diacritcs
stringlengths
1
36.7k
no_diacritcs
stringlengths
1
35.5k
Ẹṣẹ̀ rẹ̀ yóò sì dúró ni ọjọ́ náà lórí òkè Ólífì, tí ó wà níwájú Jérúsálẹ́mù ni ila-oòrùn, òkè Ólífì yóò sì làá sí méjì, sí ìhà ilà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrun, àfonífojì ńláńlá yóò wà
Ese re yoo si duro ni ojo naa lori oke Olifi, ti o wa niwaju Jerusalemu ni ila-oorun, oke Olifi yoo si laa si meji, si iha ila-oorun ati iha iwo-oorun, afonifoji nlanla yoo wa
ìdajì òké náà yóò sì sí síhà àríwá, àti ìdajì rẹ̀ síhà gúṣù
idaji oke naa yoo si si siha ariwa, ati idaji re siha gusu
Ẹ̀yin ó sì ṣá sí àfonífojì àwọn òkè mi
Eyin o si sa si afonifoji awon oke mi
nítorí pé àfonífojì òkè náà yóò dé Àṣàlì
nitori pe afonifoji oke naa yoo de Asali
nítòòtọ́, ẹ̀yin ó ṣá bí ẹ tí ṣá fún ìmímì-ilẹ̀ ni ọjọ́ Úṣáyà ọba Júdà
nitooto, eyin o sa bi e ti sa fun imimi-ile ni ojo Usaya oba Juda
Olúwa Ọlọ́run mi yóò sì wá, àti gbogbo àwọn Ẹni-mímọ́ pẹ̀lú rẹ̀
Oluwa Olorun mi yoo si wa, ati gbogbo awon Eni-mimo pelu re
Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, ìmọ́lẹ̀ kì yóò mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ṣókùnkùn
Yoo si se ni ojo naa, imole ki yoo mo, bee ni ki yoo sokunkun
Ṣùgbọ́n yóò jẹ́ ọjọ́ kan mímọ́ fún Olúwa , kì í ṣe ọ̀ṣán, kì í ṣe òru
Sugbon yoo je ojo kan mimo fun Oluwa , ki i se osan, ki i se oru
ṣùgbọ́n yóò ṣe pé, ni àṣálẹ́ ìmọ́lẹ̀ yóò wà
sugbon yoo se pe, ni asale imole yoo wa
Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, omi ìyè yóò tí Jérúsálẹ́mù ṣàn lọ
Yoo si se ni ojo naa, omi iye yoo ti Jerusalemu san lo
ìdájì wọn sìhà òkun ilà-oòrùn, àti ìdájì wọn síhà okùn ẹ̀yìn
idaji won siha okun ila-oorun, ati idaji won siha okun eyin
nígbà ẹ̀rùn àti nígbà òtútù ni yóò rí bẹ́ẹ̀
nigba erun ati nigba otutu ni yoo ri bee
Olúwa yóò sì jọba lórí gbogbo ayé
Oluwa yoo si joba lori gbogbo aye
ni ọjọ́ náà ni Olúwa kan yóò wa orúkọ rẹ̀ nìkan náà ni orúkọ
ni ojo naa ni Oluwa kan yoo wa oruko re nikan naa ni oruko
A ó yí gbogbo ilẹ̀ padà bi pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan láti Gébà dé Rímónì lápá gúsù Jérúsálẹ́mù
A o yi gbogbo ile pada bi petele kan lati Geba de Rimoni lapa gusu Jerusalemu
yóò di bí aginjù, ṣùgbọ́n a ó sì gbé Jérúsálẹ́mù ṣókè, yóò sì gbe ipò rẹ̀, láti ibodè Bẹ́ńjámínì títí dé ibi ibodè èkínní, dé ibodè igun nì, àti láti ile ìṣọ́ Hánánélì dé ibi ìfúńtí wáìnì ọba
yoo di bi aginju, sugbon a o si gbe Jerusalemu soke, yoo si gbe ipo re, lati ibode Benjamini titi de ibi ibode ekinni, de ibode igun ni, ati lati ile iso Hananeli de ibi ifunti waini oba
Ènìyàn yóò sì máa gbé ibẹ̀, kì yóò sì sí ìparun mọ́
Eniyan yoo si maa gbe ibe, ki yoo si si iparun mo
ṣùgbọ́n a o máa gbé Jérúsálẹ́mù láìléwu
sugbon a o maa gbe Jerusalemu lailewu
Èyí ni yóò sì jẹ́ àrùn tí Olúwa yóò fi kọlu gbogbo àwọn ènìyàn ti ó tí ba Jérúsálẹ́mù jà
Eyi ni yoo si je arun ti Oluwa yoo fi kolu gbogbo awon eniyan ti o ti ba Jerusalemu ja
ẹran-ara wọn yóò rù nígbà tí wọn dúró ni ẹṣẹ̀ wọn, ojú wọn yóò sì rà ni ihò wọn, ahọ́n wọn yóò sì bàjẹ́ ni ẹnu wọn
eran-ara won yoo ru nigba ti won duro ni ese won, oju won yoo si ra ni iho won, ahon won yoo si baje ni enu won
Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá yóò wà láàrin wọn
Yoo si se ni ojo naa, irokeke nla lati odo Oluwa wa yoo wa laarin won
wọn ó sì di ọwọ́ ara wọn mú, ọwọ́ ìkínní yóò sì dìde sì ọwọ́ ìkejì rẹ̀
won o si di owo ara won mu, owo ikinni yoo si dide si owo ikeji re
Júdà pẹ̀lú yóò sì jà ni Jérúsálẹ́mù
Juda pelu yoo si ja ni Jerusalemu
ọrọ̀ gbogbo awọn aláìkọlà tí ó wà káàkiri ni a ó sì kójọ, góòlu, àti fàdákà, àti aṣọ, ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀
oro gbogbo awon alaikola ti o wa kaakiri ni a o si kojo, goolu, ati fadaka, ati aso, ni opolopo
Bẹ́ẹ̀ ni àrùn ẹṣin, ìbáákà, ràkúnmí, àti tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, yóò sì wà, àti gbogbo ẹranko tí ń bẹ nínú àgọ́ wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí àrùn yìí
Bee ni arun esin, ibaaka, rakunmi, ati ti ketekete, yoo si wa, ati gbogbo eranko ti n be ninu ago wonyi gege bi arun yii
Yóò sì ṣe, olúkúlùkù ẹni tí o kù nínú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó dìde sí Jérúsálẹ́mù yóò máa gòkè lọ lọ́dọọdún láti sìn Ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, àti láti ṣe àjọyọ̀ àṣè àgọ́ náà
Yoo si se, olukuluku eni ti o ku ninu gbogbo awon orile-ede ti o dide si Jerusalemu yoo maa goke lo lodoodun lati sin Oba, Oluwa awon omo-ogun, ati lati se ajoyo ase ago naa
Yóò sì ṣe, ẹnikẹ́ni tí kì yóò gòkè wá nínú gbogbo ìdílé ayé sí Jérúsálẹ́mù láti sín Ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, òjò kì yóò rọ̀ fún wọn
Yoo si se, enikeni ti ki yoo goke wa ninu gbogbo idile aye si Jerusalemu lati sin Oba, Oluwa awon omo-ogun, ojo ki yoo ro fun won
Bí ìdílé Éjíbítì kò bá sì gòkè lọ, tí wọn kò sì wá, fi ara wọn hàn tí wọn kò ní òjò
Bi idile Ejibiti ko ba si goke lo, ti won ko si wa, fi ara won han ti won ko ni ojo
àrùn náà yóò wà, tí Olúwa yóò fi kọlù àwọn aláìkọlà tí kò gòkè wá láti se àjọyọ̀ àsè àgọ́ náà Èyí ni yóò sì jẹ́ ìyà Éjíbítì, àti ìyà gbogbo orílẹ̀-èdè tí kò gòkè wá láti pa àsè àgọ́ mọ́
arun naa yoo wa, ti Oluwa yoo fi kolu awon alaikola ti ko goke wa lati se ajoyo ase ago naa Eyi ni yoo si je iya Ejibiti, ati iya gbogbo orile-ede ti ko goke wa lati pa ase ago mo
Ní ọjọ́ náà ni MÍMỌ́ SÍ Olúwa yóò wà lára ṣaworo ẹṣin
Ni ojo naa ni MIMO SI Oluwa yoo wa lara saworo esin
àti àwọn ìkòkò ni ilé Olúwa yóò sì dàbí àwọn ọpọ́n tí ń bẹ níwájú pẹpẹ
ati awon ikoko ni ile Oluwa yoo si dabi awon opon ti n be niwaju pepe
Nítòótọ́, gbogbo ìkòkò ni Jérúsálẹ́mù àti ni Júdà yóò jẹ́ mímọ́ sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun
Nitooto, gbogbo ikoko ni Jerusalemu ati ni Juda yoo je mimo si Oluwa awon omo-ogun
àti gbogbo àwọn tí ń rubọ yóò wá, wọn ó sì mú ìkòkò díẹ̀, wọn ó sì bọ ẹran wọn nínú rẹ̀, ni ọjọ́ náà ni àwọn Kénánì kò ní sí mọ́ ni ile Olúwa àwọn ọmọ-ogun
ati gbogbo awon ti n rubo yoo wa, won o si mu ikoko die, won o si bo eran won ninu re, ni ojo naa ni awon Kenani ko ni si mo ni ile Oluwa awon omo-ogun
Okùn-Ìwọ̀n Ti Jérúsálẹ́mù
Okun-Iwon Ti Jerusalemu
Mó si tún gbé ojú mi, sòkè, mo sì wò, sì kíyèsi i, ọkùnrin kan ti o mú okùn-ìwọ̀n lọ́wọ́ rẹ̀
Mo si tun gbe oju mi, soke, mo si wo, si kiyesi i, okunrin kan ti o mu okun-iwon lowo re
Mo sí wí pé, Níbo ni ìwọ ń lọ
Mo si wi pe, Nibo ni iwo n lo
O sí wí fún mí pé, Láti wọn Jérúsálẹ́mù, láti rí iyé ìbú rẹ̀, àti iyé gígùn rẹ̀
O si wi fun mi pe, Lati won Jerusalemu, lati ri iye ibu re, ati iye gigun re
Sì kiyesí i, ańgẹ́li tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ jáde lọ, ańgẹ́lì mìíràn si jáde lọ pade rẹ̀
Si kiyesi i, angeli ti o n ba mi soro jade lo, angeli miiran si jade lo pade re
Ó si wí fún un pé, Sáré, sọ fún ọdọmọkùnrin yìí wí pé, A ó gbé inú Jérúsálẹ́mù bi ìlú ti kò ní odi, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn àti ohun-ọ̀sìn inú rẹ̀
O si wi fun un pe, Sare, so fun odomokunrin yii wi pe, A o gbe inu Jerusalemu bi ilu ti ko ni odi, nitori opo eniyan ati ohun-osin inu re
Olúwa wí pé, Èmí ó sì jẹ́ odi iná fún un yíká, èmi ó sì jẹ́ ògo láàrin rẹ̀
Oluwa wi pe, Emi o si je odi ina fun un yika, emi o si je ogo laarin re
Áà! Áà! Sá kúrò ni ilẹ̀ àriwá, ni Olúwa wí
Aa! Aa! Sa kuro ni ile ariwa, ni Oluwa wi
nítorí pé bí afẹ́fẹ́ mẹ́rin ọ̀run ni mo tú yín kákiri, ni Olúwa wí
nitori pe bi afefe merin orun ni mo tu yin kakiri, ni Oluwa wi
Gbà ara rẹ̀ sílẹ̀, Ìwọ Síonì, ìwọ tí ó ń bà ọmọbìnrin Bábílónì gbé
Gba ara re sile, Iwo Sioni, iwo ti o n ba omobinrin Babiloni gbe
Nítorí bayìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí
Nitori bayii ni Oluwa awon omo-ogun wi
Lẹ́yìn ògo rẹ̀ ni a ti rán mi sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ń kó yin
Leyin ogo re ni a ti ran mi si awon orile-ede ti n ko yin
nítorí ẹni tí ó tọ́ yin, ó tọ́ ọmọ ojú rẹ̀
nitori eni ti o to yin, o to omo oju re
Nítorí kíyèsi i, èmi ó gbọn ọwọ́ mi sí orí wọn, wọn yóò sì jẹ́ ikogun fún iránṣẹ́ wọn
Nitori kiyesi i, emi o gbon owo mi si ori won, won yoo si je ikogun fun iranse won
ẹ̀yín yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi
eyin yoo si mo pe, Oluwa awon omo-ogun ni o ran mi
Kọrin kí o sì yọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Síónì
Korin ki o si yo, iwo omobinrin Sioni
Nítorí èmi ń bọ̀ àti pé èmi yóò sì gbé àárin rẹ, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí
Nitori emi n bo ati pe emi yoo si gbe aarin re, ni Oluwa awon omo-ogun wi
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni yóò dàpọ̀ mọ́ Olúwa ní ọjọ́ náà, wọn yóò sì di ènìyàn mi
Opolopo orile-ede ni yoo dapo mo Oluwa ni ojo naa, won yoo si di eniyan mi
èmi yóò sì gbé àárin rẹ, ìwọ yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi sí ọ
emi yoo si gbe aarin re, iwo yoo si mo pe, Oluwa awon omo-ogun ni o ran mi si o
Olúwa yóò sì jogún Júdà ìní rẹ̀, ni ilẹ̀ mímọ́, yóò sì tún yan Jérúsálẹ́mù
Oluwa yoo si jogun Juda ini re, ni ile mimo, yoo si tun yan Jerusalemu
Ẹ̀ dákẹ̀, gbogbo ẹran-ara níwájú Olúwa
E dake, gbogbo eran-ara niwaju Oluwa
nítorí a jí i láti ibùgbé mímọ́ rẹ̀ wá
nitori a ji i lati ibugbe mimo re wa
Asọ Mímọ́ Fún Olórí Àlùfáà
Aso Mimo Fun Olori Alufaa
Ó sì fí Jóṣúà olorí àlùfáà hàn mí, ó dúró níwájú ańgẹ́lì Olúwa , Sátanì sí dúró lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ láti kọjú ìjà sí i
O si fi Josua olori alufaa han mi, o duro niwaju angeli Oluwa , Satani si duro lowo otun re lati koju ija si i
Olúwa si wí fún Sátanì pé, Olúwa bá ọ wí ìwọ Sátanì
Oluwa si wi fun Satani pe, Oluwa ba o wi iwo Satani
àní Olúwa tí ó ti yan Jérúsálẹ́mù, yóò bá ọ wí, igi inà kọ́ ni èyí tí a mú kúrò nínú iná
ani Oluwa ti o ti yan Jerusalemu, yoo ba o wi, igi ina ko ni eyi ti a mu kuro ninu ina
A sì wọ Jóṣúà ni àṣọ èérí, ó sì dúró níwájú ańgẹ́lì náà
A si wo Josua ni aso eeri, o si duro niwaju angeli naa
Ó sì dáhùn ó wí fún àwọn tí ó dúró níwájú rẹ̀ pé, Bọ́ aṣọ èérí nì kúrò ní ara rẹ̀
O si dahun o wi fun awon ti o duro niwaju re pe, Bo aso eeri ni kuro ni ara re
Ó sì wí fún Jóṣúà pé, Wòó, mo mú kí àìṣedéédé rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, èmi yóò sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ ẹ̀yẹ
O si wi fun Josua pe, Woo, mo mu ki aisedeede re kuro lodo re, emi yoo si wo o ni aso eye
Mó sì wí pé, Jẹ kí wọn fi gèlè mímọ́ wé e lórí
Mo si wi pe, Je ki won fi gele mimo we e lori
Wọn si fi gèlè mímọ́ wé e lorí, wọn si fi aṣọ wọ̀ ọ́
Won si fi gele mimo we e lori, won si fi aso wo o
Ańgẹ́lì Olúwa sì dúró tì í
Angeli Oluwa si duro ti i
Ańgẹ́lì Olúwa sì tẹnumọ́ ọn fún Jóṣúà pé
Angeli Oluwa si tenumo on fun Josua pe
Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí
Bayii ni Oluwa awon omo-ogun wi
Bí ìwọ ọ́ bá rìn ní ọ̀nà mi, bí ìwọ yóò bá sì pa àṣẹ mi mọ́, ìwọ yóò sì ṣe ìdájọ́ ilé mi pẹ̀lú, ìwọ yóò sì ṣe àkóso ààfin mi, èmi yóò fún ọ ní àyè láti rìn láàrin àwọn tí ó dúró yìí
Bi iwo o ba rin ni ona mi, bi iwo yoo ba si pa ase mi mo, iwo yoo si se idajo ile mi pelu, iwo yoo si se akoso aafin mi, emi yoo fun o ni aye lati rin laarin awon ti o duro yii
Gbọ́, ìwọ Jóṣúà olórí àlùfáà, ìwọ, àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ tí ó jòkòó níwájú rẹ
Gbo, iwo Josua olori alufaa, iwo, ati awon egbe re ti o jokoo niwaju re
nítorí ẹni ìyanu ni wọ́n
nitori eni iyanu ni won
nítorí kíyèsí i, èmi yóò mú ìránṣẹ́ mi, Ẹ̀ka, wá
nitori kiyesi i, emi yoo mu iranse mi, Eka, wa
Nítorí kíyèsí i, òkúta tí mo tí gbé kalẹ̀ níwájú Jóṣúà
Nitori kiyesi i, okuta ti mo ti gbe kale niwaju Josua
lórí òkúta kán ni ojú méje wà
lori okuta kan ni oju meje wa
kíyèsí i, èmi yóò fín àkọlé rẹ̀, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, èmi yóò sì mú ẹ̀bi ilẹ̀ náà kúrò ní ọjọ́ kan
kiyesi i, emi yoo fin akole re, ni Oluwa awon omo-ogun wi, emi yoo si mu ebi ile naa kuro ni ojo kan
  Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ní ọjọ́ náà ni olúkúlùkù yóò pe ẹnìkejì láti jókòó rẹ̀ sábẹ́ igi àjàrà àti sábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́
  Oluwa awon omo-ogun wi pe, ni ojo naa ni olukuluku yoo pe enikeji lati jokoo re sabe igi ajara ati sabe igi opoto
  Ọ̀pá Fìtílà Wúrà Àti Àwọn Igi Ólífì Méjì
  Opa Fitila Wura Ati Awon Igi Olifi Meji
Ańgẹ́lì tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ sì tún dé, ó sì jí mi, bí ọkùnrin tí a jí lójú oorun rẹ̀, Ó sì wí fún mi pé, Kí ni ìwọ rí
Angeli ti o n ba mi soro si tun de, o si ji mi, bi okunrin ti a ji loju oorun re, O si wi fun mi pe, Ki ni iwo ri
Mo sì wí pé, Mo wò, sì kíyèsí i, ọ̀pá fìtílà tí gbogbo rẹ̀ jẹ́ wúrà, pẹ̀lú àwokòtò rẹ̀ lórí rẹ̀ pẹ̀lú fìtílà méje rẹ̀ lórí rẹ̀, àti ẹnu méje fún fìtílà méjèèje, tí ó wà lórí rẹ̀
Mo si wi pe, Mo wo, si kiyesi i, opa fitila ti gbogbo re je wura, pelu awokoto re lori re pelu fitila meje re lori re, ati enu meje fun fitila mejeeje, ti o wa lori re
Igi ólífì méjì sì wà létí rẹ̀, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àwokòtò náà, àti èkejì ní apá òsì rẹ̀
Igi olifi meji si wa leti re, okan ni apa otun awokoto naa, ati ekeji ni apa osi re
Mo sì dáhùn mo sì wí fún ańgẹ́lì tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀, pé, Kín ni wọ̀nyí, Olúwa mi
Mo si dahun mo si wi fun angeli ti o n ba mi soro, pe, Kin ni wonyi, Oluwa mi
Ańgẹ́lì tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ dáhùn ó sì wí fún mi pé, Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí
Angeli ti o n ba mi soro dahun o si wi fun mi pe, Iwo ko mo ohun ti awon wonyi jasi
Mo sì wí pé, Èmi kò mọ̀ ọ́n, Olúwa mi
Mo si wi pe, Emi ko mo on, Oluwa mi
Ó sì dáhùn ó sì wí fún mi pé, Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Serubábélì tó wí pé
O si dahun o si wi fun mi pe, Eyi ni oro Oluwa si Serubabeli to wi pe
Kìí ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bí kò se nípa Ẹ̀mí mi, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí Ta ni ìwọ, ìwọ òkè ńlá
Kii se nipa ipa, ki i se nipa agbara, bi ko se nipa Emi mi, ni Oluwa awon Omo-ogun wi Ta ni iwo, iwo oke nla
Ìwọ yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀ níwájú Serubábélì
Iwo yoo di petele niwaju Serubabeli
òun yóò sì fi ariwo mú òkúta téńté orí rẹ̀ wá, yóò máa kígbe wí pé, Ọlọ́run bùkún-un Ọlọ́run bùkún-un!  Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé
oun yoo si fi ariwo mu okuta tente ori re wa, yoo maa kigbe wi pe, Olorun bukun-un Olorun bukun-un!  Oro Oluwa si to mi wa, wi pe
Ọwọ́ Serubábélì ni a ti ṣe ipilẹ̀ ilé yìí, ọwọ́ rẹ̀ ni yóò sì parí rẹ̀
Owo Serubabeli ni a ti se ipile ile yii, owo re ni yoo si pari re
ìwọ yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi sí i yín
iwo yoo si mo pe, Oluwa awon omo-ogun ni o ran mi si i yin
Ṣùgbọ́n ta ni ha kẹ́gàn ọjọ́ ohun kékeré
Sugbon ta ni ha kegan ojo ohun kekere
Nítorí wọn ó yọ̀ ní, ìwọ̀n lọ́wọ́ Serubábélì
Nitori won o yo ni, iwon lowo Serubabeli
Mo sì béèrè, mo sì sọ fún un pé, Kí ni àwọn igi ólífì méjì wọ̀nyí jásí, tí ó wà ní apá ọ̀tún fìtílà àti ní apá òsì rẹ̀
Mo si beere, mo si so fun un pe, Ki ni awon igi olifi meji wonyi jasi, ti o wa ni apa otun fitila ati ni apa osi re
Mo sì tún dáhùn, mo sì sọ fún un pé, Kí ni àwọn ẹ̀ka méjì igi wọ̀nyí jásí, tí ń tú òróró wúrà jáde nínú ara wọn láti ẹnu ọ̀pá oníhò wúrà méjì
Mo si tun dahun, mo si so fun un pe, Ki ni awon eka meji igi wonyi jasi, ti n tu ororo wura jade ninu ara won lati enu opa oniho wura meji
Ó sì dáhùn, ó wí fún mi pé, Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí
O si dahun, o wi fun mi pe, Iwo ko mo ohun ti awon wonyi jasi
Mo sì wí pé, Bẹ́ẹ̀ kọ́, Olúwa à mi
Mo si wi pe, Bee ko, Oluwa a mi
Ó sì wí pé, Àwọn méjì wọ̀nyí ni àwọn tí a fi òróró yàn, tí ó dúró ti Olúwa gbogbo ayé
O si wi pe, Awon meji wonyi ni awon ti a fi ororo yan, ti o duro ti Oluwa gbogbo aye
Ìwé-Kíkà Ti Ń Fò
Iwe-Kika Ti N Fo
Nígbà náà ni mo yípadà, mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsí i, ìwé-kíkà ti ń fò
Nigba naa ni mo yipada, mo si gbe oju mi soke, mo si wo, si kiyesi i, iwe-kika ti n fo
Ó sì wí fún mi pé, Kí ni ìwọ rí
O si wi fun mi pe, Ki ni iwo ri
Èmi sì dáhùn pé, Mo rí ìwé-kíkà tí ń fò
Emi si dahun pe, Mo ri iwe-kika ti n fo
gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá
gigun re je ogun igbonwo, ibu re si je igbonwo mewaa