diacritcs
stringlengths
1
36.7k
no_diacritcs
stringlengths
1
35.5k
Gbogbo wọn yóò sì dàbí ọkùnrin alágbára ni ogun tí ń tẹ àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀ ní ìgboro, wọn ó sì jagun, nítorí Olúwa wà pẹ̀lú wọn, wọn ó sì dààmú àwọn tí ń gun ẹṣin
Gbogbo won yoo si dabi okunrin alagbara ni ogun ti n te awon ota won mole ni igboro, won o si jagun, nitori Oluwa wa pelu won, won o si daamu awon ti n gun esin
Èmi o sì mú ilé Júdà ní agbára, èmi o sì gba ilé Jósẹ́fù là, èmi ó sì tún mú wọn padà nítorí mo tí ṣàánú fún wọn, ó sì dàbí ẹni pé èmi kò ì tìí ta wọ́n nù
Emi o si mu ile Juda ni agbara, emi o si gba ile Josefu la, emi o si tun mu won pada nitori mo ti saanu fun won, o si dabi eni pe emi ko i tii ta won nu
nítorí èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn, èmi o sì gbọ́ ti wọn Éfúráímù yóò sì ṣe bí alágbára, ọkàn wọn yóò sì yọ̀ bi ẹni pé nípa ọtí-wáìnì
nitori emi ni Oluwa Olorun won, emi o si gbo ti won Efuraimu yoo si se bi alagbara, okan won yoo si yo bi eni pe nipa oti-waini
àní àwọn ọmọ wọn yóò rí í, wọn o sì yọ̀, inú wọn ó sì dùn nínú Olúwa
ani awon omo won yoo ri i, won o si yo, inu won o si dun ninu Oluwa
Èmi ó kọ sí wọn, èmi ó sì ṣà wọ́n jọ
Emi o ko si won, emi o si sa won jo
nítorí èmi tí rà wọ́n padà
nitori emi ti ra won pada
wọn ó sì pọ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí wọ́n tí ń pọ̀ sí í rí
won o si po si i gege bi won ti n po si i ri
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo tú wọn kákiri orílẹ̀-èdè
Bi o tile je pe mo tu won kakiri orile-ede
ṣíbẹ̀ wọn ó sì rántí mi ni ilẹ̀ jínjìn
sibe won o si ranti mi ni ile jinjin
wọn ó sì gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, wọn ó sì tún padà
won o si gbe pelu awon omo won, won o si tun pada
Èmi ó sì tún mú wọn padà kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì pẹ̀lú, èmi ó sì ṣà wọn jọ kúrò ni ilẹ̀ Áṣíríà
Emi o si tun mu won pada kuro ni ile Ejibiti pelu, emi o si sa won jo kuro ni ile Asiria
èmi ó sì mú wọn wá sí ilẹ̀ Gílíádì àti Lébánónì
emi o si mu won wa si ile Giliadi ati Lebanoni
a a kì yóò sì rí àyè fún wọn bí ó ti yẹ
a a ki yoo si ri aye fun won bi o ti ye
Wọn yóò sì la òkun wàhálà já, yóò sì lu rírú omi nínú òkun, gbogbo ibú odò ni yóò sì gbẹ, a ó sì rẹ ìgbéraga Áṣíríà ṣílẹ̀, ọ̀pá aládé Éjíbítì yóò sí lọ kúrò
Won yoo si la okun wahala ja, yoo si lu riru omi ninu okun, gbogbo ibu odo ni yoo si gbe, a o si re igberaga Asiria sile, opa alade Ejibiti yoo si lo kuro
Èmi ó sì mú wọn ní agbára nínú Olúwa
Emi o si mu won ni agbara ninu Oluwa
wọn ó sì rìn sókè rìn sódò ni orúkọ rẹ̀, ni Olúwa wí
won o si rin soke rin sodo ni oruko re, ni Oluwa wi
Olùṣọ́ Àgùntàn Méjì
Oluso Aguntan Meji
Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ sílẹ̀, ìwọ Lébánónì, kí iná bá lè jẹ igi Kédárì rẹ run, Pohùnréré-ẹkún, igi fírì
Si awon ilekun re sile, iwo Lebanoni, ki ina ba le je igi Kedari re run, Pohunrere-ekun, igi firi
nítorí igi Kédárì ṣubú, nítorí tí a ba àwọn igi tí o lógo jẹ́
nitori igi Kedari subu, nitori ti a ba awon igi ti o logo je
ṣunkún kíkorò ẹ̀yin igi óákù tí Básánì, nítorí gé igbó àjàrà lulẹ̀
sunkun kikoro eyin igi oaku ti Basani, nitori ge igbo ajara lule
Gbọ́ ohun igbe àwọn olùṣọ́-àgùntàn
Gbo ohun igbe awon oluso-aguntan
ògo wọn bàjẹ́
ogo won baje
gbọ́ ohùn bíbú àwọn ọmọ kìnnìún nítorí ògo Jódánì bàjẹ́
gbo ohun bibu awon omo kinniun nitori ogo Jodani baje
Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run mi wí Bọ́ ọ̀wọ́-ẹran àbọ́pa
Bayii ni Oluwa Olorun mi wi Bo owo-eran abopa
Tí àwọn olúwa wọn ń pa wọ́n, tí wọn kò sì ka ara wọn sí pé wọn jẹ̀bi
Ti awon oluwa won n pa won, ti won ko si ka ara won si pe won jebi
àti àwọn tí ń tà wọ́n wí pé, Ìbùkún ni fún Olúwa , nítorí tí mo dí ọlọ́rọ̀! Àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọn kò sì ṣàánú wọn
ati awon ti n ta won wi pe, Ibukun ni fun Oluwa , nitori ti mo di oloro! Awon oluso aguntan won ko si saanu won
Nítorí èmi kì yóò ṣàánú fún àwọn ara ilẹ̀ náà mọ́, ni Olúwa wí, Ṣí kíyèsí í, èmi yóò fi olúkúlúkù ènìyàn lé aládùúgbò rẹ̀ lọ́wọ́, àti lé ọwọ́ ọba rẹ̀, wọn yóò sì fọ́ ilẹ̀ náà, èmi kì yóò sì gbà wọ́n lọ́wọ́ wọn
Nitori emi ki yoo saanu fun awon ara ile naa mo, ni Oluwa wi, Si kiyesi i, emi yoo fi olukuluku eniyan le aladuugbo re lowo, ati le owo oba re, won yoo si fo ile naa, emi ki yoo si gba won lowo won
Èmi yóò sì bọ́ ẹran àbọ́pa, àní ẹ̀yin òtòsì nínú ọ̀wọ́ ẹran
Emi yoo si bo eran abopa, ani eyin otosi ninu owo eran
Mo sì mu ọ̀pá méjì ṣọ́dọ̀
Mo si mu opa meji sodo
mo pè ọ̀kan ni Oore-ọ̀fẹ́, mo pè èkejì ni Àmùrè
mo pe okan ni Oore-ofe, mo pe ekeji ni Amure
mo sì bọ́ ọ̀wọ́-ẹran náa
mo si bo owo-eran naa
Olùṣọ àgùntàn mẹ́ta ni mo sì gé kúrò ní oṣù kan
Oluso aguntan meta ni mo si ge kuro ni osu kan
Ọkàn mi sì kòrìíra wọn, ọkàn wọn pẹ̀lú sì kóríra mi
Okan mi si koriira won, okan won pelu si korira mi
Mo sì wí pé, Èmi kì yóò bọ́ yin
Mo si wi pe, Emi ki yoo bo yin
èyí ti ń ku lọ, jẹ́ kí òkú o kú
eyi ti n ku lo, je ki oku o ku
èyí tí a o ba sì gé kúrò, jẹ́ kí a gé e kúrò
eyi ti a o ba si ge kuro, je ki a ge e kuro
ki olúkúlùkù nínú àwọn ìyókù jẹ́ ẹran-ara ẹnìkejì rẹ̀
ki olukuluku ninu awon iyoku je eran-ara enikeji re
Mo sì mu ọ̀pá mi, ti a ń pè ní Oore-ọ̀fẹ́, mo ṣẹ́ ẹ méjì, ki èmi bá lè da májẹ̀mu mi tí mo tí bá gbogbo àwọn ènìyàn náà dá
Mo si mu opa mi, ti a n pe ni Oore-ofe, mo se e meji, ki emi ba le da majemu mi ti mo ti ba gbogbo awon eniyan naa da
Ó sì dá ni ọjọ́ náà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn òtòsì nínú ọ̀wọ́-ẹran náà ti o dúró tì mí mọ̀ pé, ọ̀rọ̀ Olúwa ni
O si da ni ojo naa, bee ni awon otosi ninu owo-eran naa ti o duro ti mi mo pe, oro Oluwa ni
Mo sì wí fún wọn pé, Bí ó bá dára ní ojú yin, ẹ fún mi ni owó-ọ̀yà mi
Mo si wi fun won pe, Bi o ba dara ni oju yin, e fun mi ni owo-oya mi
bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ mú un lọ́wọ́
bi bee ko, e mu un lowo
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wọn ọgbọ̀n owó fàdákà fún iye owó-ọ̀yà mi
Bee ni won won ogbon owo fadaka fun iye owo-oya mi
Olúwa sì wí fún mi pé, Ṣọ ọ sí àpótí ìsúra! Iye dáradára náà, tí wọn yọ owó mi sí
Oluwa si wi fun mi pe, So o si apoti isura! Iye daradara naa, ti won yo owo mi si
Mo sì mu ọgbọ̀n owo fàdákà náà, mo sì sọ wọ́n sí àpótí ìsúra ní ilé Olúwa
Mo si mu ogbon owo fadaka naa, mo si so won si apoti isura ni ile Oluwa
Mo sì ṣẹ́ ọ̀pá mi kejì, àní Àmùrè, sí méjì, kí èmi lè ya ìbátan tí ó wà láàrin Júdà àti láàrin Íṣírẹ́lì
Mo si se opa mi keji, ani Amure, si meji, ki emi le ya ibatan ti o wa laarin Juda ati laarin Isireli
Olúwa sì wí fún mi pé, Tún mú ohun-èlò Olùṣọ́-àgùntàn búburú kan ṣọ́dọ̀ rẹ̀
Oluwa si wi fun mi pe, Tun mu ohun-elo Oluso-aguntan buburu kan sodo re
Nítorí Èmi o gbé olùṣọ́-àgùntàn kan dídé ni ilẹ̀ náà, tí kí yóò bẹ àwọn tí ó ṣègbé wò, ti kì yóò sì wá èyí tí ó yapa
Nitori Emi o gbe oluso-aguntan kan dide ni ile naa, ti ki yoo be awon ti o segbe wo, ti ki yoo si wa eyi ti o yapa
tí kì yóò ṣe ìtọ́jú èyí tí a pa lára tàbí kí ó bọ́ àwọn tí ara wọn dá pépé
ti ki yoo se itoju eyi ti a pa lara tabi ki o bo awon ti ara won da pepe
Ṣùgbọ́n òun yóò jẹ ẹran èyi tí ó ni ọ̀rá, yóò sì fa èékánna wọn ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ
Sugbon oun yoo je eran eyi ti o ni ora, yoo si fa eekanna won ya perepere
Ègbé ni fún olùṣọ́-àgùntàn aṣán náà, tí ó fi ọ̀wọ́-ẹran sílẹ́! Idà yóò ge apá rẹ̀ àti ojú ọ̀tún rẹ̀
Egbe ni fun oluso-aguntan asan naa, ti o fi owo-eran sile! Ida yoo ge apa re ati oju otun re
apá rẹ̀ yóò gbẹ pátapáta, ojú ọ̀tún rẹ̀ yóò sì fọ́ pátapáta! A Ó Pa Àwọn Ọ̀ta Íṣírẹ́lì Run
apa re yoo gbe patapata, oju otun re yoo si fo patapata! A O Pa Awon Ota Isireli Run
Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa fún Íṣírẹ́lì, ni Olúwa wí, ẹni tí ó na àwọn ọ̀run, tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé ṣọlẹ̀, tí ó sì da ẹ̀mi ènìyàn tí ń bẹ ni inú rẹ̀
Oro-imo oro Oluwa fun Isireli, ni Oluwa wi, eni ti o na awon orun, ti o si fi ipile aye sole, ti o si da emi eniyan ti n be ni inu re
Kíyèsí í, èmi yóò ṣọ Jérúsálẹ́mù dí àgọ́ ìwárìrì sí gbogbo ènìyàn yíká, nígbà tí wọn yóò dó ti Júdà àti Jérúsálẹ́mù
Kiyesi i, emi yoo so Jerusalemu di ago iwariri si gbogbo eniyan yika, nigba ti won yoo do ti Juda ati Jerusalemu
Ní ọjọ́ náà, nígbà tí gbogbo orilẹ̀-èdè ayé bá parapọ̀ sí i, ni èmi yóò sọ Jérúsálẹ́mù di ẹrù òkúta fún gbogbo ènìyàn
Ni ojo naa, nigba ti gbogbo orile-ede aye ba parapo si i, ni emi yoo so Jerusalemu di eru okuta fun gbogbo eniyan
gbogbo àwọn tí ó bá sì fi dẹ́rù pa ara wọn ni a ó ge sí wẹ́wẹ́, ní ọjọ́ náà, ni Olúwa wí, Ni èmi yóò fí ìdágìrì lu gbogbo ẹṣin, àti fi òmùgọ̀ kọlu ẹni tí ń gun un
gbogbo awon ti o ba si fi deru pa ara won ni a o ge si wewe, ni ojo naa, ni Oluwa wi, Ni emi yoo fi idagiri lu gbogbo esin, ati fi omugo kolu eni ti n gun un
èmi yóò sì sí ojú mi sí ilé Júdà, èmi yóò sì bu ìfọ́jú lu gbogbo ẹṣin tí orílẹ̀-èdè
emi yoo si si oju mi si ile Juda, emi yoo si bu ifoju lu gbogbo esin ti orile-ede
Àti àwọn baálẹ̀ Júdà yóò sì wí ni ọkàn wọn pé, Àwọn ara Jérúsálẹ́mù ni agbára mi nípa Olúwa Ọlọ́run wọn
Ati awon baale Juda yoo si wi ni okan won pe, Awon ara Jerusalemu ni agbara mi nipa Oluwa Olorun won
Ní ọjọ́ náà, ni èmi yóò se àwọn baálẹ̀ Júdà bí ààrò iná kan láàrin igi, àti bi ẹfúùfù iná láàrin ìtí
Ni ojo naa, ni emi yoo se awon baale Juda bi aaro ina kan laarin igi, ati bi efuufu ina laarin iti
wọn yóò sì jẹ gbogbo àwọn ènìyàn run yíká lápá ọ̀tún àti lápá òsì
won yoo si je gbogbo awon eniyan run yika lapa otun ati lapa osi
a ó sì tún máa gbé inú Jérúsálẹ́mù ní ipò rẹ̀
a o si tun maa gbe inu Jerusalemu ni ipo re
Olúwa pẹ̀lú yóò kọ́ tètè gba àgọ́ Júdà là ná, kí ògo ilé Dáfídì àti ògo àwọn ara Jérúsálẹ́mù má ba gbé ara wọn ga sí Júdà
Oluwa pelu yoo ko tete gba ago Juda la na, ki ogo ile Dafidi ati ogo awon ara Jerusalemu ma ba gbe ara won ga si Juda
Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò dáàbò bò àwọn tí ń gbé Jérúsálẹ́mù
Ni ojo naa ni Oluwa yoo daabo bo awon ti n gbe Jerusalemu
ẹni tí ó bá sì ṣe àìlera nínú wọn ní ọjọ́ náà, yóò dàbí Dáfídì
eni ti o ba si se ailera ninu won ni ojo naa, yoo dabi Dafidi
ilé Dáfídì yóò sì dàbí Ọlọ́run, bí ańgẹ́lì Olúwa níwájú wọn
ile Dafidi yoo si dabi Olorun, bi angeli Oluwa niwaju won
Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, èmi yóò wá láti pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè run tí ó wá kọjú ìjà sí Jérúsálẹ́mù
Yoo si se ni ojo naa, emi yoo wa lati pa gbogbo awon orile-ede run ti o wa koju ija si Jerusalemu
Èmi ó sì tu ẹ̀mí oore-ọ̀fẹ́ àti ẹ̀bẹ̀ ṣórí ilé Dáfídì àti sórí Jérúsálẹ́mù
Emi o si tu emi oore-ofe ati ebe sori ile Dafidi ati sori Jerusalemu
wọn ó sì máa wo ẹni tí wọn tí gún ni ọ̀kọ̀, wọn ó sì máa sọ̀fọ̀ rẹ̀, bí ẹnìkan ti ń sọ̀fọ̀ fún ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo àti gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí wọn yóò sì wà ni ìbànújẹ́, bí ẹni tí ń banújẹ́ fún àkọ́bí rẹ̀
won o si maa wo eni ti won ti gun ni oko, won o si maa sofo re, bi enikan ti n sofo fun omo re kan soso ati gege bi eniyan ti won yoo si wa ni ibanuje, bi eni ti n banuje fun akobi re
Ní ọjọ́ náà ni ẹkún, ńláńlá yóò wà ni Jérúsálẹ́mù, gẹ́gẹ́ bí ọ̀fọ̀ Hádádì Rímónì ni àfonífojì Mégídónì
Ni ojo naa ni ekun, nlanla yoo wa ni Jerusalemu, gege bi ofo Hadadi Rimoni ni afonifoji Megidoni
Ilẹ̀ náà yóò ṣọ̀fọ̀, ìdílé, ìdílé, lọ́tọ̀ọ̀tọ̀
Ile naa yoo sofo, idile, idile, lotooto
ìdílé Dáfídì lọ́tọ̀
idile Dafidi loto
àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀
ati awon aya won loto
ìdílé Nátanì lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ́
idile Natani loto, ati awon aya won loto
Ìdílé Léfì lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀
Idile Lefi loto, ati awon aya won loto
ìdílé Ṣimei lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀
idile Simei loto, ati awon aya won loto
Gbogbo àwọn ìdílé tí o kù, ìdílé, ìdílé, lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀
Gbogbo awon idile ti o ku, idile, idile, lotooto, ati awon aya won loto
Ìwẹ̀nùmọ́ Kúrò Nínú Ẹ̀ṣẹ̀
Iwenumo Kuro Ninu Ese
Ní ọjọ́ náà isun kan yóò sí sílẹ̀ fún ilé Dáfídì àti fún àwọn ará Jérúsálẹ́mù, láti wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti àìmọ́ wọn
Ni ojo naa isun kan yoo si sile fun ile Dafidi ati fun awon ara Jerusalemu, lati we won mo kuro ninu ese ati aimo won
Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ni èmi ó gé orúkọ àwọn òrìṣà kúrò ni ilẹ̀ náà, a kì yóò sì rántí wọn mọ́
Yoo si se ni ojo naa ni Oluwa awon omo-ogun wi, ni emi o ge oruko awon orisa kuro ni ile naa, a ki yoo si ranti won mo
àti pẹ̀lú èmi ó mú àwọn wòlíì èké àti àwọn ẹ̀mí àìmọ́ kọjá kúrò ni ilẹ̀ náà
ati pelu emi o mu awon wolii eke ati awon emi aimo koja kuro ni ile naa
Yóò sì ṣe, nígbà tí ẹnìkan yóò ṣọtẹ́lẹ̀ ṣíbẹ̀, ni baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ tí ó bí í yóò wí fún un pé, Ìwọ ki yóò yè
Yoo si se, nigba ti enikan yoo sotele sibe, ni baba re ati iya re ti o bi i yoo wi fun un pe, Iwo ki yoo ye
nítorí ìwọ ń sọ ọ̀rọ̀ èké ni orúkọ Olúwa
nitori iwo n so oro eke ni oruko Oluwa
Àti baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ tí o bí í yóò gun un ni àgúnpa nígbà tí ó bá ṣọtẹ́lẹ̀
Ati baba re ati iya re ti o bi i yoo gun un ni agunpa nigba ti o ba sotele
Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, ojú yóò tí àwọn wòlíì èké olúkúlúkù nítorí ìran rẹ̀, nígbà tí òun ba tí ṣọtẹ́lẹ̀
Yoo si se ni ojo naa, oju yoo ti awon wolii eke olukuluku nitori iran re, nigba ti oun ba ti sotele
bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì wọ aṣọ wòlíì onírun rẹ̀ tí o fi ń tan ní jẹ
bee ni won ki yoo si wo aso wolii onirun re ti o fi n tan ni je
Ṣùgbọ́n òun o wí pé, Èmi kí í ṣe wòlíì, àgbẹ̀ ni èmi
Sugbon oun o wi pe, Emi ki i se wolii, agbe ni emi
nítorí tí a ti fi mí ṣe ìránṣẹ́ láti ìgbà èwe mi wá
nitori ti a ti fi mi se iranse lati igba ewe mi wa
Ẹnìkan ó sì wí fún un pé, Ọgbẹ́ kín ní wọ̀nyí ni ẹ̀yìn rẹ
Enikan o si wi fun un pe, Ogbe kin ni wonyi ni eyin re
Òun o sì dáhùn pé, Wọ̀nyí ni ibi tí a ti sá mi ní ilé àwọn ọ̀rẹ́ mi
Oun o si dahun pe, Wonyi ni ibi ti a ti sa mi ni ile awon ore mi
Díde, ìwọ idà, sí olùṣọ́-àgùntàn mi, àti sí ẹni tí í ṣe ẹnìkejì mi, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí
Dide, iwo ida, si oluso-aguntan mi, ati si eni ti i se enikeji mi, ni Oluwa awon omo-ogun wi
Kọlu Olùṣọ́-àgùntàn, àwọn àgùntàn a sì túká
Kolu Oluso-aguntan, awon aguntan a si tuka
èmi o sì yí ọwọ́ mi sí àwọn kékèké
emi o si yi owo mi si awon kekeke
Yóò sì ṣe, ni gbogbo ilẹ̀, ni Olúwa wí, a ó gé apá méjì nínú rẹ̀ kúrò yóò sì kú
Yoo si se, ni gbogbo ile, ni Oluwa wi, a o ge apa meji ninu re kuro yoo si ku
ṣùgbọ́n apá kẹta yóò kù nínú rẹ̀
sugbon apa keta yoo ku ninu re
Èmi ó sì mú apá kẹ́ta náà la àárin iná, èmi yóò sì yọ́ wọn bí a ti yọ́ fàdákà, èmi yóò sì dán wọn wò, bi a tí ń dán góòlu wò
Emi o si mu apa keta naa la aarin ina, emi yoo si yo won bi a ti yo fadaka, emi yoo si dan won wo, bi a ti n dan goolu wo
wọn yóò sì pé orúkọ mi, èmi yóò sì dá wọn lóhùn
won yoo si pe oruko mi, emi yoo si da won lohun
èmi yóò wí pé, Àwọn ènìyàn mi ni, àwọn yóò sì wí pé, Olúwa ni Ọlọ́run wa
emi yoo wi pe, Awon eniyan mi ni, awon yoo si wi pe, Oluwa ni Olorun wa
Kíyèsí i, ọjọ́ Olúwa ń bọ̀, a ó sì pín ìkógun rẹ̀ láàrin rẹ̀
Kiyesi i, ojo Oluwa n bo, a o si pin ikogun re laarin re
Nítorí èmi ó kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí Jérúsálẹ́mù fún ogun
Nitori emi o ko gbogbo orile-ede jo si Jerusalemu fun ogun
a ó sì ko ìlú naà, a ó sì kó àwọn ilé, a ó sì ba àwọn obìnrin jẹ́, ààbọ̀ ìlú náà yóò lọ sí ìgbékùn, a kì yóò sì gé ìyókù àwọn ènìyàn náà kúrò ni ìlú náà
a o si ko ilu naa, a o si ko awon ile, a o si ba awon obinrin je, aabo ilu naa yoo lo si igbekun, a ki yoo si ge iyoku awon eniyan naa kuro ni ilu naa
Nígbà náà ni Olúwa yóò jáde lọ, yóò sì bá àwọn orílẹ̀-èdè náa jà, gẹ́gẹ́ bí í ti ìjà ní ọjọ́ ogun
Nigba naa ni Oluwa yoo jade lo, yoo si ba awon orile-ede naa ja, gege bi i ti ija ni ojo ogun