diacritcs
stringlengths
1
36.7k
no_diacritcs
stringlengths
1
35.5k
Ọmú rẹ méjèèjì dàbí ọmọ ẹgbin méjì tí wọ́n jẹ́ ìbejì tí ń jẹ láàrin ìtànná lílì
Omu re mejeeji dabi omo egbin meji ti won je ibeji ti n je laarin itanna lili
Títí ọjọ́ yóò fi rọ̀ tí òjìji yóò fi fò lọ, Èmi yóò lọ sí orí òkè ńlá òjíá àti sí òkè kékeré tùràrí
Titi ojo yoo fi ro ti ojiji yoo fi fo lo, Emi yoo lo si ori oke nla ojia ati si oke kekere turari
Gbogbo ara rẹ jẹ́ kìkì ẹwa, olùfẹ́ mi
Gbogbo ara re je kiki ewa, olufe mi
kò sì sí àbàwọ́n lára rẹ
ko si si abawon lara re
Kí a lọ kúrò ní Lẹ́bánónì, ìyàwó mi, ki a lọ kúrò ní Lẹ́bánónì
Ki a lo kuro ni Lebanoni, iyawo mi, ki a lo kuro ni Lebanoni
Àwa wò láti orí òkè Ámánà, láti orí òkè ti Ṣénírì, àti téńté Hérímónì, láti ibi ihò àwọn kìnnìún, láti orí òkè ńlá àwọn ẹkùn
Awa wo lati ori oke Amana, lati ori oke ti Seniri, ati tente Herimoni, lati ibi iho awon kinniun, lati ori oke nla awon ekun
Ìwọ ti gba ọkàn mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi
Iwo ti gba okan mi, arabinrin mi, iyawo mi
Ìwọ ti gba ọkàn mi pẹ̀lú ìwò ẹ̀ẹ̀kan ojú rẹ, pẹ̀lú ọ̀kan nínú ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ, Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó, arábìnrin mi, ìyàwó mi! Ìfẹ́ rẹ tu ni lára ju ọtí wáìnì lọ, òórùn ìkunra rẹ sì ju òórùn gbogbo tùràrí lọ! Ètè rẹ ń kán dídùn afárá oyin, ìyàwó mi
Iwo ti gba okan mi pelu iwo eekan oju re, pelu okan ninu ileke orun re, Ife re ti dun to, arabinrin mi, iyawo mi! Ife re tu ni lara ju oti waini lo, oorun ikunra re si ju oorun gbogbo turari lo! Ete re n kan didun afara oyin, iyawo mi
wàrà àti oyin wà lábẹ́ ahọ́n rẹ
wara ati oyin wa labe ahon re
Òórùn aṣọ rẹ sì dàbí òórùn Lébánónì
Oorun aso re si dabi oorun Lebanoni
Arábìnrin mi ni ọgbà tí a sọ, arábinrin mi, ìyàwó mi ìṣun tí a sé mọ́, oríṣun tí a fi èdìdì dì
Arabinrin mi ni ogba ti a so, arabinrin mi, iyawo mi isun ti a se mo, orisun ti a fi edidi di
Ohun ọ̀gbìn rẹ àgbàlá pàmóńgánéètì ni ti òun ti àṣàyàn èso
Ohun ogbin re agbala pamonganeeti ni ti oun ti asayan eso
kípírésì àti nádì, Nádì àti Ṣáfírónì, kálámúsì àti kínámónì, àti gbogbo igi olóòórùn dídùn, òjíá àti álóé pẹ̀lú irú wọn
kipiresi ati nadi, Nadi ati Safironi, kalamusi ati kinamoni, ati gbogbo igi olooorun didun, ojia ati aloe pelu iru won
Ìwọ ni ọgbà oríṣun, kànga omi ìyè, ìṣàn omi láti Lẹ́bánónì wá
Iwo ni ogba orisun, kanga omi iye, isan omi lati Lebanoni wa
Jí ìwọ afẹ́fẹ́ àríwá kí o sì wá, afẹ́fẹ́ gúṣù! Fẹ́ lórí ọgbà mi, kí àwọn òórùn dídùn inú rẹ lè rùn jáde
Ji iwo afefe ariwa ki o si wa, afefe gusu! Fe lori ogba mi, ki awon oorun didun inu re le run jade
Jẹ́ kí olùfẹ́ mi wá sínú ọgbà a rẹ̀ kí ó sì jẹ àṣàyàn èso rẹ̀
Je ki olufe mi wa sinu ogba a re ki o si je asayan eso re
Olùfẹ́
Olufe
Mo ti dé inú ọgbà mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi
Mo ti de inu ogba mi, arabinrin mi, iyawo mi
mo ti kó òjíá pẹ̀lú òórùn dídùn mi jọ
mo ti ko ojia pelu oorun didun mi jo
Mo ti jẹ afárá mi pẹ̀lú oyin mi
Mo ti je afara mi pelu oyin mi
mo ti mu ọtí wáìnì mi pẹ̀lú wàrà mi
mo ti mu oti waini mi pelu wara mi
Ẹ jẹ, ẹ̀yin ọ̀rẹ́, ẹ mu, àní ẹ mu àmuyó, ẹ̀yin olùfẹ́ Mo ti sùn ṣùgbọ́n ọkàn mi jí
E je, eyin ore, e mu, ani e mu amuyo, eyin olufe Mo ti sun sugbon okan mi ji
Gbọ́! Olùfẹ́ mi ń kan ilẹ̀kùn
Gbo! Olufe mi n kan ilekun
Ṣí i fún mi, arábìnrin mi, olùfẹ́ mi, àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi Orí mi kún fún omi ìrì, irun mi kún fún òtútù òru
Si i fun mi, arabinrin mi, olufe mi, adaba mi, alailabawon mi Ori mi kun fun omi iri, irun mi kun fun otutu oru
Mo ti bọ́ aṣọ ìgúnwà mi ṣé èmi gbọdọ̀ tún gbé e wọ̀
Mo ti bo aso igunwa mi se emi gbodo tun gbe e wo
Mo ti wẹ ẹsẹ̀ mi ṣé èmi gbọdọ̀ tún tì í bọ eruku
Mo ti we ese mi se emi gbodo tun ti i bo eruku
Olùfẹ́ mi na ọwọ́ rẹ̀ láti inú ihò ilẹ̀kùn inú mi sì yọ́ sí i Èmi dìde láti sílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi, òjíá bẹ̀rẹ̀ sí í kán ní ọwọ́ mi, òjíá olóòórùn ń ti ara ìka mi ń ṣàn sí orí ìdìmú ìlẹ̀kùn Èmi sí ilẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi, ṣùgbọ́n olùfẹ́ mi ti kúrò, ó ti lọ ọkàn mi gbọgbẹ́ fún lílọ rẹ̀
Olufe mi na owo re lati inu iho ilekun inu mi si yo si i Emi dide lati silekun fun olufe mi, ojia bere si i kan ni owo mi, ojia olooorun n ti ara ika mi n san si ori idimu ilekun Emi si ilekun fun olufe mi, sugbon olufe mi ti kuro, o ti lo okan mi gbogbe fun lilo re
Mo wá a kiri ṣùgbọ́n, n kò rí i
Mo wa a kiri sugbon, n ko ri i
Mo pè é ṣùgbọ́n, kò dáhùn Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ ìlú rí mi bí wọ́n ti ṣe ń rìn yí ìlú ká
Mo pe e sugbon, ko dahun Awon oluso ti n so ilu ri mi bi won ti se n rin yi ilu ka
Wọ́n nà mí, wọ́n ṣá mi lọ́gbẹ́
Won na mi, won sa mi logbe
wọ́n gba ìborùn mi lọ́wọ́ mi
won gba iborun mi lowo mi
Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ odi! Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, mo bẹ̀ yín bí ẹ̀yin bá rí olùfẹ́ mi, kí ni ẹ̀yin yóò wí fún un
Awon oluso ti n so odi! Eyin omobinrin Jerusalemu, mo be yin bi eyin ba ri olufe mi, ki ni eyin yoo wi fun un
Ẹ wí fún un pé àìṣàn ìfẹ́ ń ṣe mi
E wi fun un pe aisan ife n se mi
Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tó kù lọ Ìwọ arẹwà jùlọ láàárin àwọn obìnrin
Ki ni olufe re fi dara ju awon to ku lo Iwo arewa julo laaarin awon obinrin
Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tó kù lọ tí ìwọ fi ń rọ̀ wá bẹ́ẹ̀
Ki ni olufe re fi dara ju awon to ku lo ti iwo fi n ro wa bee
Olùfẹ́ mi ní ìtànṣán ó sì pọ́n ó ní ọlá ju ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ
Olufe mi ni itansan o si pon o ni ola ju egberun mewaa lo
Orí rẹ̀ rí bí i wúrà tí ó dára jùlọ ìdì ìrun rẹ̀ rí bí i ìmọ̀ ọ̀pẹ ó sì dúdú bí i ẹyẹ ìwò Ojú rẹ̀ rí bí i ti àdàbà ní ẹ̀bá odò tí ń ṣàn, tí a fi wàrà wẹ̀, tí ó jìn, tí ó sì dákẹ́ rọ́rọ́ Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ rí bí ibùsùn tùràrí ti ó sun òórùn tùràrí dídùn Ètè rẹ̀ rí bí i ìtànná lílì ó ń kán òjíá olóòórùn dídùn Apá rẹ̀ rí bí i ọ̀pá wúrà, tí a to ohun ọ̀ṣọ́ sí yíká Ara rẹ̀ rí bí i eyín erin dídán tí a fi Ṣáfírè ṣe lọ́ṣọ̀ọ́
Ori re ri bi i wura ti o dara julo idi irun re ri bi i imo ope o si dudu bi i eye iwo Oju re ri bi i ti adaba ni eba odo ti n san, ti a fi wara we, ti o jin, ti o si dake roro Ereke re ri bi ibusun turari ti o sun oorun turari didun Ete re ri bi i itanna lili o n kan ojia olooorun didun Apa re ri bi i opa wura, ti a to ohun oso si yika Ara re ri bi i eyin erin didan ti a fi Safire se losoo
Ẹṣẹ̀ rẹ̀ rí bi i òpó mábù tí a gbé ka ihò ìtẹ̀bọ̀ wúrà dáradára Ìrísí rẹ̀ rí bí igi kédárì Lẹ́bánónì, tí dídára rẹ̀ kò ní ẹgbẹ́
Ese re ri bi i opo mabu ti a gbe ka iho itebo wura daradara Irisi re ri bi igi kedari Lebanoni, ti didara re ko ni egbe
Ẹnu rẹ̀ jẹ́ adùn fún ara rẹ̀ ó wu ni pátapáta
Enu re je adun fun ara re o wu ni patapata
Áà! Ẹ̀yín ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, Èyí ní olùfẹ́ mi, èyí sì ni ọ̀rẹ́ mi
Aa! Eyin omobinrin Jerusalemu, Eyi ni olufe mi, eyi si ni ore mi
Ọ̀rẹ́
Ore
Níbo ni olùfẹ́ rẹ lọ, Ìwọ arẹwà jùlọ láàárin àwọn obìnrin
Nibo ni olufe re lo, Iwo arewa julo laaarin awon obinrin
Níbo ni olùfẹ́ rẹ yà sí, kí a lè bá ọ wá a
Nibo ni olufe re ya si, ki a le ba o wa a
Olùfẹ́ mi ti ṣọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọgbà rẹ̀, sí ibi ibùsùn tùràrí, láti máa jẹ nínú ọgbà láti kó ìtànná lílì jọ
Olufe mi ti sokale lo sinu ogba re, si ibi ibusun turari, lati maa je ninu ogba lati ko itanna lili jo
Èmi ni ti olùfẹ́ mi, olùfẹ́ mi sì ni tèmi, Ó ń jẹ láàárin ìtànná lílì, Ìwọ lẹ́wà olùfẹ́ mi, bí i Tírísà, Ìwọ lẹ́wà bí i Jérúsálẹ́mù, ìwọ lẹ́rù bí ogun pẹ̀lú ọ̀págun
Emi ni ti olufe mi, olufe mi si ni temi, O n je laaarin itanna lili, Iwo lewa olufe mi, bi i Tirisa, Iwo lewa bi i Jerusalemu, iwo leru bi ogun pelu opagun
Yí ojú rẹ kúrò lára mi
Yi oju re kuro lara mi
nítorí ojú rẹ borí mi
nitori oju re bori mi
Irun rẹ rí bí i ọ̀wọ́ ewúrẹ́ tí ó sọ̀kalẹ̀ wá láti Gílíádì
Irun re ri bi i owo ewure ti o sokale wa lati Giliadi
Eyín rẹ rí bí ọ̀wọ́ àgùntàn, Tí ó gòkè láti ibi ìwẹ̀ rẹ̀ wá, gbogbo wọn bí ìbejì, kò sì sí ọ̀kankan tí ó yàgàn nínú wọn
Eyin re ri bi owo aguntan, Ti o goke lati ibi iwe re wa, gbogbo won bi ibeji, ko si si okankan ti o yagan ninu won
Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́bá ìbòjú rẹ, rí bí ẹ̀là èso pómégíránéètì
Ereke re leba iboju re, ri bi ela eso pomegiraneeti
Ọgọ́ta ayaba ní ń bẹ níbẹ̀, àti ọgọ́rin àlè, àti àwọn wúndíá láìníye
Ogota ayaba ni n be nibe, ati ogorin ale, ati awon wundia lainiye
Àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi, ọ̀kan ni, ọ̀kan ṣoṣo ọmọbìnrin ìyá rẹ, ààyò ẹyọkan ṣoṣo ẹni tí ó bí i
Adaba mi, alailabawon mi, okan ni, okan soso omobinrin iya re, aayo eyokan soso eni ti o bi i
Àwọn obìnrin rí i wọ́n pè é ní alábùkún fún Àwọn ayaba àti àwọn àlè gbé oríyìn fun-un Ta ni èyí tí ó tàn jáde bí i ìràwọ̀ òwúrọ̀, tí ó dára bí òṣùpá, tí ó mọ́lẹ̀ bí òòrùn, tí ó ní ẹ̀rù bí i jagunjagun pẹ̀lú ọ̀págun
Awon obinrin ri i won pe e ni alabukun fun Awon ayaba ati awon ale gbe oriyin fun-un Ta ni eyi ti o tan jade bi i irawo owuro, ti o dara bi osupa, ti o mole bi oorun, ti o ni eru bi i jagunjagun pelu opagun
Èmi ṣọ̀kalẹ̀ lọ sí ibi ọgbà èso igi láti wo àwọn ẹ̀ka igi tuntun ní àfonífojì, láti rí i bí àjàrà rúwé, tàbí bí pómégíránéètì ti rúdìí
Emi sokale lo si ibi ogba eso igi lati wo awon eka igi tuntun ni afonifoji, lati ri i bi ajara ruwe, tabi bi pomegiraneeti ti rudii
Kí èmi tó mọ̀, àárẹ̀ ọkàn mú mi, mo sì fẹ́ kí ń wà láàárin àwọn ènìyàn mi
Ki emi to mo, aare okan mu mi, mo si fe ki n wa laaarin awon eniyan mi
Padà wá, padà wá, ìwọ Ṣúlámátì
Pada wa, pada wa, iwo Sulamati
padà wá, padà wá, kí àwa kí ó lè yọ́ ọ wò Èéṣe tí ẹ̀yin fẹ́ yọ́ Ṣúlámátì wò, bí ẹni pé orin ijo Máhánáímù
pada wa, pada wa, ki awa ki o le yo o wo Eese ti eyin fe yo Sulamati wo, bi eni pe orin ijo Mahanaimu
Báwo ni ẹṣẹ̀ rẹ ti ní ẹwà tó nínú bàtà, Ìwọ ọmọbìnrin ọba! Oríkèé itan rẹ rí bí ohun ọ̀ṣọ́ iṣẹ́ ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà Ìdodo rẹ rí bí àwo tí kì í ṣe aláìní ọtí, ìbàdí rẹ bí òkìtì àlìkámà tí a fi lílì yíká
Bawo ni ese re ti ni ewa to ninu bata, Iwo omobinrin oba! Orikee itan re ri bi ohun oso ise ologbon onisona Idodo re ri bi awo ti ki i se alaini oti, ibadi re bi okiti alikama ti a fi lili yika
Ọmú rẹ rí bí abo àgbọ̀nrín méjì tí wọ́n jẹ́ ìbejì àgbọ̀nrín
Omu re ri bi abo agbonrin meji ti won je ibeji agbonrin
Ọrùn rẹ rí bí ilé ìṣọ́ eyín-erin
Orun re ri bi ile iso eyin-erin
Ojú rẹ rí bí adágún ní Héṣébónì ní ẹ̀bá ẹnu ìbodè Bátírábímù
Oju re ri bi adagun ni Heseboni ni eba enu ibode Batirabimu
Imú rẹ rí bí ilé ìṣọ́ Lẹ́bánónì tí ó kọ ojú sí Dámásíkù
Imu re ri bi ile iso Lebanoni ti o ko oju si Damasiku
Bí òkè kámẹlì ṣe ṣe adé yí àwọn òkè ká Bẹ́ẹ̀ ni irun orí rẹ ṣe adé yí orí rẹ ká a fi àìdi irun rẹ mú ọba ní ìgbèkùn
Bi oke kameli se se ade yi awon oke ka Bee ni irun ori re se ade yi ori re ka a fi aidi irun re mu oba ni igbekun
Báwo ni ẹwà rẹ ti pọ̀ tó báwo ni o sì ti dára tó ìwọ olùfẹ́ mi nínú ìfẹ́! Ìdúró rẹ rí bí igi ọ̀pẹ, àti ọmú rẹ bí idì èso àjàrà
Bawo ni ewa re ti po to bawo ni o si ti dara to iwo olufe mi ninu ife! Iduro re ri bi igi ope, ati omu re bi idi eso ajara
Mo ní, Èmi yóò gun igi ọ̀pẹ lọ
Mo ni, Emi yoo gun igi ope lo
Èmi yóò di ẹ̀ka rẹ̀ mú Kí ọmú rẹ rí bí ìdì èso àjàrà, Àti èémi imú rẹ bí i ápù
Emi yoo di eka re mu Ki omu re ri bi idi eso ajara, Ati eemi imu re bi i apu
Àti ìfẹnukonu rẹ rí bí ọtí wáìnì tí ó dára jùlọ
Ati ifenukonu re ri bi oti waini ti o dara julo
Tí ó kúnná tí ó sì dùn, tí ń mú kí ètè àwọn tí ó sùn kí ó sọ̀rọ̀ Ti olùfẹ́ mi ni èmi í ṣe, èmí sì ni ẹni tí ó wù ú
Ti o kunna ti o si dun, ti n mu ki ete awon ti o sun ki o soro Ti olufe mi ni emi i se, emi si ni eni ti o wu u
Wá, olùfẹ́ mi, jẹ́ kí a lọ sí ibi pápá, Jẹ́ kí a lo àṣálẹ̀ ní àwọn ìletò Jẹ́ kí a lọ sínú ọgbà àjàrà ní kùtùkùtù láti wo bí àjàrà rúwé bí ìtànná àjàrà bá là
Wa, olufe mi, je ki a lo si ibi papa, Je ki a lo asale ni awon ileto Je ki a lo sinu ogba ajara ni kutukutu lati wo bi ajara ruwe bi itanna ajara ba la
Àti bí póméegíránéètì bá ti rúdí, níbẹ̀ ni èmi yóò ti fi ìfẹ́ mi fún ọ
Ati bi pomeegiraneeti ba ti rudi, nibe ni emi yoo ti fi ife mi fun o
Àwọn èṣo mánídárákì mú òórùn wọn jáde ní ẹnu ọ̀nà wa ni onírúurú àṣàyàn èso, èso ọ̀tún àti àkúgbó tí mo ti kó pamọ́ fún ọ, olùfẹ́ mi
Awon eso manidaraki mu oorun won jade ni enu ona wa ni oniruuru asayan eso, eso otun ati akugbo ti mo ti ko pamo fun o, olufe mi
Ọ̀rẹ́
Ore
Ìwọ ìbá rí bí arákùnrin mi sí mi èyí tí ó mú ọmú ìyá mi dàgbà! Èmi ìbá rí ọ ní òde, èmi ìbá fi ẹnu kò ọ́ ní ẹnu, wọn kì bá fi mi ṣe ẹlẹ́yà
Iwo iba ri bi arakunrin mi si mi eyi ti o mu omu iya mi dagba! Emi iba ri o ni ode, emi iba fi enu ko o ni enu, won ki ba fi mi se eleya
Èmi ìbá fi ọ̀nà hàn ọ́ èmi ìbá mú ọ wá sínú ilé ìyá mi, ìwọ ìbá kọ́ mi èmi ìbá fi ọtí wáìnì olóòrùn dídùn fún ọ mu àti oje èso pómégíránéètì mi
Emi iba fi ona han o emi iba mu o wa sinu ile iya mi, iwo iba ko mi emi iba fi oti waini oloorun didun fun o mu ati oje eso pomegiraneeti mi
Ọwọ́ òsì rẹ ìbá wà ní abẹ́ orí mi, ọwọ́ ọ̀tún rẹ ìbá sì gbá mí mọ́ra
Owo osi re iba wa ni abe ori mi, owo otun re iba si gba mi mora
Ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, èmi pè yín ní ìjà, Ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè, Ẹ má ṣe jí i títí tí yóò fi wù ú
Omobinrin Jerusalemu, emi pe yin ni ija, E ma se ru olufe mi soke, E ma se ji i titi ti yoo fi wu u
Ta ni ẹni tí ń gòkè bọ̀ wá láti ihà, tí ó fi ara ti olùfẹ́ rẹ̀ ní abẹ́ igi ápù ni mo ti jí ọ dìde
Ta ni eni ti n goke bo wa lati iha, ti o fi ara ti olufe re ni abe igi apu ni mo ti ji o dide
níbẹ̀ ni ẹni tí ń rọbí bí ọ sí
nibe ni eni ti n robi bi o si
Gbé mi sí àyà rẹ bí èdìdì bí èdìdì lé apá rẹ
Gbe mi si aya re bi edidi bi edidi le apa re
nítorí ìfẹ́ lágbára bí ikú, ìjowú sì le bí isà òkú jíjò rẹ̀ rí bí ìjò iná, gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ iná Olúwa
nitori ife lagbara bi iku, ijowu si le bi isa oku jijo re ri bi ijo ina, gege bi owo ina Oluwa
Omi púpọ̀ kò le paná ìfẹ́
Omi pupo ko le pana ife
Bẹ́ẹ̀ ni gbígbá omi kò le gbá a lọ
Bee ni gbigba omi ko le gba a lo
Bí ènìyàn bá fún ìfẹ́, ní gbogbo ọrọ̀ ilé rẹ̀, a ó kẹ́gàn rẹ̀ pátapáta
Bi eniyan ba fun ife, ni gbogbo oro ile re, a o kegan re patapata
Àwa ní arábìnrin kékeré kan, òun kò sì ní ọmú, kí ni àwa yóò fún arábìnrin wa, ní ọjọ́ tí a ó bá fẹ́ ẹ
Awa ni arabinrin kekere kan, oun ko si ni omu, ki ni awa yoo fun arabinrin wa, ni ojo ti a o ba fe e
Bí òun bá jẹ́ ògiri, Àwa yóò kọ́ ilé odi fàdákà lé e lórí
Bi oun ba je ogiri, Awa yoo ko ile odi fadaka le e lori
Bí òun bá jẹ́ ilẹ̀kùn, Àwa yóò fi pákó kédárì dí i Èmi jẹ́ ògiri, ọmú mi sì rí bí ilé ìṣọ́ bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe rí ní ojú rẹ̀ bí ẹni tí ń mú àlàáfíà wá
Bi oun ba je ilekun, Awa yoo fi pako kedari di i Emi je ogiri, omu mi si ri bi ile iso bee ni mo se ri ni oju re bi eni ti n mu alaafia wa
Sólómónì ní ọgbà àjàrà kan ní Báálí-Hómónì ó gbé ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́jú olúkúlùkù ni ó ń mú èso rẹ̀ wá ẹgbẹ̀rún fàdákà
Solomoni ni ogba ajara kan ni Baali-Homoni o gbe ogba ajara re fun awon alagbatoju olukuluku ni o n mu eso re wa egberun fadaka
Ṣùgbọ́n ọgbà àjàrà mi jẹ́ tèmi, ó wà fún mi
Sugbon ogba ajara mi je temi, o wa fun mi
ẹgbẹ̀rún ṣékélì jẹ́ tìrẹ, ìwọ Sólómónì, igba sì jẹ́ ti àwọn alágbàtọ́jú èso
egberun sekeli je tire, iwo Solomoni, igba si je ti awon alagbatoju eso
Ìwọ tí ń gbé inú ọgbà, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ dẹtí sí ohùn rẹ, Jẹ́ kí èmi náà gbọ́ ohùn rẹ! Yára wá, Olùfẹ́ mi, kí ìwọ kí ó sì rí bí abo egbin, tàbí gẹ́gẹ́ bí ọmọ àgbọ̀nrín, lórí òkè òórùn dídùn
Iwo ti n gbe inu ogba, awon ore re deti si ohun re, Je ki emi naa gbo ohun re! Yara wa, Olufe mi, ki iwo ki o si ri bi abo egbin, tabi gege bi omo agbonrin, lori oke oorun didun
Iṣẹ́ Títù Sí Kírétè
Ise Titu Si Kirete
Pọ́ọ̀lù, ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti Àpósítélì Jésù Kírísítì, gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run, àti ìmọ̀ òtítọ́ irú èyí tí í máa darí ènìyàn sí ìgbé ayé ìwà bí Ọlọ́run— ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ tí ó dúró lórí ìrètí iyè àìnípẹ̀kun, èyí tí Ọlọ́run tí kì í purọ́ ti se ìlérí rẹ̀ ṣáájú kí ayé tó bẹ̀rẹ̀, àti pé ní àkókò tirẹ̀, òun ti fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ hàn nínú ìwàásù tí a fi lé mi lọ́wọ́ nípa àṣẹ Ọlọ́run Olùgbàlà wa
Poolu, iranse Olorun ati Apositeli Jesu Kirisiti, gege bi igbagbo awon ayanfe Olorun, ati imo otito iru eyi ti i maa dari eniyan si igbe aye iwa bi Olorun— igbagbo ati imo ti o duro lori ireti iye ainipekun, eyi ti Olorun ti ki i puro ti se ileri re saaju ki aye to bere, ati pe ni akoko tire, oun ti fi oro re han ninu iwaasu ti a fi le mi lowo nipa ase Olorun Olugbala wa
Sí Títù, ọmọ mi tòótọ́ nínú ìgbàgbọ́ wa kan náà
Si Titu, omo mi tooto ninu igbagbo wa kan naa
Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba àti Kírísítì Jésù Olùgbàlà wa
Oore-ofe ati alaafia lati odo Olorun baba ati Kirisiti Jesu Olugbala wa
Ìdí tí mo fi fi ọ́ sílẹ̀ ní Kírétè ni pé kí o lè ṣe àsepé àwọn iṣẹ́ tó sẹ́kù
Idi ti mo fi fi o sile ni Kirete ni pe ki o le se asepe awon ise to seku
Mo sì ń rọ̀ ọ́ kí o yan àwọn alàgbà ní ìlú kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí mo ṣe darí rẹ̀
Mo si n ro o ki o yan awon alagba ni ilu kookan gege bi mo se dari re
Ẹni tí yóò jẹ́ alàgbà gbọdọ̀ jẹ́ aláìlábùkù, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onìyàwó kan, ọmọ wọn náà gbọdọ̀ jẹ́ onígbàgbọ́ tí kò ní ẹ̀sùn ìwà ipá tàbí ẹ̀sùn àìgbọ́ràn kankan
Eni ti yoo je alagba gbodo je alailabuku, won gbodo je oniyawo kan, omo won naa gbodo je onigbagbo ti ko ni esun iwa ipa tabi esun aigboran kankan
Alámójútó jẹ́ ẹni tí a gbé iṣẹ́ Ọlọ́run lé lọ́wọ́, nítorí náà, kò gbọdọ̀ ní àbùkù kankan tàbí agbéraga, oníjà, kò gbọdọ̀ jẹ́ ọ̀mùtí tàbí alágídí tàbí olójúkòkòrò
Alamojuto je eni ti a gbe ise Olorun le lowo, nitori naa, ko gbodo ni abuku kankan tabi agberaga, onija, ko gbodo je omuti tabi alagidi tabi olojukokoro
Wọ́n ní láti jẹ́ olùfẹ́ àlejò ṣíṣe, olùfẹ́ ohun tí ó dára
Won ni lati je olufe alejo sise, olufe ohun ti o dara
Wọ́n ní láti jẹ́ ẹni tí ó kò ara rẹ̀ ní ìjánu, ẹni dúró sinsin, ọlọ́kàn mímọ́, àti ẹni oníwàtítọ́
Won ni lati je eni ti o ko ara re ni ijanu, eni duro sinsin, olokan mimo, ati eni oniwatito