diacritcs
stringlengths
1
36.7k
no_diacritcs
stringlengths
1
35.5k
Bóásì sì pe mẹ́wàá nínú àwọn àgbààgbà ìlú, wí pé ki wọn jókòó, wọn sí se bẹ́ẹ̀, ó sì sọ fún ìbátan rẹ̀ náà pé, Arábìnrin Náómì tí ó dé láti ilẹ̀ Móábù fẹ́ ta ilẹ̀, èyí tí ó ṣe ti arákùnrin wa, Elimélékì
Boasi si pe mewaa ninu awon agbaagba ilu, wi pe ki won jokoo, won si se bee, o si so fun ibatan re naa pe, Arabinrin Naomi ti o de lati ile Moabu fe ta ile, eyi ti o se ti arakunrin wa, Elimeleki
Mó sì rò wí pé ó yẹ kí n mú ọ̀rọ̀ náà wá sí etí ìgbọ́ rẹ, wí pé kí o rà á ní iwájú gbogbo àwọn tí ó jòkòó sí ibi yìí
Mo si ro wi pe o ye ki n mu oro naa wa si eti igbo re, wi pe ki o ra a ni iwaju gbogbo awon ti o jokoo si ibi yii
Bí ìwọ yóò bá rà á padà, rà á
Bi iwo yoo ba ra a pada, ra a
Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ní rà á padà, sọ fún mi, kí èmi ó le è mọ̀
Sugbon bi iwo ko ba ni ra a pada, so fun mi, ki emi o le e mo
Nítorí pé kò sí ẹlòmíràn tí ó ní ẹ̀tọ́ láti rà á ju ìwọ lọ, èmi sì ni ẹni tí ó tún kàn lẹ́yìn rẹ̀
Nitori pe ko si elomiran ti o ni eto lati ra a ju iwo lo, emi si ni eni ti o tun kan leyin re
Ọkùnrin náà sì sọ wí pé, Èmi yóò rà á padà
Okunrin naa si so wi pe, Emi yoo ra a pada
Nígbà náà ni, Bóásì sọ wí pé, Bí ìwọ bá ti ra ilẹ̀ náà lọ́wọ́ Náómì àti lọ́wọ́ Rúùtù ará Móábù, ìwọ gbọdọ̀ fẹ opó ọkùnrin náà, kí orúkọ ọkùnrin tí ó kú náà má ba à parẹ́ pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀ àti kí o le è bímọ ní orúkọ rẹ̀
Nigba naa ni, Boasi so wi pe, Bi iwo ba ti ra ile naa lowo Naomi ati lowo Ruutu ara Moabu, iwo gbodo fe opo okunrin naa, ki oruko okunrin ti o ku naa ma ba a pare pelu ohun ini re ati ki o le e bimo ni oruko re
Nígbà náà ni ọkùnrin náà dáhùn sí èyí pé, Nípa ti èyí, èmi kò le rà á padà, nítorí pé, ọmọ rẹ, ọkùnrin yóò wá jẹ́ ajogún àwọn ohun-ìní mi pẹ̀lú
Nigba naa ni okunrin naa dahun si eyi pe, Nipa ti eyi, emi ko le ra a pada, nitori pe, omo re, okunrin yoo wa je ajogun awon ohun-ini mi pelu
Rà á fún ara rẹ, èmi kò le ṣe é
Ra a fun ara re, emi ko le se e
Ní ayé ìgbà a nì, kí a tó le sọ wí pé ohun ìràpadà tàbí pàsípàrọ̀ ohun-ìní, fi ìdí múlẹ̀ ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ẹnìkan ni láti yọ bàtà rẹ̀ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀ kí ó sì fi fún ẹnikejì, ó jẹ́ òfin fún ẹni tí ó fẹ́ rà á
Ni aye igba a ni, ki a to le so wi pe ohun irapada tabi pasiparo ohun-ini, fi idi mule ni ile Isireli, enikan ni lati yo bata re kuro ni ese re ki o si fi fun enikeji, o je ofin fun eni ti o fe ra a
Nípa ṣíṣe èyí, àwọn ará Ísírẹ́lì fihàn wí pé ọ̀rọ̀ náà ti fìdímúlẹ̀
Nipa sise eyi, awon ara Isireli fihan wi pe oro naa ti fidimule
Nítorí náà, nígbà tí ọkùnrin náà sọ fún Bóásì wí pé, Ìwọ rà á fúnràrẹ, ó yọ bàtà rẹ̀ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀
Nitori naa, nigba ti okunrin naa so fun Boasi wi pe, Iwo ra a funrare, o yo bata re kuro ni ese re
Nígbà náà ni Bóásì wí fún àwọn àgbààgbà àti àwọn mìíràn tí ó wà ní ibẹ̀ pé, Gbogbo yín jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní òní wí pé mo ti ra ohun gbogbo tí í ṣe ti Elimélékì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjèèjì
Nigba naa ni Boasi wi fun awon agbaagba ati awon miiran ti o wa ni ibe pe, Gbogbo yin je elerii mi ni oni wi pe mo ti ra ohun gbogbo ti i se ti Elimeleki ati awon omo re okunrin mejeeji
Málíónì àti Kílíónì lọ́wọ́ Náómì
Malioni ati Kilioni lowo Naomi
Ní àfikún, mo ra Rúùtù ará Móábù opó Málíónì padà láti di aya mi
Ni afikun, mo ra Ruutu ara Moabu opo Malioni pada lati di aya mi
Èyí tí yóò mú kí orúkọ ọkùnrin òkú náà wà pẹ̀lú ohun-ìní rẹ̀, kí ìran rẹ̀ má ba à lè parẹ́ láàrin àwọn ẹbí rẹ̀ àti ìlú rẹ̀
Eyi ti yoo mu ki oruko okunrin oku naa wa pelu ohun-ini re, ki iran re ma ba a le pare laarin awon ebi re ati ilu re
Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí ní òní
Eyin ni elerii ni oni
Nígbà náà ni àwọn àgbààgbà àti àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀ dáhùn wí pé, Bẹ́ẹ̀ ni, àwa ni ẹlẹ́rìí, kí Olúwa jẹ́ kí obìnrin tí ó ń bọ̀ wá sí inú ilẹ̀ rẹ dàbí Rákélì àti Léà láti ara àwọn ẹni tí gbogbo ìdílé Ísírẹ́lì ti jáde wá
Nigba naa ni awon agbaagba ati awon eniyan ti o wa ni ibe dahun wi pe, Bee ni, awa ni elerii, ki Oluwa je ki obinrin ti o n bo wa si inu ile re dabi Rakeli ati Lea lati ara awon eni ti gbogbo idile Isireli ti jade wa
Kí ìwọ sì di ọlọ́rọ̀ ní ìran Éfúráta àti olókìkí ní ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù
Ki iwo si di oloro ni iran Efurata ati olokiki ni ilu Betilehemu
Kí Olúwa fún ọ ní ọmọ tí yóò mú ìdílé rẹ dàbí ti Pérésì, ọmọkùnrin tí Támárì bí fún Júdà láti ipaṣẹ̀ ọ̀dọ́mọbìnrin yìí
Ki Oluwa fun o ni omo ti yoo mu idile re dabi ti Peresi, omokunrin ti Tamari bi fun Juda lati ipase odomobinrin yii
Báyìí ni Bóásì ṣe mú Rúùtù, tí ó sì di aya rẹ̀
Bayii ni Boasi se mu Ruutu, ti o si di aya re
Nígbà náà ni ó wọlé tọ aya rẹ̀, Olúwa sì mú kí ó lóyùn, ó sì bí ọmọ ọkùnrin kan
Nigba naa ni o wole to aya re, Oluwa si mu ki o loyun, o si bi omo okunrin kan
Àwọn obìnrin sì wí fún Náómì pé, Ìyìn ni fún Olúwa tí kò fi ọ sílẹ̀ ní òní yìí láìní ìbátan, Olùràpadà
Awon obinrin si wi fun Naomi pe, Iyin ni fun Oluwa ti ko fi o sile ni oni yii laini ibatan, Olurapada
Kí ọmọ náà di olókìkí ní Ísírẹ́lì
Ki omo naa di olokiki ni Isireli
Yóò tún ayé rẹ ṣe, yóò sì dáàbò bò ọ́ ní ọjọ́ ogbó rẹ
Yoo tun aye re se, yoo si daabo bo o ni ojo ogbo re
Nítorí pé ìyàwó ọmọ rẹ, èyí tí ó sàn fún ọ ju ọmọkùnrin méje lọ, tí ó sì fẹ́ràn rẹ ni ó bí ọmọ yìí fún
Nitori pe iyawo omo re, eyi ti o san fun o ju omokunrin meje lo, ti o si feran re ni o bi omo yii fun
Náómì sì gbé ọmọ náà lé orí ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì ń tọ́jú rẹ̀
Naomi si gbe omo naa le ori ese re, o si n toju re
Àwọn obìnrin àdúgbò sì wí pé, A bí ọmọkùnrin kan fún Náómì
Awon obinrin adugbo si wi pe, A bi omokunrin kan fun Naomi
Wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Óbédì
Won si pe oruko re ni Obedi
Òun sì ni baba Jésè tí í ṣe baba Dáfídì
Oun si ni baba Jese ti i se baba Dafidi
Èyí ni ìran Pérésì Pérésì ni baba Ésírónì, Ésírónì ni baba Rámú, Rámù ni baba Ámínádábù Ámínádábù ni baba Násónì, Násónì ni baba Sálímónì, Sálímónì ni baba Bóásì, Bóásì ni baba Óbédì, Óbédì ní baba Jésè, Jésè ni baba Dáfídì
Eyi ni iran Peresi Peresi ni baba Esironi, Esironi ni baba Ramu, Ramu ni baba Aminadabu Aminadabu ni baba Nasoni, Nasoni ni baba Salimoni, Salimoni ni baba Boasi, Boasi ni baba Obedi, Obedi ni baba Jese, Jese ni baba Dafidi
Olùfẹ́
Olufe
Orin àwọn orin tí i ṣe orin Sólómónì Fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kò mí ní ẹnu, nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí wáìnì lọ
Orin awon orin ti i se orin Solomoni Fi ifenukonu ife ko mi ni enu, nitori ife re dara ju oti waini lo
Òórùn ìkunra rẹ fanimọ́ra
Oorun ikunra re fanimora
Orúkọ rẹ rí bí ìkunra tí a tú jáde Abájọ tí àwọn wúndíá fi fẹ́ ọ
Oruko re ri bi ikunra ti a tu jade Abajo ti awon wundia fi fe o
Fà mí lọ pẹ̀lú rẹ, kí a lọ kíákíá Ọba ti mú mi wá sínú yàrá rẹ̀
Fa mi lo pelu re, ki a lo kiakia Oba ti mu mi wa sinu yara re
Àwa yọ̀ inú wa sì dùn sí ọ
Awa yo inu wa si dun si o
a gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí wáìnì lọ
a gbe ife re ga ju oti waini lo
Wọ́n fẹ́ ọ nítòótọ́! Èmi dúdú mo sì ní ẹwà
Won fe o nitooto! Emi dudu mo si ni ewa
Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, Dúdú bí àgọ́ Kédárì Bí àgọ́ aṣọ kọ́tìnnì ti Sólómónì Má ṣe wò mí nítorí wí pé mo dúdú Nítorí òòrùn mú mi dúdú Ọmọkùnrin ìyá mi bínú sími Ó sì fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà
Eyin omobinrin Jerusalemu, Dudu bi ago Kedari Bi ago aso kotinni ti Solomoni Ma se wo mi nitori wi pe mo dudu Nitori oorun mu mi dudu Omokunrin iya mi binu simi O si fi mi se olutoju ogba ajara
Ọgbà àjàrà tèmi ni èmi kò tọ́jú Ṣọ fún mi ìwọ ẹni tí ọkàn mí fẹ́, Níbo ni ìwọ ń da agbo ẹran lọ
Ogba ajara temi ni emi ko toju So fun mi iwo eni ti okan mi fe, Nibo ni iwo n da agbo eran lo
Níbi tí ìwọ mú agbo ẹran rẹ sinmi ní ọ̀sán
Nibi ti iwo mu agbo eran re sinmi ni osan
Kí ni ìdí tí èmi yóò fi jẹ́ obìnrin aṣán Ní ẹ̀bá agbo ẹran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ
Ki ni idi ti emi yoo fi je obinrin asan Ni eba agbo eran awon ore re
Bí ìwọ kò bá mọ̀, Ìwọ arẹwà jùlọ nínú àwọn obìnrin
Bi iwo ko ba mo, Iwo arewa julo ninu awon obinrin
Bá ọ̀nà ti agbo ẹran rìn lọ
Ba ona ti agbo eran rin lo
Kí o sì bọ́ àwọn ọmọ ewúrẹ́ rẹ
Ki o si bo awon omo ewure re
Ní ẹ̀bá àgọ́ àwọn olùsọ́ àgùntàn
Ni eba ago awon oluso aguntan
Olùfẹ́ mi, Mo fi ọ́ wé ẹṣin mi nínú kẹ̀kẹ́ Fáráò
Olufe mi, Mo fi o we esin mi ninu keke Farao
Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dára ní ohun ọ̀ṣọ́, Ọrùn rẹ sì yẹ ọ̀ṣọ́ ìlẹ̀kẹ̀ A ó fi wúrà ṣe òrùka etí fún ọ, A ó fi fàdákà ṣe ìlẹ̀kẹ̀
Ereke re dara ni ohun oso, Orun re si ye oso ileke A o fi wura se oruka eti fun o, A o fi fadaka se ileke
Nígbà tí ọba wà ní orí ìjókòó rẹ̀
Nigba ti oba wa ni ori ijokoo re
Òróró ìkunra mi tú òórùn jáde
Ororo ikunra mi tu oorun jade
Ìdì òjíá ni olùfẹ́ mi jẹ sí mi
Idi ojia ni olufe mi je si mi
Òun ó sinmi lé àárin ọmú mi
Oun o sinmi le aarin omu mi
Bí ìdì ìtàná Hénínà ni Olùfẹ́ mi rí sí mi Láti inú ọgbà àjàrà ti Énígédì
Bi idi itana Henina ni Olufe mi ri si mi Lati inu ogba ajara ti Enigedi
Báwo ni o ti lẹ́wà tó, olùfẹ́ mi! Áá à, Báwo ni o ṣe lẹ́wà tó! Ìwọ ní ojú ẹyẹlé
Bawo ni o ti lewa to, olufe mi! Aa a, Bawo ni o se lewa to! Iwo ni oju eyele
Báwo ni o ṣe dára tó, olùfẹ́ mi! Áá à, Báwo ni o ṣe wu ni! Ibùsùn wa ní ìtura
Bawo ni o se dara to, olufe mi! Aa a, Bawo ni o se wu ni! Ibusun wa ni itura
Ìtànsán ilé wa jẹ́ ti igi kédárì Ẹkẹ́ ilé wa jẹ́ ti igi Fírì
Itansan ile wa je ti igi kedari Eke ile wa je ti igi Firi
Olùfẹ́
Olufe
Èmi ni ìtànná Ṣárónì Bí ìtàná lílì àwọn àfonífojì Bí ìtànná lílì ní àárin ẹ̀gún ni olùfẹ́ mi ní àárin àwọn wúndíá
Emi ni itanna Saroni Bi itana lili awon afonifoji Bi itanna lili ni aarin egun ni olufe mi ni aarin awon wundia
Bí igi ápù láàrin àwọn igi inú igbó, ni olùfẹ́ mí láàrin àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Mo fi ayọ̀ jókòó ní abẹ́ òjìji rẹ̀, Èso rẹ̀ sì dùn mọ́ mi ní ẹnu
Bi igi apu laarin awon igi inu igbo, ni olufe mi laarin awon odomokunrin Mo fi ayo jokoo ni abe ojiji re, Eso re si dun mo mi ni enu
Ó mú mi lọ sí ibi gbọ̀ngàn àṣè, Ìfẹ́ sì ni ọ̀pàgun rẹ̀ lórí mi
O mu mi lo si ibi gbongan ase, Ife si ni opagun re lori mi
Fi agbára adùn àkàrà dá mi dúró
Fi agbara adun akara da mi duro
Fi èṣo ápù tù mi lára Nítorí àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí
Fi eso apu tu mi lara Nitori aisan ife n se mi
Ọwọ́ òsì rẹ ń bẹ lábẹ́ orí mi Ọwọ́ ọ̀tún rẹ sì ń gbà mí mọ́ra Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, mo fi abo egbin àti ọmọ àgbọ̀nrín fi yín bú Kí ẹ má ṣe ru ìfẹ́ olùfẹ́ mi sókè Kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú Gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi! Wò ó! Ibí yìí ni ó ń bọ̀
Owo osi re n be labe ori mi Owo otun re si n gba mi mora Eyin omobinrin Jerusalemu, mo fi abo egbin ati omo agbonrin fi yin bu Ki e ma se ru ife olufe mi soke Ki e ma si se ji i titi yoo fi wu u Gbo ohun olufe mi! Wo o! Ibi yii ni o n bo
Òun ń fò lórí àwọn òkè ńlá, Òun bẹ́ lórí àwọn òkè kékèké Olùfẹ́ mi dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín Wò ó! Níbẹ̀ ni ó wà lẹ́yìn ògiri wa Ó yọjú ní ojú fèrèsé Ó ń fi ara rẹ̀ hàn lójú fèrèsé ọlọ́nà Olùfẹ́ mi fọhùn ó sì sọ fún mi pé, Dìde, Olùfẹ́ mi, Arẹwà mi, kí o sì wà pẹ̀lú mi
Oun n fo lori awon oke nla, Oun be lori awon oke kekeke Olufe mi dabi abo egbin tabi omo agbonrin Wo o! Nibe ni o wa leyin ogiri wa O yoju ni oju ferese O n fi ara re han loju ferese olona Olufe mi fohun o si so fun mi pe, Dide, Olufe mi, Arewa mi, ki o si wa pelu mi
Wò ó! Ìgbà otútù ti kọjá
Wo o! Igba otutu ti koja
Òjò ti rọ̀ dawọ́, ó sì ti lọ
Ojo ti ro dawo, o si ti lo
Àwọn òdòdó fara hàn lórí ilẹ̀ Àsìkò ìkọrin àwọn ẹyẹ dé A sì gbọ́ ohùn àdàbà ní ilẹ̀ wa
Awon ododo fara han lori ile Asiko ikorin awon eye de A si gbo ohun adaba ni ile wa
Igi ọ̀pọ̀tọ́ mú èso tuntun jáde Àwọn àjàrà nípa ìtànná wọn fún ni ní òórùn dídùn Dìde, wá, Olùfẹ́ mi
Igi opoto mu eso tuntun jade Awon ajara nipa itanna won fun ni ni oorun didun Dide, wa, Olufe mi
Arẹwà mi nìkan ṣoṣo, wá pẹ̀lú mi
Arewa mi nikan soso, wa pelu mi
Àdàbà mi wà nínú pàlàpálá òkúta, ní ibi ìkọ̀kọ̀ ní orí òkè gíga, fi ojú rẹ hàn mí, jẹ́ kí èmi gbọ́ ohùn rẹ
Adaba mi wa ninu palapala okuta, ni ibi ikoko ni ori oke giga, fi oju re han mi, je ki emi gbo ohun re
Nítorí tí ohùn rẹ dùn, tí ojú rẹ sì ní ẹwà
Nitori ti ohun re dun, ti oju re si ni ewa
Bá wa mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, àní àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kékèké tí ń ba ọgbà àjàrà jẹ́, àwọn ọgbà àjàrà wa tó ní ìtàná
Ba wa mu awon kolokolo, ani awon kolokolo kekeke ti n ba ogba ajara je, awon ogba ajara wa to ni itana
Olùfẹ́ mi ni tèmi èmi sì ni tirẹ̀
Olufe mi ni temi emi si ni tire
Ó ń jẹ láàrin àwọn lílì
O n je laarin awon lili
Títí ìgbà ìtura ọjọ́ títí òjìji yóò fi fò lọ, yípadà, olùfẹ́ mi, kí o sì dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín lórí òkè Bétérì
Titi igba itura ojo titi ojiji yoo fi fo lo, yipada, olufe mi, ki o si dabi abo egbin tabi omo agbonrin lori oke Beteri
Ní orí ìbùsùn mi ní òru mo wá ẹni tí ọkàn mí fẹ́
Ni ori ibusun mi ni oru mo wa eni ti okan mi fe
mo wá a, ṣùgbọ́n èmi kò rí i
mo wa a, sugbon emi ko ri i
Èmi yóò dìde nísinsin yìí, èmi yóò sì rìn lọ káàkiri ìlú, ní àwọn òpópónà àti ní àwọn gbangba òde
Emi yoo dide nisinsin yii, emi yoo si rin lo kaakiri ilu, ni awon opopona ati ni awon gbangba ode
Èmi yóò wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́
Emi yoo wa eni ti okan mi fe
Bẹ́ẹ̀ ni mo wá a ṣùgbọ́n èmi kò rí i
Bee ni mo wa a sugbon emi ko ri i
Àwọn ọdẹ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi Bí wọ́n ṣe ń rìn yíká ìlú
Awon ode ti n so ilu ri mi Bi won se n rin yika ilu
Ǹjẹ́ ìwọ ti rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́
Nje iwo ti ri eni ti okan mi fe
Gẹ́rẹ́ tí mo fi wọ́n sílẹ̀ Ni mo rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́
Gere ti mo fi won sile Ni mo ri eni ti okan mi fe
Mo dì í mú, èmi kò sì jẹ́ kí ó lọ títí tí mo fi mú u wá sílé ìyá mi, sínú yàrá ẹni tí ó lóyún mi Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, Mo fi àwọn abo egbin àti abo àgbọ̀nrín igbó fi yín bú kí ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú Ta ni ẹni tí ń ti ijù jáde wá bí ìkuku èéfín tí a ti fi òjíá àti tùràrí kùn lára pẹ̀lú gbogbo ètù olóòórùn oníṣòwò
Mo di i mu, emi ko si je ki o lo titi ti mo fi mu u wa sile iya mi, sinu yara eni ti o loyun mi Eyin omobinrin Jerusalemu, Mo fi awon abo egbin ati abo agbonrin igbo fi yin bu ki e ma se ru olufe mi soke ki e ma si se ji i titi yoo fi wu u Ta ni eni ti n ti iju jade wa bi ikuku eefin ti a ti fi ojia ati turari kun lara pelu gbogbo etu olooorun onisowo
Wò ó! Àkéte rẹ̀ tí í ṣe ti Sólómónì, Àwọn akọni ọgọ́ta ni ó wà yí i ká, Àwọn akọni Ísírẹ́lì, Gbogbo wọn ni ó mú idà lọ́wọ́, gbogbo wọn ní ìmọ̀ nínú ogun, Idà oníkálùkù wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Wọ́n múra sílẹ̀ fún ìdágìrì òru Sólómónì ọba ṣe àkéte fún ara rẹ̀
Wo o! Akete re ti i se ti Solomoni, Awon akoni ogota ni o wa yi i ka, Awon akoni Isireli, Gbogbo won ni o mu ida lowo, gbogbo won ni imo ninu ogun, Ida onikaluku wa ni egbe re, Won mura sile fun idagiri oru Solomoni oba se akete fun ara re
Ó fi igi Lébánónì ṣe é
O fi igi Lebanoni se e
Ó fi fàdákà ṣe òpó rẹ̀ Ó fi wúrà ṣe ibi ẹ̀yìn rẹ̀ Ó fi elésè àlùkò ṣe ibùjókòó rẹ̀, Inú rẹ̀ ni ó kọ àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọ̀nyí sí Pẹ̀lú ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù
O fi fadaka se opo re O fi wura se ibi eyin re O fi elese aluko se ibujokoo re, Inu re ni o ko awon oro ife wonyi si Pelu ife lati odo awon omobinrin Jerusalemu
Ẹ jáde wá, ẹyin ọmọbìnrin Ṣíónì, kí ẹ sì wo ọba Sólómónì tí ó dé adé, Adé tí ìyá rẹ̀ fi dé e Ní ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀, Ní ọjọ́ ayọ̀ ọkàn rẹ̀
E jade wa, eyin omobinrin Sioni, ki e si wo oba Solomoni ti o de ade, Ade ti iya re fi de e Ni ojo igbeyawo re, Ni ojo ayo okan re
Olùfẹ́
Olufe
Báwo ni ìwọ ti lẹ́wà tó olùfẹ́ mi! Áá à ìwọ jẹ́ arẹwà
Bawo ni iwo ti lewa to olufe mi! Aa a iwo je arewa
Ìwọ ní ojú àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹ Irun rẹ bò ọ́ lójú bí ọ̀wọ́ ewúrẹ́
Iwo ni oju adaba labe iboju re Irun re bo o loju bi owo ewure
Tí ó sọ̀ kalẹ̀ lórí òkè Gílíádì
Ti o so kale lori oke Giliadi
Ẹyín rẹ̀ funfun bí i irun àgbò tí ó gòkè wá láti ibi ìwẹ̀
Eyin re funfun bi i irun agbo ti o goke wa lati ibi iwe
olúkúlùkù wọn bí èjìrẹ́
olukuluku won bi ejire
kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó yàgàn
ko si okan ninu won ti o yagan
Ètè rẹ dàbí òwú òdòdó
Ete re dabi owu ododo
Ẹnu rẹ̀ dùn
Enu re dun
Èrẹ̀kẹ́ rẹ dàbí ẹ̀là pàmógíránéètì lábẹ́ ìbòjú rẹ Ọrùn rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Dáfídì, tí a kọ́ pẹ̀lú ìhámọ́ra
Ereke re dabi ela pamogiraneeti labe iboju re Orun re dabi ile iso Dafidi, ti a ko pelu ihamora
lórí rẹ̀ ni a fi ẹgbẹ̀rún àpáta kọ́, gbogbo wọn jẹ́ àṣà àwọn alágbára
lori re ni a fi egberun apata ko, gbogbo won je asa awon alagbara