diacritcs
stringlengths
1
36.7k
no_diacritcs
stringlengths
1
35.5k
Ó sì wí fún mi pé, Èyí ni ègún tí ó jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀ ayé
O si wi fun mi pe, Eyi ni egun ti o jade lo si gbogbo ile aye
nítorí gbogbo àwọn tí ó bá jalè ni a ó gèé kúrò láti ìhín lọ nípa rẹ̀
nitori gbogbo awon ti o ba jale ni a o gee kuro lati ihin lo nipa re
gbogbo àwọn tí ó bá sì búra èké ni a ó gèé kúrò láti ìhín lọ nípa rẹ̀
gbogbo awon ti o ba si bura eke ni a o gee kuro lati ihin lo nipa re
Èmi o mú un jáde, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, yóò si wọ inú ilé olè lọ, àti inú ilé ẹni ti o bá fi ọrúkọ mi búra èké
Emi o mu un jade, ni Oluwa awon omo-ogun wi, yoo si wo inu ile ole lo, ati inu ile eni ti o ba fi oruko mi bura eke
yóò si wà ni àárin ilé rẹ̀, yóò si rún un pẹ̀lú igi àti òkúta inú rẹ̀
yoo si wa ni aarin ile re, yoo si run un pelu igi ati okuta inu re
  Ańgẹ́lì tí ń bá mi sọ̀rọ̀ sì jáde lọ, ó sì wí fún mi pé, Gbé ojú rẹ sókè níṣinṣin yìí, kí o sì wo nǹkan yìí tí ó jáde lọ
  Angeli ti n ba mi soro si jade lo, o si wi fun mi pe, Gbe oju re soke nisinsin yii, ki o si wo nnkan yii ti o jade lo
Mo sì wí pé, Kí ni nǹkan náà
Mo si wi pe, Ki ni nnkan naa
Ó sì wí pé, Èyí ni òṣùwọ̀n éfà tí ó jáde lọ
O si wi pe, Eyi ni osuwon efa ti o jade lo
Ó sì wí pé, Èyí ni àwòrán ní gbogbo ilẹ̀ ayé
O si wi pe, Eyi ni aworan ni gbogbo ile aye
Sì kíyèsí i, a gbé talẹ́ńtì òjé sókè
Si kiyesi i, a gbe talenti oje soke
obìnrin kan sì nìyìí tí ó jókòó sí àárin òṣùwọ̀n éfà
obinrin kan si niyii ti o jokoo si aarin osuwon efa
Ó sì wí pé, Èyí ni ìwà-búburú
O si wi pe, Eyi ni iwa-buburu
Ó sì jù ú sí àárin òṣùwọ̀n éfà
O si ju u si aarin osuwon efa
ó sì ju òṣùwọ̀n òjé sí ẹnu rẹ̀
o si ju osuwon oje si enu re
Mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsí i, obìnrin méjì jáde wá, èfúùfù sì wá nínú ìyẹ́ wọn
Mo si gbe oju mi soke, mo si wo, si kiyesi i, obinrin meji jade wa, efuufu si wa ninu iye won
nítorí wọ́n ní ìyẹ́ bí ìyẹ́ àkọ̀
nitori won ni iye bi iye ako
Wọ́n sì gbé òṣùwọ̀n éfà náà dé àárin méjì ayé àti ọ̀run
Won si gbe osuwon efa naa de aarin meji aye ati orun
Mo sì sọ fún ańgẹ́lì tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, Níbo ni àwọn wọ̀nyí ń gbé òṣùwọ̀n éfà náà lọ
Mo si so fun angeli ti o n ba mi soro pe, Nibo ni awon wonyi n gbe osuwon efa naa lo
Ó si wí fún mi pé, Sí orílẹ̀ èdè Bábílónì láti kọ ilé fún un
O si wi fun mi pe, Si orile ede Babiloni lati ko ile fun un
Tí ó bá ṣe tán, a ó sì fi ìdí rẹ̀ mulẹ̀, a o sì fi ka orí ìpìlẹ̀ rẹ̀ níbẹ̀
Ti o ba se tan, a o si fi idi re mule, a o si fi ka ori ipile re nibe
Kẹ̀kẹ́ Ogun Mẹ́rin Tí Ìdàjọ́ Ọlọ́run
Keke Ogun Merin Ti Idajo Olorun
Mo sì yípadà, mo sì gbé ojú mi sòkè, mo sì wò, sì kíyèsi i, kẹ̀kẹ́ mẹ́rin jáde wá láti àárin òkè-ńlá méjì, àwọn òkè-ńlà náà sì jẹ́ òkè-ńlà idẹ
Mo si yipada, mo si gbe oju mi soke, mo si wo, si kiyesi i, keke merin jade wa lati aarin oke-nla meji, awon oke-nla naa si je oke-nla ide
Àwọn ẹṣin pupa wà ní kẹ̀kẹ́ èkínní
Awon esin pupa wa ni keke ekinni
àti àwọn ẹṣin dúdú ní kẹ̀kẹ́ èkejì
ati awon esin dudu ni keke ekeji
Àti àwọn ẹṣin funfun ní kẹ̀kẹ́ ẹ̀kẹta
Ati awon esin funfun ni keke eketa
àti àwọn adíkálà àti alágbára ẹṣin ní kẹ̀kẹ́ ẹ̀kẹrin
ati awon adikala ati alagbara esin ni keke ekerin
Mo sì dáhùn, mo sì béèrè lọ́wọ́ ańgẹ́lì tí ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, Kí ni ìwọ̀nyí, Olúwa mi
Mo si dahun, mo si beere lowo angeli ti n ba mi soro pe, Ki ni iwonyi, Oluwa mi
Ańgẹ́lì náà si dáhùn ó sì wí fún mi pé, Wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀mí mẹ́rin ti ọ̀run, tí wọn ń lọ kúrò lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ara wọn hàn níwájú Olúwa gbogbo ayé
Angeli naa si dahun o si wi fun mi pe, Wonyi ni awon emi merin ti orun, ti won n lo kuro leyin ti won ti fi ara won han niwaju Oluwa gbogbo aye
Àwọn ẹṣin dúdú tí ó wà nínú rẹ̀ jáde lọ sí ilẹ̀ àríwá
Awon esin dudu ti o wa ninu re jade lo si ile ariwa
àwọn funfun sì jáde tẹ̀lé wọn
awon funfun si jade tele won
àwọn adíkálà sì jáde lọ sí ìhà ilẹ̀ gúsù
awon adikala si jade lo si iha ile gusu
Àwọn alágbára ẹṣin sì jáde lọ, wọ́n sì ń wá ọ̀nà àti lọ kí wọn báa lè rìn síhín-sọ́hùnún ni ayé
Awon alagbara esin si jade lo, won si n wa ona ati lo ki won baa le rin sihin-sohunun ni aye
ó sì wí pé, Ẹ lọ, ẹ lọ rìn síhìn-sọ́hùn ní ayé! Wọ́n sì rín síhìnín-sọ́hùnún ní ayé
o si wi pe, E lo, e lo rin sihin-sohun ni aye! Won si rin sihinin-sohunun ni aye
Nígbà náà ni ohùn kan sì ké sí mi, ó sì bá mi sọ̀rọ̀ wí pé, Wò ó, àwọn wọ̀nyí tí ó lọ síhà ilẹ̀ àríwá ti mú ẹ̀mí mi parọ́rọ́ ni ilẹ̀ àríwá
Nigba naa ni ohun kan si ke si mi, o si ba mi soro wi pe, Wo o, awon wonyi ti o lo siha ile ariwa ti mu emi mi paroro ni ile ariwa
Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé
Oro Oluwa si to mi wa, wi pe
Mú nínú ìgbèkùn, nínú àwọn Hélídáì, tí Tóbíyà, àti ti Jédáyà, tí ó ti Bábílónì dé, kí ìwọ sì wá ní ọjọ́ kan náà, kí o sì wọ ilé Jósáyà ọmọ Séfánáyà lọ
Mu ninu igbekun, ninu awon Helidai, ti Tobiya, ati ti Jedaya, ti o ti Babiloni de, ki iwo si wa ni ojo kan naa, ki o si wo ile Josaya omo Sefanaya lo
Kí o sì mú sílifà àti wúrà, kí o sì fi ṣe adé púpọ̀, sì gbé wọn ka orí Jóṣúà ọmọ Jósédékì, olórí àlùfáà
Ki o si mu silifa ati wura, ki o si fi se ade pupo, si gbe won ka ori Josua omo Josedeki, olori alufaa
Sì sọ fún un pé
Si so fun un pe
Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogún sọ wí pé, wo ọkùnrin náà ti orukọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹ̀ka
Bayii ni Oluwa awon omo-ogun so wi pe, wo okunrin naa ti oruko re n je Eka
yóò sì yọ ẹ̀ka láti abẹ́ rẹ̀ wá, yóò si kọ́ tẹ́ḿpìlì Olúwa wa
yoo si yo eka lati abe re wa, yoo si ko tempili Oluwa wa
Òun ni yóò sì kọ́ tẹ́ḿpìlì Olúwa òun ni yóò sì wọ̀ ní ògo, yóò sì jókòó, yóò sì jọba lorí ìtẹ́ rẹ̀
Oun ni yoo si ko tempili Oluwa oun ni yoo si wo ni ogo, yoo si jokoo, yoo si joba lori ite re
òun ó sì jẹ́ àlùfáà lorí ìtẹ́ rẹ̀
oun o si je alufaa lori ite re
ìmọ̀ àlàáfíà yóò sì wá láàrin àwọn méjèèje
imo alaafia yoo si wa laarin awon mejeeje
Adé wọ̀nyí yóò sì wà fún Hélémù àti fún Tóbíyà, àti fún Jédíà, àti fún Hénì ọmọ Sefanáyà fún irántí ni tẹ́ḿpìlì Olúwa
Ade wonyi yoo si wa fun Helemu ati fun Tobiya, ati fun Jedia, ati fun Heni omo Sefanaya fun iranti ni tempili Oluwa
Àwọn tí ó jìnnà réré yóò wá láti kọ́ tẹ́ḿpìlì Olúwa , ẹ̀yiń o sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti rán mi sí yín
Awon ti o jinna rere yoo wa lati ko tempili Oluwa , eyin o si mo pe, Oluwa awon omo-ogun ti ran mi si yin
Yóò sì rí bẹ́ẹ̀ bí ẹ̀yín o bá gbà ohùn Olúwa , Ọlọ́run yín gbọ́ nítootọ́
Yoo si ri bee bi eyin o ba gba ohun Oluwa , Olorun yin gbo nitooto
Òdodo Àti Àánú, Kì í Ṣe Ààwẹ̀
Ododo Ati Aanu, Ki i Se Aawe
Ó sì ṣe ní ọdún kẹrin Dáríúsì ọba, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ́ Sekaráyà wá ni ọjọ́ kẹrin oṣù Kísíléfì tí ń se oṣù kẹsàn-án
O si se ni odun kerin Dariusi oba, oro Oluwa to Sekaraya wa ni ojo kerin osu Kisilefi ti n se osu kesan-an
Nígbà tí wọ́n rán Sérésérì àti Régémélékì, àti àwọn ènìyàn wọn sí ilé Ọlọ́run láti wá ojú rere Olúwa
Nigba ti won ran Sereseri ati Regemeleki, ati awon eniyan won si ile Olorun lati wa oju rere Oluwa
Àti láti bá àwọn àlùfáà tí ó wà ní ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun, àti àwọn wòlíì sọ̀rọ̀ wí pé, Ṣé kí èmi ó sọkún ní oṣù kárùnún kí èmi ya ara mi sọ́tọ̀, bí mo ti ń ṣe láti ọdún mélòó wọ̀nyí wá bí
Ati lati ba awon alufaa ti o wa ni ile Oluwa awon omo-ogun, ati awon wolii soro wi pe, Se ki emi o sokun ni osu karunun ki emi ya ara mi soto, bi mo ti n se lati odun meloo wonyi wa bi
Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tọ̀ mí wá pé, Sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti fún àwọn àlùfáà pé, Nígbà tí ẹ̀yin gbààwẹ̀, tí ẹ sì ṣọ̀fọ̀ ní oṣù karùnún àti keje, àní fun àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, ǹjẹ́ èmi ni ẹ̀yin hà ń gbààwẹ̀ yín fún
Nigba naa ni oro Oluwa awon omo-ogun to mi wa pe, So fun gbogbo awon eniyan ile naa, ati fun awon alufaa pe, Nigba ti eyin gbaawe, ti e si sofo ni osu karunun ati keje, ani fun aadorin odun wonyi, nje emi ni eyin ha n gbaawe yin fun
Nígbà tí ẹ sì jẹ, àti nígbà tí ẹ mu, fún ara yín kọ́ ni ẹ̀yin jẹ, àti fún ara yín kọ́ ni ẹ̀yin mú bí
Nigba ti e si je, ati nigba ti e mu, fun ara yin ko ni eyin je, ati fun ara yin ko ni eyin mu bi
Wọ̀nyí kọ́ ni ọ̀rọ̀ ti Olúwa ti kígbe láti ọdọ àwọn wòlíì ìṣáájú wá, nígbà tí a ń gbé Jérúsálẹ́mù, tí ó sì wà ní àlàáfíà, pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀ tí ó yí i káàkiri, nígbà tí a ń gbé gúsù àti pẹ̀tẹ́lẹ̀
Wonyi ko ni oro ti Oluwa ti kigbe lati odo awon wolii isaaju wa, nigba ti a n gbe Jerusalemu, ti o si wa ni alaafia, pelu awon ilu re ti o yi i kaakiri, nigba ti a n gbe gusu ati petele
  Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Sekaráyà wá, wí pé
  Oro Oluwa si to Sekaraya wa, wi pe
Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé
Bayii ni Oluwa awon omo-ogun wi pe
Ṣe ìdájọ́ òtítọ́, kí ẹ sì ṣe àánú àti iyọ́nú olúkúlùkù sí arákùnrin rẹ̀
Se idajo otito, ki e si se aanu ati iyonu olukuluku si arakunrin re
Má sì ṣe ni opó lára tàbí aláìní baba, àlejò, tàbí tàlákà
Ma si se ni opo lara tabi alaini baba, alejo, tabi talaka
kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe gbérò ibi ní ọkàn sí arákùnrin rẹ̀
ki enikeni ninu yin ma se gbero ibi ni okan si arakunrin re
Ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ láti gbọ́, wọ́n sì gún èjìká, wọ́n sì pa ẹ̀yìn dà, wọ́n di etí wọn, kí wọn má ba à gbọ́
Sugbon won ko lati gbo, won si gun ejika, won si pa eyin da, won di eti won, ki won ma ba a gbo
Wọ́n sé àyà wọn bí òkúta ádámáńtì, kí wọn má ba à gbọ́ òfin, àti ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti fi ẹ̀mí rẹ̀ rán nípa ọwọ́ àwọn wòlíì ìṣáájú wá
Won se aya won bi okuta adamanti, ki won ma ba a gbo ofin, ati oro ti Oluwa awon omo-ogun ti fi emi re ran nipa owo awon wolii isaaju wa
ìbínú ńlá sì dé láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ ogun wá
ibinu nla si de lati odo Oluwa awon omo ogun wa
 Ó sì ṣe, gẹ́gẹ́ bí ó ti kígbe, tí wọn kò sì fẹ́ gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kígbe, tí èmi kò sì fẹ́ gbọ́, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí
 O si se, gege bi o ti kigbe, ti won ko si fe gbo, bee ni won kigbe, ti emi ko si fe gbo, ni Oluwa awon omo-ogun wi
Mo sì fi ìjì tú wọn ká sí gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọn kò mọ̀
Mo si fi iji tu won ka si gbogbo orile-ede ti won ko mo
Ilẹ̀ náà sì dáhoro lẹ́yìn wọn, tí ẹnikẹ́ni kò là á kọjà tàbí kí ó padà bọ̀
Ile naa si dahoro leyin won, ti enikeni ko la a koja tabi ki o pada bo
wọ́n sì sọ ilẹ̀ ààyò náà dáhoro
won si so ile aayo naa dahoro
  Ọlọ́run Ṣe Ìpinnu Láti Bùkún Jérúsálẹ́mù
  Olorun Se Ipinnu Lati Bukun Jerusalemu
Ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun si tún tọ́ mí wá, wí pé, Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí
Oro Oluwa awon omo-ogun si tun to mi wa, wi pe, Bayii ni Oluwa awon omo-ogun wi
Owú ńlá-ńlá ni mo jẹ fún Síónì, pẹ̀lú ìbínú ńlá-ńlá ni mo fi jowú fún un
Owu nla-nla ni mo je fun Sioni, pelu ibinu nla-nla ni mo fi jowu fun un
Báyìí ni Olúwa wí Mo yípadà sí Síónì èmi ó sì gbé àárin Jérúsálẹ́mù
Bayii ni Oluwa wi Mo yipada si Sioni emi o si gbe aarin Jerusalemu
Nígbà náà ni a ó sì pé Jérúsálẹ́mù ni ìlú ńlá otítọ́
Nigba naa ni a o si pe Jerusalemu ni ilu nla otito
àti òkè-ńlá Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ni a ó pè ní òkè-ńlá mímọ́
ati oke-nla Oluwa awon omo-ogun, ni a o pe ni oke-nla mimo
Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí
Bayii ni Oluwa awon omo-ogun wi
Arúgbó ọkùnrin, àti arúgbó obìnrin, yóò gbé ìgboro Jérúsálẹ́mù, àti olúkúlùkù pẹ̀lú ọ̀pá ni ọwọ́ rẹ̀ fún ogbó
Arugbo okunrin, ati arugbo obinrin, yoo gbe igboro Jerusalemu, ati olukuluku pelu opa ni owo re fun ogbo
Ìgboro ìlú yóò sì kún fún ọmọdékùnrin, àti ọmọdé-bìnrin, tí ń ṣiré ní ìta wọn
Igboro ilu yoo si kun fun omodekunrin, ati omode-binrin, ti n sire ni ita won
Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé
Bayii ni Oluwa awon omo-ogun wi pe
Bí ó bá ṣe ìyanú ní ojú ìyókù àwọn ènìyàn yìí ni ọjọ́ wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó ha lè jẹ́ ìyánú ni ojú mi bí
Bi o ba se iyanu ni oju iyoku awon eniyan yii ni ojo wonyi, nje o ha le je iyanu ni oju mi bi
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí
ni Oluwa awon omo-ogun wi
Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé
Bayii ni Oluwa awon omo-ogun wi pe
Kiyesi i, èmi ó gba àwọn ènìyàn mi kúrò ni ilẹ̀ ìlà-oòrùn, àti kúrò ni ilẹ̀ ìwọ̀-oòrùn
Kiyesi i, emi o gba awon eniyan mi kuro ni ile ila-oorun, ati kuro ni ile iwo-oorun
Èmi ó sì mú wọn padà wá, wọn ó sì máa gbé àárin Jérúsálẹ́mù
Emi o si mu won pada wa, won o si maa gbe aarin Jerusalemu
wọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi, èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, ní òtítọ́, àti ní òdodo
won o si je eniyan mi, emi o si je Olorun won, ni otito, ati ni ododo
Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé
Bayii ni Oluwa awon omo-ogun wi pe
Jẹ́ kí ọwọ́ yín le ẹ̀yin ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ọjọ́ wọ̀nyí ni ẹnu àwọn wòlíì tí ó wà ni ọjọ́ tí a fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun lélẹ̀, jẹ́ ki ọwọ́ rẹ̀ le kí a bá lè kọ́ tẹ́ḿpìlì
Je ki owo yin le eyin ti n gbo oro wonyi ni ojo wonyi ni enu awon wolii ti o wa ni ojo ti a fi ipile ile Oluwa awon omo-ogun lele, je ki owo re le ki a ba le ko tempili
Nítorí pé, ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí, ọ̀yà ènìyàn kò tó nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀yà ẹran pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àlàáfíà fún ẹni ń jáde lọ, tàbí ẹni ti ń wọlé bọ, nítorí ìpọ́njú náà
Nitori pe, saaju ojo wonyi, oya eniyan ko to nnkan, bee ni oya eran pelu, bee ni ko si alaafia fun eni n jade lo, tabi eni ti n wole bo, nitori iponju naa
nítorí mo dojú gbogbo ènìyàn, olukuluku kọ aládùúgbò rẹ̀
nitori mo doju gbogbo eniyan, olukuluku ko aladuugbo re
Ṣùgbọ́n ní ìṣinṣinyìí èmi kì yóò ṣè sí ìyókù àwọn ènìyàn yìí gẹ́gẹ́ bí tí ìgbà àtijọ́, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí
Sugbon ni isinsinyii emi ki yoo se si iyoku awon eniyan yii gege bi ti igba atijo, ni Oluwa awon omo-ogun wi
Nítorí irúgbìn yóò gbilẹ̀ àjàrà yóò ṣo èṣo rẹ̀, ilẹ̀ yóò sì hu ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nǹkan rẹ̀ jáde, àwọn ọ̀run yóò sì mu ìrì wọn wá
Nitori irugbin yoo gbile ajara yoo so eso re, ile yoo si hu opolopo nnkan re jade, awon orun yoo si mu iri won wa
èmi ó sì mu kí èyí jẹ ogún ìní àwọn ìyókù ènìyàn yìí ni gbogbo nǹkan wọ̀nyí
emi o si mu ki eyi je ogun ini awon iyoku eniyan yii ni gbogbo nnkan wonyi
Yóò ṣi ṣe, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí jẹ́ ègún láàrin àwọn aláìkọlà, ẹ̀yin ilé Júdà, àti ilé Íṣrẹ́lì, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó gbà yín sílẹ̀
Yoo si se, gege bi eyin ti je egun laarin awon alaikola, eyin ile Juda, ati ile Isreli, bee ni emi o gba yin sile
ẹ̀yin o sì jẹ́ ìbùkún
eyin o si je ibukun
ẹ má bẹ̀rù, ṣùgbọ́n jẹ́ ki ọwọ́ yín le
e ma beru, sugbon je ki owo yin le
Nítorí báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí
Nitori bayii ni Oluwa awon omo-ogun wi
Gẹ́gẹ́ bí mo ti rò láti ṣe yín níbi nígbà tí àwọn baba yín mú mi bínú, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, tí èmi kò sì ronúpìwàdà
Gege bi mo ti ro lati se yin nibi nigba ti awon baba yin mu mi binu, ni Oluwa awon omo-ogun wi, ti emi ko si ronupiwada
Bẹ́ẹ̀ ni èmi ṣí tí ro ọjọ́ wọ̀nyí láti ṣe rere fún Jérúsálẹ́mù, àti fún ilé Júdà ẹ má bẹ̀rù
Bee ni emi si ti ro ojo wonyi lati se rere fun Jerusalemu, ati fun ile Juda e ma beru
Wọ̀nyí ni nǹkan tí ẹ̀yin ó ṣe
Wonyi ni nnkan ti eyin o se
Ẹ ṣọ̀rọ̀ òtítọ́, olúkúlúkù sí ẹnikejì rẹ̀
E soro otito, olukuluku si enikeji re
ṣe ìdájọ́ tòótọ́ àti àlàáfíà ní àwọn ibodè yín
se idajo tooto ati alaafia ni awon ibode yin
Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ro ibi ni ọkàn rẹ̀ sí ẹnìkeji rẹ̀
E ma se je ki enikan ro ibi ni okan re si enikeji re
ẹ má fẹ ìbúra èké
e ma fe ibura eke
nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni mo kórìíra, ni Olúwa wí
nitori gbogbo nnkan wonyi ni mo koriira, ni Oluwa wi