diacritcs
stringlengths 1
36.7k
| no_diacritcs
stringlengths 1
35.5k
|
---|---|
Nítorí pé nígbà tí ẹ ti di òkú fún ẹ̀ṣẹ̀, a ti gbà yín sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ gbogbo agbára ẹ̀ṣẹ̀ | Nitori pe nigba ti e ti di oku fun ese, a ti gba yin sile kuro lowo gbogbo agbara ese |
Ẹ̀ṣẹ̀ kò ní agbára lórí yín mọ́ Níwọ̀n ìgbà tí ògbólógbòó ara yín tó ń fẹ́ máa dẹ́sẹ̀ ti kú pẹ̀lú Kírísítì, àwa mọ̀ pé, ẹ̀yin yóò pín nínú ìyè titun rẹ̀ | Ese ko ni agbara lori yin mo Niwon igba ti ogbologboo ara yin to n fe maa dese ti ku pelu Kirisiti, awa mo pe, eyin yoo pin ninu iye titun re |
Kírísítì ti jí dìde kúrò nínú òkú | Kirisiti ti ji dide kuro ninu oku |
Òun kò sì ní kú mọ́ | Oun ko si ni ku mo |
Ikú kò sì lè ní agbára lórí rẹ̀ mọ́ | Iku ko si le ni agbara lori re mo |
Kírísítì kú lẹ́ẹ̀kan soso, láti sẹ́gun agbára ẹ̀ṣẹ̀ | Kirisiti ku leekan soso, lati segun agbara ese |
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó wà láàyè títí ayé àìnípẹ̀kun ní ìdàpọ̀ mímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run | Sugbon nisinsin yii, o wa laaye titi aye ainipekun ni idapo mimo pelu Olorun |
Nítorí náà, ẹ máa wo ògbólógbòó ara ẹ̀ṣẹ̀ yín gẹ́gẹ́ bí òkú tí kò ní ohunkóhun í ṣe pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ | Nitori naa, e maa wo ogbologboo ara ese yin gege bi oku ti ko ni ohunkohun i se pelu ese mo |
Dípò èyí, máa gbé ìgbé ayé yín fún Ọlọ́run nìkan ṣoṣo | Dipo eyi, maa gbe igbe aye yin fun Olorun nikan soso |
Ẹ dúró gbọn-in gbọn-in fún un, nípasẹ̀ Jésù Kírísítì Olúwa wa | E duro gbon-in gbon-in fun un, nipase Jesu Kirisiti Oluwa wa |
Nítorí náà kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀sẹ̀ jọba lórí ara kíkú yín kí ó lè ba à máa ṣe ìfẹ́kùfẹ̀ẹ̀ rẹ̀ | Nitori naa ki e ma se je ki ese joba lori ara kiku yin ki o le ba a maa se ifekufee re |
Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀yà ara yín kan di ohun èlò ìkà, nípa ẹ̀ṣẹ̀ dídá | E ma se je ki eya ara yin kan di ohun elo ika, nipa ese dida |
Ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ǹda wọn fún Ọlọ́run pátápátá | Sugbon e yonda won fun Olorun patapata |
Wọ́n ti di ààyè, ẹ jẹ́ kí wọn di ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run, kí ó lè lò wọ́n fún àwọn ìlànà rẹ̀ tí ó dára | Won ti di aaye, e je ki won di ohun elo ni owo Olorun, ki o le lo won fun awon ilana re ti o dara |
Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ kì yóò tún ní ipá lórí yín mọ́, nítorí ẹ̀yin kò sí lábẹ́ ìdè òfin, bí kò ṣe lábẹ́ oore-ọ̀fẹ́ | Nitori ese ki yoo tun ni ipa lori yin mo, nitori eyin ko si labe ide ofin, bi ko se labe oore-ofe |
Ǹjẹ́ èyí túmọ̀ sí pé, nísinsinyìí, a lè tẹ̀ṣíwájú láti máa dẹ́ṣẹ̀ láì bìkítà | Nje eyi tumo si pe, nisinsinyii, a le tesiwaju lati maa dese lai bikita |
Àbí ẹ̀yin kò mọ̀ pé, ẹnikẹ́ni lè yan ọ̀gá tí ó bá fẹ́ | Abi eyin ko mo pe, enikeni le yan oga ti o ba fe |
Ẹ lè yan ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ìgbọ́ràn | E le yan ese tabi igboran |
Ẹnikẹ́ni tí ẹ bá yọ̀ǹda ara yín fún, òun náà ni yóò jẹ́ ọ̀gá yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ẹrú rẹ̀ | Enikeni ti e ba yonda ara yin fun, oun naa ni yoo je oga yin, eyin yoo si je eru re |
Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yin ti se ìgbọ́ràn, pẹ̀lú ọkàn yín, sí ẹ̀kọ́ èyí tí Ọlọ́run fi lé yín lọ́wọ́ | Ope ni fun Olorun pe, bi o tile je pe eyin ti se igboran, pelu okan yin, si eko eyi ti Olorun fi le yin lowo |
Nísinsìnyìí, ẹ ti dòminira kúrò lọ́wọ́ ọ̀gá yín àtijọ́, èyí tíí ṣe ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti di ẹrú ọ̀gá tuntun èyí ni òdodo | Nisinsinyii, e ti dominira kuro lowo oga yin atijo, eyi tii se ese, e si ti di eru oga tuntun eyi ni ododo |
Èmi ń sọ̀rọ̀ lọ́nà báyìí, ní lílo àpèjúwe àwọn ẹrú àti àwọn ọ̀gá nítorí kí ó ba le yé yín | Emi n soro lona bayii, ni lilo apejuwe awon eru ati awon oga nitori ki o ba le ye yin |
Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fi ìgbà kan jẹ́ ẹrú sí oríṣiríṣi ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ ní láti di ẹrú gbogbo èyí tíi ṣe rere tí ó sì jẹ́ Mímọ́ | Gege bi e ti fi igba kan je eru si orisirisi ese, bee gege, e ni lati di eru gbogbo eyi tii se rere ti o si je Mimo |
Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin kò ṣe wàhálà púpọ̀ pẹ̀lú òdodo | Ni ojo won-on-ni nigba ti eyin je eru ese, eyin ko se wahala pupo pelu ododo |
Àti pé, kí ni ìyọrísí rẹ̀ | Ati pe, ki ni iyorisi re |
Dájúdájú àbájáde rẹ̀ kò dára | Dajudaju abajade re ko dara |
Níwọ̀n ìgbà tí ojú ń tì ọ́ nísinsìnyìí láti ronu nípa àwọn wọ̀n-ọn-nì tí o ti máa ń sọ nítorí gbogbo wọn yọrí sí ìparun ayérayé | Niwon igba ti oju n ti o nisinsinyii lati ronu nipa awon won-on-ni ti o ti maa n so nitori gbogbo won yori si iparun ayeraye |
Ṣùgbọ́n báyìí, ẹ ti bọ́ kúrò lọ́wọ́ agbára ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti di ìránṣẹ́ Ọlọ́run àwọn ìbùkún rẹ̀ sí yin ni ìwà mímọ́ àti ìyè tí kò nípẹ̀kun | Sugbon bayii, e ti bo kuro lowo agbara ese, e si ti di iranse Olorun awon ibukun re si yin ni iwa mimo ati iye ti ko nipekun |
Nítorí ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn Ọlọ́run ni ìyè àìnípẹ̀kun nípaṣẹ̀ Jésù Kírísítì Olúwa wa | Nitori iku ni ere ese, sugbon ebun Olorun ni iye ainipekun nipase Jesu Kirisiti Oluwa wa |
Àpèjúwe Kan Láti Inú Ìgbèyàwó | Apejuwe Kan Lati Inu Igbeyawo |
Ẹ̀yin kò ha mọ̀, ara | Eyin ko ha mo, ara |
nítorí èmí bá àwọn tí ó mọ òfin sọ̀rọ̀ pé, òfin ní ipá lórí ènìyàn níwọ̀n ìgbà tí ó bá wà láàyè nìkan | nitori emi ba awon ti o mo ofin soro pe, ofin ni ipa lori eniyan niwon igba ti o ba wa laaye nikan |
Fún àpẹẹrẹ, nípa òfin ní a de obìnrin mọ́ ọkọ rẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ náà wà láàyè, ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá kú, a tú u sílẹ̀ kúrò nínú òfin ìgbéyàwó náà | Fun apeere, nipa ofin ni a de obinrin mo oko re niwon igba ti oko naa wa laaye, sugbon bi oko re ba ku, a tu u sile kuro ninu ofin igbeyawo naa |
Nígbà náà, bí ó bá fẹ́ ọkùnrin mìíràn nígbà tí ọkọ rẹ̀ wà láàyé, panṣagà ní a ó pè é | Nigba naa, bi o ba fe okunrin miiran nigba ti oko re wa laaye, pansaga ni a o pe e |
Ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó bọ́ lọ́wọ́ òfin náà, kí yóòsì jẹ́ panṣagà, kódà bí ó bá ní ọkọ mìíràn | Sugbon bi oko re ba ku, o bo lowo ofin naa, ki yoosi je pansaga, koda bi o ba ni oko miiran |
Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ará mi, ẹ̀yin pẹ̀lú ti di òkú sí òfin nípa ara Kírísítì, kí ẹ̀yin kí ó lè ní ẹlòmìíràn, àní ẹni náà tí a jí dìde kúrò nínú òkú, kí àwa kí ó lè so èso fún Ọlọ́run Nítorí ìgbà tí ìfẹ́kúfẹ́ ara ń darí wa, ar ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà nípa òfin, ó ń ṣisẹ́ nínú àwọn ara wa láti so èso fún ikú | Bee ni eyin ara mi, eyin pelu ti di oku si ofin nipa ara Kirisiti, ki eyin ki o le ni elomiiran, ani eni naa ti a ji dide kuro ninu oku, ki awa ki o le so eso fun Olorun Nitori igba ti ifekufe ara n dari wa, ar ese ti o wa nipa ofin, o n sise ninu awon ara wa lati so eso fun iku |
Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí, nípa kíkú láti ipasẹ̀ ohun tó so wápọ̀ tẹ́lẹ̀ rí, a ti tú wa sílẹ̀ kúrò nínú òfin, kí a lè sin ín ní ìlànà tuntun ti Ẹ̀mí, kì í se ní ìlànà ti àtijọ́ tí òfin gùnlé | Sugbon nisinsin yii, nipa kiku lati ipase ohun to so wapo tele ri, a ti tu wa sile kuro ninu ofin, ki a le sin in ni ilana tuntun ti Emi, ki i se ni ilana ti atijo ti ofin gunle |
Ǹjẹ́ àwa o ha ti wí, nígbà náà | Nje awa o ha ti wi, nigba naa |
Òfin ha ń ṣe ẹ̀ṣẹ̀ bí | Ofin ha n se ese bi |
Kí a má rí i! Ṣùgbọ́n èmi kì bá tí mọ ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́, bí kò ṣe nípa òfin | Ki a ma ri i! Sugbon emi ki ba ti mo ohun ti ese je, bi ko se nipa ofin |
Èmi kì bá tí mọ ojúkòkòrò, bí kò ṣe bí òfin ti wí pé, Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò | Emi ki ba ti mo ojukokoro, bi ko se bi ofin ti wi pe, Iwo ko gbodo se ojukokoro |
Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ sì ti ipa òfin rí àyè ṣíṣẹ onírúurú ìfẹ́kúfẹ́ nínú mi | Sugbon ese si ti ipa ofin ri aye sise oniruuru ifekufe ninu mi |
Nítorí láìsí òfin, ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ikú | Nitori laisi ofin, ese je iku |
Èmi sì ti wà láàyè láìsí òfin nígbà kan rí | Emi si ti wa laaye laisi ofin nigba kan ri |
ṣùgbọ́n nígbà tí òfin dé, ẹ̀ṣẹ̀ sọjí èmi sì kú | sugbon nigba ti ofin de, ese soji emi si ku |
Mo ṣàkíyèsí pé òfin tí ó yẹ kí ó mú ìyè wá ni ó padà mú ikú wá | Mo sakiyesi pe ofin ti o ye ki o mu iye wa ni o pada mu iku wa |
Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ti ipa òfin rí àyè láti tàn mí jẹ, ó sì ti ipa òfin se ikú pa mi | Nitori ese ti ipa ofin ri aye lati tan mi je, o si ti ipa ofin se iku pa mi |
Bẹ́ẹ̀ ni mímọ́ ni òfin, mímọ́ sì ni àṣẹ, àti òdodo, àti dídára | Bee ni mimo ni ofin, mimo si ni ase, ati ododo, ati didara |
Ǹjẹ́ ohun tí ó dára ha di ikú fún mi bí | Nje ohun ti o dara ha di iku fun mi bi |
Kí a má rí i! Ṣùgbọ́n kí ẹ̀ṣẹ̀, kí ó lè farahàn bí ẹ̀ṣẹ̀, ó ń ti ipa ohun tí ó dára ṣiṣẹ́ ikú nínú mi, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè ti ipa òfin di búburú rékọjá | Ki a ma ri i! Sugbon ki ese, ki o le farahan bi ese, o n ti ipa ohun ti o dara sise iku ninu mi, ki ese le ti ipa ofin di buburu rekoja |
Nítorí àwa mọ̀ pé ohun ẹ̀mí ni òfin | Nitori awa mo pe ohun emi ni ofin |
ṣùgbọ́n ẹni ti ara ni èmi, tí a ti tà sábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ | sugbon eni ti ara ni emi, ti a ti ta sabe ese |
Èmi pàápàá, kò mọ̀ ohun tí èmi ń se | Emi paapaa, ko mo ohun ti emi n se |
Nítorí pé, ohun tí mo fẹ́ se gan an n kò se é, ṣùgbọ́n ohun tí mo kóríra ni mo ń se | Nitori pe, ohun ti mo fe se gan an n ko se e, sugbon ohun ti mo korira ni mo n se |
Ṣùgbọ́n bí mo bá se ohun tí èmi kò fẹ́, mo gbà pé òfin dára | Sugbon bi mo ba se ohun ti emi ko fe, mo gba pe ofin dara |
Ṣùgbọ́n bí ọ̀rọ̀ se rí yìí kì í se èmi ni ó se é bí kò se ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi | Sugbon bi oro se ri yii ki i se emi ni o se e bi ko se ese ti n gbe inu mi |
Èmi mọ̀ dájú pé kò sí ohun tí ó dára kan tí ń gbé inú mi, àní, nínú ara ẹ̀ṣẹ mi | Emi mo daju pe ko si ohun ti o dara kan ti n gbe inu mi, ani, ninu ara ese mi |
Èmi fẹ́ se èyí tí ó dára, ṣùgbọ́n kò sé é ṣe | Emi fe se eyi ti o dara, sugbon ko se e se |
Níorí ohun tí èmi se kì í se ohun rere tí èmi fẹ́ láti se | Niori ohun ti emi se ki i se ohun rere ti emi fe lati se |
rárá, ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò fẹ́, éyí nì ni èmi ń se | rara, sugbon buburu ti emi ko fe, eyi ni ni emi n se |
Nísinsin yìí, bí mo bá ń se nǹkan tí n kò fẹ́ láti se, kì í se ẹ̀mi fúnra mi ni ó se é, bí kò se ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ nínú ni ó se é | Nisinsin yii, bi mo ba n se nnkan ti n ko fe lati se, ki i se emi funra mi ni o se e, bi ko se ese ti n be ninu ni o se e |
Nítorí náà, èmi kíyèsi pé òfin ní ń ṣiṣẹ́ nínú mi | Nitori naa, emi kiyesi pe ofin ni n sise ninu mi |
nígbà tí èmi bá fẹ́ se rere, búburú wà níbẹ̀ pẹ̀lú mi | nigba ti emi ba fe se rere, buburu wa nibe pelu mi |
Nínú ìjìnlẹ̀ ọkàn mi mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run | Ninu ijinle okan mi mo ni inu didun si ofin Olorun |
mo rí òfin mìíràn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yà ara mi, èyí tí ń gbógun ti òfin tó tinú ọkàn mi wá, èyí tí ó sọ mi di ẹrú òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yà ara mi | mo ri ofin miiran to n sise ninu eya ara mi, eyi ti n gbogun ti ofin to tinu okan mi wa, eyi ti o so mi di eru ofin ese ti o n sise ninu eya ara mi |
Èmi ẹni òsì! Ta ni yóò ha gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ara ikú yìí | Emi eni osi! Ta ni yoo ha gba mi sile lowo ara iku yii |
Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kírísítì Olúwa wa! Ǹjẹ́ nítorí náà, èmi fúnraà mi jẹ́ ẹrú sí òfin Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nínú ara ẹ̀ṣẹ̀ mo jẹ́ ẹrú fún òfin ẹ̀ṣẹ̀ | Ope ni fun Olorun nipase Jesu Kirisiti Oluwa wa! Nje nitori naa, emi funraa mi je eru si ofin Olorun, sugbon ninu ara ese mo je eru fun ofin ese |
Ìyè Nípaṣẹ̀ Ẹ̀mí | Iye Nipase Emi |
Nítorí náà, kò sí ìdálẹ́bi nísinsinyìí fún àwọn tí ó wà nínú Kírísitì | Nitori naa, ko si idalebi nisinsinyii fun awon ti o wa ninu Kirisiti |
Nítorí nípaṣẹ̀òfin ti ẹ̀mí ìyè nínú Kírísítì Jésù ti sọ mí di òmìnira kúrò lọ́wọ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú | Nitori nipaseofin ti emi iye ninu Kirisiti Jesu ti so mi di ominira kuro lowo ofin ese ati iku |
Nítorí ohun tí òfin kò lè ṣe, bí ó ti jẹ aláìlera nítorí ara, Ọlọ́run rán ọmọ òun tìkara rẹ̀ ní àwòrán ara ẹ̀ṣẹ̀, ó sì dá ẹ̀ṣẹ̀ | Nitori ohun ti ofin ko le se, bi o ti je alailera nitori ara, Olorun ran omo oun tikara re ni aworan ara ese, o si da ese |
àti bi ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, ó sì dá ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́bi nínú ara, | ati bi ebo fun ese, o si da ese lebi ninu ara, |
Kí a lè mú òdodo òfin ṣẹ, nínú wa, nítorí tí àwa ve gẹ́gẹ́ bí ohun ti ara, bí kò ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun ti Ẹ̀mí | Ki a le mu ododo ofin se, ninu wa, nitori ti awa ve gege bi ohun ti ara, bi ko se gege bi ohun ti Emi |
Àwọn tí ń ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun ti ara, wọn a máa ronú ohun ti ara | Awon ti n se gege bi ohun ti ara, won a maa ronu ohun ti ara |
ṣùgbọ́n àwọn ti ń e gẹ́gẹ́ bí ohun ti Ẹ̀mí, wọn a máa ronú ohun ti Ẹ̀mí | sugbon awon ti n e gege bi ohun ti Emi, won a maa ronu ohun ti Emi |
Ṣíṣe ìgbọ́ran sí ẹ̀mí Mímọ́ ń yọrí sí ìyè àti àlàáfíà | Sise igboran si emi Mimo n yori si iye ati alaafia |
Ṣùgbọ́n títẹ̀lé ara ẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ náà ń yọrí sí ikú | Sugbon titele ara ese atijo naa n yori si iku |
Nítorí pé ara ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú wa ń tako Ọlọ́run | Nitori pe ara ese ti n gbe inu wa n tako Olorun |
Ìdí nì yìí tí àwọn tí ó wà lábẹ́ àkóso ara ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n sì ń tẹ̀lé ìfẹ́ ibi wọn, kò le è tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn | Idi ni yii ti awon ti o wa labe akoso ara ese ti won si n tele ife ibi won, ko le e te Olorun lorun |
Ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ rárá | Sugbon ko ri bee rara |
Ara titun yín ni yóò máa se àkóso yín bí ẹ bá ń rìn nípa ẹ̀mí Ọlọ́run tí ń gbé inú yín Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Kírísítì ń gbé inú yín ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, ẹran ara yín yóò kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ | Ara titun yin ni yoo maa se akoso yin bi e ba n rin nipa emi Olorun ti n gbe inu yin Bi o tile je pe Kirisiti n gbe inu yin sibesibe, eran ara yin yoo ku nitori ese |
ṣùgbọ́n ẹ̀mí mímọ́ tí ń gbé inú yín yóò fún yín ní ìyè, nítorí ó ti fún un yín ní òdodo | sugbon emi mimo ti n gbe inu yin yoo fun yin ni iye, nitori o ti fun un yin ni ododo |
Àti pé, bí ẹ̀mí Ọlọ́run, ẹni tí ó jí Jésù kúrò nínú òkú bá ń gbé inú yín, òun yóò mú kí ara yín tí ó kú tún wà láàyè nípa sẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ kan náà tí ń gbé inú yín | Ati pe, bi emi Olorun, eni ti o ji Jesu kuro ninu oku ba n gbe inu yin, oun yoo mu ki ara yin ti o ku tun wa laaye nipa se emi mimo kan naa ti n gbe inu yin |
Nítorí náà ará, kò jẹ́ ọ̀rọ̀ iyàn fún un yín láti se nǹkan tí ara ẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ ń rọ̀ yín láti se | Nitori naa ara, ko je oro iyan fun un yin lati se nnkan ti ara ese atijo n ro yin lati se |
Nítorí pé bí ẹ̀yin bá ń tẹ̀lé, ẹ̀ṣẹ̀ ti ara ẹ̀yin yóò sọnù, ẹ ó sì sègbé, ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé nípaṣẹ̀ agbára ẹ̀mí mímọ́, ẹ̀yin sẹ́gun ẹ̀mí ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ ibi rẹ̀ nínú yín, ẹ̀yin yóò yè | Nitori pe bi eyin ba n tele, ese ti ara eyin yoo sonu, e o si segbe, sugbon bi o ba je pe nipase agbara emi mimo, eyin segun emi ese pelu awon ise ibi re ninu yin, eyin yoo ye |
Nítorí pé, iye àwọn tí ẹ̀mí Ọlọ́run bá ń darí ni ọmọ Ọlọ́run | Nitori pe, iye awon ti emi Olorun ba n dari ni omo Olorun |
Àti pé, àwa kò ní láti dàbí ẹrú tó ń fi ìbẹ̀rù tẹríba fún ọ̀gá rẹ̀ | Ati pe, awa ko ni lati dabi eru to n fi iberu teriba fun oga re |
Ṣùgbọ́n a ní láti hùwà bí ọmọ Ọlọ́run | Sugbon a ni lati huwa bi omo Olorun |
Ẹni tí a sọdọmọ sí ìdílé, Ọlọ́run tó sì ń pe Ọlọ́run ní Baba, Baba | Eni ti a sodomo si idile, Olorun to si n pe Olorun ni Baba, Baba |
Nítorí ẹ̀mí mímọ́ ń sọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú ọkàn wa, ó sì ń sọ fún wa pé, ní tòótọ́, àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run | Nitori emi mimo n soro ijinle ninu okan wa, o si n so fun wa pe, ni tooto, awa je omo Olorun |
Níwọ̀n ìgbà tí a jẹ́ ọmọ rẹ̀, àwa yóò pín nínú dúkìá rẹ̀ | Niwon igba ti a je omo re, awa yoo pin ninu dukia re |
Nítorí nǹkan gbogbo tí Ọlọ́run fún Jésù ọmọ rẹ̀ jẹ́ tiwa pẹ̀lú, ṣùgbọ́n bí á bá ní láti pín ògo rẹ̀, a ní láti setan láti pín nínú ìjìyà rẹ̀ | Nitori nnkan gbogbo ti Olorun fun Jesu omo re je tiwa pelu, sugbon bi a ba ni lati pin ogo re, a ni lati setan lati pin ninu ijiya re |
Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, ìyà tí a ń jẹ nísinsin yìí kò já mọ́ nǹkan nígbà tí a bá fiwé ògo tí yóò fún wa ní ìkẹyìn | Sibesibe, iya ti a n je nisinsin yii ko ja mo nnkan nigba ti a ba fiwe ogo ti yoo fun wa ni ikeyin |
Nítorí ẹ̀dá ń dúró ní ìfojúsọ́nà de ìfihàn àwọn ọmọ Ọlọ́run | Nitori eda n duro ni ifojusona de ifihan awon omo Olorun |
Nítórí a tẹrí ẹ̀dá ba fún asán, kì í se bí òun ti fẹ́, ṣùgbọ́n nípa ìfẹ́ ẹni tí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní ìrètí | Nitori a teri eda ba fun asan, ki i se bi oun ti fe, sugbon nipa ife eni ti o te ori re ba ni ireti |
Nítorí a ó sọ ẹ̀dá tìkáararẹ̀ di òmìnira kúrò nínú ẹrú ìdibàjẹ́, sí òmìnira ògo àwọn ọmọ Ọlọ́run | Nitori a o so eda tikaarare di ominira kuro ninu eru idibaje, si ominira ogo awon omo Olorun |
Nítorí àwa mọ̀ pé gbogbo ẹ̀dá ni ó jùmọ̀ ń kérora tí ó sì ń rọbí pọ̀ títí di ìsinsin yìí | Nitori awa mo pe gbogbo eda ni o jumo n kerora ti o si n robi po titi di isinsin yii |
Kì í se àwọn nìkan, ṣùgbọ́n àwa tìkara wa pẹ̀lú, tí ó nbí àkóso ẹ̀mí, àní àwa tìkara wa ń kérora nínú ara wa, àwa ń dúró de ìṣọdọmọ àní ìdáńdè ara wa | Ki i se awon nikan, sugbon awa tikara wa pelu, ti o nbi akoso emi, ani awa tikara wa n kerora ninu ara wa, awa n duro de isodomo ani idande ara wa |
Nítorí ìrètí tí a fi gbà wá là | Nitori ireti ti a fi gba wa la |
ṣùgbọ́n ìrètí tí a bá rí kì í se ìrètí nítorí ta ni ń retí ohun tí ó bá rí | sugbon ireti ti a ba ri ki i se ireti nitori ta ni n reti ohun ti o ba ri |