diacritcs
stringlengths
1
36.7k
no_diacritcs
stringlengths
1
35.5k
Ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun sì tọ mi wá wí pé
Oro Oluwa awon omo-ogun si to mi wa wi pe
Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé
Bayii ni Oluwa awon omo-ogun wi pe
Ààwẹ̀ oṣù kẹrin, ìkárun-un, kéje, àti tí ẹ̀kẹwàá, yóò jẹ́ ayọ̀, àti dídùn inú, àti àpéjọ àríyá fún ilé Júdà
Aawe osu kerin, ikarun-un, keje, ati ti ekewaa, yoo je ayo, ati didun inu, ati apejo ariya fun ile Juda
nítorí náà, ẹ fẹ́ otítọ́ àti àlàáfíà
nitori naa, e fe otito ati alaafia
Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé
Bayii ni Oluwa awon omo-ogun wi pe
Àwọn ènìyàn yóò ṣa tún wa, àti ẹni tí yóò gbe ìlú-ńlá púpọ̀
Awon eniyan yoo sa tun wa, ati eni ti yoo gbe ilu-nla pupo
Àwọn ẹni tí ń gbé ìlú-ńlá kan yóò lọ sí òmíràn, wí pé, Ẹ jẹ́ kí a yára lọ gbàdúrà kí a sì wá ojú rere Olúwa , àti láti wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun
Awon eni ti n gbe ilu-nla kan yoo lo si omiran, wi pe, E je ki a yara lo gbadura ki a si wa oju rere Oluwa , ati lati wa Oluwa awon omo-ogun
Èmi pẹ̀lú yóò sì lọ
Emi pelu yoo si lo
Nítòótọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn àti àwọn alágbára orílẹ̀-èdè yóò wá láti wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní Jérúsálẹ́mù
Nitooto opolopo eniyan ati awon alagbara orile-ede yoo wa lati wa Oluwa awon omo-ogun ni Jerusalemu
àti láti gbàdúrà, àti láti wá ojú rere Olúwa
ati lati gbadura, ati lati wa oju rere Oluwa
Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé
Bayii ni Oluwa awon omo-ogun wi pe
Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ni ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àti orílẹ̀-èdè yóò dì í mú, àní yóò di etí aṣọ ẹni tí i ṣe Júù mú, wí pé, Àwa yóò ba ọ lọ, nítorí àwa tí gbọ́ pé, Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ
Ni awon ojo wonyi ni okunrin mewaa lati inu gbogbo ede ati orile-ede yoo di i mu, ani yoo di eti aso eni ti i se Juu mu, wi pe, Awa yoo ba o lo, nitori awa ti gbo pe, Olorun wa pelu re
  Ìdájọ́ Lórí Àwọn Ọ̀tá Ísírẹ́lì
  Idajo Lori Awon Ota Isireli
Ọ̀rọ̀ Olúwa kọjú ìjà sí Hádírákì, Dámásíkù ni yóò sì jẹ́ ibi ìṣinmi rẹ̀
Oro Oluwa koju ija si Hadiraki, Damasiku ni yoo si je ibi isinmi re
nítorí ojú Olúwa ń bẹ lára ènìyàn, àti lára gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì
nitori oju Oluwa n be lara eniyan, ati lara gbogbo eya Isireli
Àti Hámátì pẹ̀lú yóò ṣe ààlà rẹ̀ Tírè àti Sídónì bí o tilẹ̀ ṣe ọlọgbọ́n gidigidi
Ati Hamati pelu yoo se aala re Tire ati Sidoni bi o tile se ologbon gidigidi
Tírè sì mọ odi líle fún ara rẹ̀, ó sì kó fàdákà jọ bí èkuru, àti wúrà dáradára bí àfọ̀ ẹ̀rẹ̀ ìgboro
Tire si mo odi lile fun ara re, o si ko fadaka jo bi ekuru, ati wura daradara bi afo ere igboro
Ṣùgbọ́n, Olúwa yóò kó gbogbo ohun ìní rẹ̀ lọ, yóò sì pa agbára rẹ̀ run ní ojú òkun, a ó sì fi iná jó o run
Sugbon, Oluwa yoo ko gbogbo ohun ini re lo, yoo si pa agbara re run ni oju okun, a o si fi ina jo o run
Ásíkélónì yóò rí í, yóò sì bẹ̀rù
Asikeloni yoo ri i, yoo si beru
Gásà pẹ̀lú yóò rí í, yóò sì káànú gidigidi, àti Ékírónì
Gasa pelu yoo ri i, yoo si kaanu gidigidi, ati Ekironi
nítorí tí ìrètí rẹ̀ yóò sákì í
nitori ti ireti re yoo saki i
Gásà yóò pàdánu ọba rẹ̀, Ásíkélónì yóò sì di ahoro
Gasa yoo padanu oba re, Asikeloni yoo si di ahoro
Ọmọ àlè yóò sì gbé inú Ásídódì, Èmi yóò sì ge ìgbéraga àwọn Fílístínì kúrò
Omo ale yoo si gbe inu Asidodi, Emi yoo si ge igberaga awon Filistini kuro
Èmi yóò sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kúrò ni ẹnu rẹ̀, àti àwọn ohun èèwọ̀ kúrò láàrin eyín rẹ̀
Emi yoo si mu eje re kuro ni enu re, ati awon ohun eewo kuro laarin eyin re
ṣùgbọ́n àwọn tó sẹ́kù yóò jẹ́ tí Ọlọ́run wa, wọn yóò sì jẹ baálẹ̀ ní Júdà, àti Ékírónì ni yóò rí bí Jébúṣì
sugbon awon to seku yoo je ti Olorun wa, won yoo si je baale ni Juda, ati Ekironi ni yoo ri bi Jebusi
Èmi yóò sì dó yí ilẹ̀ mi ká nítorí ogun àwọn tí wọ́n ń wá ohun tí wọn yóò bàjẹ́ kiri, kò sí aninilára tí yóò là wọ́n já mọ́
Emi yoo si do yi ile mi ka nitori ogun awon ti won n wa ohun ti won yoo baje kiri, ko si aninilara ti yoo la won ja mo
nítorí ni ìṣinṣin yìí ni mo fi ojú ṣọ́ wọn
nitori ni isinsin yii ni mo fi oju so won
Ẹ kún fún ayọ̀, ẹ̀yin ọmọbìnrin Ṣíónì Ẹ hó ìhó ayọ̀, ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù
E kun fun ayo, eyin omobinrin Sioni E ho iho ayo, eyin omobinrin Jerusalemu
Ẹ wo ọba yín ń bọ̀ wá ṣọ́dọ̀ yín
E wo oba yin n bo wa sodo yin
òdodo ni òun, ó sì ní ìgbàlà
ododo ni oun, o si ni igbala
ó ní ìrẹ̀lẹ̀, ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́
o ni irele, o si n gun ketekete, ani omo ketekete
Èmi ó sì gbé kẹ̀kẹ́ kúrò ni Éfúráímù, àti ẹṣin ogun kúrò ni Jérúsálẹ́mù, a ó sì ṣẹ́ ọrun ogun
Emi o si gbe keke kuro ni Efuraimu, ati esin ogun kuro ni Jerusalemu, a o si se orun ogun
Òun yóò sì kéde àlàáfíà sí àwọn aláìkọlà
Oun yoo si kede alaafia si awon alaikola
Ìjọba rẹ̀ yóò sì gbilẹ̀ láti òkun dé òkun, àti láti odò títí de òpin ayé
Ijoba re yoo si gbile lati okun de okun, ati lati odo titi de opin aye
Ní tìrẹ, nítorí ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mu mi pẹ̀lú rẹ, Èmi ó dá àwọn ìgbèkùn rẹ̀ sílẹ̀ kúrò nínú ọ̀gbun
Ni tire, nitori eje majemu mi pelu re, Emi o da awon igbekun re sile kuro ninu ogbun
Ẹ padà sínú odi agbára yín, ẹ̀yin òǹdè ìrètí
E pada sinu odi agbara yin, eyin onde ireti
àní lónìí yìí èmi sọ pé, èmi o san án fún ọ ni ìlọ́poméjì
ani lonii yii emi so pe, emi o san an fun o ni ilopomeji
Èmi ó fa Júdà le bí mo ṣe fa ọrun mi le, mo sì fi Éfúráímù kún un, Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin dìde, ìwọ Ṣíónì, sí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ìwọ Gíríkì, mo ṣe ọ́ bí idà alágbára
Emi o fa Juda le bi mo se fa orun mi le, mo si fi Efuraimu kun un, Emi yoo gbe awon omo re okunrin dide, iwo Sioni, si awon omo re okunrin, iwo Giriki, mo se o bi ida alagbara
Olúwa yóò sì fí arahàn ní orí wọn Ọ̀kọ̀ rẹ̀ yóò tàn bí mọ̀nàmọ́ná
Oluwa yoo si fi arahan ni ori won Oko re yoo tan bi monamona
Olúwa ọ̀gá-ògo yóò sì fọn ìpè, Òun yóò sì lọ nínú atẹ́gùn ìjì gúṣù
Oluwa oga-ogo yoo si fon ipe, Oun yoo si lo ninu ategun iji gusu
Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bò wọ́n
Oluwa awon omo-ogun yoo daabo bo won
wọn ó sì jẹ ni run, wọn ó sì tẹ òkúta kànnà-kànnà mọ́lẹ̀
won o si je ni run, won o si te okuta kanna-kanna mole
wọn ó sì mu ẹ̀jẹ̀ wọn bí wáìnì, wọn ó sì kún bí ọpọ́n, wọn ó sì rin ṣinṣin bí àwọn igun pẹpẹ
won o si mu eje won bi waini, won o si kun bi opon, won o si rin sinsin bi awon igun pepe
Olúwa Ọlọ́run wọn yóò sì gbà wọ́n là ni ọjọ́ náà bí agbo ènìyàn rẹ̀
Oluwa Olorun won yoo si gba won la ni ojo naa bi agbo eniyan re
nítorí wọn ó dàbí àwọn òkúta adé, tí a gbé sókè bí àmì lórí ilẹ̀ rẹ̀
nitori won o dabi awon okuta ade, ti a gbe soke bi ami lori ile re
Nítorí oore rẹ̀ tí tóbi tó, ẹwà rẹ̀ ṣi tí pọ̀! Ọkà yóò mú ọ̀dọ́mọkùnrin dárayá, ati ọtí-wáìnì tuntun yóò mú àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú
Nitori oore re ti tobi to, ewa re si ti po! Oka yoo mu odomokunrin daraya, ati oti-waini tuntun yoo mu awon odomobinrin se bee pelu
Ìkìlọ̀ fún Ìparun tí ń bọ̀
Ikilo fun Iparun ti n bo
Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Sefanáyà ọmọ Kúsì, ọmọ Gédálíyà, ọmọ Ámáríyà, ọmọ Heṣekáyà, ní ìgbà Jósíà ọmọ Ámónì ọba Júdà
Oro Oluwa ti o to Sefanaya omo Kusi, omo Gedaliya, omo Amariya, omo Hesekaya, ni igba Josia omo Amoni oba Juda
Èmi yóò mú gbogbo nǹkan kúrò lórí ilẹ̀ náà pátapáta, ni Olúwa wí
Emi yoo mu gbogbo nnkan kuro lori ile naa patapata, ni Oluwa wi
Èmi yóò mú ènìyàn àti ẹranko kúrò
Emi yoo mu eniyan ati eranko kuro
èmi yóò mú àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run kúrò àti ẹja inú òkun, àti ohun ìdìgbòlù pẹ̀lú àwọn ènìyàn búburú
emi yoo mu awon eye oju orun kuro ati eja inu okun, ati ohun idigbolu pelu awon eniyan buburu
èmi yóò ké ènìyàn kúrò lórí ilẹ̀ ayé, ni Olúwa wí Èmi yóò na ọwọ́ mi sórí Júdà àti sórí gbogbo àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jérúsálẹ́mù
emi yoo ke eniyan kuro lori ile aye, ni Oluwa wi Emi yoo na owo mi sori Juda ati sori gbogbo awon eniyan ti n gbe ni Jerusalemu
Èmi yóò sì ké kúrò níhìn-ín-yìí ìyókù àwọn Báálì, àti orúkọ àwọn abọ̀rìṣà pẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà, àti àwọn tí wọn ń foríbalẹ̀ tí wọn ń sin ogun ọ̀run lórí òrùlé
Emi yoo si ke kuro nihin-in-yii iyoku awon Baali, ati oruko awon aborisa pelu awon alufaa aborisa, ati awon ti won n foribale ti won n sin ogun orun lori orule
Àwọn tí wọn ń sìn, tí wọ́n sì ń fi Olúwa búra, tí wọ́n sì ń fi Mólékì búra
Awon ti won n sin, ti won si n fi Oluwa bura, ti won si n fi Moleki bura
Àwọn tí ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa
Awon ti o yipada kuro lodo Oluwa
Àti àwọn tí kò tí wá Olúwa , bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì béèrè rẹ̀
Ati awon ti ko ti wa Oluwa , bee ni won ko si beere re
Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run, nítorí tí ọjọ́ Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀
E dake jee niwaju Oluwa Olorun, nitori ti ojo Oluwa ku si dede
Olúwa ti pèṣè ẹbọ kan sílẹ̀, ó sì ti ya àwọn alápèjẹ rẹ̀ sí mímọ́
Oluwa ti pese ebo kan sile, o si ti ya awon alapeje re si mimo
Ní ọjọ́ ẹbọ Olúwa , Èmi yóò bẹ àwọn olórí wò, àti àwọn ọmọ ọba ọkùnrin, pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó wọ àjèjì aṣọ
Ni ojo ebo Oluwa , Emi yoo be awon olori wo, ati awon omo oba okunrin, pelu gbogbo awon ti o wo ajeji aso
Ní ọjọ́ náà, èmi yóò fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí ó yẹra láti rìn lórí ìloro ẹnu ọ̀nà, tí wọ́n sì kún tẹ́ḿpìlì Olúwa wọn pẹ̀lú ìwà-ipá àti ẹ̀tàn
Ni ojo naa, emi yoo fi iya je gbogbo awon ti o yera lati rin lori iloro enu ona, ti won si kun tempili Oluwa won pelu iwa-ipa ati etan
Ní sì ṣe ní ọjọ́ náà, ni Olúwa wí, Ohùn ẹkún yóò wà láti ìhà Ibodè ẹja, híhu láti ìhà kejì wá àti ariwo ńlá láti òkè kékeré wá
Ni si se ni ojo naa, ni Oluwa wi, Ohun ekun yoo wa lati iha Ibode eja, hihu lati iha keji wa ati ariwo nla lati oke kekere wa
Hu, ẹ̀yin tí ń gbé ní agbègbè ọjà, gbogbo àwọn oníṣòwò rẹ̀ ni a ó mú kúrò, gbogbo àwọn ẹni tí ó ń ra fàdákà ni a ó sì parun
Hu, eyin ti n gbe ni agbegbe oja, gbogbo awon onisowo re ni a o mu kuro, gbogbo awon eni ti o n ra fadaka ni a o si parun
Ní àkókò wọ̀n-ọn-nì, èmi yóò wá Jérúsálẹ́mù kiri pẹ̀lú fìtílà, èmi ó sì fi ìyà jẹ àwọn tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn, tí wọn sì dàbí àwọn ènìyàn tí ó sinmi sínú gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ wọn, àwọn tí wọn sì ń wí ní ọkàn wọn pé, Olúwa kì yóò ṣe nǹkan kan tí ó jẹ́ rere tàbí tí ó jẹ́ búburú
Ni akoko won-on-ni, emi yoo wa Jerusalemu kiri pelu fitila, emi o si fi iya je awon ti ko ni itelorun, ti won si dabi awon eniyan ti o sinmi sinu gedegede won, awon ti won si n wi ni okan won pe, Oluwa ki yoo se nnkan kan ti o je rere tabi ti o je buburu
Nítorí náà, ọrọ̀ wọn yóò di ìkógún, àti ilé wọn yóò sì run
Nitori naa, oro won yoo di ikogun, ati ile won yoo si run
Àwọn yóò sì kọ́ ilé pẹ̀lú, ṣùgbọ́n wọn kì yóò gbé nínú ilé náà, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò mu ọtí Wáìnì láti inú rẹ̀
Awon yoo si ko ile pelu, sugbon won ki yoo gbe ninu ile naa, won yoo gbin ogba ajara, sugbon won ki yoo mu oti Waini lati inu re
Ọjọ́ ńlá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀, ó kù sí dẹ̀dẹ̀ ó sì ń yára bọ̀ kánkán
Ojo nla Oluwa ku si dede, o ku si dede o si n yara bo kankan
Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ohùn ẹkún àwọn alágbára ní ọjọ́ Olúwa yóò korò púpọ̀, ọjọ́ náà yóò jẹ́ ọjọ́ ìbínú, ọjọ́ ìrora àti ìpọ́njú, ọjọ́ òfò àti idà ọjọ́ ìdahoro ọjọ́ òkùnkùn àti ìtẹ̀ba, ọjọ́ kuru àti òkùnkùn biribiri, ọjọ́ òpè àti ìdágìrì àti ìdágiri sí àwọn ìlú olódì àti sí àwọn ìsá gíga Èmi yóò sì mú ìpọ́njú wá sórí ènìyàn, wọn yóò sì máa rìn gẹ́gẹ́ bí afọ́jú, nítorí àwọn ti dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa
E teti sile, ohun ekun awon alagbara ni ojo Oluwa yoo koro pupo, ojo naa yoo je ojo ibinu, ojo irora ati iponju, ojo ofo ati ida ojo idahoro ojo okunkun ati iteba, ojo kuru ati okunkun biribiri, ojo ope ati idagiri ati idagiri si awon ilu olodi ati si awon isa giga Emi yoo si mu iponju wa sori eniyan, won yoo si maa rin gege bi afoju, nitori awon ti dese si Oluwa
Ẹ̀jẹ̀ wọn ni a ó sì tú jáde bí eruku àti ẹran-ara wọn bí ìgbẹ́
Eje won ni a o si tu jade bi eruku ati eran-ara won bi igbe
Bẹ́ẹ̀ ni fàdákà tàbí wúrà wọn kì yóò sì le gbà wọ́n là ní ọjọ́ ìbínú Olúwa
Bee ni fadaka tabi wura won ki yoo si le gba won la ni ojo ibinu Oluwa
Ṣùgbọ́n gbogbo ayé ni a ó fi iná ìjowú rẹ̀ parun, nítorí òun yóò fi ìyára fi òpin sí gbogbo àwọn tí ń gbé ní ilé ayé
Sugbon gbogbo aye ni a o fi ina ijowu re parun, nitori oun yoo fi iyara fi opin si gbogbo awon ti n gbe ni ile aye
Ìlòdì Sí Fílísítíà
Ilodi Si Filisitia
Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, àní ẹ kó ra yín jọpọ̀ orílẹ̀ èdè tí kò ní ìtìjú, kí a tó lé yín kúrò bí èrò ìyàngbò ọkà, kí gbígbóná ìbínú Olúwa tó dé bá a yín, kí ọjọ́ ìbínú Olúwa kí ó tó dé bá a yín
E ko ara yin jo po, ani e ko ra yin jopo orile ede ti ko ni itiju, ki a to le yin kuro bi ero iyangbo oka, ki gbigbona ibinu Oluwa to de ba a yin, ki ojo ibinu Oluwa ki o to de ba a yin
Ẹ wá Olúwa , gbogbo ẹ̀yin onírẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ náà, ẹ̀yin tí ń ṣe ohun tí ó bá pa láṣẹ
E wa Oluwa , gbogbo eyin onirele ile naa, eyin ti n se ohun ti o ba pa lase
Ẹ wá òdodo, ẹ wá ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú, bóyá á ó pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Olúwa
E wa ododo, e wa irele pelu, boya a o pa yin mo ni ojo ibinu Oluwa
Nítorí pé, a ó kọ Gásà sílẹ̀, Áṣíkélónì yóò sì dahoro
Nitori pe, a o ko Gasa sile, Asikeloni yoo si dahoro
Ní ọ̀sán gangan ni a ó lé Áṣídódù jáde, a ó sì fa Ékírónì tu kúrò
Ni osan gangan ni a o le Asidodu jade, a o si fa Ekironi tu kuro
Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ń gbé etí òkun, ẹ̀yin ènìyàn ara Kérétì
Egbe ni fun eyin ti n gbe eti okun, eyin eniyan ara Kereti
Ọ̀rọ̀ Olúwa dojúkọ ọ́, ìwọ Kénánì, ilẹ̀ àwọn ara Fílísítíà
Oro Oluwa dojuko o, iwo Kenani, ile awon ara Filisitia
Èmi yóò pa yín run, ẹnìkan kò sì ní ṣẹ́kù nínú yín
Emi yoo pa yin run, enikan ko si ni seku ninu yin
Ilẹ̀ náà ní etí òkun, ni ibùgbé àwọn ará Kérétì, ni yóò jẹ́ ibùjókòó fún àwọn olùṣọ́-àgùntàn àti agbo àgùntàn
Ile naa ni eti okun, ni ibugbe awon ara Kereti, ni yoo je ibujokoo fun awon oluso-aguntan ati agbo aguntan
Agbègbè náà yóò sì jẹ́ ti ìyókù àwọn ilé Júdà, níbẹ̀ ni wọn yóò sì ti rí ìjẹ fún ẹran, Ní ilé Áṣíkélónì ni wọn yóò dùbúlẹ̀ ni àṣálẹ́
Agbegbe naa yoo si je ti iyoku awon ile Juda, nibe ni won yoo si ti ri ije fun eran, Ni ile Asikeloni ni won yoo dubule ni asale
Olúwa Ọlọ́run wọn yóò bojútó wọn, yóò sì yí ìgbékùn wọn padà
Oluwa Olorun won yoo bojuto won, yoo si yi igbekun won pada
Èmi ti gbọ́ ẹ̀gàn Móábù, àti ẹlẹ́yà àwọn Ámónì, àwọn tó kẹ́gàn àwọn ènìyàn mi, tí wọ́n sì ti gbé ara wọn ga sí agbègbè wọn
Emi ti gbo egan Moabu, ati eleya awon Amoni, awon to kegan awon eniyan mi, ti won si ti gbe ara won ga si agbegbe won
Nítorí náà, bí Èmi tí wà, ni Olúwa Sódómù wí, Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì, Ní tòótọ́ Móábù yóò dàbí Sódómù àti Ámónì yóò sì dàbí Gòmórà, ibi tí ó kún fún yèrèpè àti ihó iyọ̀ àti ìdahoro títí láéláé
Nitori naa, bi Emi ti wa, ni Oluwa Sodomu wi, Olorun awon Isireli, Ni tooto Moabu yoo dabi Sodomu ati Amoni yoo si dabi Gomora, ibi ti o kun fun yerepe ati iho iyo ati idahoro titi laelae
Ìyòókù àwọn ènìyàn mi yóò kó wọn
Iyooku awon eniyan mi yoo ko won
àwọn tí ó sì yọ nínú ewu ní orílẹ̀-èdè mi ni yóò jogún ilẹ̀ wọn
awon ti o si yo ninu ewu ni orile-ede mi ni yoo jogun ile won
Èyí ni ohun tí wọn yóò gbà padà nítorí ìgbéraga wọn, nítorí wọ́n kẹ́gàn, wọn sì ti fi àwọn ènìyàn Olúwa alágbára ṣe ẹlẹ́yà
Eyi ni ohun ti won yoo gba pada nitori igberaga won, nitori won kegan, won si ti fi awon eniyan Oluwa alagbara se eleya
Olúwa yóò jẹ́ ìbẹ̀rù fún wọn
Oluwa yoo je iberu fun won
nígbà tí Òun bá pa gbogbo òrìṣa ilẹ̀ náà run
nigba ti Oun ba pa gbogbo orisa ile naa run
Orílẹ̀-èdè láti etí odò yóò máa sìn, olúkúlùkù láti ilẹ̀ rẹ̀ wá
Orile-ede lati eti odo yoo maa sin, olukuluku lati ile re wa
Ẹ̀yin Etiópíà pẹ̀lú, a ó fi idà mi pa yín
Eyin Etiopia pelu, a o fi ida mi pa yin
Òun yóò sì na ọwọ́ rẹ̀ sí apá àríwá, yóò sì pa Ásíríà run, yóò sì sọ Nínéfè di ahoro, àti di gbígbẹ bí ihà
Oun yoo si na owo re si apa ariwa, yoo si pa Asiria run, yoo si so Ninefe di ahoro, ati di gbigbe bi iha
Agbo ẹran yóò sì dùbúlẹ̀ ṣíbẹ̀ àti gbogbo ẹ̀dá ní orísìírísìí
Agbo eran yoo si dubule sibe ati gbogbo eda ni orisiirisii
Òwìwí ihà àti dídún bí ẹyẹ òwìwí yóò wọ bí ẹyẹ ni ọwọ́n rẹ̀
Owiwi iha ati didun bi eye owiwi yoo wo bi eye ni owon re
Ohùn wọn yóò kọrin ni ojú fèrèsé, ìdahoro yóò wà nínú ìloro ẹnu ọ̀nà, òun yóò sì ṣẹ́ kédárì sílẹ̀
Ohun won yoo korin ni oju ferese, idahoro yoo wa ninu iloro enu ona, oun yoo si se kedari sile
Èyí ni ìlú aláyọ̀ tí ó ń gbé láìléwu
Eyi ni ilu alayo ti o n gbe lailewu
Ó sì sọ sí ara rẹ̀ pé, Èmi ni, kò sì sí ẹnìkan tí ó ń bẹ lẹ́yìn mi
O si so si ara re pe, Emi ni, ko si si enikan ti o n be leyin mi
Irú ahoro wo ni òun ha ti jẹ́, ibùgbé fún àwọn ẹranko igbó! Gbogbo ẹni tí ó bá kọjá ọ̀dọ̀ rẹ̀ yóò fi rẹ́rìnín ẹlẹ́yà, wọ́n yóò sì gbọn ẹsẹ̀ wọn
Iru ahoro wo ni oun ha ti je, ibugbe fun awon eranko igbo! Gbogbo eni ti o ba koja odo re yoo fi rerinin eleya, won yoo si gbon ese won
Ọjọ́ Ìwájú Jérúsálẹ́mù
Ojo Iwaju Jerusalemu
Ègbé ni fún ìlú aninilára, ọlọ̀tẹ̀ àti aláìmọ́
Egbe ni fun ilu aninilara, olote ati alaimo