diacritcs
stringlengths
1
36.7k
no_diacritcs
stringlengths
1
35.5k
Ṣùgbọ́n Náómì dáhùn wí pé, Ẹ padà sílé ẹ̀yin ọmọ mi
Sugbon Naomi dahun wi pe, E pada sile eyin omo mi
Nítorí kí ni ẹ fi fẹ́ wá pẹ̀lú mi
Nitori ki ni e fi fe wa pelu mi
Ṣé mo tún le bí àwọn ọmọkùnrin mìíràn ni, tí ó le se ọkọ yin
Se mo tun le bi awon omokunrin miiran ni, ti o le se oko yin
Ẹ padà sílé, ẹ̀yin ọmọ mi, mo ti dàgbà jù láti ní ọkọ mìíràn
E pada sile, eyin omo mi, mo ti dagba ju lati ni oko miiran
Bí mo ti lẹ̀ ní èrò wí pé ìrètí sì wà fún mi, tí mo sì fẹ́ ọkọ mìíràn lónìí tí mo sì bí àwọn ọmọkùnrin mìíràn, ṣé ẹ̀yin le è dúró dìgbà tí wọ́n bá dàgbà láì fẹ́ ọkọ mìíràn nítorí wọn ni
Bi mo ti le ni ero wi pe ireti si wa fun mi, ti mo si fe oko miiran lonii ti mo si bi awon omokunrin miiran, se eyin le e duro digba ti won ba dagba lai fe oko miiran nitori won ni
Rárá, ẹ̀yin ọmọbìnrin mi
Rara, eyin omobinrin mi
Ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ fún mi ju bí ó ti jẹ́ fún ẹ̀yin lọ nítorí pé ọwọ́ Olúwa ti fìyà jẹ mi lọ́nà tó pamí lára gidi
O je ohun ibanuje fun mi ju bi o ti je fun eyin lo nitori pe owo Oluwa ti fiya je mi lona to pami lara gidi
Lẹ́ẹ̀kan sí i, wọ́n tún sunkún kíkorò
Leekan si i, won tun sunkun kikoro
Nígbà náà ní Órípà fi ẹnu ko ìyá ọkọ rẹ̀ ní ẹnu wí pé ó dìgbà, ṣùgbọ́n Rúùtù dì mọ́ ọn síbẹ̀
Nigba naa ni Oripa fi enu ko iya oko re ni enu wi pe o digba, sugbon Ruutu di mo on sibe
Náómì wí pé, Wòó, arábìnrin rẹ ti padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ àti òrìṣà rẹ̀, ìwọ náà padà pẹ̀lú rẹ̀
Naomi wi pe, Woo, arabinrin re ti pada lo si odo awon eniyan re ati orisa re, iwo naa pada pelu re
Ṣùgbọ́n Rúùtù dáhùn wí pé, Má ṣe rọ̀ mí láti fi ọ́ sílẹ̀ tàbí láti padà lẹ́yìn rẹ
Sugbon Ruutu dahun wi pe, Ma se ro mi lati fi o sile tabi lati pada leyin re
Ibi tí o bá lọ ní èmi yóò lọ, ibi ti ó bá dúró ni èmi yóò dúró, àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run, mi, Nibi tí o bá kú sí ni èmi yóò kú sí, níbẹ̀ ni wọn yóò sì sin mí sí
Ibi ti o ba lo ni emi yoo lo, ibi ti o ba duro ni emi yoo duro, awon eniyan re ni yoo je eniyan mi, Olorun re ni yoo si je Olorun, mi, Nibi ti o ba ku si ni emi yoo ku si, nibe ni won yoo si sin mi si
Kí Olúwa jẹ mí ní ìyà tí ó lágbára, bí ohunkóhun bí kò ṣe ikú bá yà wá
Ki Oluwa je mi ni iya ti o lagbara, bi ohunkohun bi ko se iku ba ya wa
Nígbà tí Náómì rí i wí pé Rúùtù ti pinnu láti tẹ̀lé òun kò rọ̀ láti padà mọ́
Nigba ti Naomi ri i wi pe Ruutu ti pinnu lati tele oun ko ro lati pada mo
Àwọn méjèèjì sì ń lọ títí wọ́n fi dé ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù
Awon mejeeji si n lo titi won fi de ilu Betilehemu
Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, ariwo ìpadàbọ̀ wọn gba ìlú kan, àwọn obìnrin ibẹ̀ sì kígbe ní ohùn rara wí pé, Náómì ni èyí bí
Nigba ti won de ibe, ariwo ipadabo won gba ilu kan, awon obinrin ibe si kigbe ni ohun rara wi pe, Naomi ni eyi bi
Náómì sì dáhùn wí pé, Ẹ má ṣe pè mí ní Náómì
Naomi si dahun wi pe, E ma se pe mi ni Naomi
Ẹ pè mí ní Márà , nítorí wí pé Olódùmarè ti mú kí ayé mi di kíkorò
E pe mi ni Mara , nitori wi pe Olodumare ti mu ki aye mi di kikoro
Mo jáde ní kíkún, ṣùgbọ́n Olúwa mú mi padà ní òfo
Mo jade ni kikun, sugbon Oluwa mu mi pada ni ofo
Nítorí náà kíń ló dé tí ẹ fi ń pè mí ní Náómì, nígbà tí Olódùmarè ti kọ̀ mí sílẹ̀, tí ó sì mú ìdààmú bá mi
Nitori naa kin lo de ti e fi n pe mi ni Naomi, nigba ti Olodumare ti ko mi sile, ti o si mu idaamu ba mi
Báyìí ni Náómì ṣe padà láti Móábù pẹ̀lú Rúùtù, ará Móábù ìyàwó ọmọ rẹ̀
Bayii ni Naomi se pada lati Moabu pelu Ruutu, ara Moabu iyawo omo re
Wọ́n gúnlẹ̀ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà bálì
Won gunle si Betilehemu ni ibere ikore oka bali
Rúùtù Pàdé Bóásì
Ruutu Pade Boasi
Náómì ní ìbátan kan láti ìdílé Elimélékì ọkọ rẹ̀, aláàánú ọlọ́rọ̀, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bóásì
Naomi ni ibatan kan lati idile Elimeleki oko re, alaaanu oloro, eni ti oruko re n je Boasi
Rúùtù, ará Móábù sì wí fún Náómì pé, Jẹ́ kí èmi kí ó lọ sí inú oko láti ṣa ọkà tí àwọn olùkórè fi sílẹ̀ ní ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni tí èmi yóò bá ojú rere rẹ̀ pàdé
Ruutu, ara Moabu si wi fun Naomi pe, Je ki emi ki o lo si inu oko lati sa oka ti awon olukore fi sile ni odo enikeni ti emi yoo ba oju rere re pade
Náómì sì sọ fún-un pé, Má a lọ, ọmọbìnrin mi
Naomi si so fun-un pe, Ma a lo, omobinrin mi
Rúùtù sì jáde lọ láti ṣa ọkà tí àwọn olùkórè fi sílẹ̀ lẹ́yìn wọn
Ruutu si jade lo lati sa oka ti awon olukore fi sile leyin won
Ó wá jẹ́ wí pé inú oko Bóásì tí ó ti ìdílé Elimélékì wá ni ó lọ láé mọ̀ ọ́ mọ̀
O wa je wi pe inu oko Boasi ti o ti idile Elimeleki wa ni o lo lae mo o mo
Nígbà náà ni Bóásì dé láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí ó sì kí àwọn olùkórè wí pé, Kí Olúwa wà pẹ̀lú yín
Nigba naa ni Boasi de lati Betilehemu ti o si ki awon olukore wi pe, Ki Oluwa wa pelu yin
Wọ́n sì dá a lóhùn padà pé, Kí Olúwa bùkún fún ọ
Won si da a lohun pada pe, Ki Oluwa bukun fun o
Bóásì sì béèrè lọ́wọ́ olórí àwọn olùkórè wí pé, Ti ta ni ọ̀dọ́mọbìnrin yẹn
Boasi si beere lowo olori awon olukore wi pe, Ti ta ni odomobinrin yen
Ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ olórí àwọn olùkórè náà sì fèsì pé, Ọ̀dọ́mọbìnrin ará Móábù tí ó tẹ̀lé Náómì wá láti ilẹ̀ Móábù ni
Iranse ti o je olori awon olukore naa si fesi pe, Odomobinrin ara Moabu ti o tele Naomi wa lati ile Moabu ni
Ó sọ wí pé, Kí ń jọ̀wọ́ jẹ́ kí òun máa ṣa ọkà lẹ́yìn àwọn olùkórè
O so wi pe, Ki n jowo je ki oun maa sa oka leyin awon olukore
Ó sì ti ń ṣe iṣẹ́ kárakára láti òwúrọ̀ títí di ìsinsìn yìí nínú oko àyàfi ìgbà tí ó lọ láti sinmi fún ìgbà díẹ̀ lábẹ́ ibojì
O si ti n se ise karakara lati owuro titi di isinsin yii ninu oko ayafi igba ti o lo lati sinmi fun igba die labe iboji
Nígbà náà ni Bóásì sọ fún Rúùtù pé, Gbọ́ ọmọbìnrin mi, má ṣe lọ sí oko mìíràn láti ṣa ọkà, má sì ṣe kúrò ní ibi
Nigba naa ni Boasi so fun Ruutu pe, Gbo omobinrin mi, ma se lo si oko miiran lati sa oka, ma si se kuro ni ibi
Dúró níbí pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́-bìnrin mi
Duro nibi pelu awon iranse-binrin mi
Wo ibi tí wọ́n ti ń kórè kí o sì máa tẹ̀lé àwọn obìnrin
Wo ibi ti won ti n kore ki o si maa tele awon obinrin
Mo ti pàṣẹ fún àwọn ọkùnrin kí wọ́n má ṣe fi ọwọ́ kàn ọ́
Mo ti pase fun awon okunrin ki won ma se fi owo kan o
Nígbàkugbà tí òǹgbẹ bá sì ń gbẹ ọ́, lọ kí ó sì mu omi nínú àmù èyí tí àwọn ọkùnrin ti pọn omi sí nínú
Nigbakugba ti ongbe ba si n gbe o, lo ki o si mu omi ninu amu eyi ti awon okunrin ti pon omi si ninu
Rúùtù wólẹ̀, ó sì wí fún Bóásì pé, Èéṣe tí èmi fi bá ojúrere rẹ pàdé tó báyìí, tí o sì kíyèsí mi, èmi àjèjì àti àlejò
Ruutu wole, o si wi fun Boasi pe, Eese ti emi fi ba ojurere re pade to bayii, ti o si kiyesi mi, emi ajeji ati alejo
Bóásì sì fèsì wí pé, Èmi ti gbọ́ gbogbo bí o ti ń ṣe sí ìyá ọkọ ọ̀ rẹ láti ìgbà tí ọkọ rẹ ti kú àti bí o ti ṣe fi baba àti ìyá rẹ àti ilẹ̀ rẹ sílẹ̀, tí o sì wá láti gbé láàárin àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ̀ rí tẹ́lẹ̀
Boasi si fesi wi pe, Emi ti gbo gbogbo bi o ti n se si iya oko o re lati igba ti oko re ti ku ati bi o ti se fi baba ati iya re ati ile re sile, ti o si wa lati gbe laaarin awon eniyan ti iwo ko mo ri tele
Kí Olúwa kí ó san ẹ̀san ohun tí o ṣe fún ọ
Ki Oluwa ki o san esan ohun ti o se fun o
Kí o sì gba èrè kíkún láti ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì abẹ́ ìyẹ́ ẹni tí ìwọ sá wá fún ààbò
Ki o si gba ere kikun lati odo Oluwa Olorun Isireli abe iye eni ti iwo sa wa fun aabo
Rúùtù sì fèsì wí pé, Kí èmi kí ó máa rí ojúrere láti ọ̀dọ̀ rẹ ṣíwájú sí i olúwa mi
Ruutu si fesi wi pe, Ki emi ki o maa ri ojurere lati odo re siwaju si i oluwa mi
Ìwọ ti tù mí nínú nípa sísọ ọ̀rọ̀ rere sí ìránṣẹ́-bìnrin rẹ, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé èmi kò tó ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́-bìnrin rẹ
Iwo ti tu mi ninu nipa siso oro rere si iranse-binrin re, bi o ti le je pe emi ko to okan ninu awon iranse-binrin re
Nígbà tí àkókò oúnjẹ sì tó, Bóásì sọ fún Rúùtù pé, Wá gba ìwọ̀n àkàrà yí kí o sì fi run wáìnì kíkan
Nigba ti akoko ounje si to, Boasi so fun Ruutu pe, Wa gba iwon akara yi ki o si fi run waini kikan
Ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn olùkórè, Bóásì sì fún-un ní ọkà yíyan
O si jokoo pelu awon olukore, Boasi si fun-un ni oka yiyan
Ó sì jẹ́, ó yó, ó sì tún ṣẹ́kù
O si je, o yo, o si tun seku
Nígbà tí ó sì dìde láti máa ṣa ọkà, Bóásì pàṣẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ wí pé, Bí ó tilẹ̀ ń ṣà láàárin oko ọkà pàápàá, ẹ má ṣe dí i lọ́wọ́
Nigba ti o si dide lati maa sa oka, Boasi pase fun awon osise re wi pe, Bi o tile n sa laaarin oko oka paapaa, e ma se di i lowo
Bí kò ṣe pé kí ẹ mú lára àwọn ìtí sílẹ̀ fún láti ṣa, kí ẹ má sì ṣe ba a wí
Bi ko se pe ki e mu lara awon iti sile fun lati sa, ki e ma si se ba a wi
Rúùtù sì ń ṣa ọkà títí ó fi di ìrọ̀lẹ́, nígbà tí ó sì pa ọkà tí ó rí ṣà, tí ó sì fẹ́ ẹ tán, èyí tí ó rí sì tó ìwọ̀n garawa kan
Ruutu si n sa oka titi o fi di irole, nigba ti o si pa oka ti o ri sa, ti o si fe e tan, eyi ti o ri si to iwon garawa kan
Ó sì gbé e lọ sí ìgboro, ìyá ọkọ rẹ sì rí ọkà tí ó rí sà bi o tí pọ̀ tó, Rúùtù sì mú oúnjẹ tí ó jẹ kù lẹ́yìn tí ó ti yó tan fún ìyá ọkọ rẹ̀
O si gbe e lo si igboro, iya oko re si ri oka ti o ri sa bi o ti po to, Ruutu si mu ounje ti o je ku leyin ti o ti yo tan fun iya oko re
Ìyá ọkọ rẹ̀ sì bi í léèrè wí pé, Níbo ni ìwọ ti ṣa ọkà lónìí
Iya oko re si bi i leere wi pe, Nibo ni iwo ti sa oka lonii
Àti wí pé oko ta ni ìwọ gbé ṣiṣẹ́
Ati wi pe oko ta ni iwo gbe sise
Alábùkún fún ni ọkùnrin náà tí ó bojú wò ọ
Alabukun fun ni okunrin naa ti o boju wo o
Rúùtù sì sọ ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ fún ìyá ọkọ rẹ̀ pé, Ní oko ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bóásì ni òun ti ṣiṣẹ́ lónìí
Ruutu si so odo eni ti o ti sise fun iya oko re pe, Ni oko okunrin kan ti oruko re n je Boasi ni oun ti sise lonii
Náómì sì wí fún-un pé, Kí Olúwa , kí ó bùkún fún ọkùnrin náà
Naomi si wi fun-un pe, Ki Oluwa , ki o bukun fun okunrin naa
Ọlọ́run kò dáwọ́ oore àti àánú ṣíṣe sí àwọn alààyè àti òkú dúró
Olorun ko dawo oore ati aanu sise si awon alaaye ati oku duro
Náómì sì sọ ṣíwájú sí i wí pé, Ìbátan tí ó súnmọ́ wa pẹ́kípẹ́kí ni ọkùnrin náà ń ṣe, ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó ní ẹ̀tó láti ra ohun-ìní ìdílé padà
Naomi si so siwaju si i wi pe, Ibatan ti o sunmo wa pekipeki ni okunrin naa n se, o si je okan ninu awon ti o ni eto lati ra ohun-ini idile pada
Rúùtù, ará Móábù sì wí pé, Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó sọ fún mi pé, Kí ń máa ṣa ọkà pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ òun, títí wọn yóò fi parí ìkórè
Ruutu, ara Moabu si wi pe, Ju gbogbo re lo, o so fun mi pe, Ki n maa sa oka pelu awon osise oun, titi won yoo fi pari ikore
  Náómì sì sọ fún Rúùtù, ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé, Ìbá dára bí ó bá le bá àwọn ìránṣẹ́-bìnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́
  Naomi si so fun Ruutu, iyawo omo re pe, Iba dara bi o ba le ba awon iranse-binrin re sise
Nítorí pé wọ́n le è dà ọ́ láàmú bí o bá lọ sí oko ẹlòmíràn
Nitori pe won le e da o laamu bi o ba lo si oko elomiran
Rúùtù sì bá àwọn ìránṣẹ́-bìnrin Bóásì ṣiṣẹ́ títí tí wọ́n fi parí ìkórè ọkà bálì àti ti jéró
Ruutu si ba awon iranse-binrin Boasi sise titi ti won fi pari ikore oka bali ati ti jero
Ó sì ń gbé pẹ̀lú ìyá ọkọ rẹ̀
O si n gbe pelu iya oko re
Rúùtù Àti Bóásì Ní Ilẹ̀ Ìpakà
Ruutu Ati Boasi Ni Ile Ipaka
Ní ọjọ́ kan, Nóámì, ìyá ọkọ Rúùtù wí fún-un pé, Ọmọbìnrin mi, ǹjẹ́ kò yẹ kí èmi bá ọ wá ilé ọkọ mìíràn fún ọ, níbi tí wọn yóò ti le è máa tọ́jú rẹ
Ni ojo kan, Noami, iya oko Ruutu wi fun-un pe, Omobinrin mi, nje ko ye ki emi ba o wa ile oko miiran fun o, nibi ti won yoo ti le e maa toju re
Wòó, Bóásì ọkùnrin nì tí ìwọ bá àwọn ìránṣẹ́-bìnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́, tí í ṣe ìbátan wa, yóò wá láti fẹ́ ọkà ní ilẹ̀-ìpakà rẹ̀ ní àṣálẹ́ yìí
Woo, Boasi okunrin ni ti iwo ba awon iranse-binrin re sise, ti i se ibatan wa, yoo wa lati fe oka ni ile-ipaka re ni asale yii
Wẹ̀, kí o sì fi ìpara-olóòórùn dídùn pa ara rẹ, kí o sì wọ aṣọ rẹ tí ó dára jùlọ, kí o sì lọ sí ilẹ̀-ìpakà tí ó gbé ń pa ọkà, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ó mọ̀ pé o wà níbẹ̀ títí tí yóò fi jẹ tí yóò sì mu tán
We, ki o si fi ipara-olooorun didun pa ara re, ki o si wo aso re ti o dara julo, ki o si lo si ile-ipaka ti o gbe n pa oka, sugbon ma se je ki o mo pe o wa nibe titi ti yoo fi je ti yoo si mu tan
Rí í dájú pé o mọ ibi tí ó sùn sí, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti sùn, lọ kí o sí aṣọ ìbora rẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè kí o sì sùn síbi ẹsẹ̀ náà
Ri i daju pe o mo ibi ti o sun si, leyin igba ti o ba ti sun, lo ki o si aso ibora re nibi ese re soke ki o si sun sibi ese naa
Òun yóò sì sọ ohun tí ìwọ yóò ṣe fún ọ
Oun yoo si so ohun ti iwo yoo se fun o
Rúùtù sì fèsì pé, Gbogbo ohun tí ìwọ sọ fún mi ni èmi yóò ṣe
Ruutu si fesi pe, Gbogbo ohun ti iwo so fun mi ni emi yoo se
Bẹ́ẹ̀ ni Rúùtù lọ sí ilẹ̀-ìpakà tí ó sì ṣe gbogbo ohun tí ìyá ọkọ rẹ̀ sọ fún-un, pé kí o se
Bee ni Ruutu lo si ile-ipaka ti o si se gbogbo ohun ti iya oko re so fun-un, pe ki o se
Nígbà tí Bóásì parí jíjẹ àti mímu tán, tí ọkàn rẹ̀ sì kún fún ayọ̀
Nigba ti Boasi pari jije ati mimu tan, ti okan re si kun fun ayo
Ó lọ, ó sì dùbúlẹ̀ ní ẹ̀yìn ọkà bálì tí wọ́n kó jọ
O lo, o si dubule ni eyin oka bali ti won ko jo
Rúùtù yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ibẹ̀, ó sí aṣọ ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè, ó sì sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀
Ruutu yo kelekele lo si ibe, o si aso ese re soke, o si sun si ibi ese re
Ó sì ṣe nígbà tí ọkùnrin náà tají ní àárin òru, ẹ̀rú bàá, ó sì yí ara padà, ó sì ṣàkíyèsí obìnrin kan tí ó sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀
O si se nigba ti okunrin naa taji ni aarin oru, eru baa, o si yi ara pada, o si sakiyesi obinrin kan ti o sun si ibi ese re
Ó sì béèrè pé, Ta ni ìwọ í ṣe
O si beere pe, Ta ni iwo i se
Rúùtù sì fèsì wí pé, Èmi ni Rúùtù, ìránṣẹ́-bìnrin rẹ
Ruutu si fesi wi pe, Emi ni Ruutu, iranse-binrin re
Da etí aṣọ rẹ bò mí, nítorí pé ìwọ ni ìbátan tí ó le è rà mí padà
Da eti aso re bo mi, nitori pe iwo ni ibatan ti o le e ra mi pada
Bóásì sì wí fún-un pé, Kí Olúwa bùkún fún ọ, ọmọbìnrin mi
Boasi si wi fun-un pe, Ki Oluwa bukun fun o, omobinrin mi
Ìfẹ́ tí o fi hàn yí ti pọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, bí ó ti jẹ́ wí pé ìwọ kò lọ láti wá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bóyá ọlọ́rọ̀ tàbí talákà
Ife ti o fi han yi ti po ju ti ateyinwa lo, bi o ti je wi pe iwo ko lo lati wa awon odomokunrin boya oloro tabi talaka
Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, ìwọ ọmọbìnrin mi, má bẹ̀rù
Nje nisinsin yii, iwo omobinrin mi, ma beru
Èmi yóò sì ṣe ohun gbogbo tí o béèrè fún ọ
Emi yoo si se ohun gbogbo ti o beere fun o
Gbogbo ènìyàn ni ó mọ̀ ọ́ ní obìnrin oníwà rere
Gbogbo eniyan ni o mo o ni obinrin oniwa rere
Nítòótọ́ ni wí pé èmi jẹ́ ìbátan tí ó sún mọ́ ọ, ṣùgbọ́n ìbátan kan wà tí ó sún mọ́ ọ ju ti tèmi lọ
Nitooto ni wi pe emi je ibatan ti o sun mo o, sugbon ibatan kan wa ti o sun mo o ju ti temi lo
Dúró síbí títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, bí ó bá sì di òwúrọ̀ tí ọkùnrin náà sì ṣe tan láti ṣe ìràpadà, ó dára kí ó ṣe bẹ́ẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí Olúwa ti ń bẹ láàyè nígbà náà ni èmi yóò ṣe ìràpadà, sùn sí ìhín títí ilẹ̀ yóò fi mọ́
Duro sibi titi ile yoo fi mo, bi o ba si di owuro ti okunrin naa si se tan lati se irapada, o dara ki o se bee, bi bee ko, bi Oluwa ti n be laaye nigba naa ni emi yoo se irapada, sun si ihin titi ile yoo fi mo
Ó sì sùn ní ẹsẹ̀ rẹ̀ títí di òwúrọ̀, ṣùgbọ́n, ó dìde ní ìdájí kùtùkùtù kí ẹnìkín-ín-ní tó le è dá ẹnìkejì mọ̀
O si sun ni ese re titi di owuro, sugbon, o dide ni idaji kutukutu ki enikin-in-ni to le e da enikeji mo
Bóásì sì sọ fún-un wí pé, Má ṣe jẹ́ kí ó di mímọ̀ wí pé obìnrin kan wá sí ilẹ̀-ìpakà
Boasi si so fun-un wi pe, Ma se je ki o di mimo wi pe obinrin kan wa si ile-ipaka
Ó sì tún wí fún-un pé, Mú aṣọ ìborùn rẹ tí o dà bora, kí o tẹ̀ ẹ sílẹ̀
O si tun wi fun-un pe, Mu aso iborun re ti o da bora, ki o te e sile
Rúùtù sì ṣe bẹ́ẹ̀, Bóásì sì wọn òṣùwọ̀n ọkà bálì mẹ́fà sí i, ó sì gbé e rù ú
Ruutu si se bee, Boasi si won osuwon oka bali mefa si i, o si gbe e ru u
Nígbà náà ni ó padà sí ìgboro
Nigba naa ni o pada si igboro
Nígbà tí Rúùtù dé ilé, Náómì, ìyá ọkọ sì bí léèrè pé, Báwo ni ó ti rí, ọmọbìnrin mi
Nigba ti Ruutu de ile, Naomi, iya oko si bi leere pe, Bawo ni o ti ri, omobinrin mi
Nígbà náà ni ó sì sọ gbogbo ohun tí ọkùnrin náà ṣe fún-un, fún ìyá ọkọ rẹ̀
Nigba naa ni o si so gbogbo ohun ti okunrin naa se fun-un, fun iya oko re
Ó fi kún-un wí pé, Ó sọ fún mi wí pé, Má ṣe padà sí ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ rẹ ní ọwọ́ òfo, nítorí náà ó fún mi ní ìwọ̀n ọkà bálì mẹ́fà
O fi kun-un wi pe, O so fun mi wi pe, Ma se pada si odo iya oko re ni owo ofo, nitori naa o fun mi ni iwon oka bali mefa
  Náómì sì wí fún-un pé, Dúró, ọmọbìnrin mi títí tí ìwọ yóò fi mọ bí ohun gbogbo yóò ti rí
  Naomi si wi fun-un pe, Duro, omobinrin mi titi ti iwo yoo fi mo bi ohun gbogbo yoo ti ri
Nítorí pé ọkùnrin náà kò ní sinmi títí tí ọ̀rọ̀ náà yóò fi yanjú lónìí
Nitori pe okunrin naa ko ni sinmi titi ti oro naa yoo fi yanju lonii
Bóásì Gbé Rúùtù Ní Ìyàwó
Boasi Gbe Ruutu Ni Iyawo
Nígbà náà ni Bóásì gòkè lọ sí ẹnu ìbodè ìlú, ó sì jòkòó síbẹ̀
Nigba naa ni Boasi goke lo si enu ibode ilu, o si jokoo sibe
Nígbà tí ìbátan tí ó sún mọ́ Elimélékì jùlọ, arákùnrin tí Bóásì ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ ń kọjá, Bóásì pè é wí pé, Máa bọ̀ wá síbí ìwọ ọ̀rẹ́ mi, kí o sì jokòó
Nigba ti ibatan ti o sun mo Elimeleki julo, arakunrin ti Boasi ti soro re n koja, Boasi pe e wi pe, Maa bo wa sibi iwo ore mi, ki o si jokoo
Ó sì lọ jokòó
O si lo jokoo