nitori tiwa pelu
A ó sì kà á sí fún wa, bí àwa bá gba ẹni tí ó gbé Jésù Olúwa wa dìde kúrò nínú òkú gbọ́
A o si ka a si fun wa, bi awa ba gba eni ti o gbe Jesu Oluwa wa dide kuro ninu oku gbo
Ẹni tí a pa fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí a sì jí dìde nítorí ìdáláre wa
Eni ti a pa fun ese wa, ti a si ji dide nitori idalare wa
Àlááfíà Àti Ayọ̀
Alaafia Ati Ayo
Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí a ti dá wa láre nípa ìgbàgbọ́, àwa ní àlàáfíà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípaṣẹ̀ Olúwa wa Jésù Kírísítì
Nitori naa, niwon igba ti a ti da wa lare nipa igbagbo, awa ni alaafia lodo Olorun nipase Oluwa wa Jesu Kirisiti
Nípasẹ̀ ẹni tí àwa sì ti rí ọ̀nà gbà nípa ìgbàgbọ́ sí inú oore-ọ̀fẹ́ yìí nínú èyí tí àwa gbé dúró
Nipase eni ti awa si ti ri ona gba nipa igbagbo si inu oore-ofe yii ninu eyi ti awa gbe duro
Àwa sì ń yọ̀ nínú ìrètí ògo Ọlọ́run
Awa si n yo ninu ireti ogo Olorun
Kì í sì ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa tún ń ṣògo nínú ìjìyà pẹ̀lú
Ki i si se bee nikan, sugbon awa tun n sogo ninu ijiya pelu
bí a ti mọ̀ pé ìjìyà ń sisẹ́ sùúrù
bi a ti mo pe ijiya n sise suuru
Àti pé sùúrù ń siṣẹ́ ìrírí
Ati pe suuru n sise iriri
àti pé ìrírí ń siṣẹ́ ìrètí
ati pe iriri n sise ireti
Ìrètí kì í sì í dójútini nítorí a ti dá ìfẹ́ Ọlọ́run sí wa lọ́kàn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a fi fún wa
Ireti ki i si i dojutini nitori a ti da ife Olorun si wa lokan lati owo Emi Mimo ti a fi fun wa
Nítorí ìgbà tí àwa jẹ́ aláìlera, ní àkókò tí ó yẹ, Kírísítì kú fún àwa aláìwà-bí-Ọlọ́run
Nitori igba ti awa je alailera, ni akoko ti o ye, Kirisiti ku fun awa alaiwa-bi-Olorun
Nítorí ó ṣọ̀wọ́n kí ẹnìkan tó kú fún olódodo
Nitori o sowon ki enikan to ku fun olododo
ṣùgbọ́n fún ènìyàn rere bóyá ẹlòmíràn tilẹ̀ lè dábàá láti kú
sugbon fun eniyan rere boya elomiran tile le dabaa lati ku
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìfẹ́ òun pàápàá sí wa hàn nínú èyí pé, nígbà tí àwa jẹ́ ẹlẹ́sẹ̀, Kírísítì kú fún wa
Sugbon Olorun fi ife oun paapaa si wa han ninu eyi pe, nigba ti awa je elese, Kirisiti ku fun wa
Mélòó mélòó sì ni tí a dá wa láre nísinn yìí nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni a ó gbà wá là kúrò nínú ìbínú nípaṣẹ̀ rẹ̀
Meloo meloo si ni ti a da wa lare nisinn yii nipa eje re ni a o gba wa la kuro ninu ibinu nipase re
Ǹjẹ́ bí, nígbà tí àwa wà ní ọ̀tá, a mú wa, ba Ọlọ́run làjà nípa ikú Ọmọ rẹ̀, mélòó mélòó, nígbà tí a là wá ní ìjà tan, ni a ó gbà wá là nípa ìyè rẹ̀
Nje bi, nigba ti awa wa ni ota, a mu wa, ba Olorun laja nipa iku Omo re, meloo meloo, nigba ti a la wa ni ija tan, ni a o gba wa la nipa iye re
Kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa ń ṣògo nínú Ọlọ́run nípa Olúwa wa Jésù Kírísítì, nípasẹ̀ ẹni tí àwa ti rí ìlàjà gbà nísinsìn yìí
Ki si i se bee nikan, sugbon awa n sogo ninu Olorun nipa Oluwa wa Jesu Kirisiti, nipase eni ti awa ti ri ilaja gba nisinsin yii
Nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipa ọ̀dọ̀ ènìyàn kan wọ ayé, àti ikú nípa ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ikú sì kọjá sórí ènìyàn gbogbo, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí gbogbo ènìyàn ti dẹ́sẹ̀
Nitori gege bi ese ti tipa odo eniyan kan wo aye, ati iku nipa ese bee ni iku si koja sori eniyan gbogbo, lati odo eni ti gbogbo eniyan ti dese
Nítorí kí òfin tó dé, ẹ̀ṣẹ̀ ti wà láyé
Nitori ki ofin to de, ese ti wa laye
ṣùgbọ́n a kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí ni lọ́rùn nígbà tí òfin kò sí
sugbon a ko ka ese si ni lorun nigba ti ofin ko si
Ṣùgbọ́n ikú jọba láti ìgbà Ádámù wá títí fi di ìgbà ti Mósè, àti lórí àwọn tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò dàbí irú ìrékọjá Ádámù, ẹni tí í ṣe àpẹẹrẹ ẹni tí ń bọ̀
Sugbon iku joba lati igba Adamu wa titi fi di igba ti Mose, ati lori awon ti ese won ko dabi iru irekoja Adamu, eni ti i se apeere eni ti n bo
Ṣùgbọ́n ẹ̀bùn-ọ̀fẹ́ kò dàbí ẹ̀ṣẹ̀
Sugbon ebun-ofe ko dabi ese
Nítorí bí nípa ẹ̀ṣẹ̀ ẹnìkan ẹni púpọ̀ kú, mélòó mélòó ni oore-ọ̀fẹ́ ọkùnrin kan, Jésù Kírísítì, di púpọ̀ fún ẹni púpọ̀
Nitori bi nipa ese enikan eni pupo ku, meloo meloo ni oore-ofe okunrin kan, Jesu Kirisiti, di pupo fun eni pupo
Kì í ṣe bí nípa ẹnìkan tí ó sẹ̀ ni ẹ̀bùn náà
Ki i se bi nipa enikan ti o se ni ebun naa
Nítorí ìdájọ́ ti ipasẹ̀ ẹnìkan wá fún ìdálẹ́bi, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn-ọ̀fẹ́ ti inú ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ wá fún ìdáláre, Ǹjẹ́ bí nípa ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin kan, ikú jọba nípasẹ̀ ẹnìkan náà
Nitori idajo ti ipase enikan wa fun idalebi, sugbon ebun-ofe ti inu ese pupo wa fun idalare, Nje bi nipa ese okunrin kan, iku joba nipase enikan naa
mélòó mélòó ni àwọn tí ń gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore-ọ̀fẹ́ àti ẹ̀bùn òdodo yóò jọba nínú ìyè nípasẹ̀ ẹnìkan, Jésù Kírísítì
meloo meloo ni awon ti n gba opolopo oore-ofe ati ebun ododo yoo joba ninu iye nipase enikan, Jesu Kirisiti
Ǹjẹ́ bí nípa ẹ̀ṣẹ̀ ẹnìkan ìdájọ́ dé bá gbogbo ènìyàn sí ìdálẹ́bi
Nje bi nipa ese enikan idajo de ba gbogbo eniyan si idalebi
gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni nípa ìwà òdodo ẹnìkan, ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ dé sórí gbogbo ènìyàn fún ìdáláre sí ìyè
gege bee ni nipa iwa ododo enikan, ebun ofe de sori gbogbo eniyan fun idalare si iye
Nítorí gẹ́gẹ́ bí nípa àìgbọ́ràn ọkùnrin kan, ènìyàn púpọ̀ di ẹlẹ́sẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni nípa ìgbọ́ràn ẹnìkan, a ó sọ ènìyàn púpọ̀ di olódodo
Nitori gege bi nipa aigboran okunrin kan, eniyan pupo di elese, bee ni nipa igboran enikan, a o so eniyan pupo di olododo
Ṣùgbọ́n òfin bọ́ sí inú rẹ̀, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè di púpọ̀, ṣùgbọ́n ni ibi ti ẹ̀ṣẹ̀ di púpọ̀, oore-ọ̀fẹ́ di púpọ̀ rékọjá
Sugbon ofin bo si inu re, ki ese le di pupo, sugbon ni ibi ti ese di pupo, oore-ofe di pupo rekoja
Pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti jọba nípa ikú bẹ́ẹ̀ ni kí oore-ọ̀fẹ́ sì lè jọba nípa òdodo títí ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Jésù Kírísítì Olúwa wa
Pe, gege bi ese ti joba nipa iku bee ni ki oore-ofe si le joba nipa ododo titi iye ainipekun nipase Jesu Kirisiti Oluwa wa
Ikú Sí Ẹ̀sẹ̀, Ìyè Nínú Kírísítì
Iku Si Ese, Iye Ninu Kirisiti
Ǹjẹ́ àwa ó ha ti wí
Nje awa o ha ti wi
Ṣé kí àwa ó jòkòó nínú ẹ̀ṣẹ̀, kí oore-ọ̀fẹ́ ba à lè máa pọ̀ sí i
Se ki awa o jokoo ninu ese, ki oore-ofe ba a le maa po si i
Kò lè rí bẹ́ẹ̀
Ko le ri bee
Ṣé a tún le máa dẹ́sẹ̀ lẹ́yìn tí a ti fún wa ní ìṣẹ́gun lórí rẹ̀
Se a tun le maa dese leyin ti a ti fun wa ni isegun lori re
Nítorí a ti ṣẹ́gun agbára ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí a di Kírísítẹ́nì tí a sì ṣe ìrìbọmi fún wa láti di apá kan Jésù Kírísítì nípasẹ̀ ikú rẹ̀, a borí agbára ìwà ẹ̀ṣẹ̀
Nitori a ti segun agbara ese nigba ti a di Kirisiteni ti a si se iribomi fun wa lati di apa kan Jesu Kirisiti nipase iku re, a bori agbara iwa ese
Ẹ ti gbé ògbólógbòó ara yín tí ń fẹ́ máa dẹ́sẹ̀ sin pẹ̀lú Kírísítì nígbà tí òun kú, àti nígbà tí Ọlọ́run Baba pẹ̀lú agbára ògo mú un padà sí ìyè, a sì fún yín ní ìyè tun tun rẹ̀ láti gbádùn rẹ̀, èyí ṣẹlẹ̀ nípa ìrìbọmi yín
E ti gbe ogbologboo ara yin ti n fe maa dese sin pelu Kirisiti nigba ti oun ku, ati nigba ti Olorun Baba pelu agbara ogo mu un pada si iye, a si fun yin ni iye tun tun re lati gbadun re, eyi sele nipa iribomi yin
Nítorí pé ẹ̀yin ti di apá kan ara rẹ̀, àti pé ẹ kú pẹ̀lú rẹ̀, nígbà tí òun kú
Nitori pe eyin ti di apa kan ara re, ati pe e ku pelu re, nigba ti oun ku
Nísinsin yìí, ẹ ń pín ìyè tuntun rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì jí dìde gẹ́gẹ́ bí òun náà ti jí dìde
Nisinsin yii, e n pin iye tuntun re, eyin yoo si ji dide gege bi oun naa ti ji dide
Gbogbo èrò burúkú ọkàn yín ni a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀
Gbogbo ero buruku okan yin ni a kan mo agbelebuu pelu re
Ẹ̀mí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sì ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ nínú yín ni a ti sọ di aláìlera
Emi ese ti o si n fe lati maa dese ninu yin ni a ti so di alailera
Nítorí náà, ara yín tí ó ń fẹ́ láti máa dẹ́sẹ̀ kò sí lábẹ́ àkóso ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, kò sì ní láti jẹ́ ẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́
Nitori naa, ara yin ti o n fe lati maa dese ko si labe akoso ese mo, ko si ni lati je eru fun ese mo