diacritcs
stringlengths
1
36.7k
no_diacritcs
stringlengths
1
35.5k
Ṣùgbọ́n bí àwa bá ń retí èyí tí àwa kò rí, ǹjẹ́ àwa ń fi sùúrù dúró dè é
Sugbon bi awa ba n reti eyi ti awa ko ri, nje awa n fi suuru duro de e
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀mí pẹ̀lú sì ń ran àìlera wa lọ́wọ́
Bee gege ni emi pelu si n ran ailera wa lowo
nítorí a kò mọ bí a ti ń gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ
nitori a ko mo bi a ti n gbadura gege bi o ti ye
ṣùgbọ́n ẹ̀mí tìkáara rẹ̀ ń fi ìrora tí a kò le fi ẹnu sọ bẹ̀bẹ̀ fún wa
sugbon emi tikaara re n fi irora ti a ko le fi enu so bebe fun wa
Ẹni tí ó sì ń wá ọkàn wò, ó mọ ohun ti inú ẹ̀mí, nítorí tí ó ń bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ènìyàn mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run
Eni ti o si n wa okan wo, o mo ohun ti inu emi, nitori ti o n bebe fun awon eniyan mimo gege bi ife Olorun
Àwa sì mọ̀ pé ohun gbogbo ni ó ń siṣẹ́ pọ̀ sí rere fún àwọn tí ó fẹ́ Ọlọ́run, àní fún àwọn ẹni tí a pè gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ̀
Awa si mo pe ohun gbogbo ni o n sise po si rere fun awon ti o fe Olorun, ani fun awon eni ti a pe gege bi ipinnu re
Nítorí àwọn ẹni tí ó mọ̀ tẹ́lẹ̀, ni ó sì yàn tẹ́lẹ̀ láti rí bí àwòrán ọmọ rẹ̀, u kí òun lè jẹ́ àkọ́bí láàrin àwọn arákùnrin púpọ̀ Àti pé lẹ́yìn tí òun ti pè wá wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sọ wá di aláìjẹ̀bi lẹ́yìn èyí, ó fi rere Kírísítì kún inú ọkàn wa
Nitori awon eni ti o mo tele, ni o si yan tele lati ri bi aworan omo re, u ki oun le je akobi laarin awon arakunrin pupo Ati pe leyin ti oun ti pe wa wa sodo ara re, o so wa di alaijebi leyin eyi, o fi rere Kirisiti kun inu okan wa
Lékè gbogbo rẹ̀, ó fún wa ní ìdúró rere pẹ̀lú rẹ̀, ó sì pinu ògo rẹ̀ fún wa
Leke gbogbo re, o fun wa ni iduro rere pelu re, o si pinu ogo re fun wa
Kí ni àwa yóò wí nísinsin yìí sí nǹkan ìyanu wọ̀nyí
Ki ni awa yoo wi nisinsin yii si nnkan iyanu wonyi
Bí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú wa, ta ni yóò kọjú ìjà sí wa
Bi Olorun ba wa pelu wa, ta ni yoo koju ija si wa
Níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ti yọ̀ǹda ọmọ rẹ̀ fún wa, ǹjẹ́ ó ha tún le sòro fún un láti fún wa ní ohunkóhun bí
Niwon igba ti Olorun ti yonda omo re fun wa, nje o ha tun le soro fun un lati fun wa ni ohunkohun bi
Ta ni ẹni náà tí ó lè dá wa lẹ́bi, àwa ẹni tí Ọlọ́run ti yàn fún ara rẹ̀
Ta ni eni naa ti o le da wa lebi, awa eni ti Olorun ti yan fun ara re
Ǹjẹ́ Ọlọ́run yóò dá wa lẹ́bi
Nje Olorun yoo da wa lebi
Bẹ́ẹ̀ kọ́! Òun ni ẹni tí ó dárí jì wá, tí ó sì fi wá sípò tí ó dára lọ́dọ̀ rẹ̀
Bee ko! Oun ni eni ti o dari ji wa, ti o si fi wa sipo ti o dara lodo re
Ta ni ẹni náà tí yóò dá wa lẹ́bi
Ta ni eni naa ti yoo da wa lebi
Ǹjẹ́ Kírísítì Yóò dá wa lẹ́bi
Nje Kirisiti Yoo da wa lebi
Bẹ́ẹ̀ kọ́! Òun ni ó kú fún wa tó sì tún jí ǹ de, nisínsin yìí, Òun jókòó ní ibi tí ó ga jùlọ tí ó lọ́lá, tí ó fara ti Ọlọ́run
Bee ko! Oun ni o ku fun wa to si tun ji n de, nisinsin yii, Oun jokoo ni ibi ti o ga julo ti o lola, ti o fara ti Olorun
Òun sì ń bẹ̀bẹ̀ fún wa lọ́run níbẹ̀
Oun si n bebe fun wa lorun nibe
Ta ni ó tilẹ̀ le yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kírísítì
Ta ni o tile le ya wa kuro ninu ife Kirisiti
Nígbà tí wàhálà tàbí ìdàmú bá dé, nígbà tí wọ́n bá já wa lulẹ̀ tàbí pa wá
Nigba ti wahala tabi idamu ba de, nigba ti won ba ja wa lule tabi pa wa
Ṣé nítórí pé Ọlọ́run kò fẹ́ràn wa mọ́ ni àwọn nǹkan wọ̀nyí yóò fi sẹlẹ̀ sí wa
Se nitori pe Olorun ko feran wa mo ni awon nnkan wonyi yoo fi sele si wa
Àti pé, Bí ebi bá ń pa wá, tàbí kò sí kọ́bọ̀ lọ́wọ́, tàbí a wà nínú ìsòro, tàbí ikú dẹ́rù bà wá, ǹjẹ́ Ọlọ́run ti fi wá sílẹ̀ bí
Ati pe, Bi ebi ba n pa wa, tabi ko si kobo lowo, tabi a wa ninu isoro, tabi iku deru ba wa, nje Olorun ti fi wa sile bi
Bẹ́ẹ̀ kọ́, nítorí ìwé mímọ́ sọ fún wa pé
Bee ko, nitori iwe mimo so fun wa pe
Nítorí yín àwa ní láti múra tan fún ikú nígbàkúgbà
Nitori yin awa ni lati mura tan fun iku nigbakugba
Àwa dàbí àgùntàn tí ń dúró de pípa
Awa dabi aguntan ti n duro de pipa
Ṣùgbọ́n nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ìṣẹ́gun ni ti wa nípaṣẹ̀ Kírísítì, ẹni tí ó fẹ́ wa tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó sì fi fún wa
Sugbon ninu gbogbo nnkan wonyi, isegun ni ti wa nipase Kirisiti, eni ti o fe wa to bee gee ti o si fi fun wa
Nítorí pé ó dá mi lójú gbangba pé, kò sí ohunkóhun tó lè yà wá nínú ìfẹ́ rẹ̀
Nitori pe o da mi loju gbangba pe, ko si ohunkohun to le ya wa ninu ife re
Kì í se ikú tàbí ìyè
Ki i se iku tabi iye
Àwọn ańgẹ́lì àti gbogbo agbára ọ̀run àpáàdì fún raarẹ̀ kò le ya ìfẹ́ Ọlọ́run kúrò lọ́dọ̀ wa
Awon angeli ati gbogbo agbara orun apaadi fun raare ko le ya ife Olorun kuro lodo wa
Ìbẹ̀rù fún wa lónìí, wàhálà nípa ti ọjọ́ ọ̀la
Iberu fun wa lonii, wahala nipa ti ojo ola
Tí ìsòro bá tilẹ̀ ga ju àwọ̀ sánmọ̀ lọ tàbí ní ìsàlẹ̀ omi, ohunkóhun kì yóò lágbára láti yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, èyí tí Jésù Kírísítì Olúwa fi hàn nígbà tí ó kú fún wa
Ti isoro ba tile ga ju awo sanmo lo tabi ni isale omi, ohunkohun ki yoo lagbara lati ya wa kuro ninu ife Olorun, eyi ti Jesu Kirisiti Oluwa fi han nigba ti o ku fun wa
Ọ̀rọ̀ Lórí Ìpinnu Àti Ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run
Oro Lori Ipinnu Ati Imotele Olorun
Ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, ìbátan mi nípa ti ara, ó wù mí púpọ̀ láti rí i pé ẹ gba Kírísítì gbọ́
Eyin omo Isireli, ibatan mi nipa ti ara, o wu mi pupo lati ri i pe e gba Kirisiti gbo
Ọkàn mi gbọgbẹ́, mo sì ń joró lọ́sán àti lóru nítorí yín
Okan mi gbogbe, mo si n joro losan ati loru nitori yin
Mo fẹ́ lọ sọ pé ó sàn fún mi kí a yọ orúkọ mi kúrò nínú ìwé Ìyè, kí ẹ̀yin lè rí ìgbàlà
Mo fe lo so pe o san fun mi ki a yo oruko mi kuro ninu iwe Iye, ki eyin le ri igbala
Kírísítì pàápàá àti ẹ̀mí mímọ́ pẹ̀lú mọ̀ pé òtítọ́ ọkàn mi ni èmi ń sọ yìí
Kirisiti paapaa ati emi mimo pelu mo pe otito okan mi ni emi n so yii
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ni Ọlọ́run ti fi fún yín
Opolopo nnkan ni Olorun ti fi fun yin
Ṣùgbọ́n síbẹ̀, ẹ kì yóò tẹ́tí sí i
Sugbon sibe, e ki yoo teti si i
Ó yàn yín bí ẹni ọ̀tọ̀ fún ara rẹ̀
O yan yin bi eni oto fun ara re
Ó sìn yín pẹ̀lú ìtànsán ògo rẹ̀, ó mú kí ó dá a yín lójú pé òun yóò bù kún yín, ó fi òfin fún yín kí ẹ le mọ ìfẹ́ rẹ̀ lójojúmọ́, ó yọ̀ǹda fún yín láti sin òun pẹ̀lú ìpinnu ńlá
O sin yin pelu itansan ogo re, o mu ki o da a yin loju pe oun yoo bu kun yin, o fi ofin fun yin ki e le mo ife re lojojumo, o yonda fun yin lati sin oun pelu ipinnu nla
Baba yín ni àwọn onígbàgbọ́ jàǹkànjàǹkàn àtijọ́ jẹ́
Baba yin ni awon onigbagbo jankanjankan atijo je
Ọ̀kan nínú yín ni Kírísítì fúnrara rẹ̀ jẹ́
Okan ninu yin ni Kirisiti funrara re je
Júù ni òun nínú ara, òun sì ni olùdarí ohun gbogbo
Juu ni oun ninu ara, oun si ni oludari ohun gbogbo
Ìyìn ló yẹ kí ẹ máa fifún Ọlọ́run láéláé
Iyin lo ye ki e maa fifun Olorun laelae
Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán
Sugbon ki i se pe oro Olorun di asan
Kì í sá íṣe gbogbo àwọn tí ó ti inú Ísírẹ́lì wá, àwọn ni Ísírẹ́lì
Ki i sa ise gbogbo awon ti o ti inu Isireli wa, awon ni Isireli
Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé, nítorí wọ́n jẹ́ irú ọmọ Ábúrámù, gbogbo wọn nii ọmọ
Bee ni ki i se pe, nitori won je iru omo Aburamu, gbogbo won nii omo
Ṣùgbọ́n, nínú Ísákì li a ó ti pe irú ọmọ rẹ̀
Sugbon, ninu Isaki li a o ti pe iru omo re
Èyí nì ni pé, kì í ṣe àwọn ọmọ nípa ti ara, ni ọmọ Ọlọ́run
Eyi ni ni pe, ki i se awon omo nipa ti ara, ni omo Olorun
ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìlérí ni a kà ní irú ọmọ
sugbon awon omo ileri ni a ka ni iru omo
Nítorí ọ̀rọ̀ ìlérí ni èyí
Nitori oro ileri ni eyi
Níwọ̀n àmọ́dún ni èmi yóò wá, Sárà yóò sì ní ọmọ ọkùnrin
Niwon amodun ni emi yoo wa, Sara yoo si ni omo okunrin
Kì sì íṣe kìkì èyí
Ki si ise kiki eyi
Ṣùgbọ́n nígbà tí Rèbékà pẹ̀lú lóyún fún ẹnìkan, fún Ísákì baba wa
Sugbon nigba ti Rebeka pelu loyun fun enikan, fun Isaki baba wa
Nítorí nígbà tí kò tí ì bá àwọn ọmọ náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tí ì ṣe rere tàbí búburú, A ti sọ fún un pé, Ẹ̀gbọ́n ni yóò máa sin àbúrò
Nitori nigba ti ko ti i ba awon omo naa, bee ni won ko ti i se rere tabi buburu, A ti so fun un pe, Egbon ni yoo maa sin aburo
Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé
Gege bi a ti ko o pe
Jákọ́bù ni mo fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Ísáù ni mo kóríra
Jakobu ni mo feran, sugbon Isau ni mo korira
Njẹ́ àwa yóò ha ti wí
Nje awa yoo ha ti wi
Àìsòdodo ha wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run bí
Aisododo ha wa lodo Olorun bi
Kí a má ri! Nítorí ó wí fún Mósè pé, Èmi ó sàánú fún ẹni tí èmi yóò sàánú fún, èmi yóò sì se ìyọ́nú fún ẹni tí èmi yóò se ìyọ́nú fún
Ki a ma ri! Nitori o wi fun Mose pe, Emi o saanu fun eni ti emi yoo saanu fun, emi yoo si se iyonu fun eni ti emi yoo se iyonu fun
Ǹjẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ti ẹni tí ó fẹ́, kì í sì í se ti ẹni tí ń sáré, bí kò se ti Ọlọ́run tí ń sàánú
Nje bee ni ki i se ti eni ti o fe, ki i si i se ti eni ti n sare, bi ko se ti Olorun ti n saanu
Nítorí ìwé mímọ́ wí fún Fáráò pé, Nítorí èyí ni mo ṣe gbé ọ dìde, kí èmi kí ó le fi agbára mi hàn lára rẹ, kí a sì le máa ròyìn orúkọ mi ká gbogbo ayé
Nitori iwe mimo wi fun Farao pe, Nitori eyi ni mo se gbe o dide, ki emi ki o le fi agbara mi han lara re, ki a si le maa royin oruko mi ka gbogbo aye
Nítorí náà ni ó ṣe sàánú fún ẹni tí ó wù ú, ẹni tí ó wù ú a sì mú lí ọkàn le
Nitori naa ni o se saanu fun eni ti o wu u, eni ti o wu u a si mu li okan le
Ìwọ ó sì wí fún mi pé, kínni ó ha tún bá ni wí fún
Iwo o si wi fun mi pe, kinni o ha tun ba ni wi fun
Nítorí tani ó ń de ìfẹ́ rẹ lọ́nà
Nitori tani o n de ife re lona
Bẹ́ẹ̀ kọ́, Ìwọ ènìyàn, tà ni ìwọ tí ń dá Ọlọ́run lóhùn
Bee ko, Iwo eniyan, ta ni iwo ti n da Olorun lohun
Ohun tí a mọ, a máa wí fún ẹni tí ó mọ ọn pé, Èéṣe tí ìwọ fi mọ mi báyì
Ohun ti a mo, a maa wi fun eni ti o mo on pe, Eese ti iwo fi mo mi bayi
Amọ̀kòkò kò ha ni agbára lórí àmọ̀, níní ìṣu kan náà láti ṣe apákan ní ohun èlò sí ọlá, àti apákan ní ohun èlò sí àìlọ́lá
Amokoko ko ha ni agbara lori amo, nini isu kan naa lati se apakan ni ohun elo si ola, ati apakan ni ohun elo si ailola
Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá fẹ́ fi ìbínú rẹ̀ hàn ń kọ́
Nje bi Olorun ba fe fi ibinu re han n ko
Tí ó sì fẹ́ sọ agbára rẹ̀ di mímọ̀, tí ó sì mú sùúrù púpọ̀ fún àwọn ohun èlò ìbínú tí a ṣe fún ìparun
Ti o si fe so agbara re di mimo, ti o si mu suuru pupo fun awon ohun elo ibinu ti a se fun iparun
Àti kí ó lè sọ ọ̀rọ̀ ògo rẹ̀ di mímọ̀ lára àwọn ohun èlò àánú tí ó ti pèsè ṣájú fún ògo, Àní àwa, tí ó ti pè, kì í ṣe nínú àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nínú àwọn aláìkọlà pẹ̀lú
Ati ki o le so oro ogo re di mimo lara awon ohun elo aanu ti o ti pese saju fun ogo, Ani awa, ti o ti pe, ki i se ninu awon Juu nikan, sugbon ninu awon alaikola pelu
Bí ó ti wí pẹ̀lú ní Hóséà pé, Èmi ó pe àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi, ní ènìyàn mi, àti ẹni tí kí í ṣe àyànfẹ́ ní àyànfẹ́
Bi o ti wi pelu ni Hosea pe, Emi o pe awon ti ki i se eniyan mi, ni eniyan mi, ati eni ti ki i se ayanfe ni ayanfe
Yóò sì ṣe, Ní ibi ti a gbé ti sọ fún wọn pé, ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi, níbẹ̀ ni a ó gbé ti sọ fún wọn pé, ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi, níbẹ̀ ni a ó gbé pè wọ́n ní ọmọ Ọlọ́run alààyè
Yoo si se, Ni ibi ti a gbe ti so fun won pe, eyin ki i se eniyan mi, nibe ni a o gbe ti so fun won pe, eyin ki i se eniyan mi, nibe ni a o gbe pe won ni omo Olorun alaaye
  Ìsáíà sì kí gbe nnítorí Ísírẹ́lì pé
  Isaia si ki gbe nnitori Isireli pe
Bí iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá rí bí iyanrìn etí òkun, apákan ni ó gbàlà
Bi iye awon omo Isireli ba ri bi iyanrin eti okun, apakan ni o gbala
Nítorí Olúwa yóò mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé, yóò parí rẹ̀, yóò sì ké e kúrò ní òdodo
Nitori Oluwa yoo mu oro re se lori ile aye, yoo pari re, yoo si ke e kuro ni ododo
Àti bí Ìsáià ti wí tẹ́lẹ̀
Ati bi Isaia ti wi tele
Bí kò ṣe bí Olúwa àwọn Ọmọ-ogun ti fi irú-ọmọ sílẹ̀ fún wa, àwa ìbá ti dàbí Sódómù, a bá sì ti sọ wá dàbí Gòmórà
Bi ko se bi Oluwa awon Omo-ogun ti fi iru-omo sile fun wa, awa iba ti dabi Sodomu, a ba si ti so wa dabi Gomora
Ǹjẹ́ kílí àwa ó ha wí
Nje kili awa o ha wi
Pé àwọn aláìkọlà, tí kò lépa òdodo, ọwọ́ wọn tẹ òdodo, ṣùgbọ́n òdodo tí ó ti inú ìgbàgbọ́ wá ni
Pe awon alaikola, ti ko lepa ododo, owo won te ododo, sugbon ododo ti o ti inu igbagbo wa ni
Ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì ti ń lépa òfin òdodo, ọwọ́ wọn kò tẹ òfin òdodo, Nítorí kíni
Sugbon Isireli ti n lepa ofin ododo, owo won ko te ofin ododo, Nitori kini
Nítorí wọn kò wá a nípa ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n bí ẹni pé nípa iṣẹ́ òfin
Nitori won ko wa a nipa igbagbo, sugbon bi eni pe nipa ise ofin
Nítorí wọn kọsẹ̀ lára òkúta ni
Nitori won kose lara okuta ni
Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé
Gege bi a ti ko o pe
Kíyèsi, mo gbé òkúta ìkọ̀sẹ̀ àti àpáta tí ó mú wọn subú kalẹ̀ ní Síónì, ẹnikẹ́ni ti ó bá sì gbà a gbọ́, ojú kì yóò tì í
Kiyesi, mo gbe okuta ikose ati apata ti o mu won subu kale ni Sioni, enikeni ti o ba si gba a gbo, oju ki yoo ti i
Náómì àti Rúùtù
Naomi ati Ruutu
Ní ìgbà tí àwọn onídaájọ́ ń ṣe àkóso ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ìyàn kan mú ní ilẹ̀ náà, ọkùnrin kan láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Júdà, òun àti aya rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjì lọ láti máa gbé ní ilẹ̀ Móábù fún ìgbà díẹ̀
Ni igba ti awon onidaajo n se akoso ile Isireli, iyan kan mu ni ile naa, okunrin kan lati Betilehemu ti Juda, oun ati aya re pelu awon omo re okunrin meji lo lati maa gbe ni ile Moabu fun igba die
Orúkọ ọkùnrin náà ń jẹ́ Elimélékì, orúkọ ìyàwó rẹ̀ ni Náómì, orúkọ àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì sì ni Málónì àti Kílíónì àwọn ará Éfúrétà, ti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Júdà
Oruko okunrin naa n je Elimeleki, oruko iyawo re ni Naomi, oruko awon omo re mejeeji si ni Maloni ati Kilioni awon ara Efureta, ti Betilehemu ti Juda
Wọ́n sì lọ sí ilẹ̀ Móábù, wọ́n ń gbé níbẹ̀
Won si lo si ile Moabu, won n gbe nibe
Ní àsìkò tí wọ́n ń gbé ibẹ̀, Elimélékì, ọkọ Náómì kú, ó sì ku òun pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjèèjì
Ni asiko ti won n gbe ibe, Elimeleki, oko Naomi ku, o si ku oun pelu awon omo re okunrin mejeeji
Wọ́n sì fẹ́ àwọn ọmọbìnrin ará Móábù méjì, orúkọ, ọ̀kan ń jẹ́ Órípà, èkejì sì ń jẹ́ Rúùtù
Won si fe awon omobinrin ara Moabu meji, oruko, okan n je Oripa, ekeji si n je Ruutu
Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sì ti gbé níbẹ̀ fún bí ọdún mẹ́wàá, Málónì àti Kílíónì náà sì kú, Náómì sì wà láìsí ọkọ tàbí ọmọ kankan fún-un mọ́
Leyin igba ti won si ti gbe nibe fun bi odun mewaa, Maloni ati Kilioni naa si ku, Naomi si wa laisi oko tabi omo kankan fun-un mo
Nígbà tí Náómì gbọ́ ní Móábù tí ó wà wí pé Olúwa ti bẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ wò nípa fí fún wọn ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ
Nigba ti Naomi gbo ni Moabu ti o wa wi pe Oluwa ti be awon eniyan re wo nipa fi fun won ni opo ounje
Ó sì dìde pẹ̀lú àwọn ìyàwó ọmọ rẹ̀ méjèèjì láti padà sí ìlú rẹ̀
O si dide pelu awon iyawo omo re mejeeji lati pada si ilu re
Òun pẹ̀lú àwọn ìyàwó ọmọ rẹ̀ méjèèjì ni wọ́n jọ fi ibi tí ó ń gbé sílẹ̀ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò wọn padà sí ilẹ̀ Júdà
Oun pelu awon iyawo omo re mejeeji ni won jo fi ibi ti o n gbe sile ti won si bere irin-ajo won pada si ile Juda
Ṣùgbọ́n ní ojú ọ̀nà, Náómì wí fún àwọn aya ọmọ rẹ̀ méjèèjì pé, Kí ẹnikọ̀ọ̀kan yín padà sí ilé ìyá rẹ̀
Sugbon ni oju ona, Naomi wi fun awon aya omo re mejeeji pe, Ki enikookan yin pada si ile iya re
Kí Olúwa ṣe àánú fún yín bí ẹ ti ṣe sí èmi àti àwọn ọkọ yín tí ó kú
Ki Oluwa se aanu fun yin bi e ti se si emi ati awon oko yin ti o ku
Kí Olúwa kí ó fi yín lọ́kàn balẹ̀ ní ilé ọkọ mìíràn
Ki Oluwa ki o fi yin lokan bale ni ile oko miiran
Náómì sì fi ẹnu kò wọ́n ní ẹnu wí pé Ó dìgbà, Wọ́n sì sunkún kíkan kíkan
Naomi si fi enu ko won ni enu wi pe O digba, Won si sunkun kikan kikan
Wọ́n sì wí fún-un pé, Rárá, a ó bà ọ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ
Won si wi fun-un pe, Rara, a o ba o lo si odo awon eniyan re